ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Gbé Ọmọ Rẹ”
Obìnrin ará Ṣúnémù náà tọ́jú Èlíṣà dáadáa (2Ọb 4:8-10)
Jèhófà jẹ́ kó bí ọmọkùnrin kan (2Ọb 4:16, 17; w17.12 4 ¶7)
Jèhófà lo Èlíṣà láti jí ọmọ obìnrin náà dìde (2Ọb 4:32-37; w17.12 5 ¶8)
Ṣé ò ń ṣọ̀fọ̀ torí ikú ọmọ rẹ? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ bí ẹ̀dùn ọkàn ẹ ṣe pọ̀ tó. Láìpẹ́, ó máa jí gbogbo àwọn èèyàn ẹ tó ti kú dìde. (Job 14:14, 15) Kò sí àní-àní pé ọjọ́ lọjọ́ náà á jẹ́!