ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Jésù ń kú lọ lórí igi oró.

      ORÍ 23

      “Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

      1-3. Àwọn nǹkan wo ló mú kí ikú Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn àwa èèyàn?

      LỌ́JỌ́ kan nígbà ìrúwé, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, wọ́n fẹ̀sùn èké kan ọkùnrin kan, wọ́n dájọ́ ikú fún un, kódà ṣe ni wọ́n dá a lóró títí tó fi kú. Ìyẹn kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fẹ̀sùn èké kan àwọn èèyàn tí wọ́n á sì pa wọ́n nípa ìkà, ó sì bani nínú jẹ́ pé wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ikú ọkùnrin yìí ṣàrà ọ̀tọ̀.

      2 Bí ọkùnrin yẹn ṣe ń jẹ̀rora tó sì ń kú lọ, ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀run tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ohun pàtàkì ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sán gangan ni, ṣe ni òkùnkùn ṣàdédé ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà. Òpìtàn kan tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sọ pé, “oòrùn ò ràn.” (Lúùkù 23:44, 45) Àmọ́, ṣáájú kí ọkùnrin náà tó kú, ó sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan, ó ní: “A ti ṣe é parí!” Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin yẹn fi ẹ̀mí ara ẹ̀ rúbọ, èyí sì mú kó ṣe ohun àgbàyanu kan láṣeparí. Ohun tó ṣe yẹn ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nínú ìtàn àwa èèyàn, ìyẹn sì ni ọ̀nà tó ga jù lọ téèyàn lè gbà fìfẹ́ hàn.​—Jòhánù 15:13; 19:30.

      3 Jésù Kristi lọkùnrin tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Jésù tí wọ́n sì pa á nípa ìkà lọ́jọ́ tá à ń sọ yìí, ìyẹn ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, ohun pàtàkì kan wà tọ́pọ̀ èèyàn ò mọ̀. Òótọ́ ni pé wọ́n fìyà jẹ Jésù gan-an lọ́jọ́ yẹn, síbẹ̀ ẹnì kan wà tó jẹ́ pé ohun tó mú mọ́ra ju ti Jésù lọ. Kódà, ohun kékeré kọ́ lẹni náà yááfì lọ́jọ́ yẹn. Ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì sẹ́ni tó tún lè fìfẹ́ hàn sí wa lọ́nà tó ga jùyẹn lọ láyé àti lọ́run. Kí lẹni náà ṣe? Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, ìyẹn ìfẹ́.

      Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ Tí Jèhófà Fi Hàn

      4. Báwo ni ọ̀gágun Róòmù kan ṣe rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán, kí ló sì sọ lẹ́yìn náà?

      4 Nígbà tí ọ̀gágun Róòmù tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù rí i tí òkùnkùn ṣú, tí ilẹ̀ sì mì tìtì lọ́nà tó lágbára, ẹnu yà á gan-an. Ó wá sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run nìyí.” (Mátíù 27:54) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí ọ̀gágun náà rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán. Ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin yìí ti bá wọn lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run Gíga Jù Lọ! Àmọ́ o, báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Ọmọ yẹn àti Bàbá ẹ̀ ṣe lágbára tó?

      5. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe iye ọdún tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti jọ wà?

      5 Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Èyí fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run ti wà kí ayé àtọ̀run tó wà. Báwo ni àkókò tí Ọmọ àti Bàbá ti jọ wà pa pọ̀ ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú bù ú pé á ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàlá ọdún tí ayé àtọ̀run ti wà. Ṣé o mọ bí ọdún yẹn ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ohun kan káwọn èèyàn lè lóye iye ọdún tí wọ́n sọ pé ayé àtọ̀run ti wà. Wọ́n ṣe ilé ńlá kan tí wọ́n fi ṣàfihàn bí àgbáálá ayé yìí ṣe rí, wọ́n wá fa ìlà kan tó gùn tó àádọ́fà (110) mítà sínú ilé náà. Wọ́n sọ pé táwọn tó wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ bá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlà náà, ẹsẹ̀ kan tí wọ́n bá gbé máa dúró fún nǹkan bíi mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún. Lápá ìparí ìlà náà, wọ́n fa ìlà bíńtín kan tí kò gùn ju fọ́nrán irun kan ṣoṣo, wọ́n sì sọ pé ó dúró fún gbogbo iye ọdún téèyàn ti wà. Ìyẹn mà ga o! Àmọ́, ká tiẹ̀ sọ pé òótọ́ lohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ yìí, gbogbo ọdún yẹn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ iye ọdún tí Ọmọ Ọlọ́run ti wà! Iṣẹ́ wo ló ń ṣe ní gbogbo àkókò yẹn?

      6. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe lọ́run kó tó wá sí ayé? (b) Báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó?

      6 Ńṣe ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ pé: “Láìsí [Ọmọ], kò sí nǹkan kan tó wà.” (Jòhánù 1:3) Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jọ ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan tó kù. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an bí wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ pa pọ̀! Gbogbo wa la mọ̀ pé ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín òbí àtọmọ máa ń jinlẹ̀ gan-an. Ìfẹ́ sì jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Torí náà, ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù jinlẹ̀ gan-an torí àìmọye ọdún ni wọ́n ti jọ wà pa pọ̀. Ká sòótọ́, kò sí ìfẹ́ tó lágbára tó ìfẹ́ àárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.

      7. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni Jèhófà sọ tó fi hàn pé inú ẹ̀ dùn sí i?

      7 Síbẹ̀, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, kí wọ́n lè bí i bí ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ èèyàn. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù ò fi sí lọ́dọ̀ Jèhófà lọ́run, ó sì dájú pé àárò ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n yìí máa sọ ọ́ gan-an. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà ń wo Jésù látọ̀run, tó sì ń kíyè sí i bó ṣe ń dàgbà di ọkùnrin pípé. Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi. Ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí Ọmọ rẹ̀ yìí gan-an. Kódà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa ṣe ló ṣe, ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ pé kó ṣe ló sì máa ń ṣe. Ó dájú pé Jésù múnú Jèhófà dùn gan-an!​—Jòhánù 5:36; 17:4.

      8, 9. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù fara dà lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, báwo ló sì ṣe rí lára Baba rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà, kó sì kú?

      8 Àmọ́, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ṣe rí lára Jèhófà? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n da Jésù, táwọn jàǹdùkú sì wá mú un lóru ọjọ́ yẹn? Ṣé o rò pé inú Jèhófà máa dùn nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jésù sá lọ, táwọn èèyàn sì mú un lọ síbi tí wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n ń fi Ọmọ ẹ̀ ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tutọ́ sí i lára, tí wọ́n sì ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń na Ọmọ ẹ̀ lẹ́gba, tí ẹgba náà sì dá egbò sí i lẹ́yìn yánnayànna? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi ìṣó kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ Ọmọ rẹ̀ mọ́ òpó igi, táwọn èèyàn sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ bó ṣe wà lórí igi oró? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń jẹ̀rora, tó sì ké jáde pé kí Bàbá òun ran òun lọ́wọ́? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù mí èémí ìkẹyìn, tó wá di pé fúngbà àkọ́kọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣaláìsí?​—Mátíù 26:14-16, 46, 47, 56, 59, 67; 27:38-44, 46; Jòhánù 19:1.

      9 A ò lè sọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó ń wo ọmọ ẹ̀ báwọn èèyàn ṣe ń fìyà jẹ ẹ́, tí wọ́n sì pa á. Àmọ́, a mọ̀ pé ó ní láti ní ìdí pàtàkì kan tí Jèhófà fi gbà kí gbogbo nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní láti fara da gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó mú kóun fara dà á nínú Jòhánù 3:16. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì gan-an débi táwọn kan fi sọ pé òun ló ṣàkópọ̀ Ìwé Ìhìn Rere. Ẹsẹ náà sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Èyí fi hàn pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà ṣe ohun tó ṣe yẹn. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni Jèhófà fún wa bó ṣe rán Ọmọ ẹ̀ wá sáyé, kó lè jìyà, kó sì kú nítorí wa. Èyí ni ìfẹ́ tó ga jù lọ!

      “Ọlọ́run . . . fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”

      Kí Ni Ìfẹ́ Túmọ̀ Sí?

      10. Kí lohun táwa èèyàn nílò jù lọ, kí nìdí táwọn èèyàn ò fi lè ṣàlàyé ohun tí “ìfẹ́” jẹ́ gan-an?

      10 Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” túmọ̀ sí? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìfẹ́ lohun táwa èèyàn nílò jù lọ. Látìgbà tí wọ́n ti bí àwa èèyàn títí dọjọ́ ikú la máa ń fẹ́ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí wa. Kódà, ó le débi pé tí wọn ò bá fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan, ayé lè sú u kó sì kú. Àmọ́, pẹ̀lú bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó yìí, ó yani lẹ́nu pé èèyàn ò lè ṣàlàyé ohun tí ìfẹ́ jẹ́. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kì í wọ́n lẹ́nu àwọn èèyàn. Àìmọye ìwé, orin àti ewì ni wọ́n ti kọ nípa ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò tíì lè sọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ gan-an. Kódà, bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” lóríṣiríṣi ọ̀nà ti mú kó túbọ̀ ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ ohun tó túmọ̀ sí gan-an.

      11, 12. (a) Ibo la ti lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa ìfẹ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? (b) Ọ̀rọ̀ mélòó ni wọ́n lò fún “ìfẹ́” nínú èdè Gíríìkì àtijọ́, ọ̀rọ̀ wo la sì lò jù fún “ìfẹ́” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (d) Tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe nínú Bíbélì, kí ló sábà máa ń túmọ̀ sí?

      11 Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Ohun tẹ́nì kan bá ṣe ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lóòótọ́.” Bíbélì jẹ́ ká mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣoore fáwa èèyàn, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìfẹ́ tó ga jù lọ tó fi hàn nígbà tó yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ kó lè kú torí wa. Ká sòótọ́, kò sọ́nà míì téèyàn tún lè gbà fìfẹ́ hàn ju ohun tí Jèhófà ṣe yẹn! Nínú àwọn orí tó wà níwájú, a máa rí oríṣiríṣi ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn. Bákan náà, a lè túbọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ìfẹ́” nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n lò fún “ìfẹ́” nínú èdè Gíríìkì àtijọ́.a Nínú ọ̀rọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà, èyí tí wọ́n lò jù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni a·gaʹpe. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé a·gaʹpe ni “ọ̀rọ̀ tó lágbára jù lọ téèyàn lè lò fún ìfẹ́.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

      12 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe sábà máa ń túmọ̀ sí ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà. Torí náà, kì í ṣe ìfẹ́ tá a ní sẹ́nì kan torí bí ọ̀rọ̀ ẹni yẹn ṣe rí lára wa. Ńṣe la máa ń dìídì fi irú ìfẹ́ yìí hàn sí gbogbo èèyàn, torí a mọ̀ pé ohun tó tọ́ nìyẹn. Ohun tó mú kí ìfẹ́ yìí wúni lórí jù ni pé, ẹni tó bá ń fi irú ìfẹ́ yìí hàn kì í ro tara ẹ̀ nìkan. Bí àpẹẹrẹ, tún wo Jòhánù 3:16 lẹ́ẹ̀kan sí i. “Ayé” wo ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ débi pé ó fún un ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo? Ọ̀rọ̀ náà “ayé” ń tọ́ka sí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní ìràpadà Jésù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ pé ìgbé ayé wọn ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ṣé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ sí Jèhófà bíi ti Ábúráhámù olóòótọ́? (Jémíìsì 2:23) Rárá o, àmọ́ Jèhófà ń fìfẹ́ ṣoore fún gbogbo èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun ńlá ló ná an. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí pa dà. (2 Pétérù 3:9) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì ń fayọ̀ sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

      13, 14. Kí ló fi hàn pé a·gaʹpe jẹ́ ìfẹ́ tó tọkàn wá?

      13 Àmọ́, èrò tí kò tọ́ làwọn kan ní lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa a·gaʹpe. Wọ́n rò pé kì í ṣe ìfẹ́ tó tọkàn wá, pé ìfẹ́ tó tutù ni. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni, ó sì máa ń tọkàn wá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jòhánù kọ̀wé pé, “Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ a·gaʹpe ló lò. Ṣé a lè sọ pé irú ìfẹ́ yìí ò jinlẹ̀? Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Jésù sọ pé, “Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó lò jẹ mọ́ phi·leʹo. (Jòhánù 3:35; 5:20) Jèhófà máa ń fìfẹ́ hàn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àmọ́, kì í ṣe bọ́rọ̀ ẹnì kan ṣe rí lára Jèhófà nìkan ló máa ń pinnu bóyá ó máa fìfẹ́ hàn sẹ́ni yẹn. Ìlànà òdodo rẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu ló máa ń lò láti ṣe bẹ́ẹ̀.

      14 Bá a ṣe rí i, gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà ló wúni lórí, tó sì fani mọ́ra. Àmọ́, ìfẹ́ ló fani mọ́ra jù nínú gbogbo wọn. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lohun pàtàkì tó mú ká sún mọ́ ọn. Inú wa sì dùn pé ìfẹ́ ló gbawájú lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

      “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

      15. Kí ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà náà ìfẹ́, tí kò sọ nípa àwọn ànímọ́ ẹ̀ tó kù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      15 Nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà mẹ́rin tó gbawájú, Bíbélì sọ nǹkan kan nípa ìfẹ́ tí kò sọ nípa àwọn mẹ́ta tó kù. Ìwé Mímọ́ kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ọgbọ́n. Ó ní àwọn ànímọ́ yẹn ni, òun ni Orísun wọn, ọ̀nà tó sì ń gbà lò wọ́n ló dáa jù. Àmọ́, Bíbélì sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ànímọ́ kẹrin. Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”b (1 Jòhánù 4:8) Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

      16-18. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́”? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé èèyàn ni Jèhófà fi ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́?

      16 Nígbà tí Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run àti ìfẹ́ dọ́gba. Ó ṣe tán, a ò lè yí ọ̀rọ̀ yẹn pa dà ká wá sọ pé “ìfẹ́ jẹ́ Ọlọ́run.” Jèhófà kọjá ẹni tá a lè fi wé ìwà àti ìṣe lásánlàsàn. Ọlọ́run wà lóòótọ́, ó máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára, ó sì ní oríṣiríṣi ànímọ́ míì láfikún sí ìfẹ́. Àmọ́, ìfẹ́ làkọ́kọ́ lára ìwà àti ìṣe Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì fi sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ló ń fi ìfẹ́ hàn.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Òótọ́ ni pé agbára tí Jèhófà ní ló fi máa ń ṣe nǹkan, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ ló sì máa ń darí ẹ̀ tó bá ń ṣe nǹkan náà. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló máa ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìfẹ́ rẹ̀ sì máa ń hàn nínú bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù.

      17 A sábà máa ń sọ pé Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn. Torí náà, ọ̀nà tó dáa jù téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ ni pé kó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àwa èèyàn náà máa ń fìfẹ́ hàn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ kíyè sóhun tí Jèhófà sọ fún Ọmọ rẹ̀ nígbà tó fẹ́ dá àwa èèyàn, ó sọ pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa, kí wọ́n jọ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá sí ayé, àwa èèyàn nìkan la lè pinnu pé a máa fìfẹ́ hàn, ìyẹn ló sì jẹ́ ká fìwà jọ Baba wa ọ̀run. Jèhófà fi onírúurú ohun alààyè ṣàpẹẹrẹ àwọn ìwà àti ìṣe pàtàkì tó ní. Àmọ́, Jèhófà lo àwa èèyàn, tó jẹ́ èyí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lára àwọn ohun tó dá sáyé, láti ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́, tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù.​—Ìsíkíẹ́lì 1:10.

      18 Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tá ò sì mọ tara wa nìkan, ńṣe là ń gbé ìfẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lára ànímọ́ Jèhófà yọ. Bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Àmọ́, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa?

      Jèhófà Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa

      19. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà dá àwọn nǹkan?

      19 Ọjọ́ pẹ́ tí ìfẹ́ ti wà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Rò ó wò ná, kí lo rò pé ó mú kí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan? Ṣé torí pé ó dá nìkan wà ni, àbí torí pé ó ń wá ẹni tí wọ́n á jọ máa ṣe nǹkan? Rárá o! Jèhófà pé pérépéré, láìkù síbì kan, kò sì nílò olùrànlọ́wọ́ kankan. Àmọ́ torí pé ó ní ìfẹ́, ó dá àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ká lè máa gbádùn àwọn nǹkan tó dá, ká sì máa láyọ̀. Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.” (Ìfihàn 3:14) Lẹ́yìn ìyẹn, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí di Àgbà Òṣìṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, Jèhófà sì lò ó láti dá gbogbo nǹkan tó kù, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:4, 7; Kólósè 1:16) Jèhófà fún àwọn áńgẹ́lì yìí ní òmìnira, làákàyè àti ìmọ̀lára, èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti mú ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, wọ́n máa ń di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Torí náà, a lè sọ pé àwọn áńgẹ́lì yìí nífẹ̀ẹ́ torí pé Jèhófà ti kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn.

      20, 21. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Ádámù àti Éfà, àmọ́ kí ni wọ́n ṣe?

      20 Bọ́rọ̀ àwa náà ṣe rí nìyẹn. Àtìgbà tí Jèhófà ti dá Ádámù àti Éfà ló ti ń fìfẹ́ hàn sí wọn lónírúurú ọ̀nà. Gbogbo ibi tí wọ́n bá yíjú sí nínú Párádísè ni wọ́n ti ń rí ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì, ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá síbẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ṣé o ti wọnú ọgbà kan tó rẹwà gan-an rí? Kí lo fẹ́ràn jù nínú ọgbà náà? Ṣé ìmọ́lẹ̀ tó ń yọ láàárín àwọn ewé tó wà lórí igi ni? Ṣé àwọn òdòdó tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ rírẹwà ni? Ṣé ìró omi tó ń dún bó ṣe ń ṣàn lọ àti orin àwọn ẹyẹ àtàwọn kòkòrò tó ń kùn ni? Àbí òórùn dídùn tó ń jáde láti ara àwọn igi, èso àti òdòdó lo fẹ́ràn jù? Ká sòótọ́ àwọn ọgbà máa ń rẹwà gan-an, àmọ́ kò sí ọgbà kankan lónìí tó rẹwà tó ọgbà Édẹ́nì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

      21 Ìdí ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló gbin ọgbà náà! Ó dájú pé ó máa rẹwà kọjá sísọ. Oríṣiríṣi igi tó rẹwà àtàwọn èso tó dùn gan-an ló wà níbẹ̀. Ọgbà náà tóbi, àwọn odò tó ń sàn wà níbẹ̀, oríṣiríṣi ẹranko tó fani mọ́ra ló sì wà níbẹ̀. Ádámù àti Éfà ní gbogbo nǹkan tó lè mú kí ayé wọn dùn, títí kan iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀. Wọ́n sì tún láyọ̀ bí wọ́n ṣe wà pa pọ̀. Jèhófà ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì yẹ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò kí wọ́n ṣègbọràn sí Baba wọn ọ̀run torí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì, orí 2.

      22. Báwo lohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ ṣe fi hàn pé ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀?

      22 Ó dájú pé ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe máa dun Jèhófà gan-an! Àmọ́, ṣéyẹn wá mú kí Jèhófà kórìíra àwọn èèyàn? Rárá o! Rántí pé “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” (Sáàmù 136:1) Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà fìfẹ́ ṣètò ìràpadà fún àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bá a ṣe sọ ṣáájú, ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà ṣe láti gba àwa èèyàn là ni bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe ẹbọ ìràpadà fún wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—1 Jòhánù 4:10.

