ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 25-29
  • ‘Jehofa ni Ọlọrun Mi, Ninu Ẹni Ti Emi Yoo Nigbẹkẹle’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Jehofa ni Ọlọrun Mi, Ninu Ẹni Ti Emi Yoo Nigbẹkẹle’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Itara Awofiṣapẹẹrẹ Awọn Obi Mi
  • Iṣileti Ọlọgbọn Ti Baba Mi
  • Ihin-iṣẹ Kan Lati Ọrun
  • Mo Kún Fun Ọpẹ fun Gbogbo Anfaani Iṣẹ-isin
  • Wíwà Ni Agbékánkánṣiṣẹ́ Niṣo Lakooko Ogun
  • Ibẹwo Kan Pẹlu Iyọrisi Ti A Kò Reti
  • Fifarada a Laika Awọn Iṣoro Si
  • Arakunrin Knorr Pada Dé
  • Awọn Iyalẹnu Titun Diẹ
  • Bawo ni ó ti dunmọni tó ni 1964 nigba ti a ké si aya mi ati emi sí kilaasi ogoji ti Gilead, ikẹhin lara awọn kilaasi oloṣu mẹwaa, ti ó ni idanilẹkọọ gbigbooro ninu, eyi ti a ti ké kuru si oṣu mẹjọ nisinsinyi. Marthe nilati kọ́ ede Gẹẹsi ni kiakia, ṣugbọn ó bojuto eyi ni ọna ti ó wuni. Ọpọ imefo ni ó wà niti ibi ti wọn yoo ran wa lọ. Ironu mi ni pe: ‘Emi kò bikita nipa ibi ti a lè yàn fun mi, kiki niwọn bi kò ba ti jẹ iṣẹ ọfiisi!’
  • Wíwò Ẹ̀hìn
  • Jalẹ 60 ọdun iṣẹ-isin alakooko kikun, mo ti ni igbẹkẹle ninu Jehofa patapata, gan-an gẹgẹ bi Baba mi ti sọ fun mi pe mo gbọdọ ṣe. Jehofa sì ti tú ọpọlọpọ oriṣi ibukun jade. Marthe ti jẹ́ orisun iṣiri ńláǹlà ni awọn akoko ijakulẹ tabi nigba ti awọn iṣẹ ti a yan fun mi ba halẹ lati bò mi mọ́lẹ̀, nitootọ ó jẹ ẹnikeji aduroṣinṣin kan pẹlu igbọkanle patapata ninu Jehofa.
  • Ìgbésí Ayé Tí N kò Kábàámọ̀ rí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 25-29

‘Jehofa ni Ọlọrun Mi, Ninu Ẹni Ti Emi Yoo Nigbẹkẹle’

GẸGẸ BI WILLI DIEHL TI SỌ Ọ

“Eeṣe ti iwọ fi fẹ́ lọ si Bẹtẹli?” Eyi ni ibeere baba mi ni igba ìrúwé 1931 nigba ti mo sọ ifẹ mi lati bẹrẹ iṣẹ-isin Bẹtẹli fun un. Awọn obi mi ti wọn ngbe ni Saarland, ti wà ninu otitọ fun ọdun mẹwaa tabi ki ó sunmọ ọn, wọn sì ti gbe apẹẹrẹ rere kalẹ fun awa ọmọkunrin mẹta. Otitọ ni gbogbo igbesi-aye wọn, mo sì fẹ́ sọ ọ di gbogbo igbesi-aye temi pẹlu.

ṢUGBỌN bawo ni awọn obi mi ṣe mọ nipa Jehofa ati ifẹ-inu mimọ rẹ̀? Lainitẹẹlọrun pẹlu isin jàǹkànjàǹkàn, wọn ti wá otitọ kiri fun ìgbà pípẹ́. Wọ́n gbiyanju oniruuru awọn ṣọọṣi ati awọn ẹ̀yà isin, ni rírí ọkọọkan nikẹhin, pe kii ṣe eyi ti ó tọna.

Ni ọjọ kan iwe ìléwọ́ ni a fisilẹ ni ẹnu ọna wa ti nṣefilọ ọrọ asọye kan pẹlu awọn aworan ati sinima nipa ete Ọlọrun ti a npe ni “Photo Drama of Creation [Awokẹkọọ Onifọto ti Iṣẹda].” Baba mi nilati ṣiṣẹ nigba ti a o fi “Photo Drama” naa hàn, ṣugbọn ó fun Mama mi niṣiiri lati lọ. O wi pe, “boya yoo ṣanfaani lati wò ó.” Lẹhin wiwo o ni alẹ yẹn, iya mi kún fun igbonara. O wi pe, “Mo ti ri i nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín! Wá wò ó funraarẹ ni alẹ ọla. Ó jẹ otitọ ti a ti nwa kiri.” Iyẹn jẹ́ ni 1921.

Gẹgẹ bi awọn Kristẹni ti a fẹmi yàn, awọn obi mi duro ni olotiitọ titi di igba ti wọn kú, baba mi kú ni 1944, lẹhin ti ó ti di ẹni ti a tì mọnu ẹwọn lati ọwọ Nazi ni ọpọlọpọ ìgbà, Iya mi sì kú ni 1970. Oun pẹlu lo akoko gigun ninu ẹwọn labẹ ijọba Nazi.

Itara Awofiṣapẹẹrẹ Awọn Obi Mi

Ṣaaju ki wọn tó kú, awọn obi mi jẹ agbekankanṣiṣẹ gan-an ninu iṣẹ-isin pápá. Iya mi ni pataki jẹ́ onitara ninu pinpin awọn ipinnu ti a tẹ jade ni apejọpọ lati 1922 si 1928 kiri. A Fẹ̀sùn Ẹṣẹ Kan Awọn Alufaa, ti ó jẹ ipinnu kan ti a gbà ni 1924 ní ariwisi mimuna ti a ṣe si awọn alufaa ninu. Pipin in kiri gba igboya. Awọn akede yoo jí ni agogo mẹrin owurọ, ni titi awọn iwe aṣaro kukuru naa bọ abẹ awọn ilẹkun. Bi o tilẹ jẹ pe mo jẹ kiki ẹni ọdun 12, awọn obi mi yọnda fun mi lati kópa. A saba maa nbẹrẹ ni agogo marun-un owurọ, ni gigun kẹ̀kẹ́ wakati mẹta si mẹrin lati dé ipinlẹ jijinna réré. A o gbe awọn kẹ̀kẹ́ naa pamọ sinu igbo, emi yoo sì maa ṣọ́ wọn nigba ti awọn miiran ba nṣiṣẹ ninu abule naa. Ni ọsan awa yoo wa kẹ̀kẹ́ lọ si ile, ati ni irọlẹ a o rin irin wakati kan lọ si ipade.

Lẹhin naa, ẹnikan ti ó tubọ kere ni a fi silẹ lati ṣọ awọn kẹkẹ naa, mo sì lọ papọ pẹlu awọn akede. Ṣugbọn ko sí ẹnikankan ti ó ronu nipa kíkọ́ mi. Wọn wulẹ sọ opopona ti mo ti nilati ṣiṣẹ ni! Pẹlu ọkan-aya ti ńlù pìpìpì mo tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ lọ si ile akọkọ, pẹlu ireti pe kò ni si ẹnikankan nile. Págà, ọkunrin kan ṣilẹkun. Emi kò le sọrọ. Pẹlu ẹ̀gbọ̀nrìrì, mo tọka si iwe naa ti ó wà ninu apo mi. Ó beere pe, “Ṣe lati ọdọ Adajọ Rutherford ni?” Mo kólòlò idahun kan. “Ṣe titun ni, ọ̀kan ti emi kò ní?” “Bẹẹni, titun ni,” mo mu un da a loju. “Nigba naa mo gbọdọ ni i. Eélòó ni?” Eyi fun mi ni iṣiri lati maa baa lọ.

Ni 1924 awọn agbalagba sọrọ pupọ nipa 1925. Lẹẹkanri a ṣebẹwo sọdọ idile awọn Akẹkọọ Bibeli kan, mo sì gbọ́ ti arakunrin kan beere pe: “Bi Oluwa bá mú wa lọ, ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọmọ wa?” Iya mi, ti ifojusọna rẹ̀ maa njẹ rere nigba gbogbo, fesi pada pe: “Oluwa yoo mọ bi yoo ṣe bojuto wọn.” Ijiroro naa fa ọkàn mi mọra. Ki ni gbogbo rẹ̀ tumọsi? Ọdun 1925 dé ó sì kọja lọ, kò sì sí ohun ti ó ṣẹlẹ. Bi o ti wu ki o ri, awọn obi mi kò juwọsilẹ ninu itara wọn.

Iṣileti Ọlọgbọn Ti Baba Mi

Nikẹhin, ni 1931, mo sọ fun baba mi nipa ohun ti mo fẹ́ lati ṣe pẹlu igbesi-aye mi. Ni ifesi pada baba mi beere pe, “Eeṣe ti iwọ fi fẹ́ lọ si Bẹtẹli?” Mo dahun pada pe, “Nitori pe mo fẹ lati ṣiṣẹsin Jehofa.” O nbaa lọ pe, “Ki a sọ pe a gbà ọ́ sí Bẹtẹli, njẹ o mọ̀ daju pe awọn arakunrin ti wọn wà nibẹ kii ṣe angẹli? Wọn jẹ́ alaipe wọn sì nṣaṣiṣe. Ominu ńkọ mi pe eyi lè mu ki o salọ ati ki o tilẹ sọ igbagbọ nù paapaa. Rí i daju pe o ronu gidigidi nipa rẹ̀.”

Jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé mi lọ́wọ́ lati gbọ iru nǹkan bẹẹ, ṣugbọn lẹhin gbigbe awọn ọran naa yẹwo fun awọn ọjọ diẹ, mo tun idaniyan mi sọ lati kọwe beere fun iṣẹ Bẹtẹli. Ó sọ fun mi pe, “Sọ fun mi lẹẹkan sii idi ti o fi fẹ lọ.” Mo da a lohun pe, “nitori pe mo fẹ lati ṣiṣẹsin Jehofa.” “Ọmọdekurin mi, maṣe gbagbe iyẹn. Bi a ba ké sí ọ, ranti idi ti o fi nlọ. Bi o ba rí ohun kan ti kò tọ́, maṣe ṣaniyan kọja bi ó ṣe yẹ. Ani bi a ba tilẹ bá ọ lò lọna ti kò tọ́, maṣe salọ. Maṣe gbagbe idi ti o fi wà ni Bẹtẹli—nitori pe o fẹ́ lati ṣiṣẹsin Jehofa! Ṣaa ti gbajumọ iṣẹ rẹ ki o sì nigbẹkẹle ninu Jehofa.”

Bẹẹ ni ó rí pe ni ibẹrẹ ọsan ni November 17, 1931, mo dé sí Bẹtẹli ni Bern, Switzerland. Mo ṣajọpin yàrá pẹlu awọn mẹta miiran mo sì ṣiṣẹ ninu ile-iṣẹ itẹwe, ni kíkọ́ bi a ti ṣe nlo ẹrọ itẹwe kekere ti a nfi ọwọ ti bébà sí lẹnu. Ọ̀kan lara awọn nǹkan ti a kọkọ yàn fun mi lati tẹ̀ ni Ilé-ìṣọ́nà ni ede Romania.

Ihin-iṣẹ Kan Lati Ọrun

Ni 1933 Society tẹ The Crisis [Yánpọnyánrin] jade, iwe kekere kan ti ó ni ọrọ asọye ori redio mẹta ti Arakunrin Rutherford ti sọ ni United States. Arakunrin Harbeck iranṣẹ ẹka, fi tó idile Bẹtẹli leti ni akoko ounjẹ ni owurọ ọjọ kan pe iwe kekere naa ni a nilati pin yika ni ọna akanṣe kan. Iwe pélébé ti nfọnrere ni a o fọ́nká lati inu ọkọ ofuurufu kekere kan ti a rẹnti ti ńfò loke Bern, nigba ti awọn akede yoo duro loju pópó ni pipin iwe pẹlẹbẹ naa fun awọn ara ilu. “Ewo ninu ẹyin arakunrin ni ó ti muratan lati bá ọkọ ofuurufu lọ soke?” ni o beere. “Fi orukọ rẹ silẹ ni bayii.” Mo ṣe bẹẹ, Arakunrin Harbeck sì ṣefilọ lẹhin naa pe a ti yàn mi.

Ni ọjọ pataki naa, a fi ọkọ kó awọn paali ẹrù iwe pélébé naa lọ sí ibudokọ ofuurufu. Mo jokoo lẹhin atukọ mo sì kó awọn iwe pélébé naa sori ijokoo lẹgbẹẹ mi. Awọn itọni pato ti a fun mi ni pe: Di awọn iwe ìléwọ́ naa ni ìdì ọgọrọọrun, ki o sì ju idipọ kọọkan jade lati oju ferese jade si ẹgbẹ kan pẹlu gbogbo ipá ti o ba le lo. Aibikita le fa ki awọn iwe naa di eyi ti ó há mọ ibi ìrù ọkọ ofuurufu naa, ni dida iṣoro silẹ. Ṣugbọn gbogbo rẹ̀ lọ laisi wahala. Awọn ara lẹhin naa sọ bi o ti gbadunmọni tó lati rí ‘ihin-iṣẹ lati ọrun.’ O ni iyọrisi ti a nilọkan. Ọpọ awọn iwe kekere ni a sì fi sode, ani bi awọn eniyan diẹ tilẹ foonu lati ṣaroye pe awọn ebè ododo awọn ni iwe pélébé naa bò.

Mo Kún Fun Ọpẹ fun Gbogbo Anfaani Iṣẹ-isin

Lojoojumọ ni mo ndupẹ lọwọ Jehofa fun ayọ ati itẹlọrun iṣẹ-isin Bẹtẹli. Ninu ijọ, a yàn mi lati ṣi Gbọngan Ijọba, lati ṣeto awọn aga ni ọna ti ó wà letoleto, ati lati gbé ife omi tutu kan sori iduro olubanisọrọ. Mo ka eyi si ọla titobi kan.

Ni Bẹtẹli, mo ṣiṣẹ lara ẹrọ-itẹwe pẹrẹsẹ titobi ti a nlo lati tẹ The Golden Age (Ji! nisinsinyi) ni ede Polish. Ni 1934 a bẹrẹ sii lo awọn ẹrọ fonogiraafu, mo sì ṣeranlọwọ ninu ṣiṣe wọn. Mo rí ayọ nla ninu lilọ lati ile de ile pẹlu ọrọ asọye Bibeli ti a ti gbà silẹ. Ọpọlọpọ awọn onile ni wọn nṣe kàyéfì nipa ẹrọ kekere yii, ati ni ọpọlọpọ ìgbà gbogbo idile yoo sì kórajọ lati fetisilẹ, kìkì lati rá nikọọkan. Nigba ti gbogbo idile naa bá ti lọ, emi yoo wulẹ lọ sí ibomiran.

Wíwà Ni Agbékánkánṣiṣẹ́ Niṣo Lakooko Ogun

Lẹhin Ogun Agbaye Kìn-ín-ní, Saarland ibilẹ mi ni a yasọtọ kuro lara Germany ti a sì ndari labẹ iranlọwọ Imulẹ Awọn Orilẹ-ede. Nipa bayii, Saarland tẹ awọn ìwé ìdánimọ̀ tirẹ funraarẹ jade. Ni 1935 ìdìbò gbogbo ara ilu ni a ṣe lati pinnu boya awọn ọlọ̀tọ̀ rẹ̀ fẹ lati tun so pọ̀ pẹlu Germany. Mo lo anfaani naa lati bẹ idile mi wò, ni mímọ̀ pe emi ko ni lè ṣe bẹẹ bi Saarland bá nilati wá sabẹ iṣakoso Nazi. Ati nitootọ, fun ọpọlọpọ ọdun lẹhin naa, emi kò gbọ́ ohunkohun lati ọdọ awọn obi mi tabi awọn arakunrin mi.

