ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ìtẹ́lọ́rùn, Ká sì Mọ̀wọ̀n Ara Wa?
Wólìí Ọlọ́run kan kọ̀ láti gba àwọn ẹ̀bùn iyebíye tí Jèróbóámù fẹ́ fún un (1Ọb 13:7-10; w08 8/15 8 ¶4)
Nígbà tó yá, wòlíì Ọlọ́run yìí ṣàìgbọràn sí àṣẹ Jèhófà (1Ọb 13:14-19; w08 8/15 11 ¶15)
Wòlíì náà pàdánù ẹ̀mí ẹ̀ torí pé ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà (1Ọb 13:20-22; w08 8/15 9 ¶10)
Tá a bá jẹ́ kí ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, tá a sì ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà ká tó ṣèpinnu, a ò ní tọrùn bọ ọ̀pọ̀ ìṣòro.—1Ti 6:8-10.
BI ARA RẸ PÉ: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé àwọn nǹkan tí mo ní tẹ́ mi lọ́rùn? Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo mọ̀wọ̀n ara mi tí mo bá fẹ́ ṣèpinnu?’—Owe 3:5; 11:2.