      23. Kí ni ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìbéèrè pàtàkì wo la máa dáhùn nínú orí tó kàn?

      23 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti ń ṣe ohun tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ti ṣe tó fi hàn pé “òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká láyọ̀ ká sì wà níṣọ̀kan. Abájọ tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Àmọ́, o lè máa rò ó pé, ‘Ṣé Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi?’ A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú orí tó kàn.

      a Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà phi·leʹo láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ọmọ ìyá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀rọ̀ náà stor·geʹ túmọ̀ sí ìfẹ́ tẹ́nì kan ní sáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé. Ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n lò ní 2 Tímótì 3:3, ẹsẹ náà sì sọ pé irú ìfẹ́ yìí máa ṣọ̀wọ́n láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ọ̀rọ̀ náà Eʹros túmọ̀ sí ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Wọn ò lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa irú ìfẹ́ yẹn.​—Òwe 5:15-20.

      b Àwọn gbólóhùn míì nínú Ìwé Mímọ́ fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀” àti pé “Ọlọ́run . . . jẹ́ iná tó ń jóni run.” (1 Jòhánù 1:5; Hébérù 12:29) Àmọ́, ó ṣe kedere pé ńṣe ni Bíbélì kàn ń fi Jèhófà wé àwọn nǹkan yẹn. Jèhófà dà bí ìmọ́lẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́ àti adúróṣinṣin. Kò sí “òkùnkùn,” ìyẹn àìmọ́, nínú rẹ̀ rárá. A sì tún lè fi Jèhófà wé iná torí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa nǹkan run.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • Sáàmù 63:1-11 Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa? Kí ló sì dá wa lójú bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

      • Hóséà 11:1-4; 14:4-8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ísírẹ́lì (tàbí, Éfúrémù) máa ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe fún wọn tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn bí Bàbá ṣe máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ?

      • Mátíù 5:43-48 Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń ṣe fún gbogbo èèyàn tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn bí Bàbá ṣe máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ?

      • Jòhánù 17:15-26 Báwo ni àdúrà tí Jésù gbà torí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

  • Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Inú obìnrin kan ò dùn, ó sì ń sunkún.

      ORÍ 24

      Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

      1. Èrò tí kò tọ́ wo ló máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn, títí kan àwọn Kristẹni tòótọ́?

      ṢÉ Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ? Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn lápapọ̀, bí Jòhánù 3:16 ṣe sọ. Àmọ́, wọ́n máa ń rò ó pé: ‘Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ èmi yìí láéláé.’ Kódà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn Kristẹni tòótọ́ náà lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ọkùnrin kan tí nǹkan tojú sú sọ pé: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti gbà pé Ọlọ́run tiẹ̀ rí tèmi rò.” Ṣé ìwọ náà máa ń ronú bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

      2, 3. Ta ló fẹ́ ká máa rò pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe lè borí èrò yẹn?

      2 Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé ká máa rò pé Jèhófà Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀. Òótọ́ ni pé Sátánì máa ń mú káwọn èèyàn gbéra ga, kí wọ́n sì jọ ara wọn lójú. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́ Sátánì tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rò pé àwọn ò wúlò, inú ẹ̀ sì máa ń dùn téèyàn bá ń ronú bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 7:47-49; 8:13, 44) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí nǹkan le gan-an yìí ló tiẹ̀ máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ jù. Lóde òní, kò sí “ìfẹ́ àdámọ́ni” nínú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Ojoojúmọ́ làwọn ẹlòmíì ń kojú àwọn èèyàn tó burú gan-an, tí wọ́n mọ tara wọn nìkan, tí wọ́n sì jẹ́ alágídí. (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn tí wọ́n ti hùwà àìdáa sí tàbí táwọn èèyàn ti kórìíra fún ọ̀pọ̀ ọdún lè máa ronú pé àwọn ò wúlò, kò sì sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ àwọn.

      3 Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn, má sọ̀rètí nù. Nígbà míì, ọ̀pọ̀ nínú wa la máa ń ro ara wa pin. Àmọ́, ká má gbàgbé pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká lè ‘mú nǹkan tọ́’ ká sì lè “borí àwọn nǹkan [tàbí èrò] tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (2 Tímótì 3:16; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Bíbélì sọ pé: “A . . . máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ níwájú rẹ̀ nínú ohunkóhun tí ọkàn wa ti lè dá wa lẹ́bi, torí Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:19, 20) Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí Bíbélì ti gbà ràn wá lọ́wọ́ láti “jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀” pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.

      Jèhófà Mọyì Rẹ

      4, 5. Báwo ni àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọyì wa?

      4 Àkọ́kọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà. Torí náà, ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ṣe rí lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà yẹn.

      Ológoṣẹ́ kan ń fún ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́ lóúnjẹ.

      “Ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ”

      5 Tá a bá gbọ́ pé ẹnì kan fẹ́ ra ẹyẹ ológoṣẹ́, ó lè yà wá lẹ́nu pé kí ló fẹ́ fi ṣe. Ìdí ni pé nígbà ayé Jésù, ẹyẹ ológoṣẹ́ ni owó rẹ̀ kéré jù téèyàn lè rà láti pa jẹ. Tẹ́nì kan bá ní ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, ó máa ra ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì. Àmọ́ Jésù wá sọ pé téèyàn bá ní ẹyọ owó méjì lọ́wọ́, ẹyẹ ológoṣẹ́ márùn-ún ni wọ́n máa tà fún un dípò mẹ́rin. Ṣe ló dà bíi pé èyí tí wọ́n fi ṣe ènì yẹn ò níye lórí rárá. Òótọ́ ni pé àwọn ẹyẹ yẹn lè má já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn, àmọ́ ojú wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wò wọ́n? Jésù sọ pé: “Ọlọ́run ò gbàgbé ìkankan nínú wọn [títí kan èyí tí wọ́n fi ṣe ènì pàápàá].” (Lúùkù 12:6, 7) Ọ̀rọ̀ yìí wá jẹ́ kí ohun tí Jésù sọ túbọ̀ yé wa. Tí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo bá níye lórí tó bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, mélòómélòó wá ni àwa èèyàn! Bí Jésù ṣe sọ, Jèhófà mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa látòkè délẹ̀. Kódà, ó mọ iye irun tó wà lórí wa!

      6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù mọ ohun tó ń sọ nígbà tó sọ pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa?

      6 Ṣé kò yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa? Àwọn kan le máa rò pé bóyá Jésù ò mọ ohun tó ń sọ. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká ronú nípa ìrètí àjíǹde. Ká sọ pé ẹnì kan kú, ṣé ẹ rò pé Jèhófà máa lè tún ẹni náà dá tí kò bá mọ ẹni náà dunjú? Jèhófà mọyì wa gan-an ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa ló mọ̀, títí kan àwọn ìsọfúnni tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì ara wa, gbogbo ohun tá a ti ṣe látìgbà tá a ti wà láàyè àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa.a Torí náà, tá a bá sọ pé Jèhófà mọ iye irun orí wa tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000), kékeré nìyẹn jẹ́ tá a bá fi wé ohun tó mọ̀ nípa wa kó tó lè jí wa dìde.

      Ohun Tó Mú Kí Jèhófà Mọyì Rẹ

      7, 8. (a) Kí ni díẹ̀ lára ànímọ́ tí Jèhófà máa ń wá nínú ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Jèhófà mọyì?

      7 Ohun kejì ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà mọyì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an sí àwọn ànímọ́ rere tá a ní àtàwọn ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Ọba Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá, ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.” (1 Kíróníkà 28:9) Torí náà, ohun tó dáa ni Ọlọ́run máa ń wá nínú ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nínú ayé oníwà ipá, tó kún fún ìkórìíra yìí. Inú ẹ̀ máa ń dùn gan-an tó bá rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tó jẹ́ olóòótọ́, tó sì máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dáa nígbà gbogbo. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe tó bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, tó sì fẹ́ sọ ohun tóun mọ̀ fáwọn ẹlòmíì? Jèhófà sọ fún wa pé òun ń kíyè sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa òun fáwọn ẹlòmíì. Ó tiẹ̀ ní “ìwé ìrántí kan” tó ń kọ nípa gbogbo “àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye lójú rẹ̀.

      8 Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Jèhófà mọyì? Ó dájú pé ó mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe láti fara wé Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. (1 Pétérù 2:21) Iṣẹ́ pàtàkì kan tí Ọlọ́run mọyì ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Róòmù 10:15 sọ pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tó ń kéde ìhìn rere àwọn ohun rere mà rẹwà o!” Àmọ́ ó lè máa ṣe wá bíi pé, ẹsẹ̀ wa ò rẹwà. Ṣùgbọ́n ńṣe lọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ohun táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, ó dájú pé gbogbo ohun tá à ń ṣe ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó sì mọyì ẹ̀ gan-an.​—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

      9, 10. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì bá a ṣe ń fara da onírúurú ìṣòro? (b) Kí ni Jèhófà kì í ṣe bó ṣe ń kíyè sí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?

      9 Jèhófà tún mọyì ìfaradà wa. (Mátíù 24:13) Rántí pé, ńṣe ni Sátánì ń fẹ́ kó o kẹ̀yìn sí Jèhófà. Gbogbo ìgbà tó o bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, lò ń jẹ́ kí Sátánì mọ̀ pé òpùrọ́ ni. (Òwe 27:11) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ìdí ni pé àìlera, àìrówó gbọ́ bùkátà, àníyàn àtàwọn ìṣòro míì lè mú kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nira gan-an. Ìrẹ̀wẹ̀sì tún lè mú wa, tí ọ̀nà ò bá gba ibi tá a fojú sí. (Òwe 13:12) Jèhófà mọyì ìfaradà wa gan-an láwọn àsìkò yẹn. Ìdí nìyẹn tí Ọba Dáfídì fi sọ pé kí Jèhófà fi omijé òun sínú “ìgò awọ” rẹ̀, tó sì sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?” (Sáàmù 56:8) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ò ní gbàgbé, kò sì ní fojú kéré gbogbo omijé àti ìyà tó ń jẹ wá bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i, torí pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀.

      Jèhófà mọyì bá a ṣe ń fara da oríṣiríṣi àdánwò

      10 Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tá a rí yìí, ó ṣì lè máa ṣe wá bíi pé a ò wúlò lójú Jèhófà. A lè máa rò ó pé: ‘Ọ̀pọ̀ èèyàn míì ló wà tó dáa jù mí lọ. Tí Jèhófà bá sì fi ohun tí mò ń ṣe wé tiwọn, ó dájú pé inú ẹ̀ ò ní dùn sí mi.’ Jèhófà kì í fi wá wé àwọn míì, ó máa ń gba tiwa rò, kì í sì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Gálátíà 6:4) Jèhófà máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa, ó sì máa ń láyọ̀ tó bá rí i pé à ń gbìyànjú láti máa ṣe rere. Kódà, tí nǹkan tá à ń ṣe ò bá tiẹ̀ tó nǹkan lójú tiwa, Jèhófà mọyì ẹ̀.

      Ibi Tá A Dáa Sí Ni Jèhófà Ń Wo

      11. Kí ni ìtàn Ábíjà kọ́ wa nípa Jèhófà?

      11 Ìkẹta, bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ wá wò, ó ń fara balẹ̀ wá ibi tá a dáa sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ìlà ìdílé Ọba Jèróbóámù run, torí pé wọ́n ti di apẹ̀yìndà, ó ní kí wọ́n ṣe ìsìnkú ẹ̀yẹ fún Ábíjà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì rí ohun rere nínú rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 14:1, 10-13) Ńṣe ni Jèhófà yẹ ọkàn ọ̀dọ́kùnrin yẹn wò, ó sì rí “ohun rere nínú rẹ̀.” Bó ti wù kí ohun rere yẹn kéré tó, Jèhófà rí i dájú pé ìtàn yẹn wà nínú Bíbélì. Ó tiẹ̀ san ọ̀dọ́kùnrin yẹn lẹ́san, ó ṣojú àánú sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé apẹ̀yìndà ló ti wá.

      12, 13. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọba Jèhóṣáfátì ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń rí iṣẹ́ rere wa kódà nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn iṣẹ́ àti ìwà rere wa, kí ni kò sì ní ṣe láé?

      12 Àpẹẹrẹ míì tó túbọ̀ jẹ́ ká rí i pé ibi tá a dáa sí ni Jèhófà máa ń wò ni ti Ọba Jèhóṣáfátì. Ọba rere ni ọba yìí, àmọ nígbà kan ó hùwà òmùgọ̀, wòlíì Jèhófà sọ fún un pé: “Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ.” Ọ̀ràn rèé o! Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà kò parí síbẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Síbẹ̀, àwọn ohun rere kan wà tí a rí nínú rẹ.” (2 Kíróníkà 19:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń bínú sí Jèhóṣáfátì, ó ṣì rí ibi tó dáa sí. Ẹ ò rí i pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà ẹ̀dá aláìpé! Nígbà tí inú bá ń bí wa sáwọn èèyàn, a lè máà rí ohun rere tí wọ́n ṣe. Nígbà tí àwa fúnra wa náà bá sì dẹ́ṣẹ̀, ìjákulẹ̀, ìtìjú àti bá a ṣe máa ń dá ara wa lẹ́bi lè máà jẹ́ ká rí àwọn nǹkan rere tá a ti ṣe. Àmọ́, ká máa rántí pé tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì ń sapá láti má ṣe pa dà sídìí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa dárí jì wá.

      13 Bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ ọ́ wò, ńṣe ló ń gbójú fo irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, bí ẹni tó ń wá góòlù ṣe ń fọwọ́ rọ́ òkúta lásán tì sápá kan. Àwọn ànímọ́ àti iṣẹ́ rere rẹ ńkọ́? Àwọn yẹn gangan ni “góòlù” tí Jèhófà ń wá! Ṣé o ti kíyè sí báwọn òbí kan ṣe máa ń tọ́jú àwòrán tí ọmọ wọn yà tàbí iṣẹ́ kan tó ṣe níléèwé, tí wọ́n á sì wá fi hàn án lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tọ́mọ ọ̀hún lè ti gbàgbé pé òun ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀? Jèhófà ni Òbí tó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ jù lọ. Tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ àti ìwà rere wa láé. Kódà, ìwà àìṣòdodo ló kà á sí láti gbàgbé wọn, a sì mọ̀ pé kì í ṣe aláìṣòdodo. (Hébérù 6:10) Jèhófà tún máa ń ṣe ohun míì kó lè rí ibi tá a dáa sí.

      14, 15. (a) Kí nìdí tá a fi ṣeyebíye lójú Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá? Sọ àpèjúwe kan. (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe sáwọn ìwà rere tá a ní, ojú wo ló sì fi ń wo àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́?

      14 Dípò kí Jèhófà máa wo àṣìṣe wa, ìwà tó dáa tá a ní àtàwọn ohun tó dáa tá a lè ṣe ló máa ń wò. Àpèjúwe kan rèé: Àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn àwòrán tàbí iṣẹ́ ọnà míì tó bà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan lọ sí ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí nílùú London, tó sì ba àwòrán kan tó ṣeyebíye jẹ́, kò sẹ́ni tó sọ pé kí wọ́n ju àwòrán náà nù torí pé ó ti bà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ẹsẹ̀ làwọn tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà bẹ̀rẹ̀ sí í tún àwòrán náà ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwòrán yẹn ṣeyebíye lójú àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà. Ṣé o ò wá níye lórí ju àwòrán lásán ni? Ó dájú pé o níye lórí ju irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, àìpé ẹ lè jẹ́ kó o rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan. (Sáàmù 72:12-14) Jèhófà Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá àwa èèyàn máa ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti mú kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń ṣègbọràn sí i di pípé.​—Ìṣe 3:21; Róòmù 8:20-22.

      15 Ó dájú pé Jèhófà ń rí àwọn ìwà tó dáa tá a ní, báwa fúnra wa ò bá tiẹ̀ rí i. Bá a sì ṣe ń sìn ín, á mú káwọn ìwà rere tá a ní máa dáa sí i títí tá a fi máa di ẹni pípé. Ohun yòówù kí ayé Sátánì ti fojú wa rí, ó dájú pé ohun iyebíye ni Jèhófà ka àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sí.​—Hágáì 2:7.

      Jèhófà Ń Fi Hàn Pé Òun Nífẹ̀ẹ́ Wa

      16. Ẹ̀rí wo ló lágbára jù lọ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú?

      16 Ìkẹrin, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dájú pé ẹbọ ìràpadà Kristi ni ohun pàtàkì tó fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa nígbà tó sọ pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Ká má gbàgbé láé pé ikú tí Jésù kú lórí igi oró àti ìrora ńlá tí Jèhófà fara dà bó ṣe ń wò ó tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń kú jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dunni pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé torí wọn ni Jésù ṣe kú. Wọ́n gbà pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tí Jésù ń kú fún. Àmọ́, rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Síbẹ̀, ó sọ pé: ‘Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’​—Gálátíà 1:13; 2:20.

      17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fà wá sún mọ́ ara rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀?

      17 Jèhófà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí ẹbọ ìràpadà Kristi lè ṣe wá láǹfààní. Jésù sọ pé: “Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.” (Jòhánù 6:44) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa ń fà wá sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, ó sì tún fún wa ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó ń dé ọ̀dọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni. Bákan náà, ó máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ká sì fi wọ́n sílò láìka àìpé wa sí. Torí náà, Jèhófà lè sọ nípa wa, bó ṣe sọ nípa Ísírẹ́lì pé: “Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jẹ́ ìfẹ́ ayérayé. Ìdí nìyẹn tí mo fi fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”​—Jeremáyà 31:3.

      18, 19. (a) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà fún wa tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa ó sì fẹ́ ká sún mọ́ òun, kí ló sì fi hàn pé òun fúnra rẹ̀ ló ń bójú tó èyí? (b) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń mọ ẹ̀dùn ọkàn wa lára?

      18 Àdúrà ni ọ̀nà tó lágbára jù lọ tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà, torí pé bó ṣe fún wa láǹfààní láti gbàdúrà sí òun fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Bíbélì rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Elétí gbáròyé ni. Òun sì ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Kò fún ẹlòmíì láṣẹ láti máa gbọ́ àdúrà, kódà kò fún Ọmọ rẹ̀ pàápàá láṣẹ yẹn. Rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà sí òun fàlàlà, ká sì sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa fóun. Tá a bá ń gbàdúrà, ṣé Jèhófà kàn máa ń gbọ́ àdúrà wa lásán ni? Rárá o. Àdúrà wa ṣe pàtàkì sí i.

      19 Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Kí ni ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò? Kristẹni olóòótọ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà sọ pé: “Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni kẹ́nì kan mọ ìrora ẹlòmíì nínú ọkàn rẹ̀.” Ṣé ìrora wa tiẹ̀ kan Jèhófà? Wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà, ó ní: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.” (Àìsáyà 63:9) Kì í ṣe pé Jèhófà kàn rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, ó mọ̀ ọ́n lára. Ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ bó ṣe mọ̀ ọ́n lára tó, ó sọ pé: “Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.”b (Sekaráyà 2:8) Ká sòótọ́, tẹ́nì kan bá fọwọ́ kan ojú wa ó máa dùn wá gan-an. Èyí fi hàn pé tá a bá wà nínú ìṣòro, àánú wa máa ń ṣe Jèhófà gan-an. Kódà, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.

      20. Èrò wo ló yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà ní Róòmù 12:3?

      20 Tí òtítọ́ bá jinlẹ̀ nínú Kristẹni kan, kò ní torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun kó wá máa ronú pé òun sàn ju àwọn míì lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.” (Róòmù 12:3) Nítorí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Baba wa ọ̀run ń fìfẹ́ hàn sí wa tí èyí sì ń mú kára tù wá, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ àṣekára wa tàbí torí pé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ wa la ṣe ní àǹfààní yìí.​—Lúùkù 17:10.

      21. Àwọn irọ́ wo ni Sátánì ń pa tí kò yẹ ká gbà gbọ́, ọ̀rọ̀ wo sì ni Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ táá máa fi wá lọ́kàn balẹ̀?

