ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jẹ́ Kí Jèhófà Fi “Ọwọ́ Ayérayé” Rẹ̀ Dáàbò Bò Ẹ́
Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin (Di 33:26; it-2 51)
Ó máa ń wù ú láti lo agbára rẹ̀ nítorí wa (Di 33:27; rr 120, àpótí)
Bíi ti Mósè, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa gbà wá là (Di 33:29; w11 9/15 19 ¶16)
Jèhófà máa ń fi ọwọ́ ayérayé rẹ̀ dáàbò bò wá tá a bá wà nínú ìṣòro. Bóyá nígbà tá à ń ṣàìsàn, tá a sorí kọ́, tá à ń ṣọ̀fọ̀ tàbí nígbà tá a ṣàṣìṣe àmọ́ tá a ronú pìwà dà.