MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Múnú Jèhófà Dùn
Àwọn ọmọdé ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. (1Sa 2:26; Lk 2:52) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì kéré, wọ́n lè múnú Jèhófà dùn tí wọ́n bá ń hùwà tó dáa. (Owe 27:11) Jèhófà ti lo ètò rẹ̀ láti pèsè onírúurú nǹkan táwọn òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́—ÌFARADÀ YÍN Ń MÚNÚ JÈHÓFÀ DÙN! KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti pèsè láwọn ọdún tó ti kọjá láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́, kó sì tọ́ wọn sọ́nà?
Àwọn nǹkan wo làwọn òbí lè lò lákòókò yìí láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́?
Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè tó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?