Ọmọ Rẹ Wà Nínú EWU!
Ìwà tó burú jáì ni bíbá ọmọdé lò pọ̀ nínú ayé burúkú yìí. Ìwé ìròyìn Lear’s sọ pé: “O ń nípa lórí wa ju àrùn jẹjẹrẹ lọ, ó ń nípa lórí wa ju àrùn ọkàn tàbí àrùn AIDS lọ.” Torí náà, ìwé ìròyìn Jí! rí i pé òun gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn òǹkàwé òun mọ̀ nípa ewu yìí àti ohun tí a lè ṣe nípa rẹ̀.—Fi wé Ìsíkíẹ́lì3:17-21; Róòmù 13:11-13.
NÍ ÀWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, ṣe làwọn èèyàn ń figbe ta nípa bíbá àwọn ọmọdé lò pọ̀. Ṣùgbọ́n ohun táwọn agbéròyìn jáde ń sọ nípa ìwà burúkú yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ohun táwọn gbajúmọ̀ ń sọ ń mú káwọn kan máa ronú pé, ọ̀rọ̀ tó lòde báyìí nìyẹn, ó máa tó rọlẹ̀. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìwà burúkú yìí ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn àwa èèyàn.
Ìṣòro Ìgbàanì Kan
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, àwọn èèyàn mọ ìlú Sódómù àti Gòmórà fún ìwà ìbàjẹ́ tó lé kenkà. Ó ṣe kedere pé wọ́n kúndùn kí wọ́n máa bá àwọn ọmọdé lò pọ̀. Jẹ́nẹ́sísì 19:4 sọ pé àti “àgbà àti èwe” àwọn èèyàn kéèyàn tí ìṣekúṣe ti wọ̀ lẹ́wù gbìyànjú láti fipá bá àwọn ọkùnrin méjì tó wá sọ́dọ̀ Lọ́ọ̀tì lò pọ̀. Ẹ wò ó ná: Kí nìdí táwọn ọmọdé lásánlàsàn á fi máa ronú àti fipá bá àwọn ọkùnrin bíi tiwọn lò pọ̀? Ó ṣe kedere pé àti kékeré ni wọ́n ti la ojú wọn sí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣí lọ si ilẹ̀ Kénáánì. Ilẹ̀ yìí kún fún ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan tímọ́tímọ́, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, bíbá ẹranko lò pọ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó àti fífi àwọn ọmọdé rúbọ nínú ètò ìsìn débi pé Ọlọ́run ka gbogbo ìwà burúkú yìí léèwọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè. (Léfítíkù 18:6, 21-23; 19:29; Jeremáyà 32:35) Láìka àwọn ìkìlọ̀ yìí sí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ọlọ̀tẹ̀, títí kan díẹ̀ nínú àwọn alákòóso wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí àwọn ìwà má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ yìí.—Orin Dáfídì 106:35-38.
Bí ó ti wù kí ó rí, ilẹ̀ Gíríìkì àti Róòmù ìgbàanì burú jáì ju Ísírẹ́lì lọ. Wọ́n máa ń pa àwọn ọmọdé, kódà nílẹ̀ Gíríìkì, ó wọ́pọ̀ pé káwọn àgbà ọkùnrin máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin. Ilé aṣẹ́wó àwọn ọmọkùnrin pọ̀ gan-an ní gbogbo ìlú ńlá Gíríìkì ìgbàanì. Ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, iṣẹ́ aṣẹ́wó pẹ̀lú àwọn ọmọdé pọ̀ débi pé wọ́n gbé àkànṣe owó orí àti ọlidé kalẹ̀ torí òwò yẹn. Nínú àwọn gbọ̀ngàn eré ìdárayá, wọ́n máa ń fipá bá àwọn ọmọdébìnrin lò pọ̀, wọ́n sì máa fipá mú kí wọ́n bá ẹranko lò pọ̀. Àwọn ìwà ìkà tó rorò bẹ́ẹ̀ gbilẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ìgbàanì.
