ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 35-36
Jèhófà Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀
Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ran Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣètò àwọn nǹkan tó máa wà nínú àgọ́ ìjọsìn. (Wo àwòrán iwájú ìwé.) Jèhófà lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lónìí. Àmọ́, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè rí i gbà?
A gbọ́dọ̀ máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ká lè ṣe ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ dáadáa
A gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé
A gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún wa
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe?