ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 April ojú ìwé 4-5
  • Báwo Lo Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • B12-A Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú (Apá Kìíní)
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • B12-B Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú (Apá Kejì)
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà Tó Wà fún Ìrántí Ikú Kristi ti Ọdún 2023
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà Tó Wà fún Ìrántí Ikú Kristi Ti Ọdún 2022
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 April ojú ìwé 4-5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Báwo Lo Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún yìí, a máa túbọ̀ ráyè múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí àárín ọ̀sẹ̀, a ò ní ṣe Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní ọ̀sẹ̀ yẹn. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí òpin ọ̀sẹ̀, a ò ní ṣe ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀, ìyẹn àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ṣé wàá fi àsìkò tó ṣí sílẹ̀ yìí ṣe àwọn nǹkan tó yẹ? Bíi ti àwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètò kan láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. (Lk 22:​7-13; km 3/15 1) Àmọ́, ó tún yẹ kí gbogbo wa múra ọkàn wa sílẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Ronú lórí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o wà níbẹ̀.​—1Kọ 11:​23-26

  • Ronú lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà tàdúràtàdúrà.​—1Kọ 11:​27-29; 2Kọ 13:5

  • Ka àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ronú lé wọn lórí.​—Jo 3:16; 15:13

Àwọn akéde kan máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n sì máa ń ronú lé e lórí, èyí tó máa ń wà nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Àwọn míì máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àtẹ tó wà ní ìsàlẹ̀ yìí. Àwọn kan máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi àti ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní sí wa. Ètò èyíkéyìí tíwọ náà bá ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i, àdúrà wa ni pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.

Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú (Apá 1 àti 2)
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́