-
‘Agbára Jèhófà Pọ̀’Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 4
‘Agbára Jèhófà Pọ̀’
1, 2. Àwọn nǹkan àgbàyanu wo ló ti ṣojú Èlíjà, àmọ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ló rí nígbà tó wà lórí Òkè Hórébù?
Ọ̀PỌ̀ nǹkan àgbàyanu ló ti ṣojú Èlíjà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ lọ fún un lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́ níbi tó sá pa mọ́ sí. Ìgbà kan tún wà tó rí i tí ìyẹ̀fun ò tán nínú ìkòkò tí wọ́n ń kó oúnjẹ sí, tí òróró ò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré kan ní gbogbo àkókò gígùn tí ìyàn fi mú. Kódà, Èlíjà ti rí i tí Jèhófà rán iná wá látọ̀run láti dáhùn àdúrà rẹ̀. (1 Àwọn Ọba, orí 17 àti 18) Síbẹ̀, ohun tí Èlíjà rí lọ́tẹ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀.
2 Nígbà tó dúró sí ẹnu ihò kan lórí Òkè Hórébù, ó rí onírúurú ohun àrà tó ṣẹlẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀fúùfù ńlá kan fẹ́. Ẹ̀fúùfù náà le débi pé ariwo ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ lè dini létí, ó sì lágbára débi tó fi ń ya àwọn òkè, tó sì ń fọ́ àwọn àpáta. Bákan náà, ilẹ̀ mì tìtì lọ́nà tó lágbára, èyí sì mú kí ooru gbígbóná tú jáde láti abẹ́ ilẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, iná sọ. Bí ooru iná yẹn ṣe ń sún mọ́ Èlíjà, ó ṣeé ṣe kó máa rà á lára.—1 Àwọn Ọba 19:8-12.
3. Kí làwọn nǹkan tí Èlíjà rí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà, àwọn nǹkan wo làwa náà ń rí lónìí tó ń jẹ́rìí sí i pé alágbára ni Jèhófà?
3 Ohun kan tó jọra nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí Èlíjà rí yìí ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló fi hàn pé alágbára ńlá ni Jèhófà Ọlọ́run. Ká sòótọ́, kò dìgbà téèyàn bá rí iṣẹ́ ìyanu kéèyàn tó mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run. Gbogbo ohun tó wà láyìíká wa ló ń jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run lágbára. Bíbélì sọ pé àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká mọ̀ nípa “agbára ayérayé tó ní àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:20) Ronú nípa bí mànàmáná ṣe ń kọ yẹ̀rì, tí òjò ń kù rìrì, tí ààrá ń sán wàá, tó sì máa ń milẹ̀ tìtì! Tún wo ọ̀nà àrà tí omi gbà ń dà ṣọ̀ọ̀rọ̀ láti orí àpáta, àti bí ìràwọ̀ ṣe lọ salalu lójú ọ̀run! Ó dájú pé àwọn nǹkan yìí jẹ́ ká mọ bí agbára Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ò kíyè sí àwọn nǹkan yìí kí wọ́n lè rí i pé Ọlọ́run lágbára. Nínú apá yìí, a máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára tí kò lẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ní, èyí sì máa mú kó wù wá gan-an láti sún mọ́ ọn.
“Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ”
Ọ̀kan Pàtàkì Lára Ìwà àti Ìṣe Jèhófà
4, 5. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa orúkọ Jèhófà? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu bí Jèhófà ṣe fi màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀?
4 Agbára Jèhófà ò láfiwé. Jeremáyà 10:6 sọ pé: “Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ. O tóbi, orúkọ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.” Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé orúkọ Jèhófà tóbi, ó sì kàmàmà. Má gbàgbé pé ẹ̀rí fi hàn pé orúkọ yìí túmọ̀ sí “Alèwílèṣe” tàbí ẹni tó lè di ohunkóhun tó bá fẹ́. Kí ló jẹ́ kí Jèhófà lè ṣẹ̀dá ohunkóhun tó bá fẹ́, kó sì lè di ohunkóhun tó bá fẹ́? Ohun kan tó mú kó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, agbára tí Jèhófà ní láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kò lópin. Agbára yẹn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀.
5 Àwa èèyàn ò lè lóye bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, ìdí nìyẹn tó fi lo àwọn àpèjúwe tó lè ràn wá lọ́wọ́. A ti kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ pé ó fi akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 1:4-10) Àpèjúwe yẹn sì bá a mu gan-an, nítorí pé akọ màlúù tí wọ́n ń sìn nílé lásán máa ń tóbi, ó sì lágbára. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bóyá ni àwọn ará Palẹ́sìnì tún mọ ẹranko míì tó lágbára ju akọ màlúù lọ. Wọ́n tiẹ̀ mọ àwọn akọ màlúù igbó kan tó bani lẹ́rù gan-an, àmọ́ àwọn màlúù náà ò sí mọ́ báyìí. (Jóòbù 39:9-12) Alákòóso ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Julius Caesar sọ nígbà kan pé akọ màlúù yìí máa ń tóbi tó erin. Nínú ìwé kan tó kọ, ó ní: “Wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń sáré gan-an.” Téèyàn bá dúró ti ẹranko yìí, ó dájú pé ńṣe lèèyàn á kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí ẹ̀rù á sì máa ba èèyàn!
6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan là ń pè ní “Olódùmarè”?
6 Bákan náà, agbára àwa èèyàn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Jèhófà, alágbára gíga jù lọ. Kódà, bí eruku fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n làwọn orílẹ̀-èdè alágbára pàápàá ṣe rí lójú ẹ̀. (Àìsáyà 40:15) Agbára Jèhófà yàtọ̀ sí ti ẹ̀dá èyíkéyìí, nítorí agbára rẹ̀ kò lópin. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo là ń pè ní “Olódùmarè.”a (Ìfihàn 15:3) “Okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu, agbára rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù.” (Àìsáyà 40:26) Òun ni Orísun agbára ńlá tí kò sì lópin. Kò gbára lé ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun kó tó lè ní agbára, torí pé “agbára jẹ́ ti Ọlọ́run.” (Sáàmù 62:11) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀?
Bí Jèhófà Ṣe Ń Lo Agbára Rẹ̀
7. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, kí làwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́?
7 Ẹ̀mí mímọ́ tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà ò lè tán láéláé. Ẹ̀mí mímọ́ yìí ni Ọlọ́run máa ń fi ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Kódà ní Jẹ́nẹ́sísì 1:2, Bíbélì pè é ní “ẹ̀mí Ọlọ́run.” Àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” lè túmọ̀ sí “ẹ̀fúùfù” tàbí “èémí,” láwọn ibòmíì. Àwọn onímọ̀ nípa èdè sọ pé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ohun kan téèyàn ò lè rí àmọ́ téèyàn ń rí iṣẹ́ tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè fojú rí afẹ́fẹ́, ṣùgbọ́n a máa ń mọ̀ ọ́n lára, a sì máa ń rí ohun tó ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ ṣe rí.
8. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí Ọlọ́run, kí sì nìdí táwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi bá a mu?
8 Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lónírúurú ọ̀nà láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí Ọlọ́run fi bá a mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pè é ní “ìka Ọlọ́run,” “ọwọ́ agbára” rẹ̀, tàbí “apá rẹ̀ tó nà jáde.” (Lúùkù 11:20; Diutarónómì 5:15; Sáàmù 8:3) Bó ṣe jẹ́ pé èèyàn lè fi ọwọ́ ẹ̀ ṣe onírúurú iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run lè lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fi ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dá àwọn nǹkan tín-tìn-tín, ó fi pín Òkun Pupa níyà, ó sì fi mú káwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sọ oríṣiríṣi èdè.
9. Kí lohun míì tó tún jẹ́ ká mọ bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó?
9 Ohun míì tó tún jẹ́ ká mọ bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó ni àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Rò ó wò ná: Jèhófà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n lágbára, tí wọ́n sì múra tán láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́! Jèhófà tún láwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ èèyàn, Ìwé Mímọ́ sì sábà máa ń fi wọ́n wé ọmọ ogun. (Sáàmù 68:11; 110:3) Àmọ́ agbára àwọn èèyàn ò tó nǹkan kan rárá tá a bá fi wé tàwọn áńgẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, lóru ọjọ́ kan péré, áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) lára àwọn ọmọ ogun Ásíríà nígbà tí wọ́n gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run! (2 Àwọn Ọba 19:35) Ká sòótọ́, “alágbára ńlá” làwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.—Sáàmù 103:19, 20.
10. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Olódùmarè ní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun? (b) Ta ló lágbára jù lọ nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá?
10 Áńgẹ́lì mélòó ló wà? Nínú ìran kan tí wòlíì Dáníẹ́lì rí nípa ọ̀run, ó rí ohun tó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù áńgẹ́lì níwájú ìtẹ́ Jèhófà, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé gbogbo wọn pátá ló rí. (Dáníẹ́lì 7:10) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì ló wà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ọlọ́run ní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Orúkọ oyè yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àìmọye àwọn áńgẹ́lì alágbára tí wọ́n wà létòlétò ni Jèhófà ń darí. Ó wá fi áńgẹ́lì alágbára kan ṣe alábòójútó àwọn áńgẹ́lì náà, ìyẹn Jésù ààyò Ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Òun ló lágbára jù lọ nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá. Bíbélì pè é ní olú áńgẹ́lì torí pé ipò tó wà ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù, títí kan àwọn séráfù àtàwọn kérúbù.
11, 12. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà ń lo agbára? (b) Kí ni Jésù sọ nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó?
11 Ọ̀nà míì tún wà tí Jèhófà gbà ń lo agbára. Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.” Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti kíyè sí agbára àrà ọ̀tọ̀ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí àwọn ìsọfúnni onímìísí tó wà nínú Bíbélì ní. Ó lè fún wa lókun, ó lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yí ìwà wa pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ míì. Lẹ́yìn náà, ó wá fi kún un pé: “Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Bẹ́ẹ̀ ni o, agbára tí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ní ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè yíwà pa dà.
12 Agbára Jèhófà pọ̀ gan-an, ọ̀nà tó sì ń gbà lò ó gbéṣẹ́ gan-an débi pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Mátíù 19:26) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń fi agbára rẹ̀ ṣe?
Ọlọ́run Máa Ń Fi Agbára Ẹ̀ Ṣe Ohun Tó Bá Ìfẹ́ Rẹ̀ Mu
13, 14. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe alágbára kan tó kàn máa ń lo agbára rẹ̀ bó ṣe wù ú? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo agbára ẹ̀?
13 Ẹ̀mí Jèhófà lágbára ju ohunkóhun tá a lè fojú rí lọ. Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn jẹ́ alágbára kan tó máa ń lo agbára náà bó ṣe wù ú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó láwọn ìwà àti ìṣe tó dáa, ìyẹn sì máa ń mú kó lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Àmọ́, kí ló máa ń mú kó lo agbára ẹ̀?
14 Bá a ṣe máa rí i níwájú, Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dá nǹkan, láti fi pa àwọn nǹkan run, láti fi dáàbò boni àti láti fi mú nǹkan bọ̀ sípò. Ìyẹn ni pé ó máa ń fi agbára ẹ̀ ṣe ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Àìsáyà 46:10) Nígbà míì, Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ láti jẹ́ ká mọ irú ẹni tóun jẹ́, ká sì mọ ohun tó ń retí pé ká ṣe ká tó lè rí ojúure rẹ̀. Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó ga jù lọ nígbà tó bá mú gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà, tó sì mú ẹ̀gàn tí Sátánì mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò, kó lè hàn kedere pè ọ̀nà tóun ń gbà ṣàkóso ló dáa jù lọ. Ó sì dájú pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.
15. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo agbára ẹ̀ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà sì ṣe jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀?
15 Jèhófà tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Kíyè sí ohun tí 2 Kíróníkà 16:9 sọ, ó ní: “Ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà, bá a ṣe rí i níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kó rí agbára rẹ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tóyẹn? Ìdí ni pé Jésíbẹ́lì Ayaba ti halẹ̀ mọ́ Èlíjà pé òun máa pa á. Ni Èlíjà bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ kí wọ́n má bàa rí i pa. Ó gbà pé òun nìkan ṣoṣo ló ń sin Jèhófà, ẹ̀rù bà á, ayé sì sú u. Ńṣe ló dà bíi pé gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ṣe ti já sí asán. Jèhófà ṣe àwọn nǹkan kan kó lè rán Èlíjà létí pé alágbára lòun, ìyẹn sì tu Èlíjà nínú gan-an. Nígbà tí Èlíjà rí ẹ̀fúùfù, ìmìtìtì ilẹ̀ àti iná tó ń jó, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ torí ó mọ̀ pé Olódùmarè tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run wà lẹ́yìn òun. Ó dájú pé kò sídìí kankan tó fi yẹ kí Èlíjà máa bẹ̀rù Jésíbẹ́lì, torí pé Ọlọ́run Olódùmarè wà lẹ́yìn rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 19:1-12.b
16. Tá a bá ń ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, báwo nìyẹn ṣe máa tù wá nínú?
16 Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í ṣe irú iṣẹ́ ìyanu tó ṣe nígbà ayé Èlíjà mọ́ lónìí, síbẹ̀ kò tíì yí pa dà. (1 Kọ́ríńtì 13:8) Bíi tìgbà ayé Èlíjà, ó ṣì ń wu Jèhófà láti lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Agbára rẹ̀ kò lópin, kò sì síbi tí kò ti lè lo agbára náà. Òótọ́ ni pé òkè ọ̀run ló ń gbé, síbẹ̀ kò jìnnà sí wa. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Ìgbà kan wà tí wòlíì Dáníẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, kò tíì parí àdúrà náà tí áńgẹ́lì kan ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀! (Dáníẹ́lì 9:20-23) Kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lókun kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 118:6.
Ṣé Agbára Ọlọ́run Mú Kó Dẹni Tí Kò Ṣeé Sún Mọ́?
17. Tá a bá ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, irú ìbẹ̀rù wo ló yẹ ká ní fún un, àmọ́ irú ìbẹ̀rù wo ni kò yẹ ká ní fún un?
17 Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ alágbára? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, a sì tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Tá a bá sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹn bá ohun tá a kọ́ ní orí tó ṣáájú èyí mu. Nínú orí náà, a kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Jèhófà tàbí ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un torí pé Ọlọ́run alágbára ni. Irú ìbẹ̀rù yìí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.” (Sáàmù 111:10) Àmọ́ a tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, torí pé kò yẹ ká jẹ́ kí agbára tí Ọlọ́run ní máa bà wá lẹ́rù débi tí àá fi máa gbọ̀n jìnnìjìnnì tá ò sì ní fẹ́ sún mọ́ ọn.
18. (a) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi í fọkàn tán àwọn alágbára? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò lè ṣi agbára rẹ̀ lò láé?
18 Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Lord Acton sọ ọ̀rọ̀ kan lọ́dún 1887, ó ní: “Ńṣe ni agbára máa ń gun alágbára, tá a bá wá lọ gbé gbogbo agbára lé ẹnì kan lọ́wọ́, gàràgàrà ni yóò máa gun onítọ̀hún.” Léraléra làwọn èèyàn ti sọ ọ̀rọ̀ yìí torí wọ́n gbà pé òótọ́ ni. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn sì ti jẹ́ ká rí i pé àwa èèyàn sábà máa ń ṣi agbára lò. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọkàn tán àwọn alágbára, kódà wọn kì í fẹ́ sún mọ́ wọn. Ní ti Jèhófà, agbára rẹ̀ pọ̀ ju ti èèyàn èyíkéyìí lọ. Àmọ́, ṣé ó ti ṣi agbára yìí lò rí? Rárá o! Bá a ṣe rí i nínú orí tó ṣáájú èyí, ẹni mímọ́ ni Ọlọ́run, kò sì ní àbààwọ́n kankan. Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ alágbára nínú ayé burúkú yìí. Kò ṣi agbára rẹ̀ lò rí, kò sì ní ṣì í lò láéláé.
19, 20. (a) Àwọn ìwà àti ìṣe míì wo ni Jèhófà máa ń lo pọ̀ mọ́ agbára ẹ̀, kí sì nìdí tí ìyẹn fi fini lọ́kàn balẹ̀? (b) Ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu, kí sì nìdí tíyẹn fi fà ọ́ mọ́ra?
19 Rántí pé Jèhófà tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó yàtọ̀ sí agbára. A ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe pé Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń lò wọ́n pa pọ̀. Bá a ṣe máa rí i nínú àwọn orí tó wà níwájú, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Bákan náà, Ọlọ́run máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu tó bá ń lo agbára rẹ̀, ìyẹn sì mú kó yàtọ̀ pátápátá sáwọn alákòóso ayé.
20 Ká sọ pé o pàdé ọkùnrin kan tó ga gan-an tó sì lágbára, ẹ̀rù wá ń bà ẹ́ nígbà tó o kọ́kọ́ rí i. Àmọ́, kò pẹ́ lo wá rí i pé èèyàn jẹ́jẹ́ ni. Ó máa ń fi agbára rẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì máa ń fi dáàbò bò wọ́n, ní pàtàkì àwọn tí kò lágbára láti dáàbò bo ara wọn. Agbára kì í gùn ún gàràgàrà. O rí i táwọn kan ń parọ́ mọ́ ọkùnrin náà láti bà á lórúkọ jẹ́, síbẹ̀ kò ṣìwà hù, kódà ṣe ló túbọ̀ ń ṣoore fáwọn èèyàn. O wá ń ronú pé bóyá ni wàá lè ní sùúrù tó ọkùnrin náà ká sọ pé o lágbára bíi tiẹ̀. Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́, ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o sún mọ́ ọn. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn, bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tó jẹ́, bẹ́ẹ̀ láá máa wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ ọn, kódà ju bó ṣe máa wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ ọkùnrin yẹn. Ronú nípa ẹsẹ Bíbélì tá a ti mú ẹṣin ọ̀rọ̀ orí yìí. Ó sọ pé: “Jèhófà kì í tètè bínú, agbára rẹ̀ sì pọ̀.” (Náhúmù 1:3) Jèhófà kì í tètè fi agbára ẹ̀ jẹ àwọn èèyàn níyà, tó fi mọ́ àwọn ẹni burúkú pàápàá. Ó jẹ́ onínú tútù àti onínúure. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti ṣe oríṣiríṣi nǹkan tó yẹ kó bí i nínú, ó ti fi hàn pé òun “kì í tètè bínú.”—Sáàmù 78:37-41.
