ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21
ORIN 21 Ẹ Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́
Ẹ Máa Wá Ìlú Tó Máa Wà Títí Láé
“À ń fi gbogbo ọkàn wá [ìlú] tó ń bọ̀.”—HÉB. 13:14.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ bí Hébérù orí 13 ṣe lè ṣe wá láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.
1. Kí ni Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù?
NÍ ỌJỌ́ mélòó kan ṣáájú ikú Jésù Kristi, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹ nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Ó kìlọ̀ pé ọjọ́ ń bọ̀ tí ‘àwọn ọmọ ogun máa pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká.’ (Lúùkù 21:20) Jésù wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé tí wọ́n bá ti rí àwọn ọmọ ogun Róòmù, kí wọ́n fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Lúùkù 21:21, 22.
2. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará ní Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù?
2 Ní ọdún mélòó kan kí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó yí Jerúsálẹ́mù ká, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ará ní Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀ de ìṣòro tó ń bọ̀. Lẹ́tà náà là ń pè ní ìwé Hébérù báyìí. Ìṣòro wo ló ń bọ̀? Ìlú Jerúsálẹ́mù máa pa run. Àmọ́ táwọn Kristẹni yẹn ò bá fẹ́ bá ogun náà lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fi ilé àti iṣẹ́ tó ń mówó wọlé fún wọn sílẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìlú Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: “A ò ní ìlú kan níbí tó ṣì máa wà.” Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Àmọ́ à ń fi gbogbo ọkàn wá èyí tó ń bọ̀.”—Héb. 13:14.
3. Kí ni “ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́,” kí sì nìdí tá a fi ń wá a?
3 Nígbà táwọn Kristẹni kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n sì pẹ̀gàn wọn, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe yẹn ló gbẹ̀mí wọn là. Bákan náà lónìí, wọ́n máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé a ò gbẹ́kẹ̀ lé àwọn èèyàn, a ò sì lépa bá a ṣe máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Kí nìdí tá a fi ṣerú ìpinnu yẹn? Ìdí ni pé a mọ̀ pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ kógbá sílé. À ń wá “ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́,” ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run “tó ń bọ̀.”a (Héb. 11:10; Mát. 6:33) Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan nínú àpilẹ̀kọ yìí máa sọ̀rọ̀ nípa: (1) bí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá “[ìlú] tó ń bọ̀,” (2) bí Pọ́ọ̀lù ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti (3) bí ìmọ̀ràn yẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí.
GBẸ́KẸ̀ LÉ ẸNI TÍ Ò NÍ FI Ẹ́ SÍLẸ̀ LÁÉ
4. Kí nìdí tí ìlú Jerúsálẹ́mù fi ṣe pàtàkì lójú àwọn Kristẹni?
4 Ìlú Jerúsálẹ́mù ṣe pàtàkì gan-an lójú àwọn Kristẹni torí ibẹ̀ ni wọ́n ti dá ìjọ Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dún 33 S.K, ibẹ̀ sì ni ìgbìmọ̀ olùdarí wà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni kọ́lé sílùú yẹn, wọ́n sì ní ohun ìní rẹpẹtẹ níbẹ̀. Síbẹ̀, Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti agbègbè Jùdíà.—Mát. 24:16.
5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe múra àwọn Kristẹni sílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀?
5 Kí àwọn Kristẹni lè múra sílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀, Pọ́ọ̀lù rán wọn létí ojú tí Jèhófà fi ń wo ìlú Jerúsálẹ́mù. Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà àtàwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù mọ́. (Héb. 8:13) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé ìlú Jerúsálẹ́mù ni ò gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Torí náà, wọ́n máa pa tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù run, àwọn èèyàn ò sì ní jọ́sìn Jèhófà níbẹ̀ mọ́.—Lúùkù 13:34, 35.
