Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Ṣé ó wù ẹ́ kí ogun àti rògbòdìyàn di ohun ìgbàgbé láyé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wù kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n gbà pé àlá tí kò lè ṣẹ ni. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn ò fi lè fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn. Ó tún jẹ́ kó dá wa lójú pé àlàáfíà máa wà níbi gbogbo kárí ayé, kódà kò ní pẹ́ mọ́.
Nínú ìwé yìí, tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà “ogunʺ àti “rògbòdìyàn,ʺ à ń tọ́ka sí ìjà láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń lo ohun ìjà láti gbógun ti ara wọn. A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ìwé yìí.