21. Kí nìdí tí Jèhófà kì í fi í fipá mú wa láti jọ́sìn òun, kí lèyí sì kọ́ wa nípa irú ẹni tó jẹ́?
21 Jẹ́ ká ronú nípa ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Ká sọ pé o lágbára tó Jèhófà, ṣé kò ní máa wù ẹ́ nígbà míì pé kó o fipá mú àwọn èèyàn ṣe ohun tó o bá fẹ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára gan-an, kì í fipá mú àwọn èèyàn láti sin òun. Òótọ́ ni pé kò sí ọ̀nà mìíràn téèyàn lè gbà rí ìyè àìnípẹ̀kun àyàfi tó bá ń sin Ọlọ́run, síbẹ̀ Jèhófà kì í fipá mú wa láti sin òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá pinnu láti ṣe ohun tí kò dáa, ó sì jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣe ohun tó tọ́. Àmọ́ àwa fúnra wa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. (Diutarónómì 30:19, 20) Jèhófà ò fẹ́ ká máa sin òun torí pé ẹnì kan fipá mú wa pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí torí pé à ń bẹ̀rù rẹ̀ pé ó jẹ́ alágbára. Dípò ìyẹn, ṣe ló fẹ́ ká máa sin òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun látọkàn wá.—2 Kọ́ríńtì 9:7.
22, 23. (a) Kí ló fi hàn pé inú Jèhófà máa ń dùn láti fún àwọn míì lágbára? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?
22 Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí míì tí kò fi yẹ kí jìnnìjìnnì máa bò wá nítorí Ọlọ́run Olódùmarè. Àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ sábà máa ń bẹ̀rù láti fún àwọn míì lágbára. Àmọ́, inú Jèhófà máa ń dùn láti fún àwọn adúróṣinṣin tó ń jọ́sìn rẹ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Jésù Ọmọ ẹ̀ lágbára láti pàṣẹ, ó sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn míì. (Mátíù 28:18) Jèhófà tún máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára lọ́nà míì. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà, tìrẹ ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá, nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ. . . . Ọwọ́ rẹ ni agbára àti títóbi wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá, òun ló sì lè fúnni lágbára.”—1 Kíróníkà 29:11, 12.
23 Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Jèhófà máa dùn láti fún ọ lágbára. Kódà, ó máa ń fún àwọn tó bá fẹ́ sìn ín ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ó dájú pé ó máa wù ọ́ pé kó o sún mọ́ Ọlọ́run wa tó lágbára, tó sì máa ń lo agbára ẹ̀ lọ́nà tó tọ́ àti lọ́nà tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? Nínú orí tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi agbára ẹ̀ dá àwọn nǹkan.
a Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “Olódùmarè” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “Alákòóso Gbogbo Ẹ̀dá Ayé Àtọ̀run tàbí Alágbára Gíga Jù Lọ.”
b Bíbélì sọ pé: “Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà . . . , ìmìtìtì ilẹ̀ náà . . . , [àti] iná náà.” Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n máa ń jọ́sìn afẹ́fẹ́, iná tàbí òjò. Jèhófà lágbára gan-an, torí náà kò lè wà nínú àwọn nǹkan tóun fúnra ẹ̀ dá.—1 Àwọn Ọba 8:27.
-
-
Agbára Ìṣẹ̀dá—“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 5
Agbára Ìṣẹ̀dá —“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”
1, 2. Báwo ni oòrùn ṣe jẹ́rìí sí i pé agbára Jèhófà Ẹlẹ́dàá pọ̀ gan-an?
ṢÉ O ti yáná rí nígbà òtútù? Bóyá ńṣe lo rọra ń fọwọ́ ra iná yẹn kó o lè gbádùn ooru tó ń ti ibẹ̀ jáde. Tó o bá sún mọ́ iná yẹn jù, ó máa ta ẹ́ lára. Tó o bá sì jìnnà sí i jù, òtútù lè bẹ̀rẹ̀ sí í mú ẹ.
2 A lè fi oòrùn wé “iná” tó máa ń rani lára. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, oòrùn fi nǹkan bí àádọ́jọ mílíọ̀nù (150,000,000) kìlómítà jìnnà sí ayé!a Ẹ ò rí i pé agbára oòrùn pọ̀ gan-an, tó fi lè máa rà wá lára pẹ̀lú bá a ṣe jìnnà sí i tó! Síbẹ̀, ó gbàfiyèsí pé ibi tó yẹ kí ayé wà gẹ́lẹ́ ló wà. Kò jìnnà jù sí oòrùn, bẹ́ẹ̀ ní kò sún mọ́ ọn jù. Tí ayé bá sún mọ́ ọn jù, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; tó bá sì jìnnà sí i jù, gbogbo omi tó wà láyé á di yìnyín. Tí èyíkéyìí nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀, kò ní sí ohun alààyè kankan tó máa wà láyé. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ tí kò bá sí oòrùn rárá. Ká sòótọ́, kòṣeémáàní ni oòrùn, ó máa ń jẹ́ kí ibi gbogbo mọ́lẹ̀ kedere, kò síbi tí kò dé, kì í ba afẹ́fẹ́ jẹ́, ó sì máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an.—Oníwàásù 11:7.
3. Kí ni oòrùn kọ́ wa nípa Jèhófà?
3 Òótọ́ ni pé oòrùn wà lára ohun tó máa ń gbé ẹ̀mí wa ró, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fiyè sí i. Ìyẹn ò jẹ́ kí wọ́n lè ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n lè kọ́ látara oòrùn. Bíbélì sọ pé ‘Jèhófà ló ṣe ìmọ́lẹ̀ àti oòrùn.’ (Sáàmù 74:16) Ó dájú pé oòrùn ń fògo fún Jèhófà tó jẹ́ “Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.” (Sáàmù 19:1; 146:6) Àmọ́, ṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára àìmọye ìràwọ̀ tó jẹ́rìí sí i pé agbára tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ní kò láfiwé. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run yìí, lẹ́yìn náà a máa sọ̀rọ̀ nípa ayé àtàwọn nǹkan tí Jèhófà dá sínú rẹ̀.
‘Jèhófà ló ṣe ìmọ́lẹ̀ àti oòrùn’
“Ẹ Gbé Ojú Yín Sókè Ọ̀run, Kí Ẹ sì Wò Ó”
4, 5. Báwo ni oòrùn ṣe lágbára tó, báwo ló sì ṣe tóbi tó, síbẹ̀ ṣe òun ló tóbi jù nínú gbogbo ìràwọ̀?
4 Oòrùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Ohun tó jẹ́ kó dà bíi pé ó tóbi ju àwọn ìràwọ̀ tí à ń rí lálẹ́ ni pé ó sún mọ́ ayé jù wọ́n lọ. Báwo ló ṣe lágbára tó? Tá a bá fi ohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe gbóná tó wọn ibi tó gbóná jù nínú oòrùn, á gbóná tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000,000°C) lórí òṣùwọ̀n náà. Ká sọ pé o lè mú èyí tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ lára oòrùn wá sí ayé yìí, ìwọ̀n bíńtín yẹn á gbóná débi pé o ò ní lè dúró ní nǹkan bí ogóje (140) kìlómítà síbi tó bá wà! Ńṣe ni agbára tó ń ti ara oòrùn jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dà bí ìgbà tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù bọ́ǹbù átọ́míìkì bá bú gbàù pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
5 Oòrùn tóbi débi pé tí wọ́n bá kó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300,000) ayé yìí sínú ẹ̀, ńṣe ló máa gbé e mì. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé oòrùn ló tóbi jù nínú àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run? Rárá, nítorí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwọn ìràwọ̀ kan wà tó tún tóbi ju oòrùn lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ògo ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.” (1 Kọ́ríńtì 15:41) Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ ló mú kó sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ìràwọ̀ kan wà tó tóbi débi pé tí wọ́n bá gbé e sí ibi tí oòrùn wà gangan, ó fẹ̀ débi pé á bo ayé mọ́lẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá míì tún wà tó jẹ́ pé tí wọ́n bá gbé òun náà síbi tí oòrùn wà, ó fẹ̀ débi pé á dé ibi tí pílánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Saturn wà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Saturn yìí jìnnà sí ayé gan-an débi pé ìrìn ọdún mẹ́rin gbáko láìdúró ni ọkọ̀ tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò ojú sánmà á rìn kó tó débẹ̀. Ọkọ̀ yìí sì máa ń sáré gan-an ní ìlọ́po ogójì ju bí ọta ìbọn ṣe máa ń fò jáde lẹ́nu ìbọn lọ!
6. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run pọ̀ ju ìwọ̀nba táwa èèyàn lè fojú rí lọ?
6 Yàtọ̀ sí bí àwọn ìràwọ̀ ṣe tóbi tó, ohun míì tó tún yani lẹ́nu ni bí wọ́n ṣe pọ̀ tó. Kódà, Bíbélì sọ pé bó ṣe jẹ́ pé kò sí èèyàn tó lè ka “iyanrìn òkun,” bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí èèyàn tó lè ka iye ìràwọ̀. (Jeremáyà 33:22) Èyí fi hàn pé àìmọye ìràwọ̀ ló wà tá ò lè fojú lásán rí. Ká sọ pé ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì bíi Jeremáyà bá wo ojú ọ̀run lálẹ́, tó sì gbìyànjú láti ka iye ìràwọ̀ tó rí, kò ní lè kà ju nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) lọ. Téèyàn bá gbójú sókè nígbà tójú ọ̀run bá mọ́lẹ̀ kedere lálẹ́, ìràwọ̀ téèyàn lè fojú kà láìlo ohun tí wọ́n fi ń wo ọ̀nà jíjìn kò ju iye yẹn náà lọ. Ńṣe ni èyí dà bí ìgbà téèyàn bá kàn bu ẹ̀kúnwọ́ iyanrìn kan péré lára gbogbo iyanrìn òkun. Ká sòótọ́, òbítíbitì ìràwọ̀ ló wà lójú ọ̀run, ṣe ló pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.b Ta ló wá lè ka iye wọn tán?
“Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn”
7. Kí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rò nípa iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tàbí iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lágbàáyé?
7 Àìsáyà 40:26 dáhùn pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó. Ta ló dá àwọn nǹkan yìí? Òun ni Ẹni tó ń mú wọn jáde bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní iye-iye; Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn.” Sáàmù 147:4 sọ pé: “Ó ń ka iye àwọn ìràwọ̀.” Àmọ́, ìràwọ̀ mélòó ló wà? Kò rọrùn láti dáhùn ìbéèrè yìí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ohun tó ju ọgọ́rùn-ún kan bílíọ̀nù ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way nìkan.c Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì tiẹ̀ tún sọ pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àìmọye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míì ṣì wà tó jẹ́ pé iye ìràwọ̀ tó wà nínú wọn pọ̀ ju ti Milky Way lọ dáadáa. Ó dáa, ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ mélòó ló wà? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé wọ́n tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù. Títí di báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè sọ iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lágbàáyé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé wọ́n máa mọ iye bílíọ̀nù ìràwọ̀ tó wà nínú gbogbo wọn lápapọ̀. Àmọ́, Jèhófà mọ àròpọ̀ iye wọn. Kódà, ó tún fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lórúkọ!
8. (a) Báwo ni ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way ṣe tóbi tó? (b) Kí ló ń darí àwọn ìṣẹ̀dá inú òfúrufú?
8 Tá a bá tún wá wo bí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ṣe tóbi tó, ẹ̀rù Ọlọ́run á túbọ̀ bà wá. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká fi bí ìtànṣán iná ṣe máa ń yára rìn tó ṣàlàyé bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way ṣe tóbi tó. Téèyàn bá tan iná lára ògiri, báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó kó tó mọ́lẹ̀ yòò? Kíákíá ni. Tẹ́nì kan bá ń yára sáré bẹ́ẹ̀, onítọ̀hún á ṣì lò tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000) ọdún kó tó rìn láti ìbẹ̀rẹ̀ Milky Way débi tó parí sí! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan tún wà tí wọ́n tóbi ju Milky Way lọ ní ìlọ́po-ìlọ́po. Bíbélì sọ pé ńṣe ni Jèhófà “na ọ̀run” bí ìgbà téèyàn kàn ta aṣọ lásán. (Sáàmù 104:2) Òun náà ló tún pàṣẹ pé káwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ náà máa lọ láti ibì kan síbòmíì, kí wọ́n sì máa yí po. Gbogbo ìṣẹ̀dá inú gbalasa òfúrufú yìí, látorí èyí tó kéré jù lọ dórí èyí tó tóbi jù lọ, ló ń lọ láti ibì kan síbòmíì níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin tí Ọlọ́run là sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé. Wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí àti létòlétò. (Jóòbù 38:31-33) Èyí ló mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ọ̀nà táwọn nǹkan tó wà ní gbalasa òfúrufú ń gbà lọ láti ibì kan sí ibòmíì dà bí ìgbà táwọn oníjó bá ń dárà lójú agbo! Ronú nípa ẹni tó dá gbogbo nǹkan yìí. Ó dájú pé o máa gbà pé Ọlọ́run tí ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ kò láfiwé ló dá wọn.
“Aṣẹ̀dá Ayé Tó Fi Agbára Rẹ̀ Dá A”
9, 10. Báwo ni ibi tí ayé wà láàárín àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù ṣe fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba?
9 Tá a bá ronú nípa ibi tí ayé yìí wà, a máa rí i pé Jèhófà tóbi lọ́ba. Ibi tó dáa jù ló dá ayé yìí sí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé ọ̀pọ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà tó jẹ́ pé ká ní ibẹ̀ layé wà ni, ohun alààyè kankan ò ní lè gbé ibẹ̀. Kódà, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tí ayé wà nínú ẹ̀ ló jẹ́ pé kò sí ohun alààyè kankan tó lè gbébẹ̀. Ìràwọ̀ tó wà láàárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí pọ̀ gan-an, ìtànṣán olóró sì pọ̀ gan-an níbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìràwọ̀ tó wà níbẹ̀ máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ lura. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ẹ̀dá alààyè ní kò sí ní eteetí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ibi tó yẹ gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run gbé oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po sí.
10 Pílánẹ́ẹ̀tì ńlá kan wà tó ń jẹ́ Jupiter, ó jìn gan-an sí ayé, àmọ́ ó máa ń dáàbò bo ayé. Pílánẹ́ẹ̀tì yìí tóbi ju Ayé lọ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, agbára òòfà rẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Tí àwọn nǹkan eléwu bá ń já bọ̀ láti gbalasa òfúrufú, ńṣe ni òòfà rẹ̀ máa ń bá wa fà á mọ́ra tàbí kó tì í dà nù. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé, tí kì í bá ṣe ti Jupiter yìí ni, àwọn ohun eléwu tó dà bí òkúta ràbàtà-ràbàtà tí ì bá máa rọ́ lu ayé yìí á pọ̀ gan-an ni. Jèhófà tún wá ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan tó wúlò gan-an fún ayé, ìyẹn òṣùpá. Yàtọ̀ sí pé òṣùpá rẹwà gan-an tó sì ń fún wa ni ìmọ́lẹ̀ lóru, ó tún ń mú kí ayé rọra dagun díẹ̀. Bí ayé ṣe dagun yìí ló mú ká lè máa ní onírúurú ìgbà tí kì í yẹ̀ lọ́dọọdún, èyí sì wà lára ohun pàtàkì tó ń mú káyé tura.
11. Báwo ni òfúrufú ṣe dà bí agboòrùn tó ń dáàbò bo ayé?
11 Gbogbo ohun tó wà láyé pátá ló ń jẹ́rìí sí i pé Jèhófà tóbi lọ́ba. Bí àpẹẹrẹ, òfúrufú dà bí agboòrùn tó ń dáàbò bo ayé yìí. Ìtànṣán tó dáa àti èyí tó léwu ló ń wá látinú oòrùn. Nígbà tí èyí tó léwu bá dé apá òkè òfúrufú, ó máa ń mú kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn di afẹ́fẹ́ tó léwu tí wọ́n ń pè ní afẹ́fẹ́ ozone. Afẹ́fẹ́ ozone yìí á wá bo òkè òfúrufú, òun ló sì máa ń gba ìtànṣán tó léwu náà sára. Èyí jẹ́ ká rí i pé ayé yìí ní ohun tó ń dáàbò bò ó!
12. Báwo ni omi tó ń yí po nínú ayé ṣe fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba?
12 Yàtọ̀ sí pé òfúrufú máa ń dáàbò bo ayé lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn, ó tún máa ń tún afẹ́fẹ́ ṣe, ó sì máa ń ṣe àwọn nǹkan míì káwọn ohun alààyè lè máa gbé ayé. Ọ̀nà àrà míì tó tún ń gbà ṣe ayé láǹfààní ni pé ó máa ń jẹ́ kí omi yí po nínú ayé. Lójoojúmọ́, omi tí oòrùn ń fà sókè látinú àwọn òkun fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tírílíọ̀nù méje (7,000,000,000,000) dúrọ́ọ̀mù. Omi tó fà sókè yìí á di ìkùukùu, afẹ́fẹ́ á sì tú u ká sójú ọ̀run. Láàárín àkókò yìí, ohun àrà kan á ti ṣẹlẹ̀ tó máa yọ ìdọ̀tí kúrò nínú omi náà. Omi tó mọ́ lóló á wá rọ̀ bí òjò, yìnyín tàbí ìrì. Bí Oníwàásù 1:7 ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Gbogbo odò ló ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n ń pa dà sí, kí wọ́n tún lè ṣàn jáde.” Ẹ ò rí i pé ọ̀nà àrà gbáà ni Jèhófà gbà ṣètò bí omi ṣe ń yí po nínú ayé!
13. Báwo làwọn ewéko àti ilẹ̀ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba?
13 Kò síbi tá a yíjú sí láyé yìí tá ò ní rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀ nínú àwọn nǹkan àrà tó dá, irú bí àwọn igi ńláńlá bí igi sequoia tó máa ń ga ju ilé tó ní ọgbọ̀n àjà, títí dórí àwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú òkun tó jẹ́ pé àwọn ló ń pèsè èyí tó pọ̀ jù lára afẹ́fẹ́ oxygen tá à ń mí sínú. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu ló wà nínú ilẹ̀, lára wọn ni àwọn kòkòrò, olú àtàwọn nǹkan tín-tìn-tín míì tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà àrà káwọn ewéko lè máa hù kí wọ́n sì máa dàgbà. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé ilẹ̀ ní agbára.—Jẹ́nẹ́sísì 4:12, àlàyé ìsàlẹ̀.