Bi o tilẹ jẹ pe a da a sí kuro ninu lilọwọ ninu Ogun Agbaye Keji ni taarata, Switzerland di àdádó patapata bi Germany ti ngba awọn orilẹ-ede agbegbe nikọọkan. A ti ntẹ iwe ikẹkọọ fun gbogbo apa Europe yatọ si Germany, ṣugbọn nisinsinyi a kò lè pese iwe ikẹkọọ ti wọn bá beere fun. Arakunrin Zürcher, ẹni ti ó jẹ́ iranṣẹ ẹ̀ka nigba naa, sọ fun wa pe awa fẹrẹẹ má ni owo kankan ti ó ṣẹ́kù, ó sì ké si wa lati wá iṣẹ lẹhin ode Bẹtẹli titi di igba ti awọn nǹkan ba bọ́ sí deedee. Bi o ti wu ki o ri, a yọnda fun mi lati duro, niwọn bi awọn nǹkan diẹ ti wà lati tẹ̀ fun nǹkan bii ẹgbẹrun kan awọn akede adugbo.

Idile Bẹtẹli kì yoo gbagbe July 5, 1940 lae. Gẹ́lẹ́ lẹhin ounjẹ ọsan ọkọ ologun kan dé. Awọn jagunjagun fò jade wọn sì já wọnu Bẹtẹli. A paṣẹ fun wa lati duro láìmira, ẹnikọọkan wa ni jagunjagun kan ti ó di ihamọra nṣọ. A dà wá lọ sinu gbọngan ijẹun nigba ti a ńtú inu iyooku ile naa. Awọn alaṣẹ fura sí wa pe a nsọ fun awọn ẹlomiran lati kọ iṣẹ-isin ologun, ṣugbọn wọ́n kuna lati rí ẹ̀rí kankan.

Laaarin akoko awọn ọdun ogun, mo jẹ́ iranṣẹ ijọ ni Thun ati Frutigen. Iyẹn tumọsi pe itolẹsẹẹsẹ ipari ọsẹ mi ni ó kún fọ́fọ́ gan-an. Ni Satide kọọkan, gbàrà lẹhin ounjẹ ọsan, emi yoo gun kẹ̀kẹ́ mi lọ si Frutigen ti ó fi 30 ibusọ jinna, nibi ti mo ti ndari Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà ni irọlẹ. Ni owurọ ọjọ Sọnde mo ndarapọ pẹlu awọn akede ninu iṣẹ-isin pápá. Lẹhin naa, ni ìyálẹ̀ta emi yoo lọ si Interlaken lati darí Ikẹkọọ Iwe Ijọ ati lẹhin naa ni ọsan lati dari ikẹkọọ Bibeli pẹlu idile kan ni Spiez. Lati pari ọjọ naa, emi yoo darí Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà ni ede Thun.

Ni alẹ́ patapata, lẹhin ti mo ba ti pari gbogbo igbokegbodo mi, emi yoo kọrin emi yoo sì súfèé pada si Bern, ní níní itẹlọrun lọna jijinlẹ. Awọn ọkọ ayọkẹlẹ ko pọ wọn si jinna si araawọn. Awọn ilẹ olókè, ti okunkun ogun bò mọ́lẹ̀, ni ó parọrọ ti kò sì ni ìdílọ́wọ́, ti imọlẹ oṣupa ńtàn síi nigba kọọkan. Ẹ wo bi awọn ipari ọsẹ wọnni ti mu igbesi-aye mi sunwọn sii tó ti ó sì mu okun mi dọtun!