      21 Ẹ jẹ́ kí kálukú wa máa sa gbogbo ipá wa láti má ṣe gba irọ́ Sátánì gbọ́, títí kan irọ́ tó pa pé a ò wúlò rárá tàbí pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ wa. Ṣé àwọn ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó jẹ́ kó o rò pé èèyàn burúkú ni ẹ́ àti pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ ẹ? Tàbí ò ń rò ó pé àwọn nǹkan tó dáa tó ò ń ṣe ti kéré jù fún Ọlọ́run láti kíyè sí? Àbí ńṣe lo rò pé o ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú gan-an débi pé ẹbọ ìràpadà Jésù ò lè ṣé ẹ láǹfààní? Máa fi sọ́kàn pé irọ́ pátápátá nìyẹn, má gbà á gbọ́ rárá! Ẹ jẹ́ ká máa rántí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sílẹ̀, kó lè máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Ó dá mi lójú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”​—Róòmù 8:38, 39.

      a Ọ̀pọ̀ ìgbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde ló máa ń rán wa létí agbára tí Jèhófà ní láti rántí nǹkan. Ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù, sọ fún Jèhófà pé: “Ká ní . . . o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!” (Jóòbù 14:13) Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí.” Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí, torí pé gbogbo àwọn òkú tí Jèhófà ní lọ́kàn láti jí dìde ló rántí dáadáa.​—Jòhánù 5:28, 29.

      b Báwọn kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lẹni tó bá fọwọ́ kan àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tọwọ́ bọ ara ẹ̀ lójú tàbí pé ó ń tọwọ́ bọ Ísírẹ́lì lójú, kì í ṣe pé ó ń tọwọ́ bọ Ọlọ́run lójú. Àwọn adàwékọ kan ló túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yẹn torí wọ́n ka ọ̀rọ̀ yẹn sí àrífín. Bí wọ́n ṣe yí ẹsẹ Bíbélì yẹn pa dà kò jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò gan-an débi pé táwọn èèyàn ẹ̀ bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • Sáàmù 139:1-24 Báwo làwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí Ọba Dáfídì láti kọ ṣe fi hàn pé Jèhófà fẹ́ràn wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

      • Àìsáyà 43:3, 4, 10-13 Èrò wo ni Jèhófà ní nípa àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló sì ń ṣe fún wọn?

      • Róòmù 5:6-8 Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá?

      • Júúdà 17-25 Báwo la ṣe lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira láti ṣe bẹ́ẹ̀?

  • “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Obìnrin kan tó lójú àánú.

      ORÍ 25

      “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”

      1, 2. (a) Kí ni abiyamọ sábà máa ń ṣe nígbà tí ọmọ rẹ̀ bá ń ké? (b) Ta lẹni tó máa ń fàánú hàn lọ́nà tó ju tàwọn abiyamọ lọ?

      LÓRU ọjọ́ kan, abiyamọ kan gbọ́ tí ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ń ké. Kíá nìyá ọmọ náà jí. Kì í kúkú sùn wọra mọ́ látìgbà tó ti bí ọmọ yìí. Kí ọmọ rẹ̀ má tíì ké ni, á ti mọ ohun tó ń ṣe é. Ó máa ń mọ̀ bóyá oúnjẹ lọmọ náà ń fẹ́, tàbí kí wọ́n gbé òun mọ́ra, tàbí kí wọ́n ṣáà tọ́jú òun. Àmọ́, ohun yòówù kó fa ẹkún ọmọ náà, ìyá ẹ̀ ò lè ṣe kó má dá a lóhùn. Ojú ẹ̀ ò ní gbà á.

      2 Bí ìyà ṣe máa ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó lágbára jù lọ táwa èèyàn máa ń gbà fìfẹ́ hàn. Àmọ́, ojú àánú Jèhófà Ọlọ́run ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ó máa wù wá ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ká sì wo bí Ọlọ́run wa ṣe máa ń fàánú hàn.

      Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Aláàánú?

      3. Kí nìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n máa ń tú sí “fi àánú hàn” tàbí “ṣe ojú àánú”?

      3 Nínú Bíbélì, ìyọ́nú àti àánú kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń lò lédè Hébérù àti Gíríìkì láti fi ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ olójú àánú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sábà máa ń tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ sí “fi àánú hàn” tàbí “ṣe ojú àánú.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ra·chamʹ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹni tó fi tinútinú ṣàánú ẹni tó fẹ́ràn nígbà tó rí i pé ìyà ń jẹ ẹni náà tàbí tó ṣojú àánú sẹ́ni tó nílò ìrànlọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ni Jèhófà lò láti fi sọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí jọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ilé ọlẹ̀,” wọ́n sì lè túmọ̀ ẹ̀ sí “ojú àánú tí ìyá máa ń ní.”a​—Ẹ́kísódù 33:19; Jeremáyà 33:26.

      Ìyá kan gbé ọmọ ẹ̀ sí àyà rẹ̀.

      “Ṣé obìnrin lè gbàgbé . . . ọmọ tó lóyún rẹ̀?”

      4, 5. Báwo ni àpèjúwe tó wà nínú Bíbélì nípa bí abiyamọ ṣe ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ jòjòló ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí àánú Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó?

      4 Bíbélì lo bí ìyá ṣe ń ṣàánú tàbí yọ́nú sí ọmọ rẹ̀ jòjòló láti fi jẹ́ ká mọ bí àánú tàbí ìyọ́nú Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Àìsáyà 49:15 sọ pé: “Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú tàbí kó má ṣàánú [ra·chamʹ] ọmọ tó lóyún rẹ̀? Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” Àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yẹn jẹ́ ká rí bí àánú tí Jèhófà ní fáwọn èèyàn rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Lọ́nà wo?

      5 Kò ṣeé gbọ́ sétí pé abiyamọ kan gbàgbé láti tọ́jú ọmọ rẹ̀ tàbí fún un lóúnjẹ. Ó ṣe tán, ọmọ jòjòló ò lè dá nǹkan kan ṣe, torí náà tọ̀sántòru ni ìyá ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa tọ́jú ẹ̀ kó sì máa fìfẹ́ hàn sí i. Àmọ́, ó dunni pé àwọn ìyá kan ti pa ọmọ wọn tì, ní pàtàkì láwọn ‘àkókò tí nǹkan le gan-an’ tá a wà yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní “ìfẹ́ àdámọ́ni” mọ́. (2 Tímótì 3:1, 3) Síbẹ̀, Jèhófà sọ pé, “mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” Kò sígbà tí Jèhófà ò ní máa ṣàánú tàbí yọ́nú sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bó ṣe ń ṣàánú wọn lágbára ju bí abiyamọ ṣe ń yọ́nú sí ọmọ rẹ̀ jòjòló tàbí bó ṣe ń ṣàánú ẹ̀. Abájọ tí òǹkọ̀wé kan fi sọ nípa Àìsáyà 49:15 pé: “Tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ yìí ló lágbára jù lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ Ọlọ́run, á jẹ́ pé ó wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tó lágbára jù.”

      6. Èrò wo lọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ẹni tó bá lójú àánú, àmọ́ kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀?

      6 Tẹ́nì kan bá lójú àánú, ṣó túmọ̀ sí pé ojo tàbí òmùgọ̀ lẹni náà? Torí pé àwa èèyàn jẹ́ aláìpé, ọ̀pọ̀ ló gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tó jẹ́ gbajúmọ̀, tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Seneca, tó gbé ayé nígbà tí Jésù wà láyé, sọ pé “aláìlera lẹni tó bá ní ojú àánú.” Ó gbà pé ì báà jẹ́ ohun tó dáa ló ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan tàbí ohun tí kò dáa, kò yẹ kí onítọ̀hún fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ hàn. Seneca sọ pé ẹni tó gbọ́n lè ran ẹni tó wà nínú wàhálà lọ́wọ́, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí káàánú ẹni náà, torí ìyẹn lè mú kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í banú jẹ́. Àmọ́, ńṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ tara ẹ̀ nìkan, kò sì ní lè fàánú hàn látọkàn wá. Ṣùgbọ́n Jèhófà kì í ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ rárá! Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun “ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an, [òun] sì jẹ́ aláàánú.” (Jémíìsì 5:11) A máa rí i nínú orí yìí pé tẹ́nì kan bá lójú àánú kò túmọ̀ sí pé ojo lẹni náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí gbogbo wa lójú àánú. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà tó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń fi àánú àti ìyọ́nú hàn.

      Jèhófà Yọ́nú sí Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì

      7, 8. Ìyà wo ló jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Íjíbítì, kí sì ni Jèhófà ṣe fún wọn?

      7 Tá a bá wo àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, a máa rí i pé ó lójú àánú gan-an. Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló di ẹrú ní Íjíbítì, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gan-an. Àwọn ará Íjíbítì “ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́.” (Ẹ́kísódù 1:11, 14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ torí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Báwo nìyẹn ṣe rí lára Jèhófà, kí ló sì ṣe?

      8 Àánú wọn ṣe Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.” (Ẹ́kísódù 3:7) Jèhófà ò lè rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ tàbí kó gbọ́ igbe ẹkún wọn láìmọ̀ ọ́n lára. Bá a ṣe rí i ní Orí 24 ìwé yìí, Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Bá a sì ṣe mọ̀, ẹni tó bá ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò máa ń mọ̀ ọ́n lára táwọn míì bá ń jìyà, èyí sì jọra pẹ̀lú kéèyàn lójú àánú. Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà kàn mọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ lára nìkan ni, ó tún ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Àìsáyà 63:9 sọ pé: “Ó tún wọn rà nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìyọ́nú rẹ̀.” Jèhófà fi “ọwọ́ agbára” gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní Íjíbítì. (Diutarónómì 4:34) Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún fàánú hàn sí wọn nípa bó ṣe fún wọn lóúnjẹ nínú aginjù, tó sì mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí.

      9, 10. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ léraléra lẹ́yìn tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jẹ́fútà, kí ló sì mú kí Jèhófà gbà wọ́n sílẹ̀?

      9 Jèhófà ń bá a lọ láti máa fàánú hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Ìyà sì máa ń jẹ wọ́n tí wọ́n bá ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tó bá tún yá wọ́n máa ń ronú pìwà dà, wọ́n á sì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Léraléra ló ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Kí nìdí? “Nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ . . . ṣe é.”​—2 Kíróníkà 36:15; Àwọn Onídàájọ́ 2:11-16.

      10 Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jẹ́fútà. Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ámónì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọdún méjìdínlógún torí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n wá kó àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò láàárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà, débi pé ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ bí Ísírẹ́lì ṣe ń jìyà.”b (Àwọn Onídàájọ́ 10:6-16) Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà látọkàn wá, ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ kí ìyà ṣì máa jẹ wọ́n. Torí náà Ọlọ́run yọ́nú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fún Jẹ́fútà lágbára láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.​—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-33.

      11. Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìyọ́nú tàbí ojú àánú?

      11 Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìyọ́nú tàbí ojú àánú? Ohun kan tá a rí kọ́ ni pé tá a bá fẹ́ fi hàn pé a lójú àánú tàbí pé a máa ń yọ́nú sáwọn èèyàn, ó kọjá pé ká kàn bá wọn kẹ́dùn torí oun kan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Rántí àpẹẹrẹ ìyá tó gbọ́ tí ọmọ ẹ̀ ń ké tó sì lọ tọ́jú ẹ̀ torí pé àánú ẹ̀ ṣe é. Lọ́nà kan náà, tí Jèhófà bá gbọ́ igbe àwọn èèyàn rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì mú kára tù wọ́n torí pé ó lójú àánú. Ohun míì tá a tún kọ́ ni pé tẹ́nì kan bá lójú àánú, kò túmọ̀ sí pé ojo lẹni náà. Bá a ṣe sọ, torí pé Jèhófà lójú àánú ló fi jà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Àmọ́, ṣé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni Jèhófà máa ń yọ́nú sí ni?

      Jèhófà Ń Ṣàánú Àwa Èèyàn Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan

      12. Báwo ni Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé àánú àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe Jèhófà?

      12 Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi hàn pé àánú àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun bìkítà fáwọn òtòṣì. Jèhófà mọ̀ pé àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, tó lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan di tálákà. Báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn òtòṣì? Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “O ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní. Kí o lawọ́ sí i dáadáa, kí o má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.” (Diutarónómì 15:7, 10) Jèhófà tún pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe kórè eteetí oko wọn tán, kí wọ́n má sì ṣa irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ rárá. Ńṣe ló yẹ kí wọ́n fi irú àwọn irè oko bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ fáwọn aláìní. (Léfítíkù 23:22; Rúùtù 2:2-7) Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà tẹ̀ lé òfin tí Jèhófà ṣe tó mú káwọn èèyàn gba tàwọn òtòṣì àárín wọn rò, àwọn aláìní ní Ísírẹ́lì kò di atọrọjẹ. Ẹ̀rí lèyí jẹ́ pé Jèhófà máa ń ṣojú àánú sáwọn aláìní.

      13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kò fi ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeré? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà wà nítòsí “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” àti “àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn”?

      13 Bákan náà lóde òní, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò fi ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeré rárá. Ó dájú pé ó ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.” (Sáàmù 34:15, 18) Ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé àwọn gbólóhùn náà, “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” àti “àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn” ń tọ́ka sáwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá torí pé wọ́n máa ń ṣàṣìṣe bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì ń rò pé àwọn ò wúlò. Àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ronú pé Jèhófà jìnnà sí àwọn, àti pé kò lè rójú ráyè tàwọn, torí pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀rọ̀ Dáfídì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn tó ń ronú pé àwọn ò wúlò, kò sì ní pa wọ́n tì. Jèhófà mọ̀ pé ìgbà tá a bá nírú èrò bẹ́ẹ̀ la nílò òun jù lọ, kì í sì í fi wá sílẹ̀ nírú àsìkò bẹ́ẹ̀ torí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la ṣe pàtàkì sí i.

      14 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì ò lè mí dáadáa, ó sì sáré gbé e lọ sílé ìwòsàn. Lẹ́yìn táwọn dókítà yẹ ọmọ náà wò, wọ́n sọ fún ìyá ẹ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ dá ọmọ náà dúró sílé ìwòsàn dọjọ́ kejì. Ṣé ìyá náà máa fi ọmọ ẹ̀ sílẹ̀? Fi í sílẹ̀ kẹ̀! Orí àga tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì ọmọ ẹ̀ nílé ìwòsàn ló sùn mọ́jú! Ohun tí ìyá yẹn ṣe fi hàn pé ó fìwà jọ Baba wa ọ̀run tó jẹ́ olójú àánú! Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:18 wọni lọ́kàn gan-an, ó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ní “ọgbẹ́ ọkàn” tàbí tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí” wa, Jèhófà “wà nítòsí” wa bíi ti òbí onífẹ̀ẹ́ àti olójú àánú, ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́.

      15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́?

      15 Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́? Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń mú ohun tó ń fìyà jẹ wá kúrò. Àmọ́, Jèhófà ti ṣètò ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mára tu àwọn tó ń ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fún wa láwọn ìmọ̀ràn gidi tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nínú ìjọ, Jèhófà fún wa ní àwọn alábòójútó táwọn náà jẹ́ olójú àánú bíi tiẹ̀, tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa ràn wá lọ́wọ́. (Jémíìsì 5:14, 15) Bákan náà, torí pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” ó máa ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 65:2; Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn lè fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè fara dà á dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ìṣòro kúrò. (2 Kọ́ríńtì 4:7) A mà mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè yìí o! Ńṣe lèyí jẹ́ ara àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun jẹ́ olójú àánú.

      16. Kí ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi àánú hàn sí wa, àǹfààní wo lèyí sì ṣe wá?

      16 Àmọ́ o, ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi àánú hàn sí wa ni bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wá pa dà. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe fún wa lẹ́bùn tó ṣeyebíye yìí, èyí ló sì mú ká nírètí láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Rántí pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Abájọ tí Sekaráyà, bàbá Jòhánù Onírìbọmi fi sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀bùn yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé “ojú àánú Ọlọ́run wa” pọ̀ gan-an.​—Lúùkù 1:78.

      Àwọn Ìgbà Tí Jèhófà Fawọ́ Ìyọ́nú Rẹ̀ Sẹ́yìn

      17-19. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń yọ́nú sáwọn èèyàn? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi ṣojú àánú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́?

      17 Ṣóhun tá à ń sọ ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń yọ́nú sí gbogbo èèyàn? Rárá o. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kì í yọ́nú sáwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i. (Hébérù 10:28) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ká lè mọ púpọ̀ sí i.

      18 Léraléra ni Jèhófà máa ń gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, àmọ́ nígbà tó yá kò fàánú hàn sí wọn mọ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò yéé bọ̀rìṣà, kódà wọ́n ṣe é débi pé wọ́n gbé àwọn òrìṣà náà wọnú tẹ́ńpìlì Jèhófà! (Ìsíkíẹ́lì 5:11; 8:17, 18) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún sọ pé: “Wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín, wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.” (2 Kíróníkà 36:16) Ìwà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hù wá burú débi pé wọn ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fàánú hàn sí mọ́. Torí náà, ó tọ̀nà bí Jèhófà ṣe bínú sí wọn. Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí?

      19 Ká sòótọ́, Jèhófà ò lè ṣojú àánú sáwọn èèyàn yẹn mọ́. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Mi ò ní yọ́nú sí wọn tàbí kí n bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní ṣàánú wọn. Kò sì sí ohun tó máa dá mi dúró láti pa wọ́n run.” (Jeremáyà 13:14) Ìdí nìyẹn tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ fi pa run, tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ó máa ń bani nínú jẹ́ gan-an táwọn èèyàn bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà débi pé kò ní lè fàánú hàn sí wọn mọ́!​—Ìdárò 2:21.

      20, 21. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá ti ṣe sùúrù tó fáwọn èèyàn burúkú? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?

      20 Ṣé Jèhófà ti wá yí pa dà ni? Rárá o. Torí pé ó lójú àánú, ó pàṣẹ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mátíù 24:14) Nígbà táwọn olóòótọ́ ọkàn bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà, Jèhófà máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. (Ìṣe 16:14) Àmọ́ iṣẹ́ yìí máa dópin lọ́jọ́ kan. Tí Jèhófà bá jẹ́ kí ayé burúkú yìí máa bá a lọ, tí kò fòpin sí wàhálà àti ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, ìyẹn ò ní fi hàn pé ó lójú àánú. Tí Jèhófà bá ti ṣe sùúrù tó fáwọn èèyàn burúkú, ó máa pa wọ́n run. Ojú àánú ló sì máa mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, torí kó lè gbé “orúkọ mímọ́” rẹ̀ ga, kó sì lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ là. (Ìsíkíẹ́lì 36:20-23) Jèhófà máa mú ìwà burúkú kúrò pátápátá, ó sì máa sọ ayé di tuntun. Jèhófà sọ nípa àwọn ẹni burúkú pé: “Mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn. Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san.”​—Ìsíkíẹ́lì 9:10.

      21 Ní báyìí tí Jèhófà ò tíì pa ayé burúkú yìí run, ó ṣì ń ṣojú àánú sáwọn èèyàn. Kódà ó ṣì fún àwọn èèyàn burúkú láǹfààní láti yí pa dà. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ga jù tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun lójú àánú ni bó ṣe múra tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nínú orí tó kàn, a máa jíròrò àwọn àpèjúwe tí Bíbélì fi ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini pátápátá.

      a Àmọ́, ní Sáàmù 103:13 wọ́n lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ fún irú àánú, tàbí ojú àánú tí bàbá kan ní sáwọn ọmọ ẹ̀.

      b Gbólóhùn náà “ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́” tún lè túmọ̀ sí pé kò lè ṣe sùúrù mọ́. Bíbélì Tanakh​—A New Translation of the Holy Scriptures túmọ̀ rẹ̀ sí pé: “Kò lè fara dà á mọ́ kí ìyà máa jẹ Ísírẹ́lì.”

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • Jeremáyà 31:20 Báwo ni ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà ṣe máa ń rí lára rẹ̀, kí nìyẹn sì kọ́ ẹ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́?

      • Jóẹ́lì 2:12-14, 17-19 Kí làwọn èèyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kí Jèhófà yọ́nú sáwọn, kí lèyí sì kọ́ wa?

      • Jónà 4:1-11 Báwo ni Jèhófà ṣe kọ́ Jónà ní ẹ̀kọ́ nípa bí ìyọ́nú ti ṣe pàtàkì tó?

      • Hébérù 10:26-31 Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lójú àánú?

  • Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Ọkùnrin kan ń gbàdúrà.

      ORÍ 26

      Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

      1-3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì lẹ́yìn tó dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ló mú kára tù ú? (b) Kí ló ṣeé ṣe ká máa rò lẹ́yìn tá a bá dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ni Jèhófà sọ tó fi wá lọ́kàn balẹ̀?