14. Báwo ni ohun bíńtín kan tí wọ́n ń pè ní átọ́ọ̀mù ṣe lágbára tó?
14 Ó hàn kedere pé Jèhófà ni “Aṣẹ̀dá ayé,” “agbára rẹ̀” ló sì fi dá a. (Jeremáyà 10:12) Kódà, a rí ọwọ́ agbára rẹ̀ nínú àwọn nǹkan tín-tìn-tín tó dá. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá to mílíọ̀nù kan átọ́ọ̀mù jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, gbogbo ẹ̀ ò lè nípọn tó ọ̀kan ṣoṣo lára irun orí àwa èèyàn. Síbẹ̀, ohun bíńtín tó wà láàárín átọ́ọ̀mù yìí ni wọ́n fi ń ṣe bọ́ǹbù tó lágbára gan-an tó lè ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́!
“Gbogbo Ohun Tó Ń Mí”
15. Kí ni Jèhófà fẹ́ kọ́ Jóòbù nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko tó lágbára?
15 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba ni oríṣiríṣi àwọn ẹranko tó wà láyé. Sáàmù 148 sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi àwọn nǹkan tó ń yin Jèhófà, ẹsẹ kẹwàá mẹ́nu kan ‘ẹranko igbó àtàwọn ẹran ọ̀sìn.’ Nígbà kan tí Jèhófà ń kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ̀ pé òun tóbi lọ́ba, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko bíi kìnnìún, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, akọ màlúù igbó, Béhémótì (tàbí erinmi) àti Léfíátánì (tàbí ọ̀nì). Ìdí tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko yìí ni pé ó fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé táwa èèyàn bá lè máa bẹ̀rù àwọn ẹranko tó lágbára yìí, ó yẹ ká bẹ̀rù ẹni tó dá wọn ju bá a ṣe bẹ̀rù wọn lọ.—Jóòbù orí 38 sí 41.
16. Kí ló wú ẹ lórí nípa àwọn ẹyẹ tí Jèhófà dá?
16 Sáàmù 148:10 tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ẹyẹ abìyẹ́.” Ronú nípa oríṣiríṣi ẹyẹ tó wà láyé! Jèhófà sọ fún Jóòbù pé ògòǹgò ń “fi ẹṣin àti ẹni tó gùn ún rẹ́rìn-ín.” Ẹyẹ yìí ga dé àtẹ́rígbà ilé, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò lè fò, àmọ́ láàárín wákàtí kan, ó lè sáré dé ibi tó jìn tó kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta (65). Kódà tó bá ń sáré, ìṣísẹ̀ rẹ̀ kan ṣoṣo tó mítà mẹ́rin ààbọ̀! (Jóòbù 39:13, 18) Ní ti ẹyẹ albatross, inú afẹ́fẹ́ ojú òkun ló ti ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú ọjọ́ ayé ẹ̀. Ìyẹ́ apá ẹ̀ gùn tó mítà mẹ́ta, ó máa ń na ìyẹ́ náà lọ́nà tí afẹ́fẹ́ á fi máa tì í lọ síwájú. Torí náà, ó lè fò ní ọ̀pọ̀ wákàtí láìju ìyẹ́ rárá. Àmọ́, ẹyẹ akùnyùnmù yàtọ̀ ní tiẹ̀, òun ni ẹyẹ tó kéré jù lọ láyé, kò gùn ju páálí ìṣáná kékeré lọ, ṣe ló sì ń dán gbinrin bí òkúta iyebíye. Ó máa ń ju ìyẹ́ apá rẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rin (80) ìgbà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo! Tí ẹyẹ yìí bá wà lójú òfúrufú, ó lè máa ju ìyẹ́ ẹ̀ lójú kan, ó sì lè fò sẹ́yìn bíi ti hẹlikọ́pítà.
17. Báwo ni ẹja àbùùbùtán ṣe tóbi tó, kí ló sì yẹ ká ṣe tá a bá ronú nípa àwọn ẹranko tí Jèhófà dá?
17 Sáàmù 148:7 sọ pé àwọn ‘ẹ̀dá inú òkun’ náà ń yin Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ẹja àbùùbùtán. Òun ló tóbi jù nínú gbogbo ẹ̀dá inú òkun àti ẹranko orí ilẹ̀. Inú “ibú omi” ni ẹja yìí ń gbé, ká sọ pé ó lè dúró, ó máa ga tó ilé alájà mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó wúwo tó ọgbọ̀n (30) erin. Ahọ́n rẹ̀ lásán wúwo tó odindi erin kan. Ọkàn rẹ̀ tóbi tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan, ìgbà mẹ́sàn-án péré ló sì máa ń lù kìkì láàárín ìṣẹ́jú kan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọkàn ẹyẹ akùnyùnmù máa ń lù kìkì tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) ìgbà láàárín ìṣẹ́jú kan péré. Ó kéré tán, ọ̀kan nínú òpó ẹ̀jẹ̀ ẹja àbùùbùtán fẹ̀ débi pé ọmọ kékeré lè rá kòrò nínú ẹ̀. Tá a bá ronú lórí àwọn nǹkan àgbàyanu yìí, ó dájú pé àwa náà á fẹ́ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó parí ìwé Sáàmù, èyí tó sọ pé: “Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà.”—Sáàmù 150:6.
Ohun Tá A Kọ́ Látara Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá
18, 19. Kí lo lè sọ nípa oríṣiríṣi ohun alààyè tí Jèhófà dá sí ayé, kí sì ni ìṣẹ̀dá jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?
18 Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà dá kọ́ wa nípa rẹ̀? Onírúurú nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ ò láfiwé. Onísáàmù kan sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! . . . Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.” (Sáàmù 104:24) Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn! Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè tó wà láyé ju mílíọ̀nù kan lọ, àmọ́ àwọn míì gbà pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa. Rò ó wò ná, oníṣẹ́ ọnà kan ti lè fi iṣẹ́ ọnà dá oríṣiríṣi àrà débi tó fi lè máa wò ó pé kò sí àrà tóun tún lè fi iṣẹ́ ọnà dá mọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, agbára àti ọgbọ́n rẹ̀ ò lópin, torí náà kò lè dá gbogbo àrà tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ tán láé.
19 Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé òun nìkan ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ó yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo àwọn nǹkan tó kù láyé àtọ̀run. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé “àgbà òṣìṣẹ́” ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà nígbà tí Jèhófà ń dá gbogbo nǹkan, síbẹ̀ Bíbélì ò sọ pé Ẹlẹ́dàá ni, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé ńṣe ni òun àti Ọlọ́run jọ jẹ́ Ẹlẹ́dàá. (Òwe 8:30; Mátíù 19:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì pè é ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Torí náà, bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ló fi agbára rẹ̀ dá gbogbo nǹkan láyé àtọ̀run, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.—Róòmù 1:20; Ìfihàn 4:11.
20. Kí ló túmọ̀ sí pé Jèhófà sinmi ní ọjọ́ keje?
20 Ṣé Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti dá àwọn nǹkan sáyé? Rárá o. Nígbà tí Jèhófà parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ọjọ́ kẹfà, Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ tó ti ń ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “ọjọ́” keje yìí gùn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, torí ó sọ pé ó ṣì ń bá a lọ nígbà ayé òun. (Hébérù 4:3-6) Ṣé bí Jèhófà ṣe “sinmi” yìí wá túmọ̀ sí pé kò ṣiṣẹ́ mọ́ rárá ni? Rárá o, Jèhófà ò fìgbà kan dáwọ́ iṣẹ́ dúró o. (Sáàmù 92:4; Jòhánù 5:17) Ohun tí ìsinmi yẹn túmọ̀ sí ni pé Jèhófà ò dá nǹkan kan sáyé mọ́. Àmọ́, ó ṣì ń bá a lọ láti ṣe ohun tó máa mú káwọn nǹkan tó ní lọ́kàn ṣẹ. Lára wọn ni bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́, tó sì ń ṣètò àwọn kan tí Bíbélì pè ní “ẹ̀dá tuntun.” A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá tuntun yìí ní Orí 19.—2 Kọ́ríńtì 5:17.
21. Àǹfààní wo ni agbára tí Jèhófà fi ń dá nǹkan máa ṣe àwọn olóòótọ́ èèyàn títí ayé?
21 Tí ọjọ́ ìsinmi Jèhófà bá ti parí, Jèhófà máa lè sọ pé gbogbo iṣẹ́ tóun ṣe láyé “dára gan-an,” gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ nígbà tó parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ní ọjọ́ kẹfà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Torí pé agbára tí Jèhófà ní láti ṣẹ̀dá kò lópin, ó ṣeé ṣe kó ṣì lo agbára rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan míì nígbà yẹn. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ó dájú pé títí láé ni agbára tí Jèhófà fi ń dá nǹkan á máa jọ wá lójú, táá sì máa múnú wa dùn. Títí ayé la ó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà látara àwọn nǹkan tó dá. (Oníwàásù 3:11) Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó tóbi lọ́ba lóòótọ́, èyí á sì mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn.
a Báwo ni ayé ṣe jìnnà sí oòrùn tó? Jẹ́ ká wò ó báyìí náà: Ká sọ pé ẹnì kan fẹ́ wa mọ́tò láti ayé lọ síbi tí oòrùn wà, tẹ́ni náà bá tiẹ̀ ń sáré ní ìwọ̀n ọgọ́jọ (160) kìlómítà láàárín wákàtí kan, tó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìdúró rárá, ó máa lò ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà kó tó lè débẹ̀!
b Àwọn kan rò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ń gbé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ní ohun kan tí wọ́n fi ń wo ohun tó wà lọ́nà tó jìn. Wọ́n ní láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe mọ̀ pé àìmọye ìràwọ̀ ló ṣì wà lójú ọ̀run téèyàn ò lè fojú rí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ro ti Jèhófà mọ́ ọn, wọn kì í rántí pé òun ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì.—2 Tímótì 3:16.
c Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí wàá fi ka ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìràwọ̀ tán? Ká sọ pé ńṣe lò ń ka ìràwọ̀ kan ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, tó o sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún tó wà nínú ọjọ́ kan láìdúró, ó máa gbà ẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mọ́kànléláàádọ́sàn-án (3,171) ọdún kó o tó kà á tán!
-
-
Agbára Ìparun—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 6
Agbára Ìparun—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”
1-3. (a) Inú ewu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì? (b) Kí ni Jèhófà ṣe láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là?
ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì wà láàárín gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti òkun kan tí kò ṣeé rọ́ lù. Àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tún ń lé wọn bọ̀ lẹ́yìn. Òǹrorò làwọn ọmọ ogun náà, ṣe ni wọ́n sì fẹ́ pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run.a Síbẹ̀, Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má sọ̀rètí nù. Ó sọ fún wọn pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ máa jà fún yín.”—Ẹ́kísódù 14:14.
2 Síbẹ̀, Mósè ṣì ké pe Jèhófà, Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ké pè mí? . . . Mú ọ̀pá rẹ, kí o na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà.” (Ẹ́kísódù 14:15, 16) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì rẹ̀, ọwọ̀n ìkùukùu tó wà níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ sẹ́yìn wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìkùukùu náà dà bí ògiri, kíyẹn sì dí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjà. (Ẹ́kísódù 14:19, 20; Sáàmù 105:39) Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀. Ẹ̀fúùfù líle wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́, ó sì pín òkun náà níyà. Ó gbá omi náà jọ sí ọ̀tún àti sí òsì bí ògiri, ó sì dúró bí omi tó dì. Àlàfo tó wà láàárín ẹ̀ fẹ̀ débi pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbabẹ̀ kọjá!—Ẹ́kísódù 14:21; 15:8.
3 Nígbà tí Fáráò rí gbogbo nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ yìí, ṣebí ńṣe ló yẹ kó sọ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n pa dà sílé. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o, kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé agbéraga ni, ṣe ló pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n máa lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 14:23) Báwọn ará Íjíbítì ṣe tẹ̀ lé wọn gba ọ̀nà tó wà láàárín òkun náà nìyẹn, àmọ́ wọn ò tíì rìn jìnnà tí nǹkan fi yíwọ́. Àgbá kẹ̀kẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn. Lẹ́yìn tí Jèhófà rí i pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò nínú òkun náà, ó sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè pa dà, kó sì bo àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti àwọn agẹṣin wọn.” Ni omi tó dúró bí ògiri yẹn bá ya wálẹ̀, ó sì bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀!—Ẹ́kísódù 14:24-28; Sáàmù 136:15.
4. (a) Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn kan tí wọ́n bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ jagunjagun tó lágbára?
4 Bí Jèhófà ṣe gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì là ní Òkun Pupa kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Ó jẹ́ ká rí i pé “jagunjagun tó lágbára” ni Jèhófà. (Ẹ́kísódù 15:3) Àmọ́, báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ̀ pé jagunjagun ni Jèhófà? Torí pé ogun ti fìyà jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn, tó sì ti mú kí nǹkan nira fún wọn, èyí lè mú káwọn kan máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní jagunjagun tó lágbára. Àmọ́, ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ó máa ń fi agbára ẹ̀ jagun nígbà míì?
Ní Òkun Pupa, Jèhófà fi hàn pé “jagunjagun tó lágbára” lòun jẹ́
Ogun Tí Ọlọ́run Ń Jà Yàtọ̀ sí Tàwa Èèyàn
5, 6. (a) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti pe Ọlọ́run ní “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun”? (b) Kí ló mú kí ogun tí Ọlọ́run ń jà yàtọ̀ sí tàwa èèyàn?
5 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgọ́rin (280) ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pe Ọlọ́run ní “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,” ìgbà méjì ló sì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. (1 Sámúẹ́lì 1:11) Torí pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, àìmọye àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì pè ní ọmọ ogun ló wà níkàáwọ́ ẹ̀. (Jóṣúà 5:13-15; 1 Àwọn Ọba 22:19) Àwọn ọmọ ogun yìí lágbára gan-an débi pé wọ́n lè pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Àìsáyà 37:36) Lóòótọ́, inú wa kì í dùn tá a bá gbọ́ pé àwọn kan pa run. Àmọ́, ó yẹ ká rántí pé ogun tí Ọlọ́run ń jà yàtọ̀ sí tàwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun àtàwọn aṣáájú olóṣèlú máa ń sọ pé torí kí nǹkan lè dáa làwọn fi ń jagun. Àmọ́, tá a bá wádìí ẹ̀ wò, àá rí i pé ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú kí wọ́n jagun.
6 Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwa èèyàn, ó máa ń ronú dáadáa kó tó ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Diutarónómì 32:4 sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni.” Bíbélì tún sọ pé ìwà ìkà àti ìwà ipá ò dáa, kò sì yẹ kéèyàn máa bínú sódì. (Jẹ́nẹ́sísì 49:7; Sáàmù 11:5) Torí náà, Jèhófà kì í jagun láìnídìí. Kì í dédé pa àwọn èèyàn run, ìgbà tọ́ràn bá dójú ẹ̀ tán ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ó sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé: “ ‘Ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn sí ikú ẹni burúkú?’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó sì máa wà láàyè?’ ”—Ìsíkíẹ́lì 18:23.
7, 8. (a) Èrò wo ni Jóòbù ní nípa ìyà tó ń jẹ ẹ́? (b) Báwo ni Élíhù ṣe tún èrò Jóòbù ṣe? (d) Kí la rí kọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?
7 Kí wá nìdí tí Jèhófà fi ń lo agbára rẹ̀ láti pa àwọn èèyàn run? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù àtàwa èèyàn lápapọ̀, ó sọ pé a ò lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tá a bá dojú kọ àdánwò. Báwo ni Jèhófà ṣe wá dá sí ọ̀rọ̀ náà? Ó gbà kí Sátánì dán Jóòbù wò. Nípa bẹ́ẹ̀, Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tó le gan-an, ó pàdánù gbogbo ohun tó ní, àwọn ọmọ ẹ̀ sì tún kú. (Jóòbù 1:1–2:8) Torí pé Jóòbù ò mọ ohun tó fa ìṣòro náà, ó gbà pé ńṣe ni Ọlọ́run kàn ń fìyà jẹ òun láìnídìí. Ó wá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí nìdí tó fi “dájú sọ” òun, tó sì ka òun sí “ọ̀tá.”—Jóòbù 7:20; 13:24.
8 Èrò Jóòbù yìí ò tọ̀nà, ìdí nìyẹn tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù fi tún èrò ẹ̀ ṣe. Ó bi í pé: “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?” (Jóòbù 35:2) Òótọ́ ni, kò bọ́gbọ́n mu ká máa rò pé a mọ̀ ju Ọlọ́run lọ tàbí ká máa ronú pé kò ṣe ohun tó tọ́. Élíhù sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” Ó tún sọ pé: “Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè; agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an, kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.” (Jóòbù 34:10; 36:22, 23; 37:23) Torí náà, ó dá wa lójú pé tí Ọlọ́run bá jagun, ó máa ní ìdí pàtàkì tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìdí tí Ọlọ́run àlàáfíà fi máa ń jagun nígbà míì.—1 Kọ́ríńtì 14:33.
Ìdí Tí Ọlọ́run Àlàáfíà Fi Máa Ń Jagun
9. Kí nìdí tí Ọlọ́run mímọ́ fi máa ń jagun?
9 Lẹ́yìn tí Mósè pe Ọlọ́run ní “jagunjagun tó lágbára,” ó wá sọ pé: “Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run? Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?” (Ẹ́kísódù 15:11) Bákan náà, wòlíì Hábákúkù sọ pé: “Ojú rẹ ti mọ́ jù láti wo ohun búburú, ìwọ kò sì ní gba ìwà burúkú láyè.” (Hábákúkù 1:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó tún jẹ́ Ọlọ́run mímọ́, olódodo àti onídàájọ́ òdodo. Àwọn ìwà àti ìṣe yìí ló máa ń mú kó fi agbára rẹ̀ pani run nígbà míì. (Àìsáyà 59:15-19; Lúùkù 18:7) Torí náà tí Ọlọ́run bá jagun, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kì í ṣe Ọlọ́run mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run mímọ́ gangan ló ń mú kó jagun. —Ẹ́kísódù 39:30.
