MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Jẹ́ Káwọn Míì Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Jèhófà máa ń lo àwọn “ará” wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti fún wa lókun. (1Pe 5:9) Wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, lára wọn ni Ákúílà àti Pírísílà, Sílà, Tímótì àtàwọn míì.—Iṣe 18:1-5.
Báwo làwọn míì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Wọ́n lè fún wa nímọ̀ràn lórí bá a ṣe lè fèsì tẹ́nì kan bá ta ko ọ̀rọ̀ wa, bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò àti bá a ṣe lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ronú nípa ẹnì kan nínú ìjọ yín tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó dájú pé ẹ̀yin méjèèjì ló máa ṣe láǹfààní, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ láyọ̀.—Flp 1:25.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—MÁA LO ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ PÈSÈ—ÀWỌN ARÁ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn nǹkan wo ni Neeta ṣe kó lè pe Jade wá sípàdé?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mú àwọn míì lọ sọ́dọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?
Gbogbo ìjọ ló ń sọ ẹnì kan di ọmọ ẹ̀yìn
Kí ló fa Jade mọ́ra nípa Arábìnrin Abigay?
Àwọn nǹkan wo lo lè kọ́ lára àwọn míì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?