Ibẹwo Kan Pẹlu Iyọrisi Ti A Kò Reti

Ni ìgbà ẹ̀rùn 1945, Arakunrin Knorr bẹ̀ wá wò. Ni ọjọ kan ó wọnu ile-iṣẹ ẹrọ gẹgẹ bi mo ti duro lori ẹrọ itẹwe Rotary. Ó ké si mi pe, “maa bọ̀ nilẹ!.” “Ki ni yoo jẹ́ ero rẹ nipa lilọ sí Ile-ẹkọ Gilead?” Ó yà mi lẹnu gidigidi. “Bi iwọ ba ronu pe mo tootun fun un, inu mi yoo dùn lati lọ,” ni mo fesi pada. Awọn ikesini fun Arakunrin Fred Borys, Arabinrin Alice Berner, ati emi dé ni ìgbà ìrúwé 1946. Ṣugbọn nitori pe a bí mi ni Saarland, emi kò ni orilẹ-ede ati nitori naa mo nilati beere fun iwe aṣẹ irin ajo akanṣe kan ni Washington D.C., U.S.A.

Nigba ti o jẹ pe awọn yooku lọ lakooko, mo nilati duro fun èsì ibeere mi. Nigba ti ile-ẹkọ bẹrẹ ni September 4, mo ṣì wà ni Switzerland sibẹ, ni sisọ ireti nù diẹdiẹ. Lẹhin naa Aṣoju ijọba U.S. ni ilẹ miiran ke si mi, ni fifi tó mi leti pe iwe aṣẹ irin ajo mi ti dé. Mo gbiyanju lati ṣe awọn eto irin ajo lẹsẹkẹsẹ mo sì rí yara ibùsùn kan gbà nikẹhin ninu ọkọ oju-omi ti ńkó awọn jagunjagun ti nlọ lati Marseilles si New York. Iru iriri wo ni eyi jẹ́! Athos II Ọkọ oju omi naa kún àkúnya. A fun mi ni ibusun kan ninu iyàrá ti ó ṣe gbayawu kan. Ni ọjọ keji ni oju omi, ìbúgbàù kan ninu ile ẹrọ ti ngbe ọkọ oju omi naa rin mu ọkọ oju omi naa wá sí ìdádúró. Awọn ero ọkọ ati awọn abọkọrin bakan naa ni ara wọn kò balẹ, ni bibẹru pe a lè rì. Eyi fun mi ni anfaani agbayanu lati jẹrii nipa ireti ajinde.

Ó gba ọjọ meji lati ṣatunṣe ọkọ oju omi naa, lẹhin eyi ti a nbaa lọ láìsáré pupọ. A dé New York ni ọjọ 18 lẹhin naa, kìkì lati di ẹni ti a fipa mú lati wà ninu ọkọ oju omi naa nitori ìdaṣẹ́sílẹ̀ awọn oṣiṣẹ etikun. Lẹhin awọn ìfọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, o ṣeeṣe fun wa lati fi ọkọ oju omi naa silẹ. Mo ti tẹ wáyà si Society nipa ipo naa, bi mo sì ti nfi awọn oṣiṣẹ ibode ati awọn ti nbojuto ìṣíwọlé sí ilu miiran silẹ, ọkunrin kan beere lọwọ mi pe: “Ṣe iwọ ni Ọgbẹni Diehl?” Oun jẹ ọ̀kan lara awọn oluranlọwọ Arakunrin Knorr, o sì fi mi wọ ọkọ oju irin alẹ́ ti nlọ sí Ithaca, lẹba Ile-ẹkọ Gilead, nibi ti mo dé sí ni agogo mẹjọ kọja diẹ ni owurọ ọjọ keji. Ẹ wò bi o ti dunmọ mi tó lati wà nibẹ lẹhin-ọ-rẹhin, ti mo lè lọ si kilaasi Gilead akọkọ ti ó mu oniruuru orilẹ-ede lọwọ!