6. Kí nìdí táwọn Kristẹni fi nílò ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n ní Hébérù 13:5, 6?
6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Hébérù, nǹkan ń lọ dáadáa nílùú Jerúsálẹ́mù. Òǹkọ̀wé ará Róòmù kan tó gbé ayé lásìkò yẹn sọ pé Jerúsálẹ́mù ni “ìlú tó gbajúmọ̀ jù lọ ní apá Ìlà Oòrùn.” Ọ̀pọ̀ àwọn Júù láti ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń wá síbẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún láti ṣe àjọyọ̀, ìyẹn jẹ́ kí ọrọ̀ ajé ìlú yẹn dáa sí i. Torí náà, ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni kan nílùú Jerúsálẹ́mù rí towó ṣe. Ó lè jẹ́ ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún wọn pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.” Ó wá fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Ìwé Mímọ́ níbi tí Jèhófà ti fi dá wọn lójú pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Ka Hébérù 13:5, 6; Diu. 31:6; Sm. 118:6) Àwọn ará Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà máa nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé lẹ́yìn tí wọ́n bá gba lẹ́tà tó kọ sí wọn, ó máa gba pé kí wọ́n fi ilé wọn, iṣẹ́ tó ń mówó wọlé àti ọ̀pọ̀ lára nǹkan ìní wọn sílẹ̀. Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tuntun níbòmíì, ìyẹn ò sì ní rọrùn.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe nǹkan tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà báyìí?
7 Ohun tá a kọ́: Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? “Ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀, òun ló sì máa fòpin sí ayé burúkú Sátánì yìí. (Mát. 24:21) A gbọ́dọ̀ wà lójúfò bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ká sì múra sílẹ̀. (Lúùkù 21:34-36) Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó lè gba pé káwa náà fi lára ohun ìní wa tàbí gbogbo ẹ̀ sílẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Kó tó dìgbà yẹn, ó yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Torí náà bi ara ẹ pé, ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe báyìí ò fi hàn pé ọrọ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, dípò kí n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tó ṣèlérí pé òun máa bójú tó mi?’ (1 Tím. 6:17) Òótọ́ ni pé tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, á ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ nígbà “ìpọ́njú ńlá,” àmọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sáwa Kristẹni nígbà yẹn máa nira gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Torí náà, tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo la ṣe máa mọ ohun tá a máa ṣe?
MÁA ṢÈGBỌRÀN SÁWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ
8. Kí ni Jésù sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe?
8 Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn táwọn Hébérù gba lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn, àwọn Kristẹni yẹn rí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó yí ìlú Jerúsálẹ́mù ká. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé àkókò ti tó láti sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù torí pé wọ́n máa pa ìlú náà run. (Mát. 24:3; Lúùkù 21:20, 24) Àmọ́ ibo ni wọ́n máa sá lọ? Jésù ò dárúkọ òkè tí wọ́n máa sá lọ gangan, ó kàn sọ pé: “Kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” (Lúùkù 21:21) Torí pé òkè pọ̀ gan-an lágbègbè Jùdíà, èwo nínú ẹ̀ ni wọ́n máa sá lọ báyìí?
9. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn Kristẹni yẹn láti mọ òkè tí wọ́n máa sá lọ? (Tún wo àwòrán ilẹ̀.)
