ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ṣé Èèyàn Wúlò fún Ọlọ́run?”
Élífásì sọ pé a ò wúlò lójú Ọlọ́run (Job 22:1, 2; w05 9/15 26 ¶6–27 ¶2)
Élífásì sọ pé téèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ olódodo, kò sí èyí tó kan Ọlọ́run níbẹ̀ (Job 22:3; w95 2/15 27 ¶6)
Tá a bá ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn, àá jẹ́ kó lè fún Sátánì tó ń pẹ̀gàn rẹ̀ lésì (Owe 27:11; w03 4/15 14-15 ¶10-12)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ̀ pé o wúlò lójú Ọlọ́run Olódùmarè?