Báwo ló ṣe rí lóde òní? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn ṣì ń gba irú ìbálòpọ̀ tó ń jáni láyà bẹ́ẹ̀ láyè? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò fara mọ́ irú èrò yìí. Wọ́n mọ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘àkókò líle koko tí ó ṣòro láti bá lò’ là ń gbé yìí. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìgbádùn, ìfẹ́ tí wọ́n sì ní sí ìdílé wọn máa lọ sílẹ̀. Ó wá fi kún un pé: “Àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa gbilẹ̀ síwájú sí i.” (2 Tímótì 3:1-5, 13; Ìfihàn 12:7-12) Ṣé bí àwọn “ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn” ṣe ń bá àwọn ọmọdé lò pọ̀ ń pọ̀ sí i ni?
Ìṣòro Kánjúkánjú Kan
Wọ́n sábà máa ń bo ìwà bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe pa mọ́ débi pé wọ́n ti pè é ní ìwà ọ̀daràn tí a kì í fi bẹ́ẹ̀ fi sùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, irú àwọn ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ ti lọ sókè gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ní United States, ìwádìí kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Los Angeles Times sọ pé ìpín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) nínú àwọn obìnrin àti ìpín mẹ́rìndínlógún (16) nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin ni a ti bá lò pọ̀ lọ́mọdé. Bí àwọn ìsọfúnni yìí ti yani lẹ́nu tó, àwọn ìwádìí míì fi hàn pé bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ti lọ sókè gan-an ní United States.
Ní Malaysia, àwọn ìròyìn nípa bíbá ọmọdé lò pọ̀ ti di ìlọ́po mẹ́rin láwọn ọdún tó kọjá yìí. Nínú ìwádìí kan ní Thailand, nǹkan bí ìpín márùndínlọ́gọ́rin (75) nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin jẹ́wọ́ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó ọmọdé. Ní Germany, àwọn aláṣẹ fojú díwọ̀n pé àwọn ọmọdé tí ó tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) ní à ń bá lò pọ̀ lọ́dọọdún. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Cape Times ti South Africa ṣe sọ, iye ẹ̀sùn irú àwọn ìbálòpọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sókè pẹ̀lú ìpín 175 nínú ọgọ́rùn-ún ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. Ní Netherlands àti Kánádà, àwọn tó ń ṣèwádìí rí i pé nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo obìnrin ni a ti bá lò pọ̀ nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Ní Finland, ìpín méjìdínlógún (18) nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdébìnrin tí ó wà ní ipele ẹ̀kọ́ kẹsàn-án (ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí mẹ́rìndínlógún) àti ìpín méje nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdékùnrin sọ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí ó jù wọ́n lọ pẹ̀lú ó kéré tán ọdún márùn-ún.
Ní onírúurú orílẹ̀-èdè, a ti gbọ́ àwọn ìròyìn tó ń bani lọ́kàn jẹ́ nípa àwọn ẹgbẹ́ awo tó ń fipá bá àwọn ọmọdé lò pọ̀ tó sì ń dá wọn lóró. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í gba irú àwọn ọmọ tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí bẹ́ẹ̀ gbọ́, wọn kì í sì í fàánú hàn sí wọn.
Nítorí náà, bíbá àwọn ọmọdé lò pọ̀ kì í ṣe ohun tuntun, ó wọ́pọ̀ gan-an, ìṣòro ọ̀hún sì ti wà tipẹ́tipẹ́ débi pé kò síbi tí kò sí. Ipa búburú ló máa ń ní lórí àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ àwọn tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan àwọn ò sì lè wúlò mọ́. Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe máa ń fà fáwọn ọmọbìnrin sọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó máa ń tibẹ̀ yọ. Lára ẹ̀ ni pé àwọn ọmọ kan máa ń sá