      DÁFÍDÌ kọ̀wé pé: “Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi; bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé. Ara mi ti kú tipiri, àárẹ̀ sì ti bá mi gidigidi.” (Sáàmù 38:4, 8) Nígbà tí ẹ̀rí ọkàn Dáfídì ń dá a lẹ́bi torí pé ó dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé ó gbé ẹrù tó wúwo. Àmọ́, ohun kan wà tó mú kára tù ú. Ó mọ̀ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kò kórìíra ẹlẹ́ṣẹ̀ náà tó bá ṣáà ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì yí pa dà. Ó dá Dáfídì lójú pé ó wu Jèhófà láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Torí náà Dáfídì sọ pé: “Jèhófà, o . . . ṣe tán láti dárí jini.” ​—Sáàmù 86:5.

      2 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rí ọkàn tiwa náà lè máa dá wa lẹ́bi kó sì dà bíi pé ńṣe la gbé ẹrù tó wúwo. Kò sì burú tí inú wa bá bà jẹ́ torí pé a dẹ́ṣẹ̀. Ìdí ni pé ó lè jẹ́ ká ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ká sì ṣàtúnṣe. Àmọ́, ewu kan wà tó yẹ ká sá fún. Ìyẹn ni pé, ó ṣeé ṣe ká ṣì máa dá ara wa lẹ́bi ká sì máa rò pé Jèhófà ò lè dárí jì wá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Sátánì fẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, tá a bá jẹ́ kí ‘ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù bò wá mọ́lẹ̀,’ ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé a ò wúlò mọ́ lójú Jèhófà àti pé irú wa ò yẹ lẹ́ni tó ń sìn ín.​—2 Kọ́ríńtì 2:5-11.

      3 Àmọ́, ṣé Jèhófà gbà pé a ò wúlò lóòótọ́? Rárá o! Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni bó ṣe máa ń dárí jì wá. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ṣe tán láti dárí jì wá. (Òwe 28:13) Torí náà, kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ pé Jèhófà lè dárí jì wá. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tí Jèhófà fi máa ń dárí jini àti bó ṣe ń dárí jini kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa dárí jì wá.

      Ìdí Tí Jèhófà Fi “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

      4. Kí ni Jèhófà máa ń rántí nípa àwa èèyàn, báwo lèyí ṣe kan bó ṣe ń ṣe sí wa?

      4 Jèhófà kì í retí ohun tó kọjá agbára wa. Sáàmù 103:14 sọ pé: “Ó mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Jèhófà máa ń rántí pé erùpẹ̀ lòun fi dá wa, ó sì mọ̀ pé a lè ṣàṣìṣe nígbà míì torí pé aláìpé ni wá. Gbólóhùn náà ó mọ “ẹ̀dá wa” rán wa létí pé Jèhófà dà bí amọ̀kòkò, a sì dà bí amọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Jeremáyà 18:2-6) Bóyá a yàn láti ṣe ohun tó tọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, Jèhófà  máa ń fòye bá gbogbo wa lò torí pé ó mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá kò sì rọrùn fún wa láti ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́ ní gbogbo ìgbà.

      5. Báwo ni ìwé Róòmù ṣe ṣàpèjúwe bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó?

      5 Jèhófà mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀ bí agbára tó máa ń darí àwọn èèyàn, tó sì máa ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó máa yọrí sí ikú. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó? Nínú ìwé Róòmù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: A wà “lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,” bí àwọn ọmọ ogun ṣe máa ń wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gágun wọn (Róòmù 3:9); pé ẹ̀ṣẹ̀ ń “jọba” lórí aráyé bí ọba (Róòmù 5:21); ó “ń gbé” inú wa (Róòmù 7:17, 20); “òfin” rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú wa nígbà gbogbo, ó sì fẹ́ máa darí gbogbo nǹkan tá à ń ṣe. (Róòmù 7:23, 25) Ká sòótọ́, ó rọrùn fún ẹ̀ṣẹ̀ láti darí àwa èèyàn torí pé a jẹ́ aláìpé.​—Róòmù 7:21, 24.

      6, 7. (a) Tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun, kí ni Jèhófà máa ṣe fún ẹni náà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú ká wá máa mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀?

      6 Torí náà, bó ti wù ká sapá tó láti ṣe ohun tó tọ́, Jèhófà mọ̀ pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣègbọràn sí òun lọ́nà pípé. Àmọ́, ó fi dá wa lójú pé tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tá a sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, òun máa dárí jì wá. Èyí sì fi wá lọ́kàn balẹ̀. Sáàmù 51:17 sọ pé: “Àwọn ẹbọ tó ń mú inú Ọlọ́run dùn ni ọkàn tó gbọgbẹ́; ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.” Èyí jẹ́ ká rí i pé tí ọkàn ẹnì kan bá “gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú” torí pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ń dá a lẹ́bi, ó dájú pé Jèhófà ò ní fi ẹni náà sílẹ̀.

      7 Àmọ́, ṣó wá yẹ ká máa mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ torí pé a jẹ́ aláìpé tá a sì mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú? Rárá o! Torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú kò túmọ̀ sí pé ó máa ń gbójú fo ìwà àìtọ́. Àánú rẹ̀ ní ààlà. Ó dájú pé kò ní dárí ji àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, tí wọn ò sì ronú pìwà dà. (Hébérù 10:26) Àmọ́ tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó ṣe tán láti dárí jì í. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó dáa tí Bíbélì gbà ṣàpèjúwe bí ìfẹ́ ṣe ń sún Jèhófà láti dárí jì wá.

      Bí Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jini

      8. Kí ni Sáàmù 32:5 jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, báwo ló sì ṣe rí lára wa?

      8 Lẹ́yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà, ó sọ pé: “Níkẹyìn, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀. . . . O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.” (Sáàmù 32:5) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí wọ́n tú sí ‘dárí jì’ nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “gbé” tàbí “rù” ní tààràtà. Nínú Sáàmù 32:5, ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run mú “ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìrélànàkọjá” kúrò. Torí náà, ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé Jèhófà gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó dájú pé ṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kan kúrò lórí Dáfídì. (Sáàmù 32:3) Àwa náà lè fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbé ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà lọ tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù.​—Mátíù 20:28.

      9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa tó?

      9 Dáfídì lo àpèjúwe míì tó dáa tó jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini. Ó sọ pé: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” (Sáàmù 103:12) Oòrùn máa ń yọ ní ìlà oòrùn, ó sì máa ń wọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn. Àmọ́ báwo ni ìlà oòrùn ṣe jìnnà tó sí ìwọ̀ oòrùn? Ìlà oòrùn ló jìnnà jù sí ìwọ̀ oòrùn, àwọn méjèèjì ò sì lè pàdé láé. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé gbólóhùn yìí túmọ̀ sí “ibi tó jìnnà gan-an; ibi tó jìnnà jù lọ téèyàn lè ronú kàn.” Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí Dáfídì láti kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò ní fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn dá wa lẹ́jọ́ mọ́.

      Yìnyín bo àwọn àpáta ńlá.

      “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín . . . máa di funfun bíi yìnyín”

      10. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa?

      10 Ṣó o ti gbìyànjú láti mú àbààwọ́n kúrò lára aṣọ funfun rí? Pẹ̀lú gbogbo bó o ṣe fọ̀ ọ́ tó, àbààwọ́n náà ò kúrò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà sọ tó jẹ́ ká mọ bí ìdáríjì rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ó ní: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín; bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò, wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.” (Àìsáyà 1:18) Bó ṣe wù ká gbìyànjú tó, a ò lè mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò fúnra wa. Àmọ́ Jèhófà lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí aṣọ rírẹ̀dòdò tàbí èyí tó pọ́n yòò di funfun gbòò bí ìrì dídì tàbí bí irun àgùntàn tí a kò tíì pa láró. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò yẹ ká máa rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.

      11. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ju ẹ̀ṣẹ̀ wa sẹ́yìn ara rẹ̀?

      11 Lẹ́yìn tí Jèhófà mú Hẹsikáyà lára dá nígbà tó ń ṣàìsàn kan tí ì bá gbẹ̀mí ẹ̀, ó kọ orin kan tó wọni lọ́kàn láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ó sọ pé: “O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.” (Àìsáyà 38:17) Ọ̀rọ̀ tí Hẹsikáyà sọ yìí fi hàn pé ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tó ti ronú pìwà dà, táá sì jù ú sẹ́yìn ara rẹ̀, níbi tí kò ti ní rí i mọ́. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ Hẹsikáyà yìí ni pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí kò tiẹ̀ wáyé rí rárá.” Ẹ ò rí i pé èyí fini lọ́kàn balẹ̀!

      12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí wòlíì Míkà sọ ṣe fi hàn pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá?

      12 Nígbà tí wòlíì Míkà ń sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe láti mú àwọn èèyàn ẹ̀ pa dà bọ̀ sípò, ó sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà máa dárí ji àwọn èèyàn ẹ̀ tó ronú pìwà dà. Ó ní: ‘Ta ló dà bí rẹ Ọlọ́run, ẹni tó ń gbójú fo ìṣìnà àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀? O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.’ (Míkà 7:18, 19) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa yé àwọn tó gbé ayé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àbí, tí wọ́n bá ju nǹkan “sí ìsàlẹ̀ òkun,” ṣé èèyàn lè rí i yọ? Rárá o. Torí náà, ọ̀rọ̀ Míkà fi hàn pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá.

      13. Kí ni gbólóhùn náà “dárí àwọn gbèsè wa jì wá” túmọ̀ sí?

      13 Jésù fi ọ̀rọ̀ ẹni tó yáni lówó àti ẹni tó jẹ gbèsè ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.” (Mátíù 6:12) Jésù tipa báyìí fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè. (Lúùkù 11:4) Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀, “gbèsè” la jẹ Jèhófà yẹn. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘dárí jì’ túmọ̀ sí pé “kẹ́nì kan yọ̀ǹda owó tí wọ́n jẹ ẹ́, kó gbójú fò ó, kó má sì béèrè mọ́.” Èyí túmọ̀ sí pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, ṣe ló fagi lé gbèsè tá a jẹ ẹ́. Torí náà, káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ti ronú pìwà dà lọ fọkàn balẹ̀. Jèhófà ò ní sìn wá ní gbèsè tó ti fagi lé láé!​—Sáàmù 32:1, 2.

      14. Báwo ni gbólóhùn náà “kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́” ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń dárí jini?

      14 Ìṣe 3:19 tún gba ọ̀nà míì ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini pátápátá. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí pa dà, kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí ‘pa rẹ́’ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí “láti nu nǹkan kúrò, . . . fagi lé nǹkan tàbí pa nǹkan run.” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ńṣe ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń ṣàpèjúwe béèyàn ṣe lè pa ohun tẹ́nì kan fọwọ́ kọ rẹ́. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe láyé ìgbà yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni. Àpòpọ̀ èédú, oje igi àti omi ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe yíǹkì láyé àtijọ́. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi irú yíǹkì bẹ́ẹ̀ kọ̀wé tán, ó lè fi kànrìnkàn tó ti rẹ sínú omi pa ohun tó kọ rẹ́. Àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yìí jẹ́ ká rí i pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, ó sì máa ń dárí jini! Tó bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ńṣe ló dà bíi pé ó fi kànrìnkàn nu ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò.

      15. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ nípa òun?

      15 Àwọn àpèjúwe yìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tó bá rí i pé a ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé ó ṣì máa fìyà jẹ wá nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun míì nípa àánú ńlá Jèhófà tó jẹ́ kí èyí túbọ̀ dá wa lójú, ìyẹn ni pé: Tó bá ti dárí jini, ó gbàgbé ọ̀rọ̀ náà nìyẹn.

      Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun “ṣe tán láti dárí jini”

      ‘Mi Ò Ní Rántí Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Mọ́’

      16, 17. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà ò ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́, kí sì nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      16 Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun pé: “Màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí Jèhófà bá dárí jini, kò lè rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́? Rárá o. Ọ̀pọ̀ èèyàn tí Jèhófà dárí jì ni àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17; 12:13) Ó dájú pé Jèhófà ṣì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà àti bí Ọlọ́run ṣe dárí jì wọ́n wà ní àkọsílẹ̀ fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Kí wá ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé tí Jèhófà bá ti dárí jini, kì í “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́?

      17 Ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Hébérù tá a tú sí ‘mi ò ní rántí mọ́’ kò mọ sórí pé kéèyàn kàn rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ìwé Theological Wordbook of the Old Testament sọ pé “téèyàn bá rántí nǹkan, ó tún túmọ̀ sí pé kí onítọ̀hún ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀.” Torí náà nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí ni láti fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan. (Hóséà 9:9) Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run sọ pé “mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́,” ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí òun bá ti lè dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, òun ò tún ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jẹ ẹ́ mọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22) Èyí jẹ́ ká rí i pé tí Jèhófà bá ti gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í ronú nípa ẹ̀ mọ́ tàbí kó máa wá fìyà rẹ̀ jẹ wá léraléra. Ká sòótọ́, ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé tí Ọlọ́run wa bá ti dárí jì wá, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́!

      Àbájáde Ẹ̀ṣẹ̀ Ńkọ́?

      18. Tí Jèhófà bá tiẹ̀ dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà, báwo la ṣe mọ̀ pé ìyẹn ò ní kó má jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

      18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ẹni náà máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ rẹ̀? Rárá o. Téèyàn bá ṣe nǹkan tí kò dáa, ó máa jìyà ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gálátíà 6:7) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó lè mú ká láwọn ìṣòro kan. Èyí ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ló ń fìyà jẹ wá lẹ́yìn tó ti dárí jì wá. Tí Kristẹni kan bá níṣòro, kò yẹ kó máa ronú pé, ‘Àbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti dá sẹ́yìn ni Jèhófà ń fìyà ẹ̀ jẹ mí ni?’ (Jémíìsì 1:13) Àmọ́, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gbà wá lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wa. Lára àwọn ohun ìbànújẹ́ tó lè jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ ni ìkọ̀sílẹ̀ tàbí oyún ẹ̀sín. Bákan náà, èèyàn lè kó àrùn látinú ìṣekúṣe, ó lè dẹni táwọn èèyàn ò fọkàn tán mọ́ tàbí kó dẹni ẹ̀tẹ́. Rántí pé, lẹ́yìn tí Jèhófà dárí ji Dáfídì nígbà tó bá Bátí-ṣébà ṣèṣekúṣe, tó sì ní kí wọ́n pa Ùráyà, Jèhófà ò dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn àjálù tó dé bá a torí ohun tó ṣe.​—2 Sámúẹ́lì 12:9-12.

      19-21. (a) Báwo ni òfin tó wà nínú Léfítíkù 6:1-7 ṣe ṣàǹfààní fún ẹni tá a ṣẹ̀ àti ẹni tó ṣẹ̀? (b) Tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ṣàkóbá fáwọn míì, kí ló yẹ ká ṣe ká lè múnú Jèhófà dùn?

      19 Ohun míì wà tó tún lè jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá, ní pàtàkì tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá ṣàkóbá fáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan lohun tó wà nínú Léfítíkù orí kẹfà. Orí yìí sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó jí nǹkan ìní ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ tàbí tó lù ú ní jìbìtì, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lèyí sì jẹ́ lábẹ́ Òfin Mósè. Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà wá sọ pé ńṣe ni wọ́n ń parọ́ mọ́ òun, ó sì tún ń búra èké. Torí pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó jẹ̀bi, wọn ò fìyà jẹ ẹ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í da ẹlẹ́ṣẹ̀ náà láàmú, ó sì wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run tó lè dárí jì í, ó gbọ́dọ̀ ṣe ohun mẹ́ta yìí: kó dá ohun tó jí pa dà, kó san owó ìtanràn fún ẹni tó jí nǹkan ẹ̀, ìyẹn ìdá márùn-ún ohun tó jí, kó sì fi àgbò kan rú ẹbọ ẹ̀bi. Òfin wá sọ pé: “Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà, yóò sì rí ìdáríjì.”​—Léfítíkù 6:1-7.

      20 Torí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú ló ṣe ṣòfin yìí. Ó ṣàǹfààní fún ẹni tí wọ́n dá nǹkan rẹ̀ pa dà, ó sì dájú pé ara máa tù ú nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bákan náà, òfin náà ṣàǹfààní fún ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, tó sì ṣàtúnṣe. Àmọ́, ká ní kò jẹ́wọ́, tí kò sì ṣàtúnṣe ni, Ọlọ́run ò ní dárí jì í.

      21 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, Òfin yẹn jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà, títí kan ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe kó tó lè dárí jì wá. (Kólósè 2:13, 14) Tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ṣàkóbá fáwọn míì, inú Ọlọ́run máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ náà. (Mátíù 5:23, 24) Lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká gbà pé a jẹ̀bi, ká sì bẹ ẹni tá a ṣẹ̀ pé kó dárí jì wá. Lẹ́yìn náà, a lè wá bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ pé ó ti dárí jì wá.​—Hébérù 10:21, 22.

      22. Tí Jèhófà bá tiẹ̀ dárí jì wá, kí ló tún máa ń ṣe nígbà míì torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

      22 Bí òbí onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń ṣe, tí Jèhófà bá dárí jì wá ó tún lè bá wa wí díẹ̀. (Òwe 3:11, 12) Bí àpẹẹrẹ, tí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà kan bá tiẹ̀ ronú pìwà dà, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn ṣì lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ó lè dùn ún pé òun máa pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tóun fẹ́ràn gan-an fún àkókò kan. Àmọ́, irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ò dárí jì í. Ká má gbàgbé pé, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe máa ń bá wa wí. Ó sì dájú pé tá a bá gba ìbáwí náà, ó máa ṣe wá láǹfààní gan-an.​—Hébérù 12:5-11.

      23. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà?

      23 Ó tuni lára láti mọ̀ pé Ọlọ́run wa “ṣe tán láti dárí jini”! Àṣìṣe yòówù ká ṣe, a ò gbọ́dọ̀ ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá. Tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a ṣàtúnṣe tó yẹ, tá a sì gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ó dájú pé ó máa dárí jì wá. (1 Jòhánù 1:9) Ó yẹ ká fara wé Jèhófà, ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá. Ká máa rántí pé Jèhófà kì í dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń fìfẹ́ dárí jì wá. Ṣé kò wá yẹ káwa tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa dárí ji ara wa?

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • 2 Kíróníkà 33:1-13 Kí nìdí tí Jèhófà fi dárí ji Mánásè, kí sì ni èyí kọ́ wa nípa àánú Jèhófà?

      • Mátíù 6:12, 14, 15 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀?

      • Lúùkù 15:11-32 Báwo ni àkàwé yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jini, báwo lèyí sì ṣe rí lára ẹ?

      • 2 Kọ́ríńtì 7:8-11 Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá?

  • “Oore Rẹ̀ Mà Pọ̀ O!”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Ìṣùpọ̀ èso àjàrà.

      ORÍ 27

      “Oore Rẹ̀ Mà Pọ̀ O!”

      1, 2. Báwo ni oore Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó, kí sì ni Bíbélì sọ nípa oore Jèhófà?

      NÍRỌ̀LẸ́ ọjọ́ kan, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà kan wà pa pọ̀. Wọ́n ń jẹun, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbádùn bí wọ́n ṣe ń wo àwọ̀ mèremère tó wà lójú ọ̀run bí oòrùn ṣe ń wọ̀. Bí àgbẹ̀ kan ṣe bojú wo oko ẹ̀, ó rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe rí i pé ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ sára àwọn irúgbìn ẹ̀. Inú tọkọtaya kan ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ṣe rí ọmọ wọn kékeré tó ń ṣísẹ̀ gáté-gàtè-gáté fúngbà àkọ́kọ́, bó ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.

      2 Bóyá àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí mọ̀ àbí wọn ò mọ̀, ńṣe ni wọ́n ń jọlá oore Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló sábà máa ń sọ pé “rere ni Olúwa” tàbí “Olúwa dára.” Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe tààràtà. Ó ní: “Oore rẹ̀ mà pọ̀ o!” (Sekaráyà 9:17) Àmọ́, ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tọ́rọ̀ yẹn túmọ̀ sí gangan. Tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere, kí ló túmọ̀ sí? Àǹfààní wo la sì ń jẹ torí pé Jèhófà máa ń ṣoore?

