ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 23-24
Má Ṣe Tẹ̀ Lé Ọ̀pọ̀ Èèyàn
Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn adájọ́ tàbí ẹnikẹ́ni tó bá wá jẹ́rìí pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mú kí wọ́n jẹ́rìí èké tàbí kí wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre. Àwa náà lè lo ìlànà yìí nínú àwọn nǹkan tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa. Ayé yìí ń wá bí wọ́n á ṣe mú káwa Kristẹni máa ronú lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Jèhófà mu.—Ro 12:2.
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tá a bá
gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn tá ò sì mọ̀ bóyá òótọ́ ni?
fẹ́ yan irú aṣọ tá a máa wọ̀, irun tá a máa ṣe tàbí eré ìnàjú tá a máa wò?
ń ronú nípa ojú tá a fi ń wo àwọn tí kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ wa, àwọn tálákà tàbí àwọn olówó?