MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo Làwọn Arábìnrin Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà?
Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn arábìnrin wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sm 68:11) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ló ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ jù, àwọn ló pọ̀ jù lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, míṣọ́nnárì, iṣẹ́ ìkọ́lé àti iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa ń gbé ìdílé wọn ró, wọ́n sì ń fún ìjọ lókun. (Owe 14:1) Òótọ́ ni pé àwọn arábìnrin ò láǹfààní láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè ṣe láti ran ìjọ lọ́wọ́. Tó o bá jẹ́ arábìnrin, báwo lo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
Máa ṣèrànwọ́ fáwọn arábìnrin tí ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí.—Tit 2:3-5
Máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i
Kọ́ èdè míì
Lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i
Sapá láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí láti yọ̀nda ara rẹ níbi tá a ti ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn
Sapá kó o lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “ÀWỌN OBÌNRIN TÓ Ń ṢIṢẸ́ KÁRA NÍNÚ OLÚWA,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí lo rí kọ́ látinú ohun táwọn arábìnrin yìí sọ?