ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 May ojú ìwé 5
  • Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Lo Ìbéèrè
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 May ojú ìwé 5
Ìyá kan àti ọmọbìnrin ẹ̀ ń gbọ́ ohun tí Jésù ń sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè, wọ́n sì ń wo àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó.

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì

Tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn lóye àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ohun tá à ń kọ́ wọn. Tá a bá fi àpèjúwe ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì yìí, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń kọ́, wọn ò sì ní tètè gbàgbé.

Tó o bá ń múra ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀, wá àwọn kókó pàtàkì tó o lè fi àpèjúwe ṣàlàyé. Má ronú jù lórí àwọn kókó tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan. Wá àwọn àpèjúwe tó máa rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti lóye. (Mt 5:14-16; Mk 2:21; Lk 14:7-11) Ronú nípa irú ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, iṣẹ́ tó ń ṣe àtàwọn nǹkan míì nípa ẹni náà. (Lk 5:2-11; Jo 4:7-15) Tó o bá rí bínú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe dùn torí pé ó lóye kókó pàtàkì kan, ó dájú pé inú tìẹ náà máa dùn.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀​—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ​—MÁA FI ÀPÈJÚWE ṢÀLÀYÉ KÓKÓ PÀTÀKÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì.’ Jade ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Neeta.

    Kí ló lè mú kó nira fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì kan?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì.’ Neeta ń sọ àpèjúwe kan fún Jade.

    Àpèjúwe wo ni Neeta fi ṣàlàyé Róòmù 5:12?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì.’ Neeta ń fi fídíò kan han Jade.

    Àpèjúwe tó dáa máa ń wọni lọ́kàn

    Báwo ni àpèjúwe tó dáa ṣe lè ràn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́?

  • Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo fídíò àtàwọn ohun èlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ míì tí ètò Ọlọ́run ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́