9 Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn òkè táwọn Kristẹni yẹn lè sá lọ yẹ̀ wò. Àwọn òkè náà ni àwọn òkè Samáríà, Gálílì, Òkè Hámónì, àwọn òkè Lẹ́bánónì àtàwọn òkè tó wà ní ìsọdá Odò Jọ́dánì. (Wo àwòrán ilẹ̀.) Àwọn ìlú kan wà lágbègbè àwọn òkè náà, ó sì lè dà bíi pé tí wọ́n bá sá lọ síbẹ̀, wọ́n máa rí ààbò. Bí àpẹẹrẹ, ìlú Gamla wà ní orí òkè gbágungbàgun kan tó ga, ibẹ̀ ò sì rọrùn láti dé. Àwọn Júù kan gbà pé táwọn bá sá lọ síbẹ̀, nǹkan kan ò ní ṣe àwọn. Àmọ́ àwọn ará Róòmù gbógun ja ìlú náà, wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn àti ìlú náà run.b
Òkè pọ̀ lágbègbè Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù táwọn Kristẹni lè sá lọ, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló léwu (Wo ìpínrọ̀ 9)
10-11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà? (Hébérù 13:7, 17) (b) Ìbùkún wo làwọn Kristẹni yẹn rí torí wọ́n ṣègbọràn sáwọn tó ń ṣàbójútó? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Àwọn alábòójútó nínú ìjọ ni Jèhófà lò láti tọ́ àwọn Kristẹni yẹn sọ́nà kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Eusebius sọ pé: “Ọlọ́run fi ìran kan han àwọn ọkùnrin tó ń ṣàbójútó nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù pé kí àwọn ará sá lọ sílùú Pẹ́là ní agbègbè Pèríà kí ogun tó bẹ̀rẹ̀.” Ibi tó sì yẹ kí wọ́n sá lọ gan-an nìyẹn. Torí pé ibẹ̀ ò jìnnà sílùú Jerúsálẹ́mù, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n tètè débẹ̀. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ìlú náà kì í ṣe Júù, torí náà wọn kì í bá àwọn ará Róòmù jà.—Wo àwòrán ilẹ̀.
11 Àwọn Kristẹni tó sá lọ sórí òkè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé kí wọ́n “máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú” nínú ìjọ. (Ka Hébérù 13:7, 17.) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn gba ẹ̀mí wọn là. Torí pé wọ́n “ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́,” ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, Jèhófà ò fi wọ́n sílẹ̀.—Héb. 11:10.
Ìlú Pẹ́là táwọn Kristẹni yẹn sá lọ wà nítòsí, kò sì séwu níbẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10-11)
12-13. Báwo ni Jèhófà ṣe tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà nígbà ìṣòro?
12 Ohun tá a kọ́: Jèhófà máa ń lo àwọn tó ń ṣàbójútó láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe lo àwọn alábòójútó láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà nígbà ìṣòro. (Diu. 31:23; Sm. 77:20) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà pé Jèhófà ṣì ń lo àwọn alábòójútó láti tọ́ wa sọ́nà.
13 Bí àpẹẹrẹ, nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, “àwọn tó ń mú ipò iwájú” sọ ohun tó yẹ káwọn ará ṣe. Wọ́n jẹ́ káwọn alàgbà mọ bí àá ṣe máa ṣèpàdé, ká lè máa sin Jèhófà nìṣó. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà bẹ̀rẹ̀, a ṣe àpéjọ agbègbè kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, a wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n, a sì gbọ́ ọ lórí rédíò. Lásìkò yẹn, Jèhófà tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà á ṣì máa ran àwọn tó ń ṣàbójútó wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tá a máa ṣe. Yàtọ̀ sí pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa pa àṣẹ ẹ̀ mọ́, ohun míì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá, táá sì jẹ́ ká ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa?
Ẹ MÁA FI ÌFẸ́ ARÁ HÀN, KẸ́ Ẹ SÌ MÁA RAN ARA YÍN LỌ́WỌ́
14. Bí Hébérù 13:1-3 ṣe sọ, àwọn ànímọ́ wo ló yẹ káwọn Kristẹni ní kí wọ́n tó pa Jerúsálẹ́mù run?
14 Tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, ó máa gba pé ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Torí náà, ohun táwọn Kristẹni tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ṣe làwa náà máa ṣe. Àwọn Kristẹni yẹn nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú gan-an. (Héb. 10:32-34) Àmọ́ láwọn ọdún tó ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù, àwọn Kristẹni yẹn fi “ìfẹ́ ará” hàn, wọ́n sì ṣe “aájò àlejò” ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.c (Ka Hébérù 13:1-3.) Àwa náà gbọ́dọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará bí ayé burúkú yìí ṣe ń lọ sópin.