      Ọ̀kan Pàtàkì Lára Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Fìfẹ́ Hàn

      3, 4. Kí ni ìwà rere, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣe wá lóore?

      3 Bíbélì fi hàn pé ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì fani mọ́ra gan-an ni ìwà rere. Tá a bá sọ pé ẹnì kan ní ìwà rere, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún níwà ọmọlúwàbí, ó sì máa ń ṣe ohun tó dáa. Kódà, a lè sọ pé gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe ló fi hàn pé òun ni olóore tó ga jù lọ. Gbogbo ànímọ́ rẹ̀, títí kan agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ ló dáa látòkèdélẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣoore. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

      4 Téèyàn bá jẹ́ ẹni rere, ńṣe láá máa wù ú láti ṣoore. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé téèyàn bá jẹ́ ẹni rere, ó máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra ju kéèyàn jẹ́ olódodo nìkan lọ. (Róòmù 5:7) Ẹni tó jẹ́ olódodo máa ń tẹ̀ lé ohun tí òfin Ọlọ́run bá ti sọ. Ṣùgbọ́n ẹni rere máa ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń wá ọ̀nà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Ohun tá a máa kọ́ ní orí yìí á jẹ́ ká rí i pé ẹni rere ni Jèhófà lóòótọ́. Ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣe wá lóore.

      5-7. Kí nìdí tí Jésù ò fi fẹ́ kí ọkùnrin yẹn pe òun ní “Olùkọ́ Rere,” ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló sì kọ́ wọn?

      5 Jèhófà ni olóore tó ga jù lọ. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ọkùnrin kan wá bá a, ó fẹ́ bi í ní ìbéèrè kan, ó wá pè é ní “Olùkọ́ Rere.” Jésù fèsì pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.” (Máàkù 10:17, 18) O lè máa ronú pé “Olùkọ́ Rere” ṣáà ni Jésù lóòótọ́, kí wá nìdí tó fi dáhùn lọ́nà yẹn?

      6 Ó hàn gbangba pé ńṣe lọkùnrin yẹn kàn lo gbólóhùn náà “Olùkọ́ Rere” bí orúkọ oyè láti fi pọ́n Jésù lé. Torí pé Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó darí ògo yìí sí Baba rẹ̀ ọ̀run, tó jẹ́ ẹni rere tí kò lẹ́gbẹ́. (Òwe 11:2) Àmọ́, ńṣe ni Jésù tún ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ, torí náà òun nìkan ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n má jẹ lára èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Àmọ́, Jésù yàtọ̀ sí wọn pátápátá. Ó níwà ìrẹ̀lẹ̀, ó sì gbà pé Bàbá òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu yẹn.

      7 Yàtọ̀ síyẹn, Jésù mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ohun rere ti ń wá. Jèhófà ló ń fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jémíìsì 1:17) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni rere nínú bó ṣe lawọ́ sáwọn èèyàn.

      Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Oore Jèhófà Pọ̀ Gan-an

      8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣoore fún gbogbo èèyàn?

      8 Gbogbo èèyàn tó wà láyé ló ti jàǹfààní nínú oore Jèhófà. Sáàmù 145:9 sọ pé: “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún gbogbo èèyàn? Bíbélì sọ pé: “Kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.” (Ìṣe 14:17) Ṣé inú ẹ máa ń dùn nígbà tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn? Bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló ń mú ká lè máa gbádùn irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣètò bí omi ṣe ń yí po kí òjò lè rọ̀, ó tún fún wa ní “àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde” ká lè máa gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ. Gbogbo èèyàn ni Jèhófà ń ṣoore yìí fún, kì í ṣe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ nìkan. Jésù sọ pé: “Ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”​—Mátíù 5:45.

      9. Báwo ni èso ápù ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ olóore?

      9 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọyì àwọn nǹkan dáadáa tí aráyé ń gbádùn, irú bí oòrùn àti òjò. Bákan náà, ó ti láwọn àsìkò tí oríṣiríṣi irè oko máa ń jáde. Àpẹẹrẹ kan ni ti èso ápù. Ọ̀pọ̀ ibi láyé làwọn èèyàn ti mọ èso yìí. Ó rẹwà, ó dùn, omi ẹ̀ àtàwọn èròjà tó wà nínú ẹ̀ sì ń ṣara lóore gan-an. Ṣé o mọ̀ pé kárí ayé, oríṣi èso ápù tó wà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (7,500)? Kì í ṣe àwọ̀ kan ṣoṣo ni wọ́n ní, wọn ò sì tóbi bákan náà. Wọ́n lè jẹ́ pupa, yẹ́lò, àwọ̀ wúrà tàbí àwọ̀ ewé. Díẹ̀ làwọn ápù kan fi tóbi ju àgbálùmọ̀ lọ, àwọn kan sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó àgbọn. Hóró èso ápù ò ju bíńtín báyìí lọ, ṣùgbọ́n hóró yìí ló ń dàgbà di ọ̀kan lára àwọn igi tó rẹwà jù lọ láyé. (Orin Sólómọ́nì 2:3) Gbogbo ìgbà ìrúwé ni igi ápù máa ń yọ òdòdó aláwọ̀ mèremère, gbogbo ìgbà ìkórè ló sì máa ń so èso. Lọ́dọọdún, ìpíndọ́gba èso tí igi ápù kọ̀ọ̀kan ń so máa ń wúwo tó ọgọ́fà (120) àpò gaàrí, bẹ́ẹ̀ láá sì ṣe máa so lọ́dọọdún fún nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75)!

      Jèhófà “ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde”

      Ọgbà kékeré tí wọ́n gbin èso ápù sí. Nínú àwòrán kékeré, a rí irúgbìn ápù tí kò ju bíńtín báyìí lọ lọ́wọ́ ẹnì kan.

      Hóró bíńtín yìí ló ń dàgbà di igi tó dùn ún wò, tó sì ń pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀ ọdún

      10, 11. Báwo lọ̀nà tí Jèhófà gbà dá wa ṣe fi hàn pé ẹni rere ni?

      10 Bí Jèhófà ṣe dá wa “tìyanutìyanu” fi hàn pé Ẹni rere ni, torí pé ó dá wa lọ́nà tá a fi lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tó dá, ká sì lè mọyì wọn. (Sáàmù 139:14) Tún ronú nípa àwọn àpèjúwe tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ká sọ pé o wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn tó o sì rí àwọn nǹkan yẹn, èwo nínú wọn ló máa múnú ẹ dùn jù? Ó lè jẹ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ tó ń rẹ́rìn-ín, ọ̀wààrà òjò tó ń rọ̀ sórí oko tàbí oríṣiríṣi àwọ̀ mèremère tó máa ń mú kójú ọ̀run rẹwà bí oòrùn ṣe ń wọ̀. Ọlọ́run dá ojú wa lọ́nà tá a fi lè dá oríṣi àwọ̀ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) mọ̀ yàtọ̀! Bákan náà, etí wa máa ń jẹ́ ká gbọ́ oríṣiríṣi ìró. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan tá a nífẹ̀ẹ́ bá ń bá wa sọ̀rọ̀, a máa ń mọ̀ nínú ohùn rẹ̀ pé ńṣe ló ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. A tún lè gbọ́ ìró atẹ́gùn tó ń fẹ́ ewé àti ẹ̀rín ọmọ kékeré nígbà tínú ẹ̀ bá dùn gan-an. Kí ló jẹ́ ká lè rí àwọn nǹkan yẹn, ká sì gbọ́ àwọn ìró yẹn? Bíbélì sọ pé: “Etí tí a fi ń gbọ́ràn àti ojú tí a fi ń ríran Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.” (Òwe 20:12) Àwọn nǹkan míì wo ni Jèhófà dá mọ́ wa tó jẹ́ ká lè gbádùn ìgbé ayé wa?

      11 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere ni bó ṣe fún wa ní imú tá a fi ń gbóòórùn. Àìmọye òórùn ni imú wa lè gbọ́. Díẹ̀ lára wọn ni: ìtasánsán oúnjẹ tá a fẹ́ràn, òórùn òdòdó, òórùn ewé gbígbẹ tó já bọ́ látorí igi, òórùn èéfín tó ń rú túú látinú iná tó ń jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Jèhófà tún dá wa ká lè mọ nǹkan lára. Ìyẹn ló ń jẹ́ ká mọ̀ tí atẹ́gùn tó ń tuni lára bá fẹ́ yẹ́ẹ́ sí wa, ó tún máa ń jẹ́ ká mọ̀ ọ́n lára tẹ́nì kan tá a nífẹ̀ẹ́ bá gbá wa mọ́ra, òun náà ló tún ń jẹ́ ká mọ bí èso kan ṣe rí tá a bá fọwọ́ kàn án. Tá a bá wá jẹ èso náà, a máa mọ adùn ẹ̀. Ohun míì tí Jèhófà sì dá mọ́ wa nìyẹn. Bá a ṣe ń jẹ èso yẹn làá máa gbádùn ẹ̀, ahọ́n wa ló sì jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe torí ó ń jẹ́ ká mọ oríṣiríṣi adùn. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tá a fi lè sọ nípa Jèhófà pé: “Oore rẹ mà pọ̀ o! O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 31:19) Àmọ́, àwọn oore wo ni Jèhófà tò jọ fáwọn tó bẹ̀rù ẹ̀?

      A Máa Gbádùn Oore Jèhófà Títí Láé

      12. Èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa, kí sì nìdí?

      12 Jésù sọ pé: “A ti kọ ọ́ pé: ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.’ ” (Mátíù 4:4) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì máa ṣe wá láǹfààní ju oúnjẹ tara lọ, torí ó lè jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní Orí 8 ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ti lo agbára ẹ̀ láti mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó tọ́, kí wọ́n sì máa gbádùn nínú Párádísè tẹ̀mí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Apá pàtàkì nínú Párádísè yẹn ni ọ̀pọ̀ ohun rere tí Jèhófà ti fún wa ká lè mọ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀, ká lè máa ṣohun táá múnú ẹ̀ dùn, ká sì lè sún mọ́ ọn.

      13, 14. (a) Kí ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, kí sì ni ìran náà túmọ̀ sí? (b) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kí wọ́n lè nírètí ìyè àìnípẹ̀kun?

      13 Ọ̀kan lára àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò ni èyí tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Ó rí tẹ́ńpìlì kan tá a mú bọ̀ sípò, tá a sì ṣe lógo. Odò kan ń ṣàn látinú tẹ́ńpìlì yẹn. Odò náà ń fẹ̀ sí i, ó sì ń jìn sí i, títí tó fi di alagbalúgbú omi. Gbogbo ibi tí odò náà bá ṣàn dé ló máa ń ṣe láǹfààní. Àwọn igi ń hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà, àwọn èso ẹ̀ jẹ́ oúnjẹ, àwọn ewé ẹ̀ sì ń woni sàn. Odò náà mú kí Òkun Òkú tí kò ní ohun ẹlẹ́mìí kankan tẹ́lẹ̀ sọ jí, àwọn ohun ẹlẹ́mìí sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá yìn-ìn nínú rẹ̀! (Ìsíkíẹ́lì 47:1-12) Àmọ́, kí làwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí?

      14 Ohun tí ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò káwọn èèyàn lè máa jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Bó ṣe jẹ́ pé odò yẹn ń fẹ̀ sí i, tó sì ń jìn sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ kí wọ́n lè wà láàyè títí láé ṣe ń pọ̀ sí i. Látìgbà tí Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò lọ́dún 1919 ló ti ń pèsè àwọn ẹ̀bùn tó ń fúnni ní ìyè fáwọn èèyàn rẹ̀. Lọ́nà wo? Jèhófà ti lo Bíbélì, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀kọ́ yìí ni ẹbọ ìràpadà Kristi. Torí pé Jésù kú nítorí wa, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ láǹfààní láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.a Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ń pa àwọn èèyàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ńṣe làwa èèyàn Jèhófà ń jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù.​—Àìsáyà 65:13.

      15. Oore wo ni Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn olóòótọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

      15 Àmọ́ odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí kò ní yéé ṣàn nígbà tí ètò àwọn nǹkan yìí bá dópin. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe láá túbọ̀ máa ṣàn sí i nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Nígbà yẹn, Jèhófà máa lo ẹbọ ìràpadà Jésù láti sọ àwọn èèyàn olóòótọ́ di pípé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé àwọn oore tí Jèhófà máa ṣe á múnú wa dùn gan-an!

      Àwọn Ọ̀nà Míì Tí Jèhófà Gbà Ń Ṣoore

      16. Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà láwọn ìwà àti ìṣe míì tó fi hàn pé ó jẹ́ ẹni rere, kí sì ni díẹ̀ lára wọn?

      16 A ti rí i pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́, àmọ́ ó tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó fi hàn pé ó jẹ́ ẹni rere. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Màá mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ, màá sì kéde orúkọ Jèhófà níwájú rẹ.” Lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.’ ” (Ẹ́kísódù 33:19; 34:6) Torí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere, ó tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó dáa gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára wọn.

      17. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwa èèyàn aláìpé lásánlàsàn, ànímọ́ wo ló sì ń jẹ́ kó máa ṣe bẹ́ẹ̀?

      17 Ọlọ́run “tó ń gba tẹni rò.” Ànímọ́ yìí tan mọ́ àánú, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń pọ́n àwa èèyàn lé àti pé ó ṣeé sún mọ́. Àwọn alágbára sábà máa ń sọ̀rọ̀ sáwọn èèyàn ṣàkàṣàkà, wọ́n máa ń kanra, wọ́n sì máa ń hùwà ìkà, àmọ́ Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Dípò ìyẹn, ó máa ń ní sùúrù, ó sì jẹ́ onínúure àti ẹni jẹ́jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Ábúrámù pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:14) Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló yọ ọ̀rọ̀ náà “jọ̀ọ́” kúrò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Ìwádìí táwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣẹ, ńṣe ló jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé, àwọn àpẹẹrẹ irú ẹ̀ míì sì wà nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 31:12; Ìsíkíẹ́lì 8:5) Àbẹ́ ò rí nǹkan, Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run ń sọ pé “jọ̀ọ́” fún èèyàn lásánlàsàn! Nínú ayé yìí táwọn èèyàn ti máa ń gbójú mọ́ ara wọn, tí wọ́n máa ń hùwà jàgídíjàgan àti ìwà àfojúdi, ẹ ò rí i pé ó tuni lára láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń gba tẹni rò!

      18. Kí ló túmọ̀ sí pé ‘òtítọ́ Jèhófà pọ̀ gidigidi,’ kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi ń fini lọ́kàn balẹ̀?

      18 ‘Òtítọ́ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ Ìwà àìṣòótọ́ pọ̀ gan-an lóde òní. Àmọ́ Bíbélì rán wa létí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́.” (Nọ́ńbà 23:19) Kódà, Títù 1:2 sọ pé “Ọlọ́run . . . kò lè parọ́.” Torí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere kò lè parọ́ láé. Ìdí nìyẹn tá a fi lè gbára lé gbogbo ìlérí Jèhófà pátápátá, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní lọ láìṣẹ. Bíbélì tiẹ̀ pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Ìmọ̀ Jèhófà pọ̀ gan-an, ó sì máa ń fi ibú ọgbọ́n rẹ̀ la àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lóye.b Ó tiẹ̀ tún ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tó ń kọ́ wọn sílò, kí wọ́n sì jàǹfààní látinú ẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa “rìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3) Tá a bá ń rántí pé ẹni rere ni Jèhófà, kí lèyí á mú ká máa ṣe?

      ‘Jẹ́ Kí Inú Ẹ Máa Dùn Nítorí Oore Jèhófà’

      19, 20. (a) Kí ni Sátánì ṣe láti mú kí Éfà ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere, kí ló sì yọrí sí? (b) Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere, kí lèyí á mú ká máa ṣe, kí sì nìdí?

      19 Nígbà tí Sátánì dán Éfà wò nínú ọgbà Édẹ́nì, ńṣe ló fẹ́ kí Éfà máa ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere. Jèhófà sọ fún Ádámù pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn.” Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún igi tó wà nínú ọgbà náà, ọ̀kan péré ni Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso ẹ̀. Àmọ́, kíyè sí ohun tí Sátánì bi Éfà. Ó ní: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16; 3:1) Sátánì yí ọ̀rọ̀ Jèhófà pa dà kí Éfà lè máa ronú pé Jèhófà ń fawọ́ ohun rere kan sẹ́yìn. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà gba Sátánì gbọ́. Éfà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló fún un ní gbogbo nǹkan tó ní. Látìgbà yẹn sì làwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń ṣe bíi ti Éfà.

      20 A kúkú mọ ìyà ńlá tó ń jẹ àwa èèyàn torí pé Éfà àtàwọn míì kò gbà pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ tó wà ní Jeremáyà 31:12 sọ́kàn. Ó sọ pé: “Inú wọn á dùn nítorí oore Jèhófà.” Ṣe ló yẹ kí oore Jèhófà máa mú wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Kò yẹ ká máa ṣiyèméjì rárá nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run wa bá ṣe torí pé ẹni rere ló jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, torí pé ohun tó dáa ló máa ń ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

      21, 22. (a) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì oore Jèhófà? (b) Ànímọ́ wo la máa jíròrò ní orí tó kàn, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí oore Jèhófà?

      21 Bákan náà, inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ní àǹfààní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa oore Ọlọ́run. Sáàmù 145:7 sọ nípa àwọn èèyàn Jèhófà pé: “Wọ́n á máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa ọ̀pọ̀ oore rẹ.” Ojoojúmọ́ la máa ń jàǹfààní oore Jèhófà lọ́nà kan tàbí òmíì. O ò ṣe jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ fún oore rẹ̀, kó o sì sọ àwọn oore yẹn ní pàtó? Tá a bá fẹ́ fara wé bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere, ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn oore tó ti ṣe fún wa, ká máa dúpẹ́ fún àwọn oore yẹn, ká sì máa sọ fún àwọn míì nípa rẹ̀. Tá a bá ń wá ọ̀nà láti máa ṣe rere bíi ti Jèhófà, èyí á mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni ọ̀wọ́n, má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú, àpẹẹrẹ rere ni kí o máa tẹ̀ lé. Ẹni tó bá ń ṣe rere wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”​—3 Jòhánù 11.

      22 Oore Jèhófà tún tan mọ́ àwọn ànímọ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé ‘ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ (Ẹ́kísódù 34:6) Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí, torí náà ànímọ́ yìí yàtọ̀ sí oore tó máa ń ṣe fún gbogbo èèyàn. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nìkan ni Jèhófà máa ń fi ànímọ́ yìí hàn sí. Ní orí tó kàn, a máa mọ bí Jèhófà ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn sí wọn.

      a Nínú gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wa, ìràpadà ló ga jù. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ló wà lọ́run, Jèhófà sì lè yan ọ̀kan nínú wọn láti wá kú torí wa, àmọ́ ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo ló yàn.

      b Bíbélì sábà máa ń fi òtítọ́ wé ìmọ́lẹ̀. Onísáàmù kan kọ ọ́ lórin pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.” (Sáàmù 43:3) Jèhófà ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tàn sórí àwọn tó bá fẹ́ gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀.​—2 Kọ́ríńtì 4:6; 1 Jòhánù 1:5.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • 1 Àwọn Ọba 8:54-61, 66 Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fi hàn pé òun moore Jèhófà, báwo lèyí sì ṣe rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

      • Sáàmù 119:66, 68 Báwo la ṣe lè fi hàn nínú àdúrà wa pé a fẹ́ máa ṣoore bíi ti Jèhófà?

      • Lúùkù 6:32-38 Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?

      • Róòmù 12:2, 9, 17-21 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni rere nínú ìgbé ayé wa ojoojúmọ́?

  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Òṣùpá ń ràn lójú ọ̀run lálẹ́.

      ORÍ 28

      “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”

      1, 2. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí Ọba Dáfídì?

      ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí Ọba Dáfídì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń ṣàkóso lé lórí dìtẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì gbìyànjú láti rọ̀ ọ́ lóyè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ kòríkòsùn Dáfídì tún dà á. Ọ̀kan lára wọn ni Míkálì, ìyàwó tó kọ́kọ́ fẹ́. Níbẹ̀rẹ̀, Míkálì “nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an,” ó sì dájú pé á ti máa tì í lẹ́yìn nígbà tó jọba. Àmọ́ nígbà tó yá, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn [Dáfídì] nínú ọkàn rẹ̀,” kódà ó pè é ní “akúrí.”​—1 Sámúẹ́lì 18:20; 2 Sámúẹ́lì 6:16, 20.

      2 Ẹlòmíì tún ni Áhítófẹ́lì, agbaninímọ̀ràn Dáfídì. Àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún Áhítófẹ́lì gan-an, wọ́n sì máa ń wo ìmọ̀ràn ẹ̀ bí i pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ń fúnni nímọ̀ràn. (2 Sámúẹ́lì 16:23) Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ yìí dalẹ̀ Dáfídì, ó sì bá wọn dìtẹ̀ mọ́ ọn. Ṣùgbọ́n ta ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ yìí? Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ni! Ó ń “dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra,” ó ta ko bàbá ẹ̀, ó sì sọ ara ẹ̀ di ọba. Ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù láti dìtẹ̀ mọ́ Ọba Dáfídì, ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé Dáfídì ní láti sá kúrò nílùú kí wọ́n má bàa pa á.​—2 Sámúẹ́lì 15:1-6, 12-17.

      3. Kí ló dá Dáfídì lójú?

      3 Ṣé kò wá sẹ́ni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì ni? Dáfídì mọ̀ pé ẹnì kan wà lẹ́yìn òun ní gbogbo ìgbà tóun bá wà nínú ìṣòro. Ta lẹni náà? Jèhófà Ọlọ́run ni. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ adúróṣinṣin?

      Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin?

      4, 5. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ “adúróṣinṣin”? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin àti kéèyàn jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé?

      4 Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “adúróṣinṣin” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti ṣàpèjúwe ẹnì kan tó dúró ti ẹni tó fẹ́ràn, tó sì ń bá a lọ láti máa ran ẹni náà lọ́wọ́. Kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin kọjá pé kó ṣeé gbára lé. Tóri tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan tó ń mú káwọn èèyàn gbára lé e, ó lè má jẹ́ ìfẹ́ ló ń mú kó máa ṣe àwọn nǹkan yẹn. Ó kàn lè máa ṣe é torí pé kò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí tàbí torí pé ó pọn dandan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìfẹ́ ló máa ń mú kẹ́nì kan jẹ́ adúróṣinṣin.a Yàtọ̀ síyẹn, nígbà míì a lè sọ pé àwọn ohun tí kò lẹ́mìí náà ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù kan pe òṣùpá ní “ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run” torí pé alaalẹ́ ló máa ń yọ. (Sáàmù 89:37) Àmọ́, a ò lè sọ pé òṣùpá jẹ́ adúróṣinṣin. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ ló ń mú kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọ̀ pé ohun tí kò lẹ́mìí ò lè fìfẹ́ hàn.

      Bíbélì pe òṣùpá ní ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé, àmọ́ àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì nìkan ló lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà

      5 Tí Bíbélì bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa hàn nínú ìwà ẹni náà. Ẹni tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹlòmíì á máa fìfẹ́ hàn sí ẹni náà, á sì máa ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹni náà jẹ òun lógún. Ọ̀rọ̀ ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin kò ní rí bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó ní sí ẹni tó fẹ́ ràn lọ́wọ́ máa lágbára débi pé tí ìṣòro bá dé, kò ní pa onítọ̀hún tì.

      6. (a) Báwo làwọn adúróṣinṣin ṣe pọ̀ tó láyé yìí, kí ni Bíbélì sì sọ tí ò jẹ́ kó yà wá lẹ́nu? (b) Ọ̀nà wo ló dáa jù lọ tá a lè gbà mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin?

      6 Ó bani nínú jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló jẹ́ adúróṣinṣin lónìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló “ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà.” Ńṣe làwọn tọkọtaya tó ń kọra wọn sílẹ̀ sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Òwe 18:24; Málákì 2:14-16) Àwọn aláìṣòótọ́ àti ọ̀dàlẹ̀ pọ̀ láyé yìí débi táwa náà fi lè sọ bíi ti wòlíì Míkà pé: “Adúrótini ti tán ní ayé.” (Míkà 7:2) Ká sòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwa èèyàn láti jẹ́ adúróṣinṣin, àmọ́ gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó ní ànímọ́ pàtàkì yìí. Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìfẹ́ ṣe ń mú kí Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin.

      Kò Sẹ́ni Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin Bíi Ti Jèhófà

      7, 8. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?

      7 Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin.” (Ìfihàn 15:4) Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ṣebí àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì kan ti ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin? (Jóòbù 1:1; Ìfihàn 4:8) Jésù Kristi náà ńkọ́? Ṣebí òun ni ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn “ẹni ìdúróṣinṣin” Ọlọ́run? (Sáàmù 16:10) Kí wá nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?

      8 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé ìfẹ́ ló máa ń mú kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìyẹn ni pé òun ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn. (1 Jòhánù 4:8) Òótọ́ ni pé àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà. Òun ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” kò sígbà tí Jèhófà kò jẹ́ adúróṣinṣin, torí náà a ò lè fi ìdúróṣinṣin ẹ̀ wé ti èèyàn tàbí áńgẹ́lì èyíkéyìí. (Dáníẹ́lì 7:9) Torí náà, Jèhófà ló jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà tó ga jù lọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

      9. Báwo ni Jèhófà ṣe “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe”?

      9 Jèhófà “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.” (Sáàmù 145:17) Lọ́nà wo? A lè rí ìdáhùn nínú Sáàmù 136. Sáàmù náà mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìgbàlà tí Jèhófà ṣe, títí kan bó ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá lọ́nà ìyanu. Kíyè sí i pé gbogbo ẹsẹ tó wà nínú sáàmù yìí ló ní gbólóhùn tó sọ pé: “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” Sáàmù yìí wà lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sábẹ́ “Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé” lójú ìwé 289. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ yẹn, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ti pé ó máa ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lásìkò tó yẹ. (Sáàmù 34:6) Jèhófà ò ní yéé fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n bá ń bá a lọ láti máa jẹ́ adúróṣinṣin sí i. 

      10. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin tó bá kan àwọn ìlànà rẹ̀?

      10 Ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé àwọn ìlànà rẹ̀ kì í yí pa dà. Àwọn èèyàn sábà máa ń yí èrò wọn pa dà torí bí nǹkan bá ṣe rí lára wọn, àmọ́ ní ti Jèhófà èrò rẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kì í yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ojú tí Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò, ìbọ̀rìṣà àti ìpànìyàn kò tíì yí pa dà. Ó sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà pé: “Títí o fi máa dàgbà, mi ò ní yí pa dà.” (Àìsáyà 46:4) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé a máa jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé òfin tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.​—Àìsáyà 48:17-19.

      11. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

      11 Jèhófà tún máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nípa bó ṣe máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde . . . kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ, àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí, ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.” (Àìsáyà 55:11) Bí Jèhófà ṣe ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn èèyàn rẹ̀. Kì í sọ ohun tí kò bá ní lọ́kàn láti ṣe, kó wá jẹ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà lásán. Jèhófà ṣeé fọkàn tán gan-an, kódà Jóṣúà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ìlérí tí kò ṣẹ nínú gbogbo ìlérí dáadáa tí Jèhófà ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ pátá.” (Jóṣúà 21:45) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ láé, kò sì sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ tí ò fi ní mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—Àìsáyà 49:23; Róòmù 5:5.

      12, 13. Àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ fi wà títí láé?

      12 Bá a ṣe sọ ṣáájú, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ “wà títí láé.” (Sáàmù 136:1) Kí ló fi hàn bẹ́ẹ̀? Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀ ni bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Bá a ṣe sọ ní Orí 26, tí Jèhófà bá dárí ji ẹnì kan, kò ní pa dà fìyà jẹ ẹni náà mọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,” torí náà ó yẹ kí gbogbo wa máa dúpẹ́ pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé.​—Róòmù 3:23.

      13 Àmọ́, ohun míì wà tó fi hàn pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé olódodo “máa dà bí igi tí a gbìn sétí odò, tó ń so èso ní àsìkò rẹ̀, tí ewé rẹ̀ kì í sì í rọ. Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.” (Sáàmù 1:3) Fojú inú wo igi kan tó rẹwà , táwọn ewé ẹ̀ sì tutù minimini, ó dájú pé ó máa fani mọ́ra gan-an! Bákan náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ jinlẹ̀, ọkàn wa á balẹ̀, ayé wa á dùn bí oyin, àwọn nǹkan tá à ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. Torí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, títí láé làwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ á máa gbádùn àwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wọn. Nínú ayé tuntun, títí láé ni Jèhófà á máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn.​—Ìfihàn 21:3, 4.

      Jèhófà Ò “Ní Kọ Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀”

      14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun mọyì báwọn ìránṣẹ́ òun ṣe jẹ́ adúróṣinṣin?

      14 Nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti ṣe ohun tó fi hàn pé adúróṣinṣin lòun. Torí pé awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà, títí láé láá máa jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Onísáàmù kan sọ pé: “Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó, síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri. Nítorí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:25, 28) Ká sòótọ́, Jèhófà ló yẹ ká máa sìn torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Ìfihàn 4:11) Àmọ́ torí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa ń mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe fún un látọkàn wá.​—Málákì 3:16, 17.

      15. Ṣàlàyé bí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé adúróṣinṣin ni.

      15 Torí pé Jèhófà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀, léraléra ló máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé bá wọn. Onísáàmù kan sọ pé: “Ó ń ṣọ́ ẹ̀mí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 97:10) Rántí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tó mú kí wọ́n la Òkun Pupa kọ já, wọ́n kọrin sí i pé: “O fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn tí o rà pa dà.” (Ẹ́kísódù 15:13) Lóòótọ́, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló mú kí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là létí Òkun Pupa. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín, ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn. Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú, kúrò lọ́wọ́ Fáráò ọba Íjíbítì.”​—Diutarónómì 7:7, 8.

      16, 17. (a) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tó fi hàn pé wọn ò moore, àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe fàánú hàn sí wọn? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tí ọ̀rọ̀ wọn fi “kọjá àtúnṣe,” kí la sì rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn?

      16 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn, torí pé lẹ́yìn tó gbà wọ́n là, ńṣe ni “wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí [Jèhófà] nìṣó, bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sáàmù 78:17) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, léraléra ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pa Jèhófà tì, wọ́n ń bọ òrìṣà, wọ́n tún ń tẹ̀ lé àṣà àwọn kèfèrí tó yí wọn ká, ìyẹn sì sọ wọ́n di ẹlẹ́gbin. Síbẹ̀, Jèhófà ò da májẹ̀mú tó bá wọn dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ní kí wòlíì Jeremáyà pàrọwà fáwọn èèyàn òun pé: “Pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ . . . mi ò ní wò ọ́ tìbínútìbínú, nítorí adúróṣinṣin ni mí.” (Jeremáyà 3:12) Àmọ́, bá a ṣe ṣàlàyé ní Orí 25, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ronú pìwà dà. Kódà, ńṣe ni “wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín, wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tó yá? Ńṣe ni ‘ìbínú Jèhófà ru sí àwọn èèyàn rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.’​—2 Kíróníkà 36:15, 16.

      17 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? A rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò ní ṣe nǹkan kan nípa àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Òótọ́ ni pé “ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ . . . pọ̀ gidigidi,” ó sì ṣe tán láti fàánú hàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí ni Jèhófà máa ṣe sí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ò jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù? Ńṣe ni Jèhófà máa ṣe ohun tó bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu, tó sì máa fìyà jẹ ẹni náà. Ó sọ fún Mósè pé òun “kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.”​—Ẹ́kísódù 34:6, 7.

      18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin bó ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú? (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe láti fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kú nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn?

      18 Jèhófà tún máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nígbà tó bá ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú. Lọ́nà wo? Àpẹẹrẹ kan lèyí tó wà nínú ìwé Ìfihàn, níbi tí Jèhófà ti pàṣẹ fáwọn áńgẹ́lì méje kan pé: “Ẹ lọ da abọ́ méje tí ìbínú Ọlọ́run wà nínú rẹ̀ sórí ayé.” Nígbà tí áńgẹ́lì kẹta da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ “sínú àwọn odò àti àwọn ìsun omi,” wọ́n di ẹ̀jẹ̀. Áńgẹ́lì náà wá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ, Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo, torí o ti ṣe àwọn ìdájọ́ yìí, torí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀, o sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu; ó tọ́ sí wọn.”​—Ìfihàn 16:1-6.

      19 Kíyè sí i pé nígbà tí áńgẹ́lì náà ń jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ yẹn, ó pe Jèhófà ní “Ẹni ìdúróṣinṣin.” Kí nìdí? Ìdí ni pé tí Jèhófà bá pa àwọn ẹni ibi run, ńṣe ló ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ òun tọ́pọ̀ nínú wọn ti kú nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Torí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, kò ní gbàgbé wọn láé. Ó wù ú kó tún pa dà rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí, Bíbélì sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa jí wọn dìde, kó lè san wọ́n lẹ́san. (Jóòbù 14:14, 15) Jèhófà kì í gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ torí pé wọ́n ti kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “gbogbo wọn wà láàyè” lójú rẹ̀. (Lúùkù 20:37, 38) Bó ṣe ń wu Jèhófà pé kó jí àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé adúróṣinṣin ni.

      Torí pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ó máa rántí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i títí dójú ikú, ó sì máa jí wọn dìde

      Ìjọba Násì ló pa Bernard Luimes (lókè) àti Wolfgang Kusserow (láàárín)

      Ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló fi ọ̀kọ̀ gún Moses Nyamussua pa

      Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ló Jẹ́ Ká Nírètí Láti Wà Láàyè Títí Láé

      20. Àwọn wo ni “ohun èlò àánú,” báwo ni Jèhófà sì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí wọn?

      20 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà ti “fi ọ̀pọ̀ sùúrù gba àwọn ohun èlò ìrunú tó yẹ fún ìparun láyè.” Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó “ṣe èyí láti jẹ́ ká mọ ọrọ̀ ògo rẹ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tó ti pèsè sílẹ̀ fún ògo.” (Róòmù 9:22, 23) Àwọn “ohun èlò àánú” yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti jọba pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 19:28) Torí pé Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn ẹni àmì òróró yìí láti rí ìgbàlà, ó fi hàn pé ó dúró lórí májẹ̀mú tó ṣe fún Ábúráhámù nígbà tó sọ fún un pé: “Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ torí pé o fetí sí ohùn mi.”​—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

      Inú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń dùn, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, ọjọ́ orí wọn sì yàtọ̀ síra.

      Torí pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ọkàn gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ balẹ̀ pé ó máa mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ lọ́jọ́ iwájú

      21. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó nírètí láti la “ìpọ́njú ńlá” já? (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin?

      21 Jèhófà tún fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó nírètí láti la “ìpọ́njú ńlá” já, kí wọ́n sì gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Ìfihàn 7:9, 10, 14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn èèyàn yìí, Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí wọn torí bó ṣe fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kí ló mú kéyìí ṣeé ṣe? Nípasẹ̀ ìràpadà ni, ìyẹn sì ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8) Ó máa ń wu àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láti sún mọ́ Jèhófà torí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin. (Jeremáyà 31:3) Ní báyìí tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, ṣé kò wu ìwọ náà kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn? Tá a bá pinnu pé a máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àá fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, èyí á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.

      a Ọ̀rọ̀ kan náà tá a túmọ̀ sí “adúróṣinṣin” nínú 2 Sámúẹ́lì 22:26 la túmọ̀ sí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” nínú àwọn ẹsẹ míì.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • 1 Sámúẹ́lì 24:1-22 Àwọn nǹkan wo ni Dáfídì ṣe sí Ọba Sọ́ọ̀lù tó fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà?

      • Ẹ́sítà 3:7-9; 4:6–5:1 Kí ni Ẹ́sítà ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ tó fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà, kódà nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu?

      • Sáàmù 136:1-26 Kí la rí kọ́ nínú sáàmù yìí nípa ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀?

      • Ọbadáyà 1-4, 10-16 Nígbà táwọn ọmọ Édómù hùwà ìkà sáwọn èèyàn Jèhófà, kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn èèyàn rẹ̀?

  • Kí Ẹ Lè “Mọ Ìfẹ́ Kristi”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Jésù ń fàánú hàn sí ẹnì kan.

      ORÍ 29

      Kí Ẹ Lè “Mọ Ìfẹ́ Kristi”

      1-3. (a) Kí ló mú kó wu Jésù láti fìwà jọ Bàbá rẹ̀? (b) Kí la máa kọ́ nínú orí yìí?

      ṢÉ O ti rí ọmọ kékeré kan tó ń gbìyànjú láti ṣe bíi ti bàbá rẹ̀ rí? Ọmọ náà lè máa fara wé bàbá ẹ̀ nínú ìrìn, ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Bọ́mọ náà bá ṣe ń dàgbà, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi ti bàbá ẹ̀, kó fìwà jọ ọ́, kí wọ́n sì jọ máa sin Ọlọ́run kan náà. Bẹ́ẹ̀ ni, tí bàbá kan bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀, ọmọ náà á fẹ́ràn bàbá ẹ̀, á bọ̀wọ̀ fún un èyí á sì mú kó fẹ́ máa ṣe bíi ti bàbá ẹ̀.

      2 Irú àjọṣe wo ló wà láàárín Jésù àti Baba rẹ̀? Ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòhánù 14:31) Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti Ọmọ yìí, torí pé ọjọ́ pẹ́ tó ti wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ ṣáájú kí Bàbá rẹ̀ tó dá àwọn áńgẹ́lì tó kù. Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ ló fi wù ú pé kó fìwà jọ ọ́.​—Jòhánù 14:9.

      3 Láwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé yìí, a sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fara wé agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n Jèhófà lọ́nà tó pé. Àmọ́ báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn bíi ti Bàbá rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà mẹ́ta tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn, ìyẹn bó ṣe ni ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, bó ṣe jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú àti bó ṣe múra tán láti dárí jini.

      “Kò Sí Ẹni Tí Ìfẹ́ Rẹ̀ Ju Èyí Lọ”

      4. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó bá di pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ látọkàn wá?

      4 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan látọkàn wá, a máa múra tán láti yááfì ohunkóhun ká lè ran ẹni náà lọ́wọ́, tíyẹn bá tiẹ̀ gba pé ká kú torí ẹni náà. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Òun fúnra ẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Tọkàntọkàn ni Jésù fi gbà láti fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ torí tiwa. Ohun tó ṣe yẹn ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí ẹnikẹ́ni ti gbà fìfẹ́ hàn. Àmọ́ Jésù tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn látọkàn wá láwọn ọ̀nà míì.

      5. Àwọn nǹkan wo ni Ọmọ Ọlọ́run fi sílẹ̀ lọ́run kó lè wá sáyé?

      5 Kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run tó wá sáyé, ipò ńlá ló wà lọ́run. Ó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún Ọmọ ọ̀wọ́n yìí lọ́run, ó “fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀, ó gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì di èèyàn.” (Fílípì 2:7) Ó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti wá gbé láàárín àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú ayé tó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ó dájú pé ohun tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe yìí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an!

      6, 7. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe nígbà tó wà láyé tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an? (b) Àpẹẹrẹ wo la rí nínú Jòhánù 19:25-27 nípa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá?

      6 Jálẹ̀ gbogbo àsìkò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yááfì kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Kò mọ tara ẹ̀ nìkan. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì fi du ara ẹ̀ torí kó lè lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:20) Káfíńtà tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ ni Jésù, torí náà ó lè kọ́ ilé ńlá tó tura fún ara ẹ̀, tàbí kó máa ṣe àwọn àga tó jojú ní gbèsè, kó lè máa tà wọ́n, kó sì rówó gbádùn ara ẹ̀. Àmọ́, kò ṣe iṣẹ́ káfíńtà torí kó lè kó ọrọ̀ jọ.

