ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 12-13
Ìbáwí Máa Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
Ohun tí ìbáwí túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n na ẹnì kan, kí wọ́n fún un ní ìtọ́ni tàbí kí wọ́n kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe máa bá ọmọ rẹ̀ wí, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń bá wa wí. Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà máa ń gbà bá wa wí, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ . . .
Tá a bá ń kà Bíbélì, tá à ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá à ń lọ sípàdé, tá a sì ń ṣàṣàrò
Tí Kristẹni míì bá bá wa wí
Tá a bá ń jìyà àbájáde àṣìṣe wa
Tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ bá bá ẹnì kan wí tàbí tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́
Nígbà tó bá fàyè gba àdánwò tàbí inúnibíni—w15 9/15 21 ¶13; it-1 629