Fifarada a Laika Awọn Iṣoro Si

Ikẹkọọyege kilaasi kẹjọ ti Gilead jẹ́ ni February 9, 1947, gbogbo eniyan ni ó sì niriiri imọlara aniyan ohun ti yoo ṣẹlẹ. Nibo ni a o ran wa lọ? Fun emi, “awọn okùn iwọn” bọ sori ile-iṣẹ ẹrọ itẹwe Society ti a ṣẹṣẹ ṣí ni Wiesbaden, Germany. (Saamu 16:6) Mo pada sí Bern lati beere fun awọn iwe ti ó pọndandan, ṣugbọn ẹgbẹ ọmọ ogun U.S. ti nbẹ ni Germany nyọnda iwọle fun kìkì awọn ẹni ti ó ti gbe nibẹ ṣaaju ogun. Niwọn bi emi kò ti gbe ibẹ, mo nilo ibi ayanfunni titun kan lati orile-iṣẹ ni Brooklyn. Ó yọrisi iṣẹ ayika ni Switzerland, mo sì tẹwọgba a pẹlu igbẹkẹle kikun ninu Jehofa. Ṣugbọn nigba ti mo nduro de iṣẹ ayanfunni yii, a beere lọwọ mi ni ọjọ kan lati fi ayika Bẹtẹli han awọn arabinrin mẹta ti nṣebẹwo ni ọjọ kan. Ọkan ninu wọn jẹ́ aṣaaju-ọna ti a npe ni Marthe Mehl.

Ni May 1949, mo fi tó orile-iṣẹ ni Bern leti pe mo ṣeto lati fẹ́ Marthe ati pe a fẹ lati maa baa lọ ninu iṣẹ-isin alakooko kikun. Ki ni idahunpada wọn? Kò si anfaani kankan yatọ si ṣiṣe aṣaaju-ọna deedee. Eyi ni a bẹrẹ ni Biel, tẹle igbeyawo wa ni June 1949. A kò yọnda fun mi lati sọ asọye, bẹẹ ni a kò le wá ile ibuwọ fun awọn ayanṣaṣoju fun apejọ ti nbọ, bi o tilẹ jẹ pe alaboojuto ayika wa ti damọran wa fun anfaani yii. Ọpọlọpọ kò kí wa mọ, ni biba wa lò gẹgẹ bii awọn ẹni ti a yọ lẹgbẹ, ani bi o tilẹ jẹ pe aṣaaju-ọna ni wa.

Bi o ti wu ki o ri, a mọ pe ṣiṣegbeyawo kii ṣe eyi ti kò bá iwe mimọ mu, nitori naa a wá isadi ninu adura a sì fi igbẹkẹle wa sinu Jehofa. Niti tootọ, ihuwa yii kò ṣagbeyọ oju-iwoye Society. O wulẹ jẹ́ iyọrisi ifi awọn ilana eto-ajọ silo lọna odi.

Arakunrin Knorr Pada Dé

Ni 1951, Arakunrin Knorr bẹ Switzerland wò lẹẹkan si. Lẹhin ti ó ti sọ ọrọ asọye kan, a sọ fun mi pe ó fẹ lati bá mi sọrọ. Bi o tilẹ jẹ pe mo nimọlara aibalẹ àyà lọna kan ṣá inu mu dun pe ó wù ú lati ri mi. Ó beere bi emi yoo ba fẹ lati tẹwọgba iṣẹ ayanfunni kan ni ile ojihin iṣẹ Ọlọrun kan ti a npete ni Geneva. Ó dun mọ wa ninu lọna ti ẹda bi o tilẹ jẹ pe fifi Biel silẹ ki yoo jẹ laisi ikẹdun kankan. Ni ọjọ keji ibeere siwaju sii lati ọdọ Arakunrin Knorr kan wá lara. Awa yoo ha muratan lati bẹrẹ iṣẹ ayika bi, niwọn bi eyi ti nilo afikun afiyesi ni Switzerland? A gbà loju ẹsẹ. Iṣarasihuwa mi ti jẹ lati gba iṣẹ eyikeyii ti a yan fun mi nigba gbogbo.