10. Kí lohun kan ṣoṣo tó máa fòpin sí ìkórìíra tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́, báwo nìyẹn sì ṣe máa ṣe àwọn olódodo láǹfààní?
10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí tọkọtaya àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ká sọ pé Jèhófà ò ṣe nǹkan nípa ìwà àìṣòdodo tí wọ́n hù ni, Jèhófà ò ní fi hàn pé òun lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó di dandan pé kó dájọ́ ikú fáwọn ọlọ̀tẹ̀ náà. (Róòmù 6:23) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì, ó sọ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa di ọ̀tá àwọn alátìlẹyìn “ejò” náà, ìyẹn Sátánì. (Ìfihàn 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Jèhófà sì mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé kí Sátánì pa run. (Róòmù 16:20) Àmọ́ ìparun yẹn máa ṣe àwọn olódodo láǹfààní gan-an, torí pé ó máa fòpin sí gbogbo wàhálà tí Sátánì ti fà, ìyẹn á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti gbádùn ayé nínú Párádísè. (Mátíù 19:28) Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, àwọn alátìlẹ́yìn Sátánì á máa ta ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n á máa ṣenúnibíni sí wọn, wọ́n á sì máa gbìyànjú láti pa wọ́n run. Torí náà, àtìgbàdégbà ló máa ń di dandan pé kí Jèhófà jà nítorí àwọn èèyàn ẹ̀.
Ọlọ́run Jà Kó Lè Mú Ìwà Ibi Kúrò
11. Kí nìdí tó fi di dandan kí Ọlọ́run mú ìkún omi wá sórí gbogbo ayé?
11 Ọ̀kan lára ìgbà tí Ọlọ́run rí i pé ó yẹ kóun jà ni ìgbà ayé Nóà. Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 12 sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́; ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara ń hù ní ayé.” Ṣé Ọlọ́run á wá gbà káwọn oníwà ipá àtàwọn oníṣekúṣe yẹn pa ìwọ̀nba èèyàn rere tó kù sáyé run ni? Rárá o. Jèhófà rí i pé ó di dandan kóun fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú náà run.
12. (a) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé òun máa pa àwọn Ámórì run?
12 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti pa àwọn ọmọ Kénáánì run. Jèhófà ti ṣèlérí fún Ábúráhámù pé nípasẹ̀ ọmọ ẹ̀ ni gbogbo ìdílé ayé máa gba ìbùkún fún ara wọn. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run sọ pé òun máa fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní ilẹ̀ Kénáánì, ibi táwọn ọmọ Ámórì ń gbé. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe é tó fi máa jàre tó bá fipá lé àwọn èèyàn yẹn jáde kúrò ní ilẹ̀ wọn? Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé òun ò ní lé wọn jáde títí di nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún sí ìgbà yẹn, ìyẹn títí di ìgbà tí “ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ámórì” fi máa “kún rẹ́rẹ́.”b (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; 13:14, 15; 15:13, 16; 22:18) Láàárín àkókò yìí, kàkà kí wọ́n yí pa dà, ńṣe ni ìwà ìbàjẹ́ àwọn Ámórì ń pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n ń pa èèyàn, wọ́n sì ń ṣe ìṣekúṣe tó burú gan-an. (Ẹ́kísódù 23:24; 34:12, 13; Nọ́ńbà 33:52) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tú ń sun àwọn ọmọ wọn nínú iná láti fi rúbọ. Ṣé Ọlọ́run mímọ́ á wá gbà kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa gbé láàárín àwọn èèyàn burúkú yìí? Rárá o! Ọlọ́run sọ pé: “Ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, màá fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ jáde.” (Léfítíkù 18:21-25) Ṣé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ni Jèhófà máa pa run? Rárá. Ó dá àwọn tó ní ọkàn tó dáa lára àwọn ọmọ Kénáánì sí, irú bíi Ráhábù àtàwọn ará Gíbéónì.—Jóṣúà 6:25; 9:3-27.
Ó Ń Jà Nítorí Orúkọ Rẹ̀
13, 14. (a) Kí nìdí tó fi di dandan kí Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
13 Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, orúkọ rẹ̀ náà jẹ́ mímọ́. (Léfítíkù 22:32) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: ‘Kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́.’ (Mátíù 6:9) Nígbà tí Ádámù àti Éfà tẹ́tí sí Sátánì, tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì, ńṣe ni wọ́n ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tí wọ́n sì dọ́gbọ́n sọ pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso ò dáa. Irú nǹkan báyìí ò lè ṣẹlẹ̀ kí Jèhófà má ṣe nǹkan sí i, ó dájú pé ó máa mú ẹ̀gàn tí wọ́n mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò.—Àìsáyà 48:11.
14 Tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé máa gba ìbùkún fún ara wọn. Ká ní Jèhófà ò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní oko ẹrú, ó lè jọ pé ìlérí yẹn ò ní ṣẹ. Àmọ́, Jèhófà gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, ó sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè, ìyẹn sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀. Abájọ tí wòlíì Dáníẹ́lì fi sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Ìwọ tí o fi ọwọ́ agbára mú àwọn èèyàn rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí o sì ṣe orúkọ fún ara rẹ.”—Dáníẹ́lì 9:15.
15. Kí nìdí tí Jèhófà fi mú àwọn Júù kúrò nígbèkùn Bábílónì?
15 Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé, nígbà tí Dáníẹ́lì gbàdúrà yìí, àwọn Júù ń retí pé kí Jèhófà gba àwọn sílẹ̀ kó lè mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀. Lásìkò yẹn, àwọn Júù wà nígbèkùn ní Bábílónì torí pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn ti di ahoro. Dáníẹ́lì mọ̀ pé tí Jèhófà bá mú àwọn Júù pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn á mú ògo bá orúkọ rẹ̀. Torí náà, Dáníẹ́lì gbàdúrà pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì. Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”—Dáníẹ́lì 9:18, 19.
Ó Ń Jà Nítorí Àwọn Èèyàn Rẹ̀
16. Ṣé bí Jèhófà ṣe fẹ́ràn láti máa gbèjà orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí pé aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan ni? Ṣàlàyé.
16 Torí pé Jèhófà fẹ́ràn láti máa gbèjà orúkọ rẹ̀, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan ni? Rárá o. Kì í ṣe torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ tó sì nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo nìkan ló fi máa ń jà, ó tún máa ń jà kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Jẹ́ ká wo ohun tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì orí kẹrìnlá. Orí yẹn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba mẹ́rin tó gbógun ja ìlú Sódómù àti Gòmórà, tí wọ́n sì mú Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lẹ́rú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá náà lágbára ju Ábúráhámù lọ, Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun wọn! Ó jọ pé ìtàn bí Jèhófà ṣe ran Ábúráhámù lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yìí ni wọ́n kọ́kọ́ kọ sínú “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà,” ìyẹn ìwé kan tó ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn ogun míì tí Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Nọ́ńbà 21:14) Ọ̀pọ̀ ogun làwọn èèyàn Jèhófà tún jà tí wọ́n sì ṣẹ́gun lẹ́yìn ìyẹn.
17. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì? Sọ àpẹẹrẹ kan.
17 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, Mósè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín máa lọ níwájú yín, ó sì máa jà fún yín, bó ṣe jà fún yín ní Íjíbítì tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.” (Diutarónómì 1:30; 20:1) Jèhófà sì jà fáwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́, torí ó mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ayé Jóṣúà tó rọ́pò Mósè àtìgbà ayé àwọn Onídàájọ́, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìṣàkóso àwọn ọba Júdà tó jẹ́ olóòótọ́.—Jóṣúà 10:1-14; Àwọn Onídàájọ́ 4:12-17; 2 Sámúẹ́lì 5:17-21.
18. (a) Kí nìdí tọ́kàn wa fi balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò yí pa dà? (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe nígbà táwọn alátìlẹyìn Sátánì bá dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó rorò gan-an?
18 Jèhófà ò tíì yí pa dà; bẹ́ẹ̀ ni ohun tó ní lọ́kàn pé kí ayé yìí di Párádísè kò tíì yí pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ọlọ́run ṣì kórìíra ìwà ibi. Àmọ́, ó fẹ́ràn àwọn èèyàn ẹ̀ gan-an, ó sì máa jà fún wọn láìpẹ́. (Sáàmù 11:7) Kódà, ìkórìíra tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ máa le sí i láìpẹ́ débi pé àwọn alátìlẹyìn Sátánì á dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó rorò gan-an. Àmọ́, Jèhófà máa fi hàn pé “jagunjagun tó lágbára” lòun lẹ́ẹ̀kan sí i, kó lè sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ kó sì dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀!—Sekaráyà 14:3; Ìfihàn 16:14, 16.
19. (a) Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ó ń fi agbára ẹ̀ pa àwọn èèyàn burúkú run? Sọ àpèjúwe kan. (b) Báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ń fẹ́ láti jà fún wa?
19 Wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé ẹranko búburú kan yọ sí ìdílé ọkùnrin kan, ọkùnrin náà wá dojú kọ ẹranko yìí, ó bá a jà, ó sì pa á. Ṣé o rò pé ohun tí ọkùnrin náà ṣe á mú kí ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa bẹ̀rù ẹ̀? Rárá o, ńṣe ni wọ́n máa mọyì bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó sì dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Jèhófà torí pé ó ń fi agbára ẹ̀ pa àwọn èèyàn burúkú run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí pé ó ń dáàbò bò wá. Ó sì yẹ ká túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé agbára rẹ̀ kò lópin. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè máa “ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀.”—Hébérù 12:28.
Sún Mọ́ Jèhófà Tó Jẹ́ “Jagunjagun Tó Lágbára”
20. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ka ìtàn Bíbélì kan nípa ogun tí Ọlọ́run jà, tá ò sì mọ ìdí tó fi ja ogun náà? Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
20 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Bíbélì máa ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdí tí Jèhófà fi pinnu láti ja àwọn ogun kan. Àmọ́, ó yẹ kó dá wa lójú pé: Jèhófà kì í jagun torí kó lè fi ṣèkà tàbí torí pé agbára ń gùn ún, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Torí náà, tá a bá ka ìtàn kan nínú Bíbélì, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ìtàn náà kí ìtàn náà lè yé wa dáadáa. (Òwe 18:13) Tá ò bá tiẹ̀ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan, tá a bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá a sì ń ronú lórí àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀, a ò ní ṣiyèméjì mọ́, àá sì rí i pé ó yẹ ká fọkàn tán Jèhófà Ọlọ́run wa.—Jóòbù 34:12.
21. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń di “jagunjagun tó lágbára” nígbà míì, kí làwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?
21 A ti rí i pé “jagunjagun tó lágbára” ni Jèhófà torí ó máa ń jà nígbà tó bá rí i pé ó di dandan kóun ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ràn láti máa jagun. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run, ìrísí Jèhófà dà bíi tẹnì kan tó múra ogun láti bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà. Àmọ́, Ìsíkíẹ́lì tún rí òṣùmàrè tó yí Jèhófà ká, bẹ́ẹ̀ sì rèé àmì àlàáfíà ni òṣùmàrè. (Jẹ́nẹ́sísì 9:13; Ìsíkíẹ́lì 1:28; Ìfihàn 4:3) Èyí fi hàn pé ọlọ́kàn tútù àti ẹni àlàáfíà ni Jèhófà jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà ló máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà tó pé pérépéré. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní, pé a lè sún mọ́ Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ ò lópin, síbẹ̀ tó tún jẹ́ onífẹ̀ẹ́!
a Nígbà tí òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pọ̀ tó, ó sọ pé “wọ́n ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn tó ń gun ẹṣin lára wọn tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000), wọ́n sì ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200,000) ọmọ ogun tó di ìhámọ́ra.”—Jewish Antiquities, Apá Kejì, ojú ìwé 324 [xv, 3].
b Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn èèyàn Kénáánì lápapọ̀ ni Bíbélì pè ní “àwọn Ámórì.”—Diutarónómì 1:6-8, 19-21, 27; Jóṣúà 24:15, 18.
-
-
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 7
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
1, 2. Inú ewu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà bí wọ́n ṣe ń wọ agbègbè ilẹ̀ Sínáì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
INÚ ewu làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà bí wọ́n ṣe ń wọ agbègbè ilẹ̀ Sínáì níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìrìn àjò náà ò lè rọrùn rárá, torí wọ́n ní láti gba inú “aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù, tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé.” (Diutarónómì 8:15) Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lójú ọ̀nà tún kórìíra wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbéjà kò wọ́n. Jèhófà Ọlọ́run wọn ló ní kí wọ́n rin ìrìn àjò yẹn. Ṣé ó máa lè dáàbò bò wọ́n?
2 Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an, ó ní: “Ẹ ti fojú ara yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì, kí n lè fi àwọn ìyẹ́ idì gbé yín wá sọ́dọ̀ ara mi.” (Ẹ́kísódù 19:4) Jèhófà sọ pé òun gbé wọn bíi ti ẹyẹ idì kó lè rán wọn létí pé òun lòun gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, tóun sì gbé wọn dé ibi ààbò. Àmọ́, àwọn ìdí míì tún wà tó fi bá a mu bí Jèhófà ṣe fi “ìyẹ́ idì” ṣàpèjúwe bóun ṣe ń dáàbò boni.
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi fi “ìyẹ́ idì” ṣàpèjúwe bóun ṣe ń dáàbò boni?
3 Ẹyẹ idì máa ń fi ìyẹ́ rẹ̀ fò, ó sì máa ń fi ṣe àwọn nǹkan míì. Téèyàn bá wọn ìyẹ́ apá ẹyẹ idì láti apá kan sí ìkejì, ó máa ń gùn tó èèyàn tó ga dáadáa. Nígbà tí oòrùn bá mú gan-an, abo idì máa na ìyẹ́ apá ẹ̀ láti fi ṣíji bo àwọn ọmọ ẹ̀ kéékèèké kúrò lọ́wọ́ oòrùn tó gbóná gan-an. Ó tún máa ń fi ìyẹ́ apá ẹ̀ bo àwọn ọmọ ẹ̀ nígbà òtútù, kí ara wọn lè móoru. Bí ẹyẹ idì ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di orílẹ̀-èdè. Ní báyìí tí wọ́n ti wà nínú aginjù, Jèhófà á ṣì máa dáàbò bò wọ́n bíi pé wọ́n wà lábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, ìyẹn tí wọ́n bá ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Diutarónómì 32:9-11; Sáàmù 36:7) Ṣé àwa náà lè retí pé kí Ọlọ́run dáàbò bò wá?
Jèhófà Ṣèlérí Pé Òun Máa Dáàbò Bo Àwọn Ìránṣẹ́ Òun
4, 5. Kí nìdí tá a fi lè gbọ́kàn lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa dáàbò bò wá?
4 Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bíbélì pè é ní “Ọlọ́run Olódùmarè,” orúkọ yìí sì fi hàn pé kò sẹ́ni tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ní lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Agbára Jèhófà ò láàlà, kò sì sóhun tó lè dá a dúró. Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú, a lè béèrè pé, ‘Ṣé ó wu Jèhófà láti fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?’
5 Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Sáàmù 46:1 sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.” Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ‘ò lè parọ́,’ torí náà a lè gbọ́kàn lé ìlérí tó ṣe pé òun máa dáàbò bò wá. (Títù 1:2) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àpèjúwe tí Jèhófà lò láti jẹ́ ká mọ bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.
6, 7. (a) Kí làwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń ṣe láti dáàbò bo àwọn àgùntàn wọn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé ó wù ú kó dáàbò bò wá?
6 Jèhófà fi ara ẹ̀ wé Olùṣọ́ Àgùntàn, ó sì pè wá ní “èèyàn rẹ̀ àti àgùntàn ibi ìjẹko rẹ̀.” (Sáàmù 23:1; 100:3) Àwọn àgùntàn ò lè dáàbò bo ara wọn rárá. Torí náà, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní láti jẹ́ onígboyà kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn àgùntàn wọn lọ́wọ́ kìnnìún, ìkookò, béárì àtàwọn olè. (1 Sámúẹ́lì 17:34, 35; Jòhánù 10:12, 13) Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tó máa gba pé kí olùṣọ́ àgùntàn ṣe àwọn àgùntàn jẹ́jẹ́ kó lè dáàbò bò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan kì í sábà rọrùn fún àgùntàn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ní pàtàkì tí ibi tó bímọ sí bá jìnnà síbi táwọn tó kù wà. Nírú àsìkò yìí, olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ á rọra máa bójú tó àgùntàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ náà, á sì gbé ọmọ ẹ̀ lọ síbi táwọn tó kù wà.
“Ó . . . máa gbé wọn sí àyà rẹ̀”
7 Nígbà tí Jèhófà fi ara ẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ńṣe ló fẹ́ ká mọ̀ dájú pé ó wu òun pé kóun dáàbò wá. (Ìsíkíẹ́lì 34:11-16) Ṣé o rántí ohun tí Àìsáyà 40:11 sọ nípa Jèhófà bá a ṣe jíròrò ẹ̀ ní Orí 2 ìwé yìí? Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” Báwo ni ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ṣe dé “àyà” olùṣọ́ àgùntàn náà, tó sì fi aṣọ ẹ̀ wé e? Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni àgùntàn yẹn lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn náà, bóyá kó tiẹ̀ máa forí nù ún lẹ́sẹ̀. Àmọ́, ó dájú pé olùṣọ́ àgùntàn yẹn fúnra ẹ̀ ló máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, táá sì gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà sí àyà rẹ̀ kó lè dáàbò bò ó. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé ó wu Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn wa láti bójú tó wa, kó sì dáàbò bò wá. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!
8. (a) Àwọn wo ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò, báwo ni Òwe 18:10 sì ṣe fi èyí hàn? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti fi orúkọ Ọlọ́run ṣe ààbò?
