ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 44-45
Jósẹ́fù Dárí Ji Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀
Kì í rọrùn láti dárí jini, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìkà sí wa. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti dárí ji àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nígbà tí wọ́n hùwà ìkà sí i?
Dípò kí Jósẹ́fù gbẹ̀san, ṣe ló sapá láti dárí jì wọ́n.—Sm 86:5; Lk 17:3, 4
Dípò kí Jósẹ́fù di àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ sínú, ṣe ló fara wé Jèhófà tó máa ń dárí jini látọkàn wá.—Mik 7:18, 19
Báwo ni mo ṣe lè máa dárí jini bíi ti Jèhófà?