KAMAL VIRDEE | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
“Mo Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ Gan-an”
Ní August 1973, èmi àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjì lọ sí Àpéjọ Àgbáyé “Ìṣẹ́gun Àtọ̀runwá” tí wọ́n ṣe ní Twickenham, lórílẹ̀-èdè England. Níbẹ̀, a pàdé Arákùnrin Edwin Skinner, tó ti ń ṣe míṣọ́nnárì ní Íńdíà láti ọdún 1926. Nígbà tó mọ̀ pé à ń sọ èdè Punjabi, ó ní: “Kí lẹ̀ ń ṣe níbí? Ẹ máa bọ̀ ní Íńdíà jàre!” Nígbà tó yá, a lọ sí Íńdíà, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè Punjabi nìyẹn o. Àmọ́ kí n tó máa bọ́rọ̀ lọ, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ìrìn àjò ìgbésí ayé mi fún yín.
April 1951 ni wọ́n bí mi ní ìlú Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kenya. Orílẹ̀-èdè Íńdíà làwọn òbí mi ti wá, ẹ̀sìn Sikh ni wọ́n sì ń ṣe. Ìyàwó méjì ni bàbá mi fẹ́, ìyá mi ni ìyálé kò sì sí ohun tí wọ́n lè ṣe nígbà tí bàbá mi fẹ́ ìyàwó kejì. Ìyá mi àti ìyàwó kejì sábà máa ń bímọ sákòókò kan náà. Torí náà, àwa ọmọ méje la wà nínú ilé. Nígbà tó di ọdún 1964, bàbá mi kú, ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) péré ni mí nígbà yẹn.
Mo Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ
Bí mo ṣe ń dàgbà mo rí i pé àwọn èèyàn kórìíra ara wọn, wọ́n sì máa ń ṣojúsàájú. Torí inú ilé olórogún ni mo gbé dàgbà, ṣe ni ọ̀rọ̀ ìdílé wa dà bíi ti Líà àti Réṣẹ́lì nínú Bíbélì. Bákan náà, a sábà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kenya, torí wọ́n sọ fún wa pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ bàbá mi máa ń fẹ́ ká sún mọ́ àwọn òyìnbó tó ń gbé lágbègbè wa, wọ́n máa ń sọ fún wa pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára wọn. Àmọ́ wọ́n sọ fún wa pé àwọn ò fẹ́ rí wa pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ dúdú torí kò sí nǹkan gidi tá a lè rí kọ́ lára wọn. Bákan náà wọn ò fẹ́ ká ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè Pakistan torí ọ̀tá wa ni wọ́n kà wọ́n sí. Mi ò fi taratara gba ohun tí bàbá mi sọ yẹn torí pé mo kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ gan-an.
Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n dá ẹ̀sìn Sikh sílẹ̀, Guru Nānak ló sì bẹ̀rẹ̀ ẹ̀. Mo fara mọ́ ẹ̀kọ́ Nānak, torí lára ohun tó sọ ni pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ló wà. Àmọ́ ìwà ìrẹ́jẹ tí mò ń rí láàárín àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yìí jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í tún inú rò.
Ìyẹn nìkan kọ́ ló mú kí n máa ṣiyèméjì. Mo tún ronú pé nígbà tí kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Sikh, ‘Báwo ni wọ́n ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run ṣáájú ìgbà yẹn, àti pé ọ̀nà ìjọsìn wo gan-an ni Ọlọ́run fẹ́?’ Onírúurú kàlẹ́ńdà tó ní àwòrán àwọn guru Sikh mẹ́wàá la gbé kọ́ ara ògiri ilé wa. Ìyẹn máa ń mú kí n ronú pé, báwo la ṣe mọ bí wọ́n ṣe rí, àti pé, kí nìdí tí a fi máa ń forí balẹ̀ fún àwòrán wọn nígbà tí àwọn fúnra wọn sọ pé Ọlọ́run ló yẹ ká máa jọ́sìn?