8 Àmọ́ o, àwọn tó bá sún mọ́ Jèhófà nìkan ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò. Òwe 18:10 sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń kọ́ ilé gogoro sínú aginjù káwọn èèyàn lè wá ààbò lọ síbẹ̀. Tí ẹni tó wà nínú ewu bá fẹ́ rí ààbò, ó ní láti sá lọ sínú ilé gogoro náà. Bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run nìyẹn, a lè fi ṣe ààbò. Àmọ́, ìyẹn kọjá pé ká kàn máa pe orúkọ náà léraléra, torí kì í ṣe oògùn ajẹ́bíidán. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti mọ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Inú rere Jèhófà mà pọ̀ o, ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé òun, òun máa di ilé gogoro tó lágbára fún wa, òun á sì dáàbò bò wá!
“Ọlọ́run Wa . . . Lè Gbà Wá Sílẹ̀”
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?
9 Jèhófà ṣe ju kó kàn ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé ó máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà fi “ọwọ́” agbára ńlá rẹ̀ gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó lágbára jù wọ́n lọ. (Ẹ́kísódù 7:4) Àmọ́, Jèhófà tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
10, 11. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta náà, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Nígbà tí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì ṣe, inú bí ọba náà, ó sì halẹ̀ mọ́ wọn pé òun máa jù wọ́n sínú iná ìléru tó gbóná gan-an. Nebukadinésárì ni ọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn, torí náà ó pẹ̀gàn Jèhófà, ó ní: “Ta . . . ni ọlọ́run tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ mi?” (Dáníẹ́lì 3:15) Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run wọn, ó sì dá wọn lójú pé ó lè dáàbò bò wọ́n, àmọ́ wọn ò sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ọba, Ọlọ́run wa tí à ń sìn lè gbà wá sílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:17) Lẹ́yìn ìyẹn, ọba ní kí wọ́n mú kí iná ìléru náà gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àmọ́ ìyẹn ò tó nǹkan kan rárá lójú Ọlọ́run wọn, torí pé agbára rẹ̀ ò ní ààlà. Ọlọ́run dáàbò bo àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn, ìyẹn sì ya ọba náà lẹ́nu débi tó fi sọ pé: “Kò sí ọlọ́run míì tó lè gbani là bí èyí.”—Dáníẹ́lì 3:29.
11 Jèhófà tún fi hàn pé òun lágbára láti dáàbò boni nígbà tó fi ẹ̀mí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. Áńgẹ́lì kan sọ fún Màríà pé: “O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan.” Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́.” (Lúùkù 1:31, 35) Ó dájú pé ẹ̀mí Ọmọ Ọlọ́run wà nínú ewu lásìkò yẹn. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí Màríà ti jogún ò ní kó àbààwọ́n bá a nígbà tó wà nínú ilé ọlẹ̀ náà? Ṣé Sátánì ò ní ṣe ọmọ náà ní jàǹbá tàbí kó tiẹ̀ pa á kí wọ́n tó bí i? Rárá o! Jèhófà dáàbò bo ọmọ náà ní gbogbo ìgbà tó fi wà nínú ikùn ìyá rẹ̀. Kò jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ṣèpalára fún un, ì báà jẹ́ àìpé, àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí àwọn tó gbìyànjú láti pa á. Jèhófà tún ń bá a lọ láti dúró ti Jésù bó ṣe ń dàgbà. (Mátíù 2:1-15) Ọlọ́run ń bá a lọ láti dáàbò bo Jésù látìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ títí dìgbà tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.
12. Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
12 Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ, torí pé ìyẹn lohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn ọ̀tá rí Jésù pa nígbà tó wà ní kékeré ni, ìfẹ́ Ọlọ́run pé káwọn èèyàn máa gbé ayé títí láé ò ní ṣẹ. A lè ka ìtàn nípa onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú Bíbélì. Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ìtàn náà “fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn àpẹẹrẹ yìí máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì ń jẹ́ ká fọkàn tán Ọlọ́run wa tí agbára rẹ̀ kò ní ààlà. Àmọ́ o, ṣé bí Ọlọ́run ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn náà ló ṣe máa dáàbò bò wá lónìí?
Ṣé Gbogbo Ìgbà Ni Ọlọ́run Máa Ń Dáàbò Bo Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀?
13. Ṣé ó pọn dandan kí Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ ìyanu torí tiwa? Ṣàlàyé.
13 Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò wá lóòótọ́, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu. Ọlọ́run ò ṣèlérí pé a ò ní níṣòro kankan nínú ayé yìí. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti dojú kọ àwọn ìṣòro tó le gan-an, irú bí àìlówó lọ́wọ́, ogun, àìsàn àti ikú. Jésù dìídì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa àwọn kan lára wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Torí náà, ó tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí wọ́n fara dà á dé òpin. (Mátíù 24:9, 13) Tí Jèhófà bá ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu ní gbogbo ìgbà, Sátánì máa pẹ̀gàn Jèhófà, á sọ pé ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà ló ń mú ká jọ́sìn rẹ̀ kì í ṣe torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ látọkànwá.—Jóòbù 1:9, 10.
14. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà kì í dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà kan náà?
14 Kódà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Jèhófà ò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n má bàa kú ikú òjijì. Bí àpẹẹrẹ, Hẹ́rọ́dù pa àpọ́sítélì Jémíìsì lọ́dún 44 Sànmánì Kristẹni, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni Ọlọ́run gba Pétérù sílẹ̀ “lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù.” (Ìṣe 12:1-11) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jòhánù arákùnrin Jémíìsì pẹ́ láyé ju Pétérù àti Jémíìsì lọ. Ó dájú pé a ò lè retí pé kí Ọlọ́run máa dáàbò bo gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà kan náà. Ó ṣe tán, gbogbo wa pátá ni “ìgbà àti èèṣì” ń ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:11) Báwo ni Jèhófà ṣe wá ń dáàbò bò wá lónìí?
Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tara
15, 16. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀? (b) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní báyìí àti nígbà “ìpọ́njú ńlá”?
15 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá tó sì ń dá ẹ̀mí wa sí. Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀. Rò ó wò ná: Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì tó jẹ́ “alákòóso ayé yìí” fi ń wá bó ṣe máa pa àwa ìránṣẹ́ Jèhófà run kó lè fòpin sí ìjọsìn mímọ́. Ká sọ pé Jèhófà ò dáàbò bò wá ni, Sátánì ì bá ti pa wá run. (Jòhánù 12:31; Ìfihàn 12:17) Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé ló ti ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù, tí wọ́n sì ti gbìyànjú láti pa wá run. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin sí i, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa fìgboyà wàásù! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà kéré, tá ò sì lágbára tó àwọn ìjọba ayé, kí nìdí táwọn ìjọba yẹn ò fi lè fòpin sí iṣẹ́ wa? Ìdí ni pé Jèhófà ń fi ìyẹ́ apá rẹ̀ tó lágbára dáàbò bò wá!—Sáàmù 17:7, 8.
16 Ṣé Jèhófà máa dáàbò bò wá nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ wá sórí àwọn ẹni burúkú. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun ní ọjọ́ ìdájọ́.” (Ìfihàn 7:14; 2 Pétérù 2:9) Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kí àwọn nǹkan méjì yìí máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Àkọ́kọ́, Jèhófà ò ní gbà kí Sátánì pa gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ run. Ìkejì, Jèhófà máa jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun. Táwọn kan lára wọn bá tiẹ̀ kú kí ayé tuntun yẹn tó dé, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ò ní gbàgbé wọn, ó máa jí wọn dìde.—Jòhánù 5:28, 29.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bò wá?
17 Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá ní báyìí ni pé ó ń fi “ọ̀rọ̀” rẹ̀ tù wá nínú, ó fi ń tún ayé wa ṣe, ìyẹn sì ń jẹ́ ká láyọ̀. (Hébérù 4:12) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, a ò ní máa ṣe àwọn nǹkan tó lè pa wá lára tàbí àwọn nǹkan tó lè ba ayé wa jẹ́. Àìsáyà 48:17 sọ pé: “Èmi, Jèhófà, . . . ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Ká sòótọ́, tá a bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé wa, ó lè mú kí ìlera wa dáa sí i, kí ẹ̀mí wa sì gùn. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká máa sá fún àgbèrè, ó tún ní ká wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin. Torí pé à ń fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò, a ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwà àìmọ́ àtàwọn ìwà burúkú míì tó ń bayé ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ torí pé wọn ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 15:29; 2 Kọ́ríńtì 7:1) A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bò wá!
Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tẹ̀mí
18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí?
18 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń dáàbò bò wá nípa tara, ó tún máa ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, èyí ló sì ṣe pàtàkì jù. Báwo ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ń gbà wá lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, ó sì ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa. Bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lọ́nà yìí ló máa jẹ́ ká lè wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an! Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.
19. Báwo ni ẹ̀mí Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àdánwò èyíkéyìí?
19 “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. (Sáàmù 65:2) Tó bá dà bíi pé ìṣòro wa fẹ́ kọjá agbára wa, tá a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un nínú àdúrà, ara máa tù wá. (Fílípì 4:6, 7) Jèhófà lè má ṣe iṣẹ́ ìyanu láti mú ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ó lè fún wa ní ọgbọ́n tá a máa fi bójú tó ìṣòro náà. (Jémíìsì 1:5, 6) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ní kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó máa fún wa. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára gan-an, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tá a bá ní. Ó lè fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa títí dìgbà tí Jèhófà fi máa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, ìyẹn nínú ayé tuntun tí kò ní pẹ́ dé mọ́.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
20. Báwo ni Jèhófà ṣe lè lo àwọn ará wa láti dáàbò bò wá?
20 Nígbà míì, Jèhófà máa ń lo àwọn tá a jọ ń sìn ín láti dáàbò bò wá. Lónìí, Ọlọ́run ń fa àwa èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ká lè máa sìn ín, ó sì sọ wá di ẹgbẹ́ “ará” tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. (1 Pétérù 2:17; Jòhánù 6:44) Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ló wà láàárín wa, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wa. Ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká láwọn ìwà tó dáa, irú bí ìfẹ́, inú rere àti ìwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tá a bá wà nínú ìṣòro, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà máa ń fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa tàbí kí wọ́n fún wa níṣìírí kí ara lè tù wá. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń lo àwọn ará wa láti dáàbò bò wá!
21. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń pèsè fún wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (b) Ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè láti fi dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí?
21 Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá ni pé ó máa ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kí wọ́n lè máa ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ẹrú yìí máa ń tẹ oríṣiríṣi ìwé kí wọ́n lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, lára wọn ni Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, wọ́n tún máa ń lo ìkànnì jw.org, àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti ti agbègbè láti fi pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tó yẹ,’ ìyẹn ni pé wọ́n ń pèsè àwọn ohun tá a nílò lásìkò. (Mátíù 24:45) Ṣé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan rí nípàdé ìjọ, tó fún ẹ lókun àti ìṣírí tó o nílò gẹ́lẹ́, bóyá nínú ìdáhùn ẹnì kan, àsọyé tàbí nínú àdúrà? Àbí ṣe lo ka àpilẹ̀kọ kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé wa tó ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an? Má gbàgbé pé Jèhófà ló ń fún wa láwọn nǹkan yìí kó lè dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí.
22. Kí ló máa ń mú kí Jèhófà fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
22 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ apata “fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.” (Sáàmù 18:30) Ní báyìí, Jèhófà kì í yọ wá nínú gbogbo ìṣòro. Àmọ́, ó máa ń fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà tó bá pọn dandan, kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe wá láǹfààní. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà tá a sì ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, Jèhófà máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé, àá sì ní ìlera pípé. Èyí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, torí a mọ̀ pé ńṣe làwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá ní báyìí wà ‘fún ìgbà díẹ̀, wọn ò sì lágbára’ tá a bá fi wọ́n wé àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.—2 Kọ́ríńtì 4:17.
-
-
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 8
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
1, 2. Àwọn nǹkan wo làwa èèyàn máa ń pàdánù, báwo nìyẹn sì ṣe máa ń rí lára wa?
FOJÚ inú wo ọmọ kékeré kan tó ń wá ohun ìṣeré ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an. Ó wá a títí, kò rí i, ló bá bú sẹ́kún. Ó sunkún débi pé àánú ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ́! Àmọ́, ká sọ pé bàbá tàbí ìyá ọmọ náà bá a rí ohun ìṣeré ẹ̀ tó sọ nù, báwo ló ṣe máa rí lára ọmọ náà? Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn gan-an. Lójú òbí náà, ó lè dà bíi pé nǹkan kékeré ló ṣe nígbà tó rí nǹkan ìṣeré yẹn. Àmọ́ ní ti ọmọ náà, inú ẹ̀ dùn, ohun tí òbí ẹ̀ ṣe sì jọ ọ́ lójú gan-an. Ó ti pa dà rí ohun ìṣeré rẹ̀ tó rò pé òun ò ní rí mọ́!
2 Baba tó ju baba lọ ni Jèhófà, ó lágbára láti ṣàtúnṣe gbogbo ohun tó dà bíi pé kò ní àtúnṣe mọ́. Ọ̀rọ̀ ohun ìṣeré ọmọdé kọ́ là ń sọ o, ọ̀rọ̀ nípa ayé yìí ni. ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé, àwọn nǹkan tá a sì ń pàdánù láyé yìí pọ̀ gan-an, kódà ó ju ohun ìṣeré ọmọdé kan tó sọ nù lọ. (2 Tímótì 3:1-5) Bí àpẹẹrẹ, a lè pàdánù ilé tàbí ohun ìní wa, iṣẹ́ lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, ara wa sì lè má le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa kì í dùn tá a bá ronú nípa báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́, tí wọ́n sì ń ṣèpalára fáwọn ẹranko àtàwọn ewéko débi tí ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan yìí ò fi sí mọ́. Àmọ́, èyí ò tó nǹkan tá a bá fi wé ẹ̀dùn ọkàn tá a máa ń ní nígbà táwọn èèyàn wa bá kú. Ìrora yẹn máa ń pọ̀ gan-an, nǹkan sì máa ń tojú sú wa.—2 Sámúẹ́lì 18:33.
3. Kí ni Ìṣe 3:21 sọ pé Ọlọ́run máa ṣe, báwo ni Jèhófà sì ṣe máa ṣe é?
3 Ó dájú pé ọkàn wa máa balẹ̀ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára tí Jèhófà ní láti mú nǹkan bọ̀ sípò! Nínú orí yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Baba wa ọ̀run lágbára láti tún ṣe, àá sì rí i pé ó wù ú kó tún àwọn nǹkan náà ṣe fún wa. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ṣe ‘ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo.’ (Ìṣe 3:21) Ó máa lo Ìjọba Mèsáyà, tí Jésù Kristi máa ṣàkóso láti ṣe ìmúbọ̀sípò náà. Ẹ̀rí fi hàn pé Ìjọba yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run látọdún 1914.a (Mátíù 24:3-14) Àwọn nǹkan wo ni Ọlọ́run máa mú bọ̀ sípò? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti mú bọ̀ sípò ní báyìí àtàwọn nǹkan tó máa mú bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú.
Ìmúbọ̀sípò Ìjọsìn Mímọ́
4, 5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
4 Ohun kan tí Jèhófà ti mú bọ̀ sípò báyìí ni ìjọsìn mímọ́. Ká lè lóye ohun téyìí túmọ̀ sí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọba ń ṣàkóso nílẹ̀ Júdà. Èyí á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò.—Róòmù 15:4.
5 Wo bí nǹkan ṣe máa rí lára àwọn Júù olóòótọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n pa ìlú wọn àtàtà run, wọ́n sì wó odi rẹ̀ palẹ̀. Èyí tó burú jù ni pé, wọ́n wó tẹ́ńpìlì tó rẹwà tí Sólómọ́nì kọ́, tó jẹ́ ibì kan ṣoṣo táwọn èèyàn ti lè máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́. (Sáàmù 79:1) Wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn tó kù nílùú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n ba ìlú náà jẹ́ gan-an débi pé àwọn ẹranko búburú nìkan ló wá ń gbébẹ̀. (Jeremáyà 9:11) Lójú àwọn Júù yẹn, ṣe ló dà bíi pé ìlú náà ò ní ṣeé gbé mọ́ láé. (Sáàmù 137:1) Àmọ́, Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa mú ìlú náà pa dà bọ̀ sípò, ó ṣe tán òun ló sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú náà run.
6-8. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa ṣe, báwo sì ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe nímùúṣẹ lápá kan? (b) Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣe nímùúṣẹ lásìkò wa yìí?
6 Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì ló sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa mú nǹkan bọ̀ sípò.b Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mí sí àwọn wòlíì náà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn tó pọ̀ á pa dà máa gbé ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ilẹ̀ náà á máa méso jáde, àwọn ẹranko búburú àtàwọn ọ̀tá ò sì ní yọ wọ́n lẹ́nu. Jèhófà sọ pé ilẹ̀ náà máa dà bíi Párádísè! (Àìsáyà 65:25; Ìsíkíẹ́lì 34:25; 36:35) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn èèyàn náà á pa dà máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, wọ́n sì máa tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Míkà 4:1-5) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn nírètí, ó sì jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á ní gbogbo àádọ́rin ọdún (70) tí wọ́n fi wà nígbèkùn ní Bábílónì.
7 Nígbà tí àsìkò tó, Jèhófà mú àwọn Júù kúrò nígbèkùn ní Bábílónì, ó mú wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Ní gbogbo àsìkò tí wọ́n fi ń sin Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, Jèhófà ń bù kún wọn, ó ń mú kí ilẹ̀ wọn méso jáde, nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn. Ó ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lọ́wọ́ àwọn ẹranko búburú tó ti ń gbé ilẹ̀ náà ní gbogbo àsìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn. Ó dájú pé bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò máa múnú wọn dùn gan-an! Àmọ́, ńṣe nìyẹn kàn jẹ́ apá kan lára bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò yẹn ṣe máa ṣẹ. Ọlọ́run sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn lásìkò wa yìí, nígbà tí Ọmọ Dáfídì tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa di ọba bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.—Àìsáyà 2:2-4; 9:6, 7.
8 Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi Jésù jọba ní ọ̀run lọ́dún 1914, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í pèsè ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà láyé nílò kí wọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Bí Kírúsì tó jẹ́ olórí ogun ilẹ̀ Páṣíà ṣe dá àwọn Júù nídè kúrò ní Bábílónì lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe dá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nídè kúrò ní “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé yìí. (Ìfihàn 18:1-5; Róòmù 2:29) Látọdún 1919 làwọn Kristẹni tòótọ́ ti pa dà ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. (Málákì 3:1-5) Àtìgbà yẹn làwọn èèyàn Jèhófà ti ń jọ́sìn rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó sọ di mímọ́, ìyẹn ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn mímọ́. Kí nìdí téyìí fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí?
