MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Túbọ̀ Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Rẹ
Káfíńtà tó bá mọṣẹ́ dáadáa gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe máa lo gbogbo irinṣẹ́ ẹ̀ lámọ̀dunjú. Lọ́nà kan náà, ẹni tó bá jẹ́ “òṣìṣẹ́ tí kò ní ohunkóhun tó máa tì í lójú” gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe ń lo àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. (2Ti 2:15) Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo mọ bó ṣe yẹ kó o lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lámọ̀dunjú.
TẸ́TÍ SÍ ỌLỌ́RUN KÓ O LÈ WÀ LÁÀYÈ TÍTÍ LÁÉ
Àwọn wo la dìídì ṣe ìwé yìí fún?—mwb17.03 5 ¶1-2
Báwo lo ṣe lè fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—km 7/12 3 ¶6
Ìtẹ̀jáde míì wo lo lè lò kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó lè ṣèrìbọmi? —km 7/12 3 ¶7
ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!
Kí ló mú kí ìwé yìí yàtọ̀ sáwọn ìwé míì tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—km 3/13 4-5 ¶3-5
Kí ló yẹ kó o ṣe nígbà tó o bá fún ẹnì kan ní ìwé yìí?—km 9/15 3 ¶1
Báwo lo ṣe lè fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—mwb16.01 8
Ìgbà wo ló yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? —km 3/13 7 ¶10
KÍ NI BÍBÉLÌ KỌ́ WA?
Báwo la ṣe lè lo àwọn àtúnyẹ̀wò àti àfikún àlàyé tó wà nínú ìwé yìí? —mwb16.11 5 ¶2-3
ÀWỌN WO LÓ Ń ṢE ÌFẸ́ JÈHÓFÀ LÓDE ÒNÍ?
Ìgbà wo ló yẹ kó o lo ìwé yìí?—mwb17.03 8 ¶1
Báwo lo ṣe lè lò ó?—mwb17.03 8, àpótí