MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ló Ń Mú Ká Fara Mọ́ Ìbáwí Jèhófà
Ìyọlẹ́gbẹ́ máa ń dáàbò bo ìjọ, ó tún jẹ́ ìbáwí fún ẹni tí kò ronú pìwà dà. (1Kọ 5:6, 11) Tá a bá sì fara mọ́ ìbáwí yìí látọ̀dọ̀ Jèhófà, ṣe là ń fìfẹ́ hàn. Àmọ́ ṣé a gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́, torí kì í rọrùn tí wọ́n bá yọ èèyàn wa kan lẹ́gbẹ́. Ó máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí ẹni yẹn àtàwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó bójú tó ọ̀rọ̀ náà?
Ohun àkọ́kọ́ ni pé tá a bá fara mọ́ ìbáwí Jèhófà, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rè, a sì bọ̀wọ̀ fún ìlànà rẹ̀ lórí ìwà mímọ́. (1Pe 1:14-16) Ìyẹn á sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà. Ìbáwí kì í ṣe ohun ayọ̀, àmọ́ ó máa ń “so èso àlàáfíà ti òdodo.” (Heb 12:5, 6, 11) Tá a bá ṣì ń ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ tàbí ẹni tó mú ara ẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́, a ò fi hàn pé a fara mọ́ ìbáwí Jèhófà. Ká má gbàgbé pé Jèhófà kì í bá àwa èèyàn rẹ̀ wí “kọjá ààlà.” (Jer 30:11) Tá a bá fara mọ́ ìbáwí Jèhófà, tá a sì gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ẹni náà máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Baba wa aláàánú.—Ais 1:16-18; 55:7.
WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÓ O ṢE Ń FI ỌKÀN KAN SIN JÈHÓFÀ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn òbí tí ọmọ wọn bá fi Jèhófà sílẹ̀?
Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn tó wà nínú ìdílé náà lọ́wọ́?
Àpẹẹrẹ wo la rí látinú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà pọ̀ ju ti àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà la jẹ́ adúróṣinṣin sí dípò àwọn mọ̀lẹ́bí wa?