Ìmúbọ̀sípò Nípa Tẹ̀mí—Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú, àmọ́ kí ni Jèhófà ṣe lásìkò wa yìí?
9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sin Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. (Mátíù 13:24-30; Ìṣe 20:29, 30) Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fara hàn, wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n mú látinú ẹ̀sìn èké. Wọ́n ń kọ́ni pé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run, wọ́n sì ń mú kó nira fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn. Bákan náà, wọ́n ní káwọn èèyàn máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Màríà àtàwọn “ẹni mímọ́” míì dípò Jèhófà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìdàkudà, tí wọ́n sì ti mú oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ èké wọlé, Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Èyí sì ni ọ̀kan pàtàkì lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe lóde òní.
10, 11. (a) Apá méjì wo ni párádísè tẹ̀mí pín sí, báwo lo sì ṣe lè fi hàn pé inú párádísè tẹ̀mí náà lo wà? (b) Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà ń mú wá sínú Párádísè tẹ̀mí náà, kí ni wọ́n sì máa láǹfààní láti gbádùn?
10 Ní báyìí tí Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbádùn párádísè tẹ̀mí. Apá méjì ni párádísè tẹ̀mí yìí pín sí. Apá àkọ́kọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. Ọlọ́run ti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké, ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Ó ń fún wa láwọn nǹkan táá mú ká mọ̀ ọ́n dáadáa, ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Jòhánù 4:24) Apá kejì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà. Wòlíì Àìsáyà sọ pé, “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” Jèhófà máa kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi máa wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ti ń ṣẹ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, àwa Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ogun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbé “ìwà tuntun” wọ̀. Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ní àwọn ìwà tó dáa. (Éfésù 4:22-24; Gálátíà 5:22, 23) Tó o bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ, a jẹ́ pé inú párádísè tẹ̀mí lo wà nìyẹn.
11 Àwọn èèyàn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló ń mú wá sínú párádísè tẹ̀mí yìí. Ìdí tó sì fi ń mú wọn wá ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n fẹ́ràn àlàáfíà, wọ́n sì ń “wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mátíù 5:3) Àwọn èèyàn yìí máa láǹfààní láti gbádùn àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn àti ayé yìí lọ́jọ́ iwájú.
“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
12, 13. (a) Kí nìdí tá a fi gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣì tún máa nímùúṣẹ lọ́nà míì? (b) Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé yìí níbẹ̀rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
12 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣì tún máa nímùúṣẹ lọ́nà míì. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí kò ní sí àìsàn mọ́, táwọn arọ, afọ́jú àti adití sì máa rí ìwòsàn, kódà ó sọ pé Ọlọ́run máa gbé ikú mì títí láé. (Àìsáyà 25:8; 35:1-7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlérí yẹn ò ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, à ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ nípa tẹ̀mí lónìí, èyí sì mú kó dá wa lójú pé wọ́n máa nímùúṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lọ́jọ́ iwájú. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
13 Nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí, ìyẹn sì ni pé káwọn èèyàn máa láyọ̀, kára wọn le, kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa bójú tó ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀, ó sì fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, ní báyìí, ayé ò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀, ó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Àìsáyà 55:10, 11) Tó bá yá, Jèhófà máa lo Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run láti sọ gbogbo ayé di Párádísè.—Lúùkù 23:43.
14, 15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa “sọ ohun gbogbo di tuntun”? (b) Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè, kí ló sì wù ẹ́ jù lọ nínú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run máa ṣe nígbà yẹn?
14 Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí gbogbo ayé bá di Párádísè! Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà yẹn, ó sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìfihàn 21:5) Fojú inú wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run, á wá ku “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.” Èyí túmọ̀ sí pé ìjọba tuntun kan máa wà lọ́run, á sì máa ṣàkóso lórí àwùjọ èèyàn tuntun tó wà láyé, ìyẹn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Pétérù 3:13) Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ò ní lágbára, wọn ò sì ní lè ṣe ẹnikẹ́ni léṣe. (Ìfihàn 20:3) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Sátánì ti ń ṣi aráyé lọ́nà, àwa èèyàn á bọ́ lọ́wọ́ ìwà burúkú àti ìkórìíra. Ó dájú pé ara máa tu gbogbo wa nígbà yẹn!
15 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àá lè máa bójú tó ayé tó rẹwà yìí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe níbẹ̀rẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà dá ayé yìí lọ́nà tó fi lè máa tún ara ẹ̀ ṣe. Táwọn èèyàn ò bá da ìdọ̀tí sínú omi mọ́, àwọn adágún àti odò lè pa dà sọ ara wọn di mímọ́, táwọn èèyàn ò bá sì jagun mọ́, gbogbo ilẹ̀ tí ogun ti sọ dìbàjẹ́ lè pa dà di ibi ẹlẹ́wà. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá tún ayé yìí ṣe kó lè di Párádísè tó rẹwà bíi ti ọgbà Édẹ́nì, tá a sì ń rí oríṣiríṣi ewéko àtàwọn ẹranko tó wà níbẹ̀! Àwọn èèyàn ò ní máa pa àwọn ẹranko àti ewéko run mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe làwa èèyàn àtàwọn ohun alààyè yòókù á máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Kódà, àwọn ọmọdé ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko búburú mọ́.—Àìsáyà 9:6, 7; 11:1-9.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa mú nǹkan bọ̀ sípò fún gbogbo olóòótọ́ èèyàn nínú Párádísè?
16 Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Jèhófà máa mú kí nǹkan pa dà bọ̀ sípò fún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa là á já nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ọlọ́run sì máa wo gbogbo wọn sàn lọ́nà ìyanu. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù máa ṣe àwọn nǹkan tó ṣe nígbà tó wà láyé, ó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti la ojú àwọn afọ́jú, ó máa ṣí etí àwọn adití, ó máa mú kí arọ rìn, ó sì máa mú gbogbo àwọn aláìsàn lára dá. (Mátíù 15:30) Inú àwọn arúgbó máa dùn nígbà yẹn, torí ara wọ́n máa le, wọ́n sì máa pa dà lókun bíi tìgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́. (Jóòbù 33:25) Ara tó hun jọ á pa dà máa jọ̀lọ̀, gbogbo ẹ̀yà ara á sì pa dà máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Gbogbo olóòótọ́ èèyàn á máa kíyè sí i pé àwọn ń bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé díẹ̀díẹ̀. Títí ayé làá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó lo agbára rẹ̀ lọ́nà àgbàyanu láti sọ gbogbo nǹkan di tuntun! Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa èyí tó máa múnú wa dùn jù lọ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run máa mú bọ̀ sípò nígbà yẹn.
Ó Máa Jí Àwọn Òkú Dìde
17, 18. (a) Kí nìdí tí Jésù fi bá àwọn Sadusí wí? (b) Kí nìdí tí Èlíjà fi gbàdúrà pé kí Jèhófà jí ọmọ kan dìde?
17 Nígbà ayé Jésù, àwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ò gbà pé àjíǹde máa wà. Torí náà Jésù bá wọn wí, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run.” (Mátíù 22:29) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti jí òkú dìde. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ tó jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni.
18 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wòlíì Èlíjà. Opó kan tó ti gba wòlíì náà lálejò fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ gbé ọmọ rẹ̀ dání, ọmọ náà sì ti kú. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa ya Èlíjà lẹ́nu gan-an, torí ṣáájú ìgbà yẹn ni Èlíjà ti gba ẹ̀mí ọmọ náà là kí ebi máa bàa lù ú pa. Kódà, ó ṣeé ṣe kí ọmọ kékeré náà ti mojú Èlíjà. Ní báyìí tí ọmọ náà ti kú, ó dájú pé ikú ẹ̀ máa dun ìyá ẹ̀ gan-an. Ọmọ yìí nìkan ni obìnrin yìí fi ń tu ara ẹ̀ nínú látìgbà tí ọkọ ẹ̀ ti kú. Ó ṣeé ṣe kí obìnrin náà máa ronú pé ọmọ yìí ló máa tọ́jú òun tóun bá darúgbó. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìdààmú bá obìnrin náà débi tó fi ń ronú pé bóyá ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tóun ti dá sẹ́yìn lòun ń jẹ. Àánú obìnrin náà ṣe Èlíjà gan-an. Ló bá rọra gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, ó gbé e lọ sínú yàrá tiẹ̀, ó sì gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ náà sọ jí.—1 Àwọn Ọba 17:8-21.
19, 20. (a) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde, kí ló sì mú kó nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san Èlíjà lẹ́san torí pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára?
19 Èlíjà kọ́ lẹni àkọ́kọ́ tó gbà pé Ọlọ́run lè jí òkú dìde. Ábúráhámù tó gbé ayé lọ́pọ̀ ọdún ṣáájú Èlíjà náà gbà pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde. Kí ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ti pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí Sérà sì ti pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti mú kí Sérà bí ọmọkùnrin kan lọ́nà ìyanu. (Jẹ́nẹ́sísì 17:17; 21:2, 3) Nígbà tọ́mọ náà dàgbà, Jèhófà ní kí Ábúráhámù fi rúbọ. Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ Ísákì gan-an, àmọ́ torí pé ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó pinnu pé òun máa ṣe ohun tí Jèhófà sọ, torí ó gbà pé Jèhófà lè jí ọmọ náà dìde. (Hébérù 11:17-19) Kí Ábúráhámù tó gorí òkè tó ti fẹ́ fi ọmọ náà rúbọ, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé òun àti Ísákì máa pa dà wá bá wọn. Ó ní láti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ní nínú Jèhófà ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:5.
“Wò ó, ọmọ rẹ yè”!
20 Àmọ́ o, Jèhófà ò jẹ́ kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ nígbà yẹn, torí náà kò sídìí tó fi máa jí i dìde. Ní ti ìgbà ayé Èlíjà, ọmọ opó yẹn ti kú ní tiẹ̀. Àmọ́ láìpẹ́ sígbà yẹn, Jèhófà jẹ́ kí Èlíjà jí ọmọ náà dìde torí ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ní. Èlíjà wá fa ọmọ náà lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè”! Ó dájú pé obìnrin yẹn ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn láé!—1 Àwọn Ọba 17:22-24.
21, 22. (a) Kí nìdí tí àkọsílẹ̀ nípa àwọn tí Jèhófà jí dìde fi wà nínú Bíbélì? (b) Báwo làwọn tó máa jíǹde nínú Párádísè ṣe máa pọ̀ tó, ta ló sì máa jí wọn dìde?
21 Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti jí òkú dìde. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà fún Èlíṣà, Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Pétérù lágbára láti jí òkú dìde. Lóòótọ́, àwọn tí wọ́n jí dìde tún pa dà kú nígbà tó yá. Síbẹ̀, ńṣe làwọn àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.
22 Nínú Párádísè, Jésù máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé òun ni “àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Ó máa jí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn dìde, wọ́n sì máa láǹfààní láti máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Jòhánù 5:28, 29) Ronú nípa bó ṣe máa rí nígbà tó o bá pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú, tẹ́ ẹ sì dì mọ́ra yín. Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an! Gbogbo èèyàn ló máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò.
23. Ọ̀nà tó ga jù lọ wo ni Jèhófà gbà lo agbára rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe mú kó dá wa lójú pé ó máa jí àwọn òkú dìde lóòótọ́?
23 Jèhófà ti ṣe ohun kan tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó lágbára láti jí àwọn òkú dìde lóòótọ́. Ó lo agbára ẹ̀ lọ́nà tó ga jù lọ nígbà tó jí Jésù Ọmọ ẹ̀ dìde, tó sọ ọ́ di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára, tó sì gbé e sípò tó ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:5, 6) Ó yẹ kíyẹn jẹ́ ẹ̀rí fáwọn tó ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde. Ká sòótọ́, Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde.
24. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, àǹfààní wo la sì lè rí lọ́jọ́ iwájú?
24 Kì í ṣe pé Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde nìkan ni, ó tún wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run mí sí Jóòbù láti sọ pé ó wu òun gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. (Jóòbù 14:15) Báwo ló ṣe rí lára ẹ ní báyìí tó o ti rí i pé ó wu Ọlọ́run pé kó lo agbára rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde? Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn! Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú nínú orí yìí, ńṣe ni àjíǹde jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, máa ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó dá ọ lójú pé ìwọ náà lè wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá ń “sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìfihàn 21:5.
a ‘Àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀, tí ẹnì kan tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba sì gorí ìtẹ́. Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ẹnì kan látinú ìlà ìdílé rẹ̀ á máa ṣàkóso títí láé. (Sáàmù 89:35-37) Àmọ́, lẹ́yìn tí Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kò sẹ́nì kankan láti ìlà ìdílé Dáfídì tó ń ṣàkóso lórí ìtẹ́ Ọlọ́run. Torí pé ìlà ìdílé Dáfídì ni wọ́n bí Jésù sí, Ọlọ́run sì ti fi jọba lọ́run, òun ni Ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí náà.
b Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn wòlíì yìí ló sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀: Mósè, Àìsáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì, Hósíà, Jóẹ́lì, Émọ́sì, Ọbadáyà, Míkà àti Sefanáyà.
-
-
“Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 9
“Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”
1-3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lórí Òkun Gálílì, kí ni Jésù sì ṣe? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé “Kristi ni agbára Ọlọ́run”?
LỌ́JỌ́ kan, báwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń wa ọkọ̀ ojú omi lọ lórí Òkun Gálílì, ìjì líle bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an! Òótọ́ ni pé ìyẹn kọ́ nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa rí i tí ìjì ń jà lórí òkun, ó ṣe tán ó pẹ́ tí ọ̀pọ̀ lára wọn ti ń ṣe iṣẹ́ apẹja.a (Mátíù 4:18, 19) Àmọ́, tọ̀tẹ̀ yìí yàtọ̀, torí pé ‘ìjì náà le gan-an, ó sì ń fẹ́ atẹ́gùn gidigidi,’ ó le débi pé kíá ni gbogbo ojú òkun dà rú, tó sì ń ru gùdù. Torí náà, láìka báwọn ọkùnrin yẹn ṣe ń gbìyànjú tó, kò rọrùn fún wọn láti darí ọkọ̀ wọn. Ńṣe ni ‘ìgbì òkun ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi náà ṣáá,’ tí omi sì ń kún inú rẹ̀. Ní gbogbo àsìkò táwọn ọmọ ẹ̀yìn fi ń ṣe wàhálà yẹn, ńṣe ni Jésù ń sùn torí pé àtàárọ̀ ló ti ń kọ́ àwọn èèyàn, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Nígbà tó yá, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n pé wọ́n lè kú sínú omi náà, ni wọ́n bá lọ jí Jésù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́ ṣègbé!”—Máàkù 4:35-38; Mátíù 8:23-25.
2 Ẹ̀rù ò ba Jésù ní tiẹ̀, ó mọ̀ pé òun lágbára láti bá ìgbì òkun náà wí. Torí náà, ó sọ fún ìjì náà pé: “Ó tó! Dákẹ́ jẹ́ẹ́!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ìgbì òkun náà rọlẹ̀, ìjì náà sì dáwọ́ dúró, “ni gbogbo ẹ̀ bá pa rọ́rọ́.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dẹ́rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà gan-an, ni wọ́n bá ń bi ara wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an?” Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an bí wọ́n ṣe rí i tí èèyàn ń bá ìgbì òkun wí bí ìgbà tó ń bá ọmọ tó ń ṣe ìjàngbọ̀n wí.—Máàkù 4:39-41; Mátíù 8:26, 27.
3 Kí ló mú kí Jésù lè ṣe ohun tó ṣe yẹn? Jèhófà ló fún un lágbára, òun ló sì jẹ́ kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé “Kristi ni agbára Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 1:24) Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe lágbára tó? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú agbára tí Jèhófà fún Jésù?
Agbára Ọmọ Bíbí Kan Ṣoṣo Ọlọ́run
4, 5. (a) Kí ni Jèhófà fún Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo lágbára láti ṣe? (b) Kí ni Jèhófà fún Jésù kó lè ràn án lọ́wọ́ láti dá àwọn nǹkan?
4 Ronú nípa agbára tí Jésù ní kó tó wá sáyé. Jèhófà lo “agbára ayérayé” rẹ̀ láti dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Ọmọ yìí la wá mọ̀ sí Jésù Kristi nígbà tó yá. (Róòmù 1:20; Kólósè 1:15) Lẹ́yìn náà, Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ yìí ní agbára tó pọ̀ gan-an, ó sì ní kó ran òun lọ́wọ́ láti dá àwọn nǹkan. Bíbélì sọ nípa Ọmọ yìí pé: “Ohun gbogbo wà nípasẹ̀ rẹ̀ àti pé láìsí i, kò sí nǹkan kan tó wà.”—Jòhánù 1:3.
5 Fojú inú wo bí agbára tí Ọlọ́run fún Jésù nígbà yẹn ṣe máa pọ̀ tó. Ó dájú pé agbára kékeré kọ́ ló fi dá àìmọye àwọn áńgẹ́lì alágbára, àìmọye bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ àti àìmọye ìràwọ̀ tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, títí kan ayé àti onírúurú ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀. Ọlọ́run fún Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, torí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló lágbára jù lọ láyé àti lọ́run. Inú Jésù dùn gan-an pé òun ni Àgbà Òṣìṣẹ́ tí Jèhófà lò láti dá gbogbo nǹkan tó kù láyé àti lọ́run.—Òwe 8:22-31.
6. Agbára àti àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún Jésù lẹ́yìn tó kú tó sì jíǹde?
6 Ṣé nǹkan míì tún wà tí Jèhófà lè fún Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí lágbára láti ṣe? Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, ó sọ pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.” (Mátíù 28:18) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní àṣẹ láti jọba lórí ohun gbogbo láyé àti lọ́run. Jèhófà ti fi Jésù ṣe “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,” ó sì ti fún un ní àṣẹ láti “sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára” tó bá ta ko òun “di asán,” yálà èyí tó ṣeé fojú rí tàbí èyí tí kò ṣeé fojú rí. (Ìfihàn 19:16; 1 Kọ́ríńtì 15:24-26) Jèhófà ti fún Jésù ní àṣẹ láti darí ohun gbogbo, ẹnì kan ṣoṣo tí ò sí lábẹ́ Jésù ni Jèhófà fúnra rẹ̀.—Hébérù 2:8; 1 Kọ́ríńtì 15:27.
7. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jésù ò ní ṣi agbára tí Jèhófà fún un lò láé?
7 Ṣé ó yẹ kẹ́rù máa bà wá pé Jésù lè ṣi agbára rẹ̀ lò? Rárá o! Jésù fẹ́ràn Bàbá rẹ̀ gan-an, torí náà kò lè ṣe ohunkóhun tó máa bí i nínú. (Jòhánù 8:29; 14:31) Jésù mọ̀ pé agbára Jèhófà ò láàlà, ó sì mọ̀ pé Jèhófà ò ṣi agbára yẹn lò rí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti rí i tí Jèhófà ń “fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” (2 Kíróníkà 16:9) Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn bí Bàbá ẹ̀ ṣe fẹ́ràn wọn, torí náà ó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà láá máa fi agbára rẹ̀ ṣe àwa èèyàn láǹfààní. (Jòhánù 13:1) Àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe lo agbára rẹ̀ nígbà tó wà láyé, ká sì wo ohun tó mú kó lo agbára náà.
‘Alágbára Nínú Ọ̀rọ̀’
8. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù, kí ló fún un lágbára láti ṣe, báwo ló sì ṣe lo agbára náà?
8 Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù ò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan nígbà tó wà ní kékeré ní Násárẹ́tì. Àmọ́, nǹkan yí pa dà lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún. (Lúùkù 3:21-23) Bíbélì sọ nípa Jésù pé: ‘Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn.’ (Ìṣe 10:38) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé Jésù “ń ṣe rere” jẹ́ ká rí i pé ó ń lo agbára rẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó “fi hàn pé wòlíì tó lágbára ni òun nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.”—Lúùkù 24:19.
9-11. (a) Ibo ni Jésù ti sábà máa ń kọ́ni, ìṣòro wo ló sì ṣeé ṣe kó ní? (b) Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ fi ya àwọn èrò náà lẹ́nu?
9 Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀? Ó sábà máa ń kọ́ni ní ìta gbangba, irú bí etíkun, ẹ̀gbẹ́ òkè, ojú ọ̀nà àti ọjà. (Máàkù 6:53-56; Lúùkù 5:1-3; 13:26) Ká sọ pé ọ̀rọ̀ Jésù kì í wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ńṣe ni wọ́n kàn máa kúrò níbi tó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀. Bó tún ṣe jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ kọ́ ni wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀ sílẹ̀ nígbà yẹn, àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ gbọ́dọ̀ fọkàn sí ohun tó ń sọ. Torí náà, Jésù ní láti kọ́ àwọn èèyàn dáadáa kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kó sì yé wọn, kí wọ́n má bàa gbàgbé. Tá a bá sì wo bí Jésù ṣe kọ́ni nínú Ìwàásù Orí Òkè, àá rí i pé ìyẹn ò ṣòro fún un rárá.
10 Láàárọ̀ ọjọ́ kan lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 31 Sànmánì Kristẹni, àwùjọ èèyàn kan kóra jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè kan tó wà nítòsí Òkun Gálílì. Àwọn kan lára wọn wá láti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù, ìyẹn sì jìn tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) tàbí àádọ́fà (110) kìlómítà. Àwọn míì wá láti etíkun Tírè àti Sídónì lápá àríwá. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ló sún mọ́ Jésù kí wọ́n lè fọwọ́ kàn án, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Lẹ́yìn náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. (Lúùkù 6:17-19) Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn nǹkan tó sọ ya àwọn èèyàn náà lẹ́nu. Kí nìdí?
11 Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn yẹn, ọkàn lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù yẹn kọ̀wé pé: “Bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu, torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ.” (Mátíù 7:28, 29) Ohun tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn náà jẹ́ kí wọ́n rí i pé alágbára ni lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, gbogbo ohun tó ń kọ́ni ló sì bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Jòhánù 7:16) Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ò lọ́jú pọ̀ rárá, ọ̀rọ̀ ẹ̀ sì máa ń mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀. Ó máa ń rọrùn fáwọn èèyàn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀ ló sì ṣeé gbára lé. Kì í fòótọ́ pa mọ́, ó sì máa ń sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ káwọn èèyàn yẹ ara wọn wò, kí wọ́n lè ṣàtúnṣe tó yẹ. Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè láyọ̀, bí wọ́n ṣe lè máa gbàdúrà, bí wọ́n ṣe lè máa wá Ìjọba Ọlọ́run, àti ohun tí wọ́n lè ṣe kí ọjọ́ ọ̀la wọn lè dáa. (Mátíù 5:3–7:27) Ọ̀rọ̀ ẹ̀ ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kódà wọ́n múra tán láti “sẹ́” ara wọn, kí wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé e. (Mátíù 16:24; Lúùkù 5:10, 11) Èyí jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ Jésù lágbára gan-an!
‘Alágbára Nínú Ìṣe’
12, 13. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ ‘alágbára nínú ìṣe,’ oríṣiríṣi iṣẹ́ ìyanu wo ló sì ṣe?
12 Jésù tún jẹ́ ‘alágbára nínú ìṣe.’ (Lúùkù 24:19) Ó ju ọgbọ̀n (30) iṣẹ́ ìyanu táwọn Ìwé Ìhìn Rere sọ pé Jésù ṣe, “agbára Jèhófà” ló sì fi ṣe gbogbo wọn.b (Lúùkù 5:17) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jàǹfààní iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó pèsè oúnjẹ fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin lọ́nà ìyanu, ó tún pèsè oúnjẹ fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin lásìkò míì. Ká sọ pé wọ́n ka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ ni, ó dájú pé iye àwọn tó pèsè oúnjẹ fún máa pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ gan-an!—Mátíù 14:13-21; 15:32-38.
13 Oríṣiríṣi iṣẹ́ ìyanu ni Jésù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ó sì máa ń rọrùn fún un láti lé wọn jáde. (Lúùkù 9:37-43) Ó lágbára lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, irú bí ìjì àti omi. Kódà, ó sọ omi di wáìnì. (Jòhánù 2:1-11) Wo bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn nígbà tí “wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun.” (Jòhánù 6:18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù lágbára lórí oríṣiríṣi àìsàn, kódà ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn tó le gan-an lára dá, títí kan àwọn tó ní àrùn tí kò gbóògùn. (Máàkù 3:1-5; Jòhánù 4:46-54) Oríṣiríṣi ọ̀nà ló gbà mú àwọn tó ń ṣàìsàn lára dá. Jésù ò sí nítòsí àwọn kan nígbà tó wò wọ́n sàn, àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ṣe ló fọwọ́ kàn wọ́n nígbà tó ń wò wọ́n sàn. (Mátíù 8:2, 3, 5-13) Àwọn kan wà tí Jésù wò sàn lójú ẹsẹ̀, àwọn míì sì wà tó wò sàn díẹ̀díẹ̀.—Máàkù 8:22-25; Lúùkù 8:43, 44.
“Wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun”
14. Àwọn ipò tó yàtọ̀ síra wo ni Jésù ti fi hàn pé òun lágbára láti jí òkú dìde?
14 Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ lára àwọn nǹkan tí Jésù lágbára láti ṣe ni pé ó lè jí òkú dìde. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ìgbà tó jí ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá dìde fáwọn òbí ẹ̀, ìgbà tó jí ọmọ kan ṣoṣo tí obìnrin opó kan bí dìde àtìgbà tó jí ọkùnrin kan dìde fáwọn arábìnrin ẹ̀. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-56; Jòhánù 11:38-44) Kò sí ìkankan nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó nira fún Jésù láti jí dìde. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ tí ọmọbìnrin yẹn kú tí Jésù fi jí i dìde, kódà wọn ò tíì gbé e kúrò lórí ibi tó kú sí. Orí àga ìgbókùú ni ọmọkùnrin opó yẹn ṣì wà nígbà tí Jésù jí i dìde, ó sì dájú pé ọjọ́ yẹn gangan ló kú. Bákan náà, ẹ̀yìn ọjọ́ kẹrin tí Lásárù kú ni Jésù jí i dìde kúrò nínú ibojì.
Jésù Máa Ń Fi Agbára Ẹ̀ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
15, 16. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jésù ò mọ tara ẹ̀ nìkan bó ṣe ń lo agbára tí Jèhófà fún un?
15 Ká sọ pé èèyàn aláìpé ni Ọlọ́run fún nírú agbára tí Jésù ní yìí, ńṣe lẹ̀rù á máa bà wá pé ẹni náà máa ṣi agbára yẹn lò. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ sábà máa ń mọ tara wọn nìkan, wọ́n máa ń gbéra ga, wọ́n tún máa ń ṣojúkòkòrò, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lo agbára wọn láti fi ni àwọn èèyàn lára. Àmọ́ Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀, torí pé ẹni pípé ni.—1 Pétérù 2:22
16 Jésù ò mọ tara ẹ̀ nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló máa ń fi agbára ẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ebi ń pa á, ó kọ̀ láti sọ òkúta di búrẹ́dì. (Mátíù 4:1-4) Kò ní ohun ìní tó pọ̀, ìyẹn sì fi hàn pé kò lo agbára rẹ̀ láti fi kó ọrọ̀ jọ. (Mátíù 8:20) Bákan náà, tí Jésù bá ṣe iṣẹ́ ìyanu, agbára máa ń kúrò lára ẹ̀. Kódà, tó bá jẹ́ pé ẹnì kan péré ló mú lára dá, ó máa ń mọ̀ ọ́n lára pé agbára ti jáde lára òun. (Máàkù 5:25-34) Síbẹ̀ ó gbà káwọn èrò fọwọ́ kan òun, gbogbo wọn sì rí ìwòsàn. (Lúùkù 6:19) Ká sòótọ́, Jésù ò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, ó sì múra tán láti fi agbára rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.
17. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun máa ń fi ọgbọ́n lo agbára?
17 Jésù máa ń fi ọgbọ́n lo agbára ẹ̀. Kì í lo agbára rẹ̀ torí kó lè gbéra ga tàbí torí káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí i. (Mátíù 4:5-7) Bí àpẹẹrẹ, ó kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìyanu nígbà tí Hẹ́rọ́dù ní kó ṣe é kóun lè mọ irú ẹni tó jẹ́. (Lúùkù 23:8, 9) Dípò tí Jésù á fi máa sọ bóun ṣe lágbára tó fáwọn èèyàn, ṣe ló sábà máa ń sọ fáwọn tó wò sàn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnikẹ́ni. (Máàkù 5:43; 7:36) Kò fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé òun ni Mèsáyà torí pé wọ́n gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tóun ṣe.—Mátíù 12:15-19.
18-20. (a) Kí nìdí tí Jésù fi lo agbára rẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o ronú nípa ọ̀nà tí Jésù gbà tọ́jú ọkùnrin kan tó nílò ìtọ́jú tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù lágbára gan-an, ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn alákòóso ayé yìí tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa ń lo agbára bó ṣe wù wọ́n láìka ti ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn sí. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lógún ní tiẹ̀. Ó máa ń dùn ún gan-an tó bá rí i táwọn èèyàn ń jìyà, ó sì máa ń rí i pé òun wá nǹkan ṣe láti yanjú ìṣòro wọn. (Mátíù 14:14) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ó tún máa ń fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ̀ wò, ìyẹn sì máa ń mú kó lo agbára rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan tó wúni lórí wà nínú Máàkù 7:31-37.
19 Lọ́jọ́ kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbé àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì wo gbogbo wọn sàn. (Mátíù 15:29, 30) Àmọ́, Jésù kíyè sí ọkùnrin kan láàárín wọn, tó nílò ìtọ́jú tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọkùnrin náà ò gbọ́ràn, kò sì lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti kíyè sí i pé ẹ̀rù ń ba ọkùnrin náà tàbí pé ojú ń tì í. Torí náà, Jésù gba tiẹ̀ rò, ó sì mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò yẹn. Jésù wá ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ ohun tóun fẹ́ ṣe fún un. Ó “ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.”c (Máàkù 7:33) Lẹ́yìn náà, Jésù wo ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀. Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yẹn máa jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé agbára Ọlọ́run ló fẹ́ fi wo òun sàn. Jésù wá sọ pé: “Là.” (Máàkù 7:34) Bó ṣe di pé ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́rọ̀ nìyẹn, tó sì lè sọ̀rọ̀ ketekete.
20 Tá a bá ronú nípa bí Jésù ṣe gba tàwọn èèyàn rò, tó sì fìfẹ́ lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi wò wọ́n sàn, ìyẹn máa tù wá nínú gan-an! Ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Alákòóso tó jẹ́ aláàánú tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni Jèhófà yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba rẹ̀!
Àpẹẹrẹ Àwọn Nǹkan Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú
21, 22. (a) Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? (b) Torí pé Jésù lágbára lórí àwọn nǹkan tó wà láyé, kí la lè máa retí nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé?
21 Ṣe làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé kàn jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣe nígbà tó bá ń ṣàkóso ayé. Nínú ayé tuntun, Jésù tún máa ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ kárí ayé. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣe nígbà yẹn.
22 Jésù máa tún gbogbo ohun táwọn èèyàn ti bà jẹ́ láyé yìí ṣe, kó lè rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. Ìgbà kan wà tí Jésù mú kí ìjì líle rọlẹ̀, èyí jẹ́ ká rí i pé ó lágbára lórí àwọn nǹkan tó wà láyé. Torí náà, lábẹ́ Ìjọba Kristi, àwa èèyàn ò ní máa bẹ̀rù nítorí ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀, òkè ayọnáyèéfín tó ń bú gbàù, tàbí àwọn àjálù míì. Kò sóhun tí Jésù ò mọ̀ nípa ayé yìí, torí òun ni Àgbà Òṣìṣẹ́ tí Jèhófà lò láti dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. Jésù mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti bójú tó àwọn nǹkan tó wà láyé. Tí Jésù bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa sọ ayé di Párádísè.—Lúùkù 23:43.
23. Báwo ni Jésù ṣe máa pèsè ohun táwa èèyàn nílò nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé?
23 Ṣé Jésù máa lè pèsè gbogbo ohun táwa èèyàn nílò? Bẹ́ẹ̀ ni. Rántí pé Jésù fi ìwọ̀nba oúnjẹ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, tí gbogbo wọn sì jẹ àjẹṣẹ́kù. Torí náà, ó dájú pé ebi ò ní pa wá mọ́ nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Ká sòótọ́, tí oúnjẹ bá pọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń pín in bó ṣe yẹ, a ò ní gbúròó ebi mọ́. (Sáàmù 72:16) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé òun lágbára lórí onírúurú àìsàn, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé kò ní sí afọ́jú, adití, aláàbọ̀ ara àti arọ nínú Ìjọba rẹ̀. Ó dájú pé ó máa wo gbogbo wọn sàn, a ò sì ní gbúròó àìsàn mọ́ láé. (Àìsáyà 33:24; 35:5, 6) Bákan náà, Jésù jí òkú dìde, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wa lójú pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa jí àìmọye mílíọ̀nù èèyàn tó wà ní ìrántí Bàbá rẹ̀ dìde.—Jòhánù 5:28, 29.
24. Bá a ṣe ń ronú nípa bí agbára Jésù ṣe pọ̀ tó, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn, kí sì nìdí?
24 Tá a bá ń ronú nípa bí agbára Jésù ṣe pọ̀ tó, ó yẹ ká máa rántí pé àpẹẹrẹ Bàbá rẹ̀ ló ń tẹ̀ lé láìkù síbì kan. (Jòhánù 14:9) Torí náà, ọ̀nà tí Jésù gbà ń lo agbára jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń lo agbára. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sí ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan, tó sì wò ó sàn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àánú adẹ́tẹ̀ yìí ṣe Jésù débi pé ó fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀!” (Máàkù 1:40-42) Ńṣe ni Jèhófà ń lo irú àkọsílẹ̀ bí èyí láti sọ fún wa pé, ‘Bí mo ṣe ń lo agbára mi lẹ̀ ń rí yẹn o!’ Tó o bá ń ronú nípa bí Ọlọ́run wa Olódùmarè ṣe ń lo agbára ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó dájú pé á máa wù ẹ́ láti yìn ín lógo, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀!
a Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjì máa ń dédé jà lójú Òkun Gálílì. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ibi tí òkun náà wà lọ sísàlẹ̀ gan-an (ó fi nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì (200) mítà lọ sísàlẹ̀ ju ojú òkun), afẹ́fẹ́ ibẹ̀ sì sábà máa ń gbóná ju tàwọn òkun míì lọ. Torí náà, ìgbàkigbà ni ojú ọjọ́ lè yí pa dà níbẹ̀. Atẹ́gùn líle tó ń rọ́ wá láti orí Òkè Hámónì tó wà lápá àríwá máa ń fẹ́ lọ sí Àfonífojì Jọ́dánì. Torí náà, ojú ọjọ́ ti lè pa rọ́rọ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ kí ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í jà lẹ́yìn ìṣẹ́jú bíi mélòó kan.
b Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà míì wà táwọn Ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ ṣókí nípa iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe níbì kan, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ló ṣe níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí “gbogbo ìlú” wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì wo “ọ̀pọ̀” àwọn tó ń ṣàìsàn lára wọn sàn.—Máàkù 1:32-34.
c Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ló gbà pé itọ́ wà lára ohun tí wọ́n lè fi woni sàn. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Jésù tutọ́ kó lè jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé òun fẹ́ wò ó sàn. Èyí ó wù kó jẹ́, ó dájú pé itọ́ kọ́ ni Jésù fi wo ọkùnrin náà sàn.
-
-
“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo AgbáraSún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 10
“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
1. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn bá wà nípò àṣẹ?
ÒWE kan sọ pé: “Kò sẹ́ni tí wọ́n máa gbé gẹṣin tí kò ní ju ìpàkọ́.” Òwe yìí jẹ́ ká rí i pé táwọn èèyàn bá wà nípò àṣẹ, wọ́n sábà máa ń ṣi agbára lò. Ó dunni pé ọ̀pọ̀ èèyàn nirú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Kódà, àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn jẹ́rìí sí i pé “èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ká sòótọ́, àwọn tó wà nípò àṣẹ kì í fìfẹ́ hàn bí wọ́n ṣe ń lo agbára wọn, ìyẹn sì ti mú kí nǹkan nira gan-an fáwọn èèyàn.