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14) lọ́dún 1965, ìdílé wa kó pa dà sí Íńdíà. Àtijẹ-àtimu ṣòro gan-an torí pé kò sówó lọ́wọ́ wa rárá. Ọdún kan lẹ́yìn náà a kó lọ sí ìlú Leicester lórílẹ̀-èdè England. Torí náà àwa méjì la kọ́kọ́ wá torí a ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe onírúurú iṣẹ́ tí mo bá rí, tó bá sì dalẹ́ màá lọ sí ilé ìwé kí n lè parí ẹ̀kọ́ mi. Níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ mo rí i pé wọ́n máa ń ṣojúsàájú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń sanwó gidi fún àwọn tó jẹ́ ọmọ ìlú, àmọ́ owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n máa ń san fún àwa tá a wá láti orílẹ̀-èdè míì. Torí pé mo kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tó ń gbèjà àwọn òṣìṣẹ́. Mo tiẹ̀ ṣètò bí àwọn òṣìṣẹ́ tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ṣe máa dáṣẹ́ sílẹ̀ káwọn náà lè máa rówó gidi gbà. Ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bí mo ṣe kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ tó.
Wọ́n Dáhùn Ìbéèrè Mi
Lọ́dún 1968 àwọn ọkùnrin méjì kan ilẹ̀kùn ilé mi, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, ìgbà àkọ́kọ́ tí mo sì máa pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kò ní sí ojúsàájú ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ọ̀kan lára wọn pa dà wá pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀. Bí èmi àtàwọn àbúrò mi Jaswinder àti Chani ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Nígbà tá a fi máa dé ẹ̀kọ́ kẹfà, ó ti dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ àti pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn a ti rí i pé Ìjọba ẹ̀ nìkan ló lè yanjú ìṣòro ìrẹ́jẹ tó kún inú ayé.
Àmọ́, àwọn tó wà nínú ìdílé wa ta kò wá gan-an. Lẹ́yìn tí bàbá wa kú, ọmọkùnrin ìyàwó kejì di olórí ẹbí. Ṣe ni ìyá ẹ̀ ń sọ fún un pé kó gbógun tì wá. Ṣe ló máa ń lu àwọn àbúrò mi Jaswinder àti Chani bí ẹni lu bàrà, ó sì máa ń fi bàtà tó ní irin ta wọ́n nípàá. Àmọ́ kò lè fọwọ́ kàn mí torí mo ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18). Ìdí ni pé lábẹ́ òfin tó bá fọwọ́ kàn mí pẹ́nrẹ́n ṣe ló máa kan ìdin nínú iyọ̀. Àmọ́, torí àwọn àbúrò mi ṣì kéré ó rí ìyẹn ṣe. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó mú Bíbélì, tó sọná sí i, tó wá nà án sí wọn lójú pé: “Ẹ sọ fún Jèhófà yín pé kó pa iná ẹ̀!” Lákòókò yẹn ṣe la máa ń yọ́ lọ sípàdé. Ó wù wá gan-an láti sin Jèhófà. Àmọ́ ṣe ló dà bí ohun tí ò lè ṣeé ṣe nínú ilé yẹn. La bá pinnu pé ká sá kúrò nílé ká lè ráyè sin Jèhófà.
A bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú owó oúnjẹ ọ̀sán wa àti owó tí mo fi ń wọkọ̀ lọ sí ibi iṣẹ́, lẹ́yìn náà mo máa fi ọgbọ́n yọ díẹ̀ lára owó oṣù mi, kí ìyàwó kejì tí bàbá mi fẹ́ tó gba gbogbo ẹ̀ lọ́wọ́ mi. A ra báàgì mẹ́ta tá a gbé pa mọ́, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó aṣọ sínú ẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Nígbà tó fi máa di May 1972, Jaswinder ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) a sì ti tu ọgọ́rùn-ún (100) pounds jọ, la bá gbéra a sì wọkọ̀ ojú irin lọ sí ìlú Penzance ní orílẹ̀-èdè England. Nígbà tá a débẹ̀, a kàn sí àwọn ará, wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Onírúurú iṣẹ́ la ṣe títí kan yíyọ ìdọ̀tí inú ẹja ká ṣáà lè rówó gbalé.
