ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jèhófà Sọ Ègún Di Ìbùkún
Àwọn ọmọ Móábù ń wá bí wọ́n ṣe máa hùwà ìkà sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Nọ 22:3-6)
Jèhófà gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ (Nọ 22:12, 34, 35; 23:11, 12)
Kò sẹ́ni tó lè gbéjà ko Jèhófà kó sì ṣàṣeyọrí (Nọ 24:12, 13; bt 53 ¶5; it-2 291)
Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká wàásù ìhìn rere, kò sì sí ohunkóhun tó lè dí i lọ́wọ́, títí kan inúnibíni tàbí àjálù. Ṣé a máa ń gbára lé Baba wa ọ̀run, tá a sì ń fi ìjọsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́, kódà nígbà tí nǹkan ò bá rọrùn fún wa?