2, 3. (a) Kí ló wúni lórí nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo agbára? (b) Àwọn nǹkan wo la lè lágbára láti ṣe, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa lo agbára náà?
2 Jèhófà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sáwa èèyàn. Òun ló lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, síbẹ̀ kò ṣi agbára rẹ̀ lò rí. Bá a ṣe rí i nínú àwọn orí tó ṣáájú, Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, láti pani run, láti dáàbò boni tàbí láti mú nǹkan bọ̀ sípò. Gbogbo ìgbà tó bá sì lo agbára náà ló fi ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀, ó máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Èyí sì lè mú ká ‘máa fara wé e’ nínú bá a ṣe ń lo agbára. (Éfésù 5:1) Àmọ́ o, agbára wo làwa èèyàn lásánlàsàn ní?
3 Rántí pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn “ní àwòrán rẹ̀” ká lè fìwà jọ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Torí náà àwa èèyàn ní agbára díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè ní agbára tàbí okun tá a lè fi ṣe iṣẹ́ àṣekára, a lè ní àṣẹ lórí àwọn èèyàn, a lè ní nǹkan ìní tó pọ̀ ju tàwọn èèyàn kan lọ, a tún lè gbọ́n ju àwọn míì tàbí ká ní ìmọ̀ jù wọ́n lọ, kíyẹn sì mú ká máa fún wọn nímọ̀ràn lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ní pàtàkì àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́, agbára wa kéré gan-an tá a bá fi wé ti Ọlọ́run. Onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Torí náà, Ọlọ́run ni orísun gbogbo agbára tá a ní. Ó sì yẹ ká máa lo agbára náà lọ́nà táá múnú ẹ̀ dùn. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì
4, 5. (a) Kí ló máa jẹ́ ká lo agbára wa lọ́nà tó dáa, báwo ni àpẹẹrẹ Ọlọ́run sì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? (b) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa lọ́nà tó dáa?
4 Kẹ́nì kan tó lè lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó dáa, ẹni náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Rántí pé ní Orí Kìíní, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà àti ìṣe pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ní, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ìwà àti ìṣe mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà? Ìfẹ́ ni. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ ni Jèhófà, ìfẹ́ yìí ló sì máa ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí náà, ìfẹ́ ló máa ń mú kí Ọlọ́run lo agbára rẹ̀, ó sì máa ń lò ó láti ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́.
5 Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àá máa lo agbára wa lọ́nà tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ máa ń ní “inú rere” àti pé “kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Torí náà tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a ò ní máa kanra mọ́ wọn tàbí hùwà ìkà sí wọn, ní pàtàkì àwọn tá a bá láṣẹ lé lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa ṣenúure sáwọn èèyàn, àá máa bọ̀wọ̀ fún wọn, àá sì máa gba tiwọn rò dípò ká máa ro tara wa nìkan.—Fílípì 2:3, 4.
6, 7. (a) Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe lè mú ká yẹra fún àṣìlò agbára? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká tó lè bẹ̀rù rẹ̀.
6 Jẹ́ ká wo ọ̀nà míì tí ìfẹ́ lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa lọ́nà tó dáa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ ká bẹ̀rù ẹ̀. Òwe 16:6 sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà . . . máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.” Ọ̀kan lára ohun búburú tó sì yẹ ká máa yẹra fún ni pé ká má ṣe máa ṣi agbára wa lò. Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, a ò ní máa hùwà ìkà sáwọn tá a láṣẹ lé lórí. Kí nìdí? Ìdí ni pé, a mọ̀ pé a máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa bá a ṣe ń hùwà sí wọn. (Nehemáyà 5:1-7, 15) Àmọ́ o, ìdí míì tún wà tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ìbẹ̀rù” sábà máa ń tọ́ka sí pé kéèyàn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká tó lè bẹ̀rù rẹ̀. (Diutarónómì 10:12, 13) Àmọ́, kò yẹ kó jẹ́ pé torí kí Ọlọ́run má bàa fìyà jẹ wá nìkan ló ṣe yẹ ká máa sá fún ìwà burúkú o! Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí i, àá sì máa bọ̀wọ̀ fún un.
7 Bí àpẹẹrẹ: Ronú nípa bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré gan-an. Ọmọ náà mọ̀ pé bàbá òun ò fọ̀rọ̀ òun ṣeré, síbẹ̀ ó máa gbà pé bàbá òun ń retí pé kóun máa ṣe àwọn nǹkan kan, ó sì mọ̀ pé tóun bá ṣe ohun tí kò dáa, bàbá òun máa bá òun wí. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ náà á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì torí bàbá ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa fẹ́ràn bàbá ẹ̀ gan-an. Ó sì máa wù ú pé kó máa ṣe ohun tó máa múnú bàbá ẹ̀ dùn. Bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn. Torí pé a fẹ́ràn Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6) Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa ṣe ohun tó máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Torí náà, a ò ní máa lo agbára wa lọ́nà tí kò dáa. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa lo agbára wa lọ́nà tó dáa.
Nínú Ìdílé
8. (a) Àṣẹ wo ni ọkọ ní nínú ìdílé, báwo ló sì ṣe yẹ kó lò ó? (b) Báwo ni ọkọ kan ṣe lè máa fi hàn pé òun ń bọlá fún ìyàwó òun?
8 Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè lo agbára lọ́nà tó dáa nínú ìdílé. Éfésù 5:23 sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀.” Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún un yìí? Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n máa “fi òye” bá àwọn aya wọn gbé, kí wọ́n sì máa “bọlá fún wọn bí ohun èlò ẹlẹgẹ́.” (1 Pétérù 3:7) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “bọlá fún” nínú ẹsẹ yìí tún máa ń túmọ̀ sí ‘kà sí pàtàkì, kà sí ohun tó ṣeyebíye tàbí bọ̀wọ̀ fún.’ A sì tún máa ń túmọ̀ ẹ̀ sí “ẹ̀bùn” àti “iyebíye.” (Ìṣe 28:10; 1 Pétérù 2:7) Tí ọkọ kan bá ń bọlá fún ìyàwó rẹ̀, kò ní máa nà án; bẹ́ẹ̀ ni kò ní máa bú u tàbí kó máa sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i tí obìnrin náà á fi máa wo ara ẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà máa mọyì ìyàwó rẹ̀, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ó máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà ẹ̀ pé ìyàwó ẹ̀ ṣeyebíye sí i, ì báà jẹ́ nígbà tí wọ́n dá nìkan wà tàbí nígbà tí wọ́n wà láàárín àwọn èèyàn. (Òwe 31:28) Tí ọkọ kan bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó máa rọrùn fún ìyàwó ẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ní pàtàkì jù lọ, inú Jèhófà máa dùn sí i.
Tọkọtaya máa fi hàn pé àwọn ń lo agbára àwọn lọ́nà tó dáa tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn
9. (a) Kí làwọn aya ní agbára láti ṣe nínú ìdílé? (b) Kí ló máa ran aya kan lọ́wọ́ láti máa lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti fi ṣètìlẹyìn fún ọkọ rẹ̀, àǹfààní wo ló sì máa rí tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀?
9 Àwọn aya náà ní agbára láti ṣe àwọn nǹkan kan nínú ìdílé. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin olóòótọ́ tó gbìyànjú láti ran àwọn ọkọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó tọ́, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn tó jẹ́ olórí ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12; 27:46–28:2) Aya kan lè ní ìmọ̀ ju ọkọ rẹ̀ lọ tàbí kó láwọn ìwà àti ìṣe míì tí ọkọ rẹ̀ kò ní. Síbẹ̀, ó yẹ kó ní “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀ kó sì “máa tẹrí ba” fún un “bíi fún Olúwa.” (Éfésù 5:22, 33) Tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣe pàtàkì sí obìnrin kan ni báá ṣe máa múnú Ọlọ́run dùn, á máa lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tó ní láti máa ṣètìlẹyìn fún ọkọ rẹ̀ dípò táá fi máa fojú kéré ọkọ rẹ̀ tàbí kó máa ṣe bí ọ̀gá lórí rẹ̀. Irú aya bẹ́ẹ̀ máa fi hàn pé “ọlọ́gbọ́n obìnrin” lòun, á máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti gbé ìdílé wọn ró, èyí á sì jẹ́ kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Òwe 14:1.
10. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún àwọn òbí? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí,” báwo ló sì ṣe yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 Ọlọ́run tún fún àwọn òbí ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” lè túmọ̀ sí kí wọ́n tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó lè ṣe ohun tó tọ́. Ká sòótọ́, àwọn ọmọ nílò ìbáwí; wọ́n sábà máa ń ṣe dáadáa táwọn òbí bá fún wọn ní ìtọ́ni tó dáa, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. (Òwe 13:24) Torí náà táwọn òbí bá ń lo “ọ̀pá ìbáwí,” kò yẹ kí wọ́n máa lò ó lọ́nà tí wọ́n á fi ṣe àwọn ọmọ wọn léṣe tàbí lọ́nà tí wọ́n á fi kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn.a (Òwe 22:15; 29:15) Tí òbí kan bá ń kanra mọ́ ọmọ ẹ̀ tàbí tó le koko jù mọ́ ọn, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọmọ náà. Ìyẹn ò sì ní fi hàn pé irú òbí bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa fi hàn pé òbí náà ń ṣi agbára rẹ̀ lò. (Kólósè 3:21) Àmọ́, táwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ̀ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n á sì gbà pé ohun tó dáa làwọn òbí wọ́n fẹ́ fún wọn.
11. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà tó dáa?
11 Àwọn ọmọ ńkọ́? Báwo ni wọ́n ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà tó dáa? Òwe 20:29 sọ pé: “Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” Ó dájú pé ọ̀nà tó dáa jù lọ táwọn ọ̀dọ́ lè gbà lo okun àti agbára wọn ni pé kí wọ́n fi sin ‘Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá.’ (Oníwàásù 12:1) Bákan náà, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa rántí pé ohun tí wọ́n bá ṣe lè mú inú àwọn òbí wọn dùn, ó sì lè bà wọ́n nínú jẹ́. (Òwe 23:24, 25) Táwọn ọmọ bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó tọ́, wọ́n máa múnú àwọn òbí wọn dùn. (Éfésù 6:1) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń “dára gidigidi lójú Olúwa.”—Kólósè 3:20.
Nínú Ìjọ
12, 13. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwọn alàgbà máa lo àṣẹ wọn nínú ìjọ? (b) Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà máa fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú àwọn àgùntàn Jèhófà.
12 Jèhófà pèsè àwọn alábòójútó kí wọ́n lè máa múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. (Hébérù 13:17) Ó yẹ káwọn ọkùnrin yìí máa lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn láti bójú tó àwọn ará àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ṣó wá yẹ káwọn alàgbà máa ṣe bí ọ̀gá lórí àwọn ará? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ káwọn alàgbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nínú ìjọ. (1 Pétérù 5:2, 3) Bíbélì sọ fáwọn alábòójútó pé kí wọ́n máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ káwọn alábòójútó máa fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú gbogbo àwọn ará nínú ìjọ.
13 Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà yìí. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ní kó o bá òun tọ́jú ohun ìní kan tó fẹ́ràn gan-an, tó o sì mọ̀ pé ohun kékeré kọ́ ni ọ̀rẹ́ rẹ san kó tó lè ra ohun ìní náà. Ó dájú pé o máa tọ́jú ẹ̀ dáadáa kó má bàa bà jẹ́! Bákan náà, Ọlọ́run yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa bójú tó ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye, ìyẹn àwọn ará tó wà nínú ìjọ, Bíbélì sì sábà máa ń fi àwọn ará yìí wé àgùntàn. (Jòhánù 21:16, 17) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ gan-an débi pé ó fi ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wọ́n. Ohun tó ṣeyebíye jù lọ ni Jèhófà san láti fi ra àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn alàgbà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa ń fi èyí sọ́kàn ní gbogbo ìgbà, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.
“Ahọ́n Ní Agbára”
14. Kí ni ahọ́n lágbára láti ṣe?
14 Bíbélì sọ pé: “Ahọ́n ní agbára láti fa ikú tàbí ìyè.” (Òwe 18:21) Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè kó àwa tàbí àwọn ẹlòmíì sí wàhálà. Ó ṣe tán, gbogbo wa ló máa ń mọ̀ ọ́n lára tẹ́nì kan bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wa. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ ẹnu wa tún lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Òwe 12:18 sọ pé: “Ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.” Ká sòótọ́, tá a bá sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún ẹnì kan, ṣe ló máa dà bíi pé a fún ẹni náà ní oògùn táá mára tù ú. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
15, 16. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo ahọ́n wa láti fún àwọn èèyàn níṣìírí?
15 Ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:14 sọ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́.” Ká sòótọ́, nígbà míì àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn náà máa ń sorí kọ́. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? A lè sọ àwọn nǹkan dáadáa tí wọ́n ti ṣe, ká sì gbóríyìn fún wọn látọkàn wá kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fún wọn táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ní “ọgbẹ́ ọkàn” àtàwọn tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn.” (Sáàmù 34:18) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ láti tu àwọn èèyàn nínú, ńṣe là ń fara wé Ọlọ́run wa, tó máa ń tu àwọn tó sorí kọ́ nínú.—2 Kọ́ríńtì 7:6.
16 A tún lè sọ ọ̀rọ̀ tó máa fún àwọn èèyàn níṣìírí àtèyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá rí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kú, a lè bá a kẹ́dùn, ká sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ara máa tù ú. Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan tó ti darúgbó nínú ìjọ ló ń ronú pé òun ò wúlò mọ́, a lè sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó gbà pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà. Bákan náà, tá a bá mọ ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an, a lè sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un látorí fóònù tàbí ká kọ lẹ́tà sí i, a sì lè lọ kí i láti ṣaájò rẹ̀. Ìyẹn á múnú ẹni náà dùn, á sì mára tù ú. Tá a bá ń sọ “ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró,” ó dájú pé inú Ẹlẹ́dàá wa máa dùn gan-an!—Éfésù 4:29.
17. Ọ̀nà tó dáa jù lọ wo la lè gbà lo ahọ́n wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà lo ahọ́n wa ni pé ká fi sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Òwe 3:27 sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún tó bá wà níkàáwọ́ rẹ láti ṣe é.” Jèhófà ti fún wa ní iṣẹ́ pàtàkì kan, ó fẹ́ ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, ó sì fẹ́ kí wọ́n tètè gbọ́ ìhìn rere yìí kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Torí náà, kò yẹ ká fà sẹ́yìn láti sọ fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 9:16, 22) Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe nínú iṣẹ́ yìí pọ̀ tó?
Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà lo agbára wa ni pé ká máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn
Máa Fi “Gbogbo Okun” Rẹ Sin Jèhófà
18. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ tó?
18 Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń wù wá láti wàásù ìhìn rere. Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí pọ̀ tó? Ohun tó fẹ́ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé láìka ipò wa sí. Bíbélì sọ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn bíi pé Jèhófà lẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.” (Kólósè 3:23) Nígbà tí Jésù ń sọ àṣẹ tó ṣe pàtàkì jù, ó ní: “Kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:30) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ òun ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa sin òun.
19, 20. (a) Bó ṣe jẹ́ pé ara, èrò, àti okun ló para pọ̀ di ọkàn, kí nìdí tí Jésù fi dìídì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú Máàkù 12:30? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà?
19 Kí ló túmọ̀ sí láti máa fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run? Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkàn, ohun tó máa ń túmọ̀ sí ni àwa èèyàn lódindi, ìyẹn sì kan ara wa, okun wa àti èrò wa. Kí wá nìdí tí Jésù fi dìídì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú Máàkù 12:30? Wo àpèjúwe yìí ná. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹnì kan lè ta ara rẹ̀ sóko ẹrú. Síbẹ̀, ẹni náà lè má fi tọkàntọkàn sin ọ̀gá ẹ̀; ó lè má lo gbogbo okun ẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ ọ̀gá ẹ̀, ó sì lè má fọkàn siṣẹ́ náà. (Kólósè 3:22) Torí náà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkàn, ara, èrò àti okun wa, ńṣe ló fẹ́ ká rí i pé gbogbo wọn ló yẹ ká máa lò nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run.
20 Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé iye àkókò àti okun kan náà ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ìyẹn ò lè ṣeé ṣe, torí ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yàtọ̀ síra, a ò sì lókun bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tára ẹ̀ le koko lè máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ju ẹnì kan tó ti ń dàgbà tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ẹni tí kò tíì lọ́kọ tàbí ẹni tí kò tíì láya ní ọ̀pọ̀ àkókò láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ju ẹni tó ti ní ìdílé lọ. Tá a bá lókun dáadáa, tí ipò wa sì gbà wá láyé láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́! Àmọ́ o, kò yẹ ká máa fi ohun tá a lè ṣe wé tàwọn ẹlòmíì, kò sì yẹ ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn. (Róòmù 14:10-12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa gbìyànjú láti fún àwọn èèyàn níṣìírí.
21. Ọ̀nà wo ló dáa jù lọ tá a lè gbà lo agbára wa?
21 Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó dáa, àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn sì jẹ́ fún wa. Torí náà, ó yẹ ká gbìyànjú láti fara wé e débi tágbára àwa èèyàn aláìpé bá lè gbé e dé. A máa fi hàn pé à ń lo agbára wa lọ́nà tó dáa tá a bá ń buyì kún àwọn tá a láṣẹ lé lórí, tá a sì ń ṣenúure sí wọn. Bákan náà, ó yẹ ká máa fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé fún wa, torí ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn èèyàn rí ìgbàlà. (Róòmù 10:13, 14) Rántí pé inú Jèhófà máa dùn tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn ni pé tó o bá ń fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín. Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa sin Ọlọ́run yìí, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń ṣenúure sí wa. Ká sòótọ́, kò sí ọ̀nà míì tó dáa jùyẹn lọ tá a lè gbà lo agbára wa.
a Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ọ̀pá” ni wọ́n máa ń lò fún igi táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi ń da àgùntàn. (Sáàmù 23:4) Torí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé káwọn òbí fi “ọ̀pá” bá àwọn ọmọ wọn wí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, kì í ṣe pé kí wọ́n kanra mọ́ wọn tàbí kí wọ́n hùwà ìkà sí wọn.
-