      7 Àpẹẹrẹ kan tó wọni lọ́kàn gan-an nípa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá wà nínú Jòhánù 19:25-27. Ronú nípa oríṣiríṣi nǹkan tó máa wà lọ́kàn Jésù lọ́sàn-án ọjọ́ tó máa kú. Bó ṣe ń joró lórí igi tí wọ́n kàn án mọ́, bẹ́ẹ̀ ló ń ronú nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù, àti ní pàtàkì jù lọ, bó ṣe máa jẹ́ adúróṣinṣin, táá sì dá orúkọ Bàbá rẹ̀ láre. Ká sòótọ́, ohun tí Jésù bá ṣe lọ́jọ́ yẹn ló máa pinnu bóyá àwa èèyàn máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́! Síbẹ̀, nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó tún ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Màríà ìyá rẹ̀ tó ṣeé ṣe kó ti di opó nígbà yẹn. Jésù ní kí àpọ́sítélì Jòhánù máa bá òun tọ́jú Màríà bó ṣe máa tọ́jú ìyá tiẹ̀, àpọ́sítélì náà wá mú Màríà lọ sílé ara ẹ̀. Èyí fi hàn pé Jésù ṣètò bí wọ́n á ṣe máa bójú tó ìyá rẹ̀ nípa tara àti bí wọ́n ṣe máa ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù jẹ́ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn!

      ‘Àánú Wọn Ṣe É’

      8. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe bọ́rọ̀ àwọn èèyàn ṣe ń ká Jésù lára tó?

      8 Jésù máa ń ṣàánú àwọn èèyàn bíi ti Bàbá rẹ̀. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé tí Jésù bá rí ẹni tí ìyà ń jẹ, àánú ẹni náà máa ṣe é, ó sì máa wù ú kó ran ẹni náà lọ́wọ́. Nígbà tí Bíbélì ń sọ bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣe ká Jésù lára tó, ó sọ pé ‘àánú wọn ṣe é.’ Ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe . . . ìmọ̀lára tó jinlẹ̀ gan-an téèyàn máa ń ní látọkàn wá. Ọ̀rọ̀ yìí ló lágbára jù lọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò nínú èdè Gíríìkì láti fi ṣàpèjúwe ẹni tó jẹ́ aláàánú.” Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìgbà tí Jésù ṣàánú àwọn èèyàn, tíyẹn sì mú kó ṣe ohun kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

      9, 10. (a) Kí nìdí tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi fẹ́ lọ síbi tó dá? (b) Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn èèyàn ò jẹ́ kó ráyè sinmi, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

      9 Jésù máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ aláàánú. Ohun tó wà nínú Máàkù 6:30-34 jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì tí Jésù fi máa ń ṣàánú àwọn èèyàn. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì dé látibi tí wọ́n ti lọ wàásù. Iṣẹ́ náà ò rọrùn rárá, àmọ́ inú wọn ń dùn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù. Wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n rí, tí wọ́n sì gbọ́ fún un. Bí ọ̀pọ̀ èrò ṣe rọ́ dé nìyẹn, tí wọn ò jẹ́ kí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tiẹ̀ ráyè jẹun. Jésù kíyè sí i pé ó ti rẹ àwọn àpọ́sítélì òun. Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” Ni wọ́n bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbì kan tó pa rọ́rọ́ ní ìpẹ̀kun àríwá Òkun Gálílì. Àmọ́, àwọn èrò náà rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ, àwọn míì sì gbọ́ nípa rẹ̀. Bí gbogbo wọn tún ṣe sáré gba etídò lọ sí apá àríwá náà nìyẹn, wọ́n sì débẹ̀ kí ọkọ̀ ojú omi náà tó gúnlẹ̀!

      10 Ṣé inú bí Jésù torí pé àwọn èèyàn yẹn ò jẹ́ kí òun àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ráyè sinmi? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń dúró dè é, àánú wọn ṣe é. Máàkù sọ pé: “Ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn sì ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.” Jésù mọ̀ pé àwọn èèyàn yìí nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Torí ńṣe ni wọ́n dà bí àgùntàn tó ti sọ nù, tí kò sì ní olùṣọ́ àgùntàn tó máa darí wọn tàbí dáàbò bò wọ́n. Jésù mọ̀ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó yẹ kí wọ́n máa tọ́jú àwọn àgùntàn Jèhófà ti pa wọ́n tì, wọn ò sì bójú tó wọn. (Jòhánù 7:47-49) Àánú àwọn èèyàn náà ṣe Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn “nípa ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:11) Kíyè sí i pé àánú àwọn èèyàn yẹn ṣe Jésù kó tiẹ̀ tó mọ̀ bóyá wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ òun àbí wọn ò ní gbọ́. Lédè míì, kì í ṣe ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn náà ló tó ṣàánú wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀ ni àánú wọn ti ṣe é, ìyẹn gan-an ló sì mú kó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

      Jésù ń fàánú hàn sí adẹ́tẹ̀ kan, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án. Ìrísí adẹ́tẹ̀ náà ń kó àwọn tó wà nítòsí ẹ̀ nírìíra.

      “Ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án”

      11, 12. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe sáwọn adẹ́tẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àmọ́ kí ni Jésù ṣe nígbà tí ọkùnrin kan “tí ẹ̀tẹ̀ bò” lọ bá a? (b) Báwo ló ṣe rí lára adẹ́tẹ̀ yẹn nígbà tí Jésù fọwọ́ kàn án, kí lohun tí dókítà kan sọ sì jẹ́ ká mọ̀?

      11 Jésù máa ń ran àwọn tó ń jìyà lọ́wọ́ torí pé ó jẹ́ aláàánú. Àwọn èèyàn tó ní onírúurú àìsàn rí i pé ẹlẹ́yinjú àánú ni Jésù, torí náà ó wù wọ́n kí wọ́n sún mọ́ ọn. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkùnrin kan “tí ẹ̀tẹ̀ bò” lọ bá Jésù láàárín èrò. (Lúùkù 5:12) Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Òfin Jèhófà sọ pé ẹ̀yìn ibùdó ni káwọn adẹ́tẹ̀ máa gbé, kí wọ́n má bàa kó àrùn náà ran àwọn èèyàn. (Nọ́ńbà 5:1-4) Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbé òfin tiwọn kalẹ̀ nípa àwọn tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, òfin náà le gan-an, kì í sì í jẹ́ káwọn èèyàn ṣàánú àwọn adẹ́tẹ̀.a Àmọ́ kíyè sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí adẹ́tẹ̀ náà wá bá a. Bíbélì sọ pé: “Bákan náà, adẹ́tẹ̀ kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́, àní lórí ìkúnlẹ̀, ó sọ fún un pé: ‘Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.’ Àánú rẹ̀ wá ṣe é, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wá sọ fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀.” (Máàkù 1:40-42) Jésù mọ̀ pé kò bófin mu rárá bí adẹ́tẹ̀ yẹn ṣe wà láàárín èrò. Síbẹ̀, dípò tí Jésù á fi lé e dà nù, àánú rẹ̀ ṣe Jésù débi pé ó ṣe nǹkan kan tó jọni lójú gan-an. Jésù fọwọ́ kàn án!

      12 Wo bó ṣe máa rí lára adẹ́tẹ̀ yẹn nígbà tí Jésù fọwọ́ kàn án! Ká lè mọ bó ṣe rí lára adẹ́tẹ̀ náà, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣẹ́nì kan. Dókítà Paul Brand, tó jẹ́ onímọ̀ nípa àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ń tọ́jú adẹ́tẹ̀ kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Bí dókítà yẹn ṣe ń ṣàyẹ̀wò adẹ́tẹ̀ náà, ó gbọ́wọ́ lé e léjìká, ó sì ní kí ògbufọ̀ kan bá òun ṣàlàyé ọ̀nà tóun fẹ́ gbà tọ́jú rẹ̀ fún un. Ni adẹ́tẹ̀ náà bá bú sẹ́kún! Dókítà náà wá béèrè pé: “Àbí mo ṣi ọ̀rọ̀ sọ ni?” Ògbufọ̀ béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà lédè rẹ̀, ó sì fèsì pé: “Rárá o, dókítà. Ó sọ pé ohun tó ń pa òun lẹ́kún ni pé dókítà náà gbé ọwọ́ lé òun léjìká. Ó fi kún un pé kó tó di pé òun wá sọ́dọ̀ dókítà náà, kò sẹ́nì kankan tó ti fọwọ́ kan òun fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Ó dájú pé inú adẹ́tẹ̀ tó lọ bá Jésù yẹn máa dùn gan-an nígbà tí Jésù fọwọ́ kàn án, ìyẹn á sì mú kára tù ú. Àmọ́, ohun tí Jésù ṣe fún un tún jùyẹn lọ! Lẹ́yìn tí Jésù fọwọ́ kàn án lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo yẹn, àìsàn burúkú tó ń ṣe é yẹn lọ, ó wá láǹfààní láti pa dà wà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀, ó sì tún ṣeé ṣe fún un láti máa sin Jèhófà pẹ̀lú wọn!

      13, 14. (a) Àwọn wo ni Jésù pàdé bó ṣe fẹ́ wọ ìlú Náínì, kí sì nìdí tí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà fi bani nínú jẹ́ gan-an? (b) Nígbà tí àánú opó Náínì ṣe Jésù, kí ni Jésù ṣe fún un?

      13 Jésù máa ń ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ torí pé ó jẹ́ aláàánú. Ojú Jésù kì í gbà á tó bá rí i tí ìbànújẹ́ dorí àwọn èèyàn kodò. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo ìtàn tó wà nínú Lúùkù 7:11-15. Ìtòsí ìlú Náínì ní ìpínlẹ̀ Gálílì lọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, Jésù sì ti lo nǹkan bí ọdún kan àti oṣù mẹ́sàn-án lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn. Bí Jésù ṣe ń sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, ó pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ lọ sin òkú ọ̀dọ́kùnrin kan. Òkú ọ̀fọ̀ ni òkú ọmọ yìí, torí òun nìkan ni ìyá ẹ̀ bí, opó sì ni ìyá náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà kejì rèé tí ìyá ọmọ náà máa bára ẹ̀ nípò yìí. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tọ́kọ ẹ̀ kú. Àmọ́ ọmọ ẹ̀ ni lọ́tẹ̀ yìí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ yìí nìkan ló ń gbọ́ bùkátà ẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń sunkún àtàwọn tó ń kọrin arò wà lára àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé ìyá ọmọ náà. (Jeremáyà 9:17, 18; Mátíù 9:23) Àmọ́ obìnrin tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà ni Jésù tẹjú mọ́, torí ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ àwọn tó gbé òkú ọmọ náà ló ti ń rìn.

      14 Bí Jésù ṣe ń wo obìnrin tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà “àánú rẹ̀ ṣe é.” Ó wá fi ohùn tó tura sọ fún un pé: “Má sunkún mọ́.” Lẹ́yìn náà, Jésù sún mọ́ ohun tí wọ́n fi gbé òkú náà, ó sì fọwọ́ kàn án. Làwọn tó gbé òkú náà bá dúró, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn mú káwọn èrò tó ń tẹ̀ lé wọn náà dúró. Jésù wá pàṣẹ fún òkú náà pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!” Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? ‘Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀’ àfi bí ẹni tó jí lójú oorun! Ohun tí Bíbélì sọ lẹ́yìn náà wọni lọ́kàn gan-an, ó ní: “Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.”

      15. (a) Bá a ṣe rí i nínú ìtàn Bíbélì nípa bí Jésù ṣe máa ń ṣàánú àwọn èèyàn, kí ló yẹ kẹ́nì kan ṣe lẹ́yìn tí àánú àwọn èèyàn bá ṣe é? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

      15 Kí la rí kọ́ nínú àwọn ìtàn yìí? Kíyè sí i pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtàn yẹn ló jẹ́ ká rí i pé tí Jésù bá rí àwọn tí ìyà ń jẹ, kì í ṣe pé àánú wọn máa ń ṣe é nìkan, ó tún máa ń rí i dájú pé òun ṣe ohun kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Ọlọ́run ti fún àwa Kristẹni ní iṣẹ́ pàtàkì kan pé ká wàásù ìhìn rere, ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Òótọ́ ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ni olórí ìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì kí àánú àwọn èèyàn máa ṣe wá ká tó lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Tí àánú àwọn èèyàn bá ń ṣe wá bíi ti Jésù, a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere fún wọn. (Mátíù 22:37-39) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn tá a jọ ń sin Jèhófà bá ń jìyà tàbí tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ torí èèyàn wọn tó kú, kí la lè ṣe láti fi hàn pé àánú wọn ń ṣe wá? Àwa ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu láti yanjú ìṣòro wọn, a ò sì lè jí èèyàn wọn tó kú dìde. Àmọ́, a lè fàánú hàn sí wọn tá a bá ń ṣaájò wọn, tá a sì ń ṣe ohun kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Éfésù 4:32.

      “Baba, Dárí Jì Wọ́n”

      16. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó ṣe tán láti dárí jini, kódà nígbà tó wà lórí òpó igi oró?

      16 Ọ̀nà míì tún wà tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn lọ́nà tó pé bíi ti Bàbá rẹ̀, ìyẹn ni bí òun náà ṣe “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Kódà, ó ṣì fi hàn pé òun ṣe tán láti dárí jini nígbà tó wà lórí òpó igi oró. Rò ó wò ná: Kí ni Jésù sọ nígbà táwọn èèyàn fẹ́ pa á ní ìpa ìkà, tó sì ń jẹ̀rora bí wọ́n ṣe kànṣó mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀? Ṣé ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà pé kó fìyà jẹ àwọn tó fẹ́ pa òun? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, lára ọ̀rọ̀ tó sọ kó tó kú ni pé: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”​—Lúùkù 23:34.b

      17-19. Láìka bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe ṣẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹta, àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó ti dárí jì í?

      17 A tún rí àpẹẹrẹ míì tó wọni lọ́kàn nípa bí Jésù ṣe ń dárí jini látinú ohun tó ṣe nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù sẹ́ ẹ. Òótọ́ kan ni pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an. Ní alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ìyẹn alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, mo ṣe tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n, kí n sì bá ọ kú.” Àmọ́ ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ Jésù, tó lóun ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rí! Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pétérù sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀kẹta. Bíbélì sọ pé: “Olúwa . . . yíjú pa dà, ó sì wo Pétérù tààràtà.” Nígbà tí Pétérù rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lòun dá bóun ṣe sẹ́ Jésù, ẹ̀dùn ọkàn bá a, torí náà ó “bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.” Lẹ́yìn tí Jésù kú lọ́jọ́ yẹn, ó ṣeé ṣe kí Pétérù máa bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé Olúwa mi dárí jì mí báyìí?’​—Lúùkù 22:33, 61, 62.

      18 Kò pẹ́ tí Pétérù fi rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Àárọ̀ ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Nísàn ni Jésù jíǹde, ó sì jọ pé ọjọ́ yẹn gan-an ló fara han Pétérù. (Lúùkù 24:34; 1 Kọ́ríńtì 15:4-8) Láìka bí Pétérù ṣe sẹ́ Jésù kanlẹ̀, kí nìdí tí Jésù fi rí i pé òun wáyè bá a sọ̀rọ̀? Jésù mọ̀ pé Pétérù ti ronú pìwà dà, torí náà ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jésù fẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àti pé òun ṣì mọyì ẹ̀. Àmọ́ Jésù tún ṣe ohun míì tó jẹ́ kí ọkàn Pétérù balẹ̀.

      19 Ní àkókò kan lẹ́yìn náà, Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn létí Òkun Gálílì. Lọ́jọ́ yẹn, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù bi Pétérù (ẹni tó sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹta) bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun. Nígbà tó bi í lẹ́ẹ̀kẹta, Pétérù fèsì pé: “Olúwa, o mọ ohun gbogbo; o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ká sòótọ́, Jésù mọ̀ pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ òun, torí ó mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Síbẹ̀, Jésù fẹ́ kí Pétérù fẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́ jáde. Bákan náà, Jésù sọ fún Pétérù pé kó ‘máa bọ́ àwọn àgùntàn òun kéékèèké,’ kó sì “máa bójú tó” wọn. (Jòhánù 21:15-17) Ṣáájú àkókò yẹn, Jésù ti ní kí Pétérù máa wàásù. (Lúùkù 5:10) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, kí Pétérù lè mọ̀ pé Jésù fọkàn tán òun, Jésù fún un ní iṣẹ́ pàtàkì míì, ó ní kó máa bójú tó àwọn tó máa di ọmọlẹ́yìn òun. Láìpẹ́ sígbà yẹn, Jésù lo Pétérù láti kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe. (Ìṣe 2:1-41) Ó dájú pé ọkàn Pétérù máa balẹ̀ gan-an nígbà tó rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ti dárí ji òun àti pé ó ṣì fọkàn tán òun!

      Ṣé O “Mọ Ìfẹ́ Kristi”?

      20, 21. Báwo la ṣe lè “mọ ìfẹ́ Kristi” dáadáa?

      20 Ní tòótọ́, ọ̀nà tó dáa gan-an ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà ṣàpèjúwe ìfẹ́ Kristi. Àmọ́ tá a bá ronú nípa ìfẹ́ tí Jésù fi hàn, kí ló yẹ ká ṣe? Bíbélì rọ̀ wá pé ká “mọ ìfẹ́ Kristi tó ré kọjá ìmọ̀.” (Éfésù 3:19) Lóòótọ́, àwọn Ìwé Ìhìn Rere tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ti jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìfẹ́ tí Kristi fi hàn. Àmọ́, ká tó lè “mọ ìfẹ́ Kristi” dáadáa, a gbọ́dọ̀ ṣe ju ká kàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.

      21 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “mọ̀” túmọ̀ sí kéèyàn mọ nǹkan “nípasẹ̀ àwọn nǹkan tóun fúnra ẹ̀ ń ṣe.” Tá a bá ń lo okun àti àkókò wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tá à ń ṣàánú wọn nígbà ìṣòro, tá a sì ń dárí jì wọ́n látọkàn wá, a máa fi hàn pé à ń fara wé Jésù, a sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ̀. Ìgbà tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí la tó lè sọ pé a “mọ ìfẹ́ Kristi tó ré kọjá ìmọ̀.” Ká má gbàgbé pé bá a bá ṣe túbọ̀ ń fara wé Kristi, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, ẹni tí Jésù fìwà jọ lọ́nà tó pé.

      a Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣòfin pé, ó kéré tán èèyàn gbọ́dọ̀ jìnnà sí adẹ́tẹ̀ tó ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin (nǹkan bíi mítà méjì). Àmọ́ tí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́, adẹ́tẹ̀ náà gbọ́dọ̀ jìnnà tó, ó kéré tán, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (nǹkan bíi mítà márùndínláàádọ́ta) síbi téèyàn bá wà. Ìwé Midrash Rabbah sọ̀rọ̀ nípa rábì kan tó ń fara pa mọ́ fáwọn adẹ́tẹ̀ àti rábì míì tó ń sọ àwọn adẹ́tẹ̀ lókùúta, láti fi lé wọn dà nù. Torí náà, kì í ṣe ohun tuntun sáwọn adẹ́tẹ̀ táwọn èèyàn bá kórìíra wọn, tí wọ́n sì ń fojú àbùkù wò wọ́n.

      b Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan yọ ọ̀rọ̀ yìí kúrò nínú Lúùkù 23:34. Àmọ́, ó wà nínú ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ míì tó ṣeé gbára lé, torí náà a ò yọ ọ́ nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó sì tún wà nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì míì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kan Jésù mọ́gi ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ká sòótọ́, wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, torí wọn ò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Ó tún ṣeé ṣe káwọn Júù tó ní kí wọ́n pa Jésù wà lára àwọn tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, torí àwọn kan lára wọn ronú pìwà dà nígbà tó yá. (Ìṣe 2:36-38) Àmọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn jẹ̀bi ní tiwọn, torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, wọ́n fúngun mọ́ àwọn ará Róòmù pé kí wọ́n pa á. Torí náà, Ọlọ́run ò lè dárí ji ọ̀pọ̀ lára wọn.​—Jòhánù 11:45-53.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • Mátíù 9:35-38 Ọ̀nà pàtàkì wo ni Jésù gbà fàánú hàn, kí ló sì yẹ kíyẹn mú ká ṣe?