15. Kí nìdí táwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni fi gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ ará hàn, kí wọ́n sì ran ara wọn lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n sá kúrò nílùú?
15 Nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù tó yí Jerúsálẹ́mù ká ṣàdédé fi ibẹ̀ sílẹ̀, àwọn Kristẹni yẹn sá kúrò nílùú, àmọ́ nǹkan tí wọ́n kó dání ò tó nǹkan. (Mát. 24:17, 18) Torí náà, ó máa gba pé kí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò àti nígbà tí wọ́n débi tí wọ́n sá lọ. Ó dájú pé àwọn “ọ̀rọ̀ pàjáwìrì” tó wáyé máa jẹ́ káwọn Kristẹni yẹn fi ìfẹ́ ará hàn, kí wọ́n ṣe aájò àlejò, kí wọ́n pín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ará. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn sì fi hàn pé wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́.—Títù 3:14.
16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará nígbà ìṣòro? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ohun tá a kọ́: Ìfẹ́ ló ń jẹ́ ká ran àwọn ará lọ́wọ́ tí wọ́n bá níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ṣe tán láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó sá kúrò nílùú nítorí ogun àtàwọn àjálù míì. Wọ́n pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò nípa tara fún wọn, wọ́n sì fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè máa sin Jèhófà nìṣó. Arábìnrin ọmọ ilẹ̀ Ukraine kan tó sá kúrò nílé nítorí ogun sọ pé: “A ti rí bí Jèhófà ṣe ń lo àwọn ará láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n gbà wá sílé, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́ ní Ukraine, Hungary àti Jámánì tá a wà báyìí.” Torí náà, tá a bá ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ó fi hàn pé à ń jẹ́ kí Jèhófà lò wá.—Òwe 19:17; 2 Kọ́r. 1:3, 4.
Ó yẹ ká ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí ogun tàbí àjálù míì lé kúrò nílùú (Wo ìpínrọ̀ 16)
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìfẹ́ ará, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́ báyìí?
17 Ó dájú pé nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa gba pé ká túbọ̀ ran ara wa lọ́wọ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Háb. 3:16-18) Àmọ́ Jèhófà ń kọ́ wa báyìí ká lè ní ìfẹ́ ará, ká sì máa ṣaájò ara wa, ó sì dájú pé àwọn nǹkan yìí máa ràn wá lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.
KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ?
18. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni?
18 Ìtàn jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni tó sá lọ sórí àwọn òkè bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n sá kúrò nílùú náà, àmọ́ Jèhófà ò fi wọ́n sílẹ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa yìí? A ò mọ gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ Jésù ti kìlọ̀ fún wa pé ká ṣègbọràn. (Lúùkù 12:40) Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni láwọn ìmọ̀ràn tó ṣì wúlò fún wa lónìí, bó ṣe wúlò fáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Jèhófà sì ti fi dá wa lójú pé òun ò ní fi wá sílẹ̀ tàbí pa wá tì. (Héb. 13:5, 6) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìtara wá ìlú tó máa wà títí láé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, níbi tá a ti máa gbádùn àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Mát. 25:34.
ORIN 157 Àlàáfíà Ayérayé!
a Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọba ló sábà máa ń ṣàkóso ìlú. Ilẹ̀ ọba ni wọ́n máa ń pe àwọn ìlú bẹ́ẹ̀.—Jẹ́n. 14:2.
b Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn táwọn Kristẹni sá kúrò ní agbègbè Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ìyẹn lọ́dún 67 S.K.
c Ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ìfẹ́ ará” lè jẹ́ ìfẹ́ tí ẹnì kan ní sí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ táwọn ará máa ń ní síra wọn, tó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ra.