Igbokegbodo wa ninu iṣẹ ayika ni ila-oorun Switzerland ni a bukun gidigidi. A nwọ ọkọ oju irin lati lọ si awọn ijọ, ni gbigbe gbogbo awọn ohun ìní wa sinu apoti meji. Awọn ará niye igba npade wa ni ibudokọ pẹlu kẹ̀kẹ́, nitori diẹ ninu wọn ni ó ni ọkọ ayọkẹlẹ ni awọn ọjọ wọnni. Ọpọlọpọ ọdun lẹhin naa arakunrin kan pese ọkọ ayọkẹlẹ kan fun wa, eyi ti o mu ki iṣẹ-isin wa rọrun sii lọna kan ṣá.

Awọn Iyalẹnu Titun Diẹ

Bawo ni ó ti dunmọni tó ni 1964 nigba ti a ké si aya mi ati emi sí kilaasi ogoji ti Gilead, ikẹhin lara awọn kilaasi oloṣu mẹwaa, ti ó ni idanilẹkọọ gbigbooro ninu, eyi ti a ti ké kuru si oṣu mẹjọ nisinsinyi. Marthe nilati kọ́ ede Gẹẹsi ni kiakia, ṣugbọn ó bojuto eyi ni ọna ti ó wuni. Ọpọ imefo ni ó wà niti ibi ti wọn yoo ran wa lọ. Ironu mi ni pe: ‘Emi kò bikita nipa ibi ti a lè yàn fun mi, kiki niwọn bi kò ba ti jẹ iṣẹ ọfiisi!’

Ṣugbọn ohun ti ó ṣẹlẹ gan-an niyẹn! Ni ọjọ ikẹkọọyege, September 13, 1965, a yàn mi gẹgẹ bi iranṣẹ ẹ̀ka Switzerland. Bẹtẹli yoo jẹ́ iriri titun fun Marthe. Fun emi, ó tumọ si pipada lọ si “Ile Ọlọrun,” kii ṣe sí ile-ẹrọ itẹwe, nibi ti mo ti ṣiṣẹsin lati 1931 si 1946, ṣugbọn sinu ọfiisi naa. Mo ni ọpọlọpọ ohun titun lati mọ̀, ṣugbọn pẹlu iranlọwọ Jehofa ó ṣeeṣe fun mi lati ṣe bẹẹ.

Wíwò Ẹ̀hìn

Jalẹ 60 ọdun iṣẹ-isin alakooko kikun, mo ti ni igbẹkẹle ninu Jehofa patapata, gan-an gẹgẹ bi Baba mi ti sọ fun mi pe mo gbọdọ ṣe. Jehofa sì ti tú ọpọlọpọ oriṣi ibukun jade. Marthe ti jẹ́ orisun iṣiri ńláǹlà ni awọn akoko ijakulẹ tabi nigba ti awọn iṣẹ ti a yan fun mi ba halẹ lati bò mi mọ́lẹ̀, nitootọ ó jẹ ẹnikeji aduroṣinṣin kan pẹlu igbọkanle patapata ninu Jehofa.

Ki iyin jẹ ti Jehofa fun ọpọlọpọ awọn anfaani iṣẹ-isin ti mo ti gbadun! Mo ṣì nṣiṣẹsin gẹgẹ bi olùṣekòkáárí Igbimọ Ẹ̀ka ni Thun, mo sì ti ririn-ajo gẹgẹ bi alaboojuto ipinlẹ ńlá ni ọpọlọpọ igba. Ohun yoowu ti a sọ fun mi pe ki nṣe, mo nwo Jehofa fun itọsọna nigba gbogbo. Laika ọpọlọpọ aṣiṣe ati awọn aidoju ila mi sí, mo gbagbọ tọkantọkan pe Jehofa ti dariji mi nipasẹ Kristi. Njẹ ki emi maa baa lọ lati maa wu u daradara. Njẹ ki oun sì maa baa lọ lati maa tọ́ awọn iṣisẹ mi sọna, gẹgẹ bi mo ti nwo o nigba gbogbo gẹgẹ bi “Ọlọrun mi, ninu ẹni ti emi yoo nigbẹkẹle.”—Saamu 91:2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Arakunrin Diehl ni ibẹrẹ iṣẹ igbesi-aye rẹ̀ ni Bẹtẹli

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́