ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Fi Ọgbọ́n Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́
Sólómọ́nì ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu ní ti pé ó fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ abọ̀rìṣà (1Ọb 11:1, 2; w18.07 18 ¶7)
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó Sólómọ́nì yí i lọ́kàn pa dà, kò sì sin Jèhófà mọ́ (1Ọb 11:3-6; w19.01 15 ¶6)
Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì (1Ọb 11:9, 10; w18.07 19 ¶9)
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn Kristẹni tí kò tíì ní ọkọ tàbí aya níyànjú pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1Kọ 7:39) Síbẹ̀, ti pé ẹnì kan ti ṣèrìbọmi kò túmọ̀ sí pé ẹni náà máa jẹ́ ọkọ tàbí aya rere. Bi ara ẹ pé, Ṣé ẹni yìí máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa sin Jèhófà tọkàntọkàn? Ṣé ẹni náà ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú? Rí i dájú pé ó fara balẹ̀ mọ ẹnì kan dáadáa kó o tó pinnu pé ẹni náà lo máa fẹ́.