      • Jòhánù 13:34, 35 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ wa?

      • Róòmù 15:1-6 Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú bíi ti Kristi?

      • 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15 Tá a bá mọyì ìràpadà, báwo nìyẹn ṣe máa hàn nínú ìgbésí ayé wa, ìwà wa àti ohun tá a kà sí pàtàkì?

  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń kí ara wọn tẹ̀rín-tọ̀yàyà ní ìpàdé ìjọ.

      ORÍ 30

      ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’

      1-3. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà?

      “AYỌ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé: Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn látọkàn wá, ó máa ṣe wá láǹfààní. Òótọ́ ni pé a máa ń láyọ̀ táwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn sí wa, àmọ́ táwa fúnra wa bá fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ayọ̀ tá a máa ní á pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

      2 Kò sẹ́ni tó lóye òtítọ́ yìí tó Baba wa ọ̀run. Bá a ṣe ṣàlàyé láwọn orí tó ṣáájú nínú apá yìí, Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn. Kò sẹ́ni tó tíì fìfẹ́ hàn lọ́nà tó ga bíi ti Jèhófà, ó sì pẹ́ gan-an tó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu bí Bíbélì ṣe pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.”​—1 Tímótì 1:11.

      3 Ó wu Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ pé ká fara wé òun, ní pàtàkì tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn. Éfésù 5:1, 2 sọ fún wa pé: “Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìfẹ́.” Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, a máa rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. Inú wa tún máa dùn pé à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, torí pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká “máa nífẹ̀ẹ́ ara [wa].” (Róòmù 13:8) Àmọ́ àwọn ìdí míì tún wà tó fi yẹ ká “máa rìn nínú ìfẹ́.”

      Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì

      Arákùnrin àgbàlagbà kan rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ọ̀dọ́kùnrin kan, ó sì rọra fọwọ́ kan èjìká ẹ̀.

      Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará wa

      4, 5. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa?

      4 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Ìdí ni pé ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Tá ò bá sì nífẹ̀ẹ́, a ò lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Èyí tó wá bani nínú jẹ́ jù ni pé a ò ní wúlò fún Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìdí tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn.

      5 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kíyè sí gbólóhùn tí Jésù lò yẹn: “Bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.” Èyí fi hàn pé, bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ló ṣe fẹ́ káwa náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Ní Orí 29, a kẹ́kọ̀ọ́ pé, àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìfẹ́, torí ìfẹ́ ló mú kó yááfì àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí i kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan, ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó sì yẹ ká ṣe é tọkàntọkàn débi pé àwọn tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwa máa rí i pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ara wa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, ńṣe là ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá.

      6, 7. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an? (b) Kí ni kókó ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8?

      6 Téèyàn kan ò bá wá nífẹ̀ẹ́ ńkọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí mi ò [bá] ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ tó ń dún tàbí síńbálì olóhùn gooro.” (1 Kọ́ríńtì 13:1) Tí wọ́n bá fi síńbálì méjì gbá ara wọn, ńṣe ló máa ń han èèyàn létí. Abala idẹ ńkọ́? Ńṣe lòun náà máa ń han èèyàn létí. Àwọn àpèjúwe yìí mà bá a mu o! Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dà bí ohun èlò ìkọrin tó ń han èèyàn létí, tí kò sì dùn ún gbọ́ létí. Ká sòótọ́, ó máa ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: ‘Tí mo bá ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè nípò pa dà, àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mi ò já mọ́ nǹkan kan.’ (1 Kọ́ríńtì 13:2) Torí náà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn, àmọ́ tí kò nífẹ̀ẹ́, kò sí bó ṣe lè wúlò fún Jèhófà. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.

      7 Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8. Nínú àwọn ẹsẹ yẹn, kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tàbí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ lé lórí gangan. Kàkà bẹ́ẹ̀, kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí ara wa. Ó ṣàlàyé àwọn nǹkan tí àá máa ṣe àtàwọn nǹkan tá ò ní ṣe tá a bá nífẹ̀ẹ́.

      Ohun Tí Ìfẹ́ Máa Ń Ṣe

      8. Báwo ni sùúrù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?

      8 “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù.” Èyí túmọ̀ sí pé tá a bá ń ṣe sùúrù fáwọn èèyàn, tá a sì ń fara dà á fún wọn, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (Kólósè 3:13) Ká sòótọ́, ó yẹ ká máa ní sùúrù. Torí pé aláìpé làwa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n lè ṣẹ̀ wá tàbí káwa náà ṣẹ̀ wọ́n. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù àti ìfaradà, àá máa gbójú fo àwọn àṣìṣe tí kò tó nǹkan, a ò sì ní máa dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.

      9. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a jẹ́ onínúure?

      9 “Ìfẹ́ máa ń ní . . . inú rere.” Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tá a sì ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé a gba tiwọn rò, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ onínúure. Ìfẹ́ máa ń mú ká wá ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ní pàtàkì àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ jù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan bíi pé kò rẹ́ni fojú jọ, ó sì lè nílò ẹni táá ràn án lọ́wọ́ tàbí ẹni táá fún un níṣìírí. Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ tàbí arábìnrin kan tó wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè nílò ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́. Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tàbí tó níṣòro tó le gan-an, ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn tẹ́nì kan tó sún mọ́ ọn bá bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ kára lè tù ú. (Òwe 12:25; 17:17) Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà yìí, àá fi hàn pé a jẹ́ onínúure, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́.​—2 Kọ́ríńtì 8:8.

      10. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́, ká sì máa sọ òtítọ́, kódà nígbà tí ò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?

      10 “Ìfẹ́ . . . máa ń yọ̀ lórí òtítọ́.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . máa ń fi tayọ̀tayọ̀ gbè sẹ́yìn òtítọ́.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́, ó sì máa ń jẹ́ ká “bá ara [wa] sọ òtítọ́.” (Sekaráyà 8:16) Bí àpẹẹrẹ, téèyàn wa kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà á jẹ́ ká fara mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run. Torí náà, a ò ní máa gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ tàbí ká máa wí àwíjàre tàbí ká tiẹ̀ máa parọ́ nípa ohun tẹ́ni náà ṣe. Òótọ́ ni pé ó lè ṣòro láti gbà pé ẹni náà ṣe ohun tí kò dáa. Síbẹ̀, tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́, tá a sì fẹ́ káyé ẹ̀ dáa, àá fara mọ́ ọn pé kí Jèhófà bá a wí kó lè ṣàtúnṣe. (Òwe 3:11, 12) Bákan náà, tá a bá fẹ́ fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a máa “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

      11. Nítorí pé ìfẹ́ “máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra,” kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí ibi táwọn ará wa kù sí tàbí tí wọ́n bá ṣàṣìṣe?

      11 “Ìfẹ́ . . . máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra.” Ní èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé ìfẹ́ máa ń “bo gbogbo nǹkan.” Ìwé 1 Pétérù 4:8 sọ pé: “Ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa látọkàn wá, a ò ní máa sọ̀rọ̀ nípa àṣìṣe wọn àti ibi tí wọ́n kù sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àṣìṣe àwọn ará wa kì í tó nǹkan, torí náà a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá gbójú fo àṣìṣe wọn.​—Òwe 10:12; 17:9.

      12. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán Fílémónì, kí la sì rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

      12 “Ìfẹ́ . . . máa ń gba ohun gbogbo gbọ́.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé ìfẹ́ “máa ń múra tán láti gba ẹ̀rí àwọn èèyàn jẹ́.” Kò yẹ ká máa fura òdì sáwọn ará wa, ńṣe ló yẹ ká gbà pé ohun tó dáa ló wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe. Ìfẹ́ ń jẹ́ ká ‘gba ẹ̀rí àwọn ará wa jẹ́,’ ká sì fọkàn tán wọn.a Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Fílémónì. Ónísímù sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀, ìyẹn Fílémónì, àmọ́ Ónísímù di Kristẹni nígbà tó yá. Torí náà, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí Fílémónì láti rọ̀ ọ́ pé kó tẹ́wọ́ gbà á nígbà tó bá pa dà wálé. Pọ́ọ̀lù ò fi dandan mú Fílémónì láti gba Ónísímù pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fìfẹ́ rọ̀ ọ́. Ó fọkàn tán Fílémónì pé ó máa ṣe ohun tó tọ́, ó sọ pé: “Mò ń kọ̀wé sí ọ torí ó dá mi lójú pé o máa ṣe ohun tí mo sọ. Mo sì mọ̀ pé wàá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá.” (Ẹsẹ 21) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tá a sì fọkàn tán wọn, èyí á mú kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe ohun tó dáa.

      13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń retí pé àwọn ará wa ṣì máa ṣe dáadáa?

      13 “Ìfẹ́ . . . máa ń retí ohun gbogbo.” Bí ìfẹ́ ṣe ń jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará wa, ó tún máa ń jẹ́ ká retí pé wọ́n ṣì máa ṣe dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀,” ó máa ń wù wá pé kó tẹ́tí sáwọn tó fẹ́ ràn án lọ́wọ́, kó sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ. (Gálátíà 6:1) Bákan náà, ó máa ń wù wá pé káwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára dẹni tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. A máa ń mú sùúrù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára. (Róòmù 15:1; 1 Tẹsalóníkà 5:14) Tí èèyàn wa kan bá tiẹ̀ fi Jèhófà sílẹ̀, a ò ní yéé rétí pé lọ́jọ́ kan ó máa ronú pìwà dà, á sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bíi ti ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù.​—Lúùkù 15:17, 18.

      14. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó lè gba pé ká ní ìfaradà, báwo ni ìfẹ́ sì ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?

      14 “Ìfẹ́ . . . máa ń fara da ohun gbogbo.” Ìfaradà máa ń jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tá a bá níṣòro tàbí tí nǹkan bá tojú sú wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun tó dùn wá tàbí ohun tó lè fa ìṣòro fún wa. Àmọ́ nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà náà lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Torí pé aláìpé ni wọ́n, wọ́n lè ṣe ohun tó dùn wá. Ẹnì kan lè sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wa, kó sì dùn wá gan-an. (Òwe 12:18) Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, tá a gbà pé àwọn alàgbà ò bójú tó dáadáa. Tí arákùnrin kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún bá hùwà kan tó bí wa nínú, a lè máa rò ó pé: ‘Báwo lẹni tó pera ẹ̀ ní Kristẹni ṣe lè hu irú ìwà yẹn?’ Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé àá wá torí ìyẹn sọ pé a ò ní sin Jèhófà mọ́ ni? A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ní ìfẹ́! Ó dájú pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ṣẹ̀ wá, a ò ní torí ìyẹn gbà pé kò síbi tẹ́ni náà dáa sí rárá, tàbí ká wá máa fojú burúkú wo gbogbo àwọn ará nínú ìjọ. Bákan náà tá a bá ní ìfẹ́, àá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àá sì máa dúró ti àwọn ará wa nínú ìjọ, kódà tí èèyàn aláìpé bíi tiwa bá ṣe ohun tó dùn wá.​—Sáàmù 119:165.

      Ohun Tí Ìfẹ́ Kì Í Ṣe

      15. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa jowú, báwo sì ni ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

      15 “Ìfẹ́ kì í jowú.” Kò yẹ ká máa jowú àwọn èèyàn torí àwọn ohun tí wọ́n ní, ẹ̀bùn àbínibí wọn tàbí àwọn ohun míì tí wọ́n lè ṣe. Tá a bá ń jowú àwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé tara wa nìkan la mọ̀, ó sì lè ṣàkóbá fún wa àtàwọn ẹlòmíì. Tá ò bá sì wá nǹkan ṣe sí i, a lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ṣe ìlara? (Jémíìsì 4:5) Ìfẹ́ ló máa ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ní ìfẹ́, ńṣe làá máa bá àwọn míì yọ̀ tí wọ́n bá ní ohun táwa ò ní. (Róòmù 12:15) Bákan náà, a ò ní máa bínú tàbí ká máa jowú tí wọ́n bá gbóríyìn fún ẹnì kan torí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tó ní tàbí torí ó ṣe ohun kan dáadáa.

      16. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, kí nìdí tá ò fi ní máa fàwọn àṣeyọrí wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe fọ́rífọ́rí?

      16 “Ìfẹ́ . . . kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga.” Tá a bá nífẹ̀ẹ́, a ò ní máa fi àwọn ẹ̀bùn àbínibí tàbí àṣeyọrí wa ṣe fọ́rífọ́rí. Torí tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń fọ́nnu nítorí ohun tá a ṣe láṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí nítorí àwọn àǹfààní tá a ní nínú ìjọ, ìyẹn lè mú káwọn ará wa rẹ̀wẹ̀sì. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ sì lè mú kí wọ́n máa wo ara wọn bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a ò ní máa fàwọn àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa yán wọn lójú, àá máa rántí pé Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́ tá a fi ṣàwọn àṣeyọrí náà. (1 Kọ́ríńtì 3:5-9) Ó ṣe tán, ìfẹ́ “kì í gbéra ga,” tàbí bí Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹ̀, ‘ìfẹ́ kì í jẹ́ kéèyàn máa ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká máa rò pé a dáa ju àwọn míì lọ.​—Róòmù 12:3.

      17. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àwọn nǹkan wo làá máa ṣe, àwọn nǹkan wo la ò sì ní máa ṣe?

      17 “Ìfẹ́ . . . kì í hùwà tí kò bójú mu.” Ẹni tó ń hùwà lọ́nà tí kò bójú mu máa ń hùwà àìnítìjú, ó sì máa ń hùwà tó lè kan àwọn míì lábùkù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ìfẹ́ torí ìwà tó ń hù fi hàn pé kò ka àwọn èèyàn sí, kò sì gba tiwọn rò. Àmọ́ tá a bá ní ìfẹ́, a máa jẹ́ onínúure, a ò sì ní fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣeré rárá. Bákan náà, ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká hùwà ọmọlúwàbí, ká máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, á sì jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ní ìfẹ́, a ò ní hu “ìwà àìnítìjú,” ìyẹn ìwà èyíkéyìí tí kò ṣeé gbọ́ sétí tàbí tó máa múnú bí àwọn ará wa.​—Éfésù 5:3, 4.

      18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi dandan mú àwọn èèyàn láti fara mọ́ èrò wa?

      18 “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í rin kinkin mọ́ èrò tiẹ̀.” Ẹni tó ní ìfẹ́ kì í sọ pé èrò tòun nìkan ló tọ̀nà, kò sì ní máa sọ pé nǹkan tóun bá sọ làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Kò ní máa fọgbọ́n àyínìke darí àwọn èèyàn, kò sì ní fi dandan yí wọn lérò pa dà kí wọ́n lè ṣe ohun tó fẹ́. Ńṣe nirú ìwà yìí fi hàn pé ẹni náà jẹ́ alágídí àti agbéraga, Bíbélì sì sọ pé: “Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun.” (Òwe 16:18) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, àá máa ka ọ̀rọ̀ wọn sí pàtàkì, àá sì máa fara mọ́ èrò wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Irú ìwà yìí bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu. Ó sọ pé: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

      19. Tá a bá ní ìfẹ́, kí la máa ṣe táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá?

      19 “Ìfẹ́ . . . kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú.” Tá a bá ní ìfẹ́, a ò ní tètè máa bínú táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá. Òótọ́ ni pé inú lè bí wa táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá. Àmọ́ tí ìdí bá tiẹ̀ wà fún wa láti bínú lóòótọ́, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká yarí kanlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ò ní yanjú. (Éfésù 4:26, 27) A ò ní gbé ohun tẹ́nì kan ṣe tó dùn wá sọ́kàn, bí ẹni pé a lọ kọ ọ́ síbì kan tá ò ti ní gbàgbé, ká lè ṣíwèé kàn án lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ní ìfẹ́ á mú ká fìwà jọ Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Bá a ṣe rí i ní Orí 26, Jèhófà máa ń dárí jini nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Tó bá sì ti dárí jì wá, ó gbàgbé nìyẹn, ìyẹn ni pé kò ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jẹ wá mọ́ lọ́jọ́ iwájú. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà kì í dì wá sínú!

      20. Kí ni kò yẹ ká ṣe tí ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ìyà sì wá ń jẹ ẹ́?

      20 “Ìfẹ́ . . . kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í yọ̀ rárá nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí kò dáa.” Ìfẹ́ kì í fi ìwà àìṣòdodo ṣayọ̀. Torí náà, a ò ní fàyè gba ìwà ìṣekúṣe èyíkéyìí. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ọ̀kan lára àwọn ará wa bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ìyà sì wá ń jẹ ẹ́? Tá a bá nífẹ̀ẹ́, a ò ní máa yọ̀, ká wá máa sọ lọ́kàn wa pé, ‘Ọwọ́ ti bà á! Kò tán nídìí ẹ̀!’ (Òwe 17:5) Àmọ́, a máa ń yọ̀ nígbà tí arákùnrin kan tó ṣi ẹsẹ̀ gbé bá ṣàtúnṣe, tó sì pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

      “Ọ̀nà Tó Ta Yọ”

      21-23. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé”? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kẹ́yìn?

      21 “Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.” Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bọ̀ àtèyí tó sọ lẹ́yìn gbólóhùn yìí fi hàn pé ẹ̀bùn ẹ̀mí táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àwọn ẹ̀bùn yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà wà pẹ̀lú ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló lè mú aláìsàn lára dá, kì í ṣe gbogbo wọn ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, gbogbo wọn kọ́ ló sì lè fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Tẹ́nì kan ò bá tiẹ̀ wá láwọn ẹ̀bùn yìí, kì í ṣe nǹkan bàbàrà, torí pé bó pẹ́ bó yá, ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ò ní sí mọ́. Àmọ́, ohun kan wà tí kò ní dópin láé tó yẹ kí gbogbo Kristẹni ní. Ó ṣe pàtàkì ju àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu lọ, ó sì máa wà pẹ́ jù wọ́n lọ. Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ pè é ní “ọ̀nà tó ta yọ.” (1 Kọ́ríńtì 12:31) Kí ni “ọ̀nà tó ta yọ” yìí? Ìfẹ́ ni.

      22 Ká sòótọ́, ìfẹ́ Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ “kì í yẹ̀ láé,” ìyẹn ni pé, kò ní dópin láé. Títí di báyìí, ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ ni bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Irú ìfẹ́ yìí sì wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Ìfẹ́ yẹn máa wà títí láé, ó ṣe tán Jèhófà ti ṣèlérí fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Sáàmù 37:9-11, 29) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè “máa rìn nínú ìfẹ́.” Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí ayọ̀ púpọ̀ tó wà nínú fífúnni. Ní pàtàkì jù lọ, a máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé, títí ayérayé làá sì máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.

      Ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwọn èèyàn Jèhófà mọ̀ ni bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn

      23 Nínú ìwé yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó gbawájú jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ tó ta gbogbo wọn yọ. A tún ti rí bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní. Ní báyìí tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́?’ A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú orí tó kẹ́yìn ìwé yìí.

      a Òótọ́ ni pé ìfẹ́ “máa ń gba ohun gbogbo gbọ́,” àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn tàn wá. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa ṣọ́ àwọn tó ń fa ìyapa àti ìkọ̀sẹ̀ . . . , kí ẹ sì yẹra fún wọn.”​—Róòmù 16:17.

      Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé

      • 2 Kọ́ríńtì 6:11-13 Kí ló túmọ̀ sí pé ká ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá, báwo la sì ṣe lè fi ìmọ̀ràn yẹn sílò?

      • 1 Pétérù 1:22 Báwo lohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa dénú, ká sì máa ṣe ohun táá mú kára tù wọ́n?

      • 1 Jòhánù 3:16-18 Báwo la ṣe lè fi hàn pé “ìfẹ́ Ọlọ́run” wà nínú wa?

      • 1 Jòhánù 4:7-11 Kí ni ohun tó lágbára jù lọ tó yẹ kó sún wa láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́