ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 19-20
Ẹ̀kọ́ Tí Òfin Mẹ́wàá Náà Kọ́ Wa Lónìí
Àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Kol 2:13, 14) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àǹfààní wo ni Òfin Mẹ́wàá náà àtàwọn Òfin tó kù ń ṣe wá lónìí?
Ó jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ kan
Ó jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè múnú Jèhófà dùn
Ó jẹ́ ká mọ ìwà tó yẹ ká máa hù sáwọn míì
Kí ni Òfin Mẹ́wàá náà kọ́ ẹ nípa Jèhófà?