Tọkọtaya kan tó jẹ́ àgbàlagbà ìyẹn Harry àti Betty Briggs bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní September 1972, a ṣe ìrìbọmi láìka pé à ń fara pa mọ́ fún àwọn tó wà nínú ìdílé wa. Inú odò kékeré kan tó wà lábẹ́ pèpéle ní Ilé Ìpàdé Truro la ti ṣe ìrìbọmi. Chani bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, èmi àti Jaswinder sì ń ṣiṣẹ́ ká lè pèsè ohun tó nílò.
A Sìn Níbi Tí Àìní Wà
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Harry àti Betty ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, àtìgbàdégbà ni wọ́n máa ń lọ wàásù ní erékùṣù kékeré kan tó wà ní ìlú Scilly, lórílẹ̀-èdè England. Àpẹẹrẹ wọn mú kó wù wá láti sìn níbi tí àìní wà. Torí náà, lẹ́yìn tí Arákùnrin Skinner bá wa sọ̀rọ̀ bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tó di ọdún 1973, a ti mọ ohun tá a máa ṣe.
Ní January 1974, a pa dà sí ìlú New Delhi, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, Arákùnrin Dick Cotterill sì gbà ká máa gbé ní ilé míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Chani ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ, èmi àti Jaswinder sì fi kún ohun tí à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Nígbà tó yá, wọ́n ní ká lọ sí Punjab, ìyẹn ìlú kan tó wà ní apá àríwá Íńdíà. Níbẹ̀, a gbé ní ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Chandigarh ká tó gba ilé tiwa. Èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà tó sì di ọdún 1975, ètò Ọlọ́run sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Bí mo ṣe ń wàásù níbẹ̀ jẹ́ kí n rí i pé ó máa dáa gan-an tí àwọn ìwé wa bá lè wà ní èdè Punjabi torí ìyẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo. Lọ́dún 1976, ẹ̀ka ọ́fíìsì Íńdíà pe àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé ká wá máa tú àwọn ìwé wa sí èdè Punjabi. Iṣẹ́ náà ò rọrùn rárá torí kò tíì sí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àti typewriter nígbà yẹn. Ọwọ́ la fi máa ń kọ gbogbo ohun tá a bá tú, a sì máa kà á lákàtúnkà ká lè rí i dájú pé kò sí àṣìṣe níbẹ̀. Àá wá kó àwọn ìwé tá a ti tú yẹn lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tẹ̀wé ládùúgbò, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan.
Ìjọ wa ní Chandigarh, Punjab, Íńdíà
Mo Ní Àìlera Síbẹ̀ Mò Ń Láyọ̀
Kò pẹ́ tí nǹkan yí pa dà bìrí. Jaswinder pàdé arákùnrin kan, wọ́n fẹ́ra, wọ́n sì kó lo sí orílẹ̀-èdè Kánádà. Kò pẹ́ tí Chani náà fẹ́ arákùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì, wọ́n sì kó lo sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó yá, mo ṣàìsàn, kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀ ṣe ló ń le sí i. Torí náà mo pa dà sí England ní October 1976. Ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi tó ń gbé ni Leicester gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, wọn ò sì ta ko ẹ̀sìn tí mò ń ṣe. Nígbà tí mo lọ ṣe àyẹ̀wò nílé ìwòsàn, wọ́n sọ pé àìsàn kan tí kò wọ́pọ̀ ló ń ṣe mí, àìsàn yìí sì máa ń ba àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀jẹ̀ jẹ́. Oríṣiríṣi ìtọ́jú ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbà, ó le débi pé wọ́n yọ ọlọ inú mi. Ìyẹn wá gba pé kí n fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀.
Mo gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé tó bá jẹ́ kí ara mi yá díẹ̀, màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pa dà. Ohun tí mo sì ṣe nìyẹn! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ò fi mí sílẹ̀ pátápátá, mo kó lọ sí ìlú Wolverhampton ní 1978, mo sì ń ṣiṣẹ́ ní agbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Punjabi. A fi ọwọ́ kọ àwọn ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sípàdé, a sì ṣe ẹ̀dá ẹ̀ ládùúgbò. A wá pín in fáwọn tó ń sọ èdè Punjabi, ká lè fi pè wọ́n wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ní báyìí, ìjọ Punjabi márùn-ún àti àwùjọ mẹ́ta ló wà ní Britain.
Àṣé gbogbo ìgbà tí mò ń túmọ̀ èdè Punjabi ní Íńdíà, wọ́n mọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Britain. Torí náà, nígbà tó di ìparí àwọn ọdún 1980, wọ́n pè mí láti ẹ̀ka ọ́fíìsì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í tilé lọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London. Mo bá wọn ṣiṣẹ́ lórí ètò kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi pilẹ̀ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì Gurmukhi tí wọ́n ń lò nínú èdè Punjabi. Nǹkan ò rọrùn fún mi rárá nígbà yẹn torí pé mo ṣì ń ṣiṣẹ́ tara mi, mò ń tọ́jú ìyá mi tọ́nà wọn jìn díẹ̀, mo sì wá ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, iṣẹ́ yẹn fún mi láyọ̀ gan-an.
Wọ́n ń dá mi lẹ́kọ̀ọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London ní ìparí àwọn ọdún 1980
Ní September 1991, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí mi ò retí rárá. Wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì ní kí n máa bá àwọn tó ń túmọ̀ èdè Punjabi ṣiṣẹ́. Ó yà mí lẹ́nu gan-an. Mo ronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò tọ́ sí mi torí mò ń ṣàìsàn, mo tún ti dàgbà kọjá ẹni tí wọ́n lè pè wá sí Bẹ́tẹ́lì. Síbẹ̀, Jèhófà fi ojú rere àrà ọ̀tọ̀ yìí hàn sí mi. Mò ń láyọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ò fi mí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ yọ jú láwọn ìgbà tí mò ń gba ìtọ́jú chemotherapy àtàwọn ìtọ́jú míì. Ó ya dókítà tó ń tọ́jú mi lẹ́nu gan-an nígbà tó rí bí mo ṣe ń kọ́ fẹ pa dà. Kódà, ó pè mí sí ibi àpérò kan tí àwọn dókítà tó tó ogójì (40) tí wọ́n jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ṣe ní ilé ìwòsàn ńlá kan ní London. Wọ́n fún mi láǹfààní láti fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá ṣàlàyé ìpinnu mi lórí ẹ̀jẹ̀. Lẹ́yìn náà, arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn bójú tó apá ìbéèrè àti ìdáhùn.
Lákòókò tí nǹkan le gan-an yìí, àwọn àbúrò mi Jaswinder àti Chani ò fi mí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ míì náà dúró tì mí. Mo mọyì gbogbo wọn gan-an. Láìka gbogbo ìṣòro mi sí, Jèhófà fún mi lókun láti máa ba iṣẹ́ ìsìn mi lọ.—Sáàmù 73:26.
Ìbùkún Jèhófà Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀
Ọdún kẹjìlélọ́gbọ̀n (32) mi rèé ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì ti rí i pé “ẹni rere ni Jèhófà.” (Sáàmù 34:8; Òwe 10:22) Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára àwọn àgbàlagbà tí mo bá ní Bẹ́tẹ́lì. Tí mo bá rí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Punjabi tí mo ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ti ń sin Jèhófà báyìí, inú mi máa ń dùn gan-an. Àárín èmi àti àwọn ọmọ ìyá mi gún régé gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, màmá mi sábà máa ń sọ pé, “Ò ń fọkàn sin Ọlọ́run lóòótọ́.” Nígbà tí mo sọ fún wọn pé mo máa fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ kí n lè wá tọ́jú ìyá wa, ẹ̀gbọ́n mi sọ fún mi pé: “Dúró síbẹ̀, kó o máa bá iṣẹ́ ẹ lọ.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tí ìyá mi wà jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì, mo máa ń lọ wò wọ́n látìgbàdégbà.
Nígbàkigbà tí ìṣòro bá dé bá mi, mo máa ń sọ fún ara mi pé: ‘Kamal, má bẹ̀rù. Apata ni Jèhófà jẹ́ fún ọ. Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.’ (Jẹ́nẹ́sísì 15:1) Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, “Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo,” pé ó rí mi nígbà tí mo wà ní kékeré, ó sì fún mi ní iṣẹ́ aláyọ̀ tí mo fi ìgbésí ayé mi ṣe. (Àìsáyà 30:18) Mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ẹnì kankan ò ní “sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’”—Àìsáyà 33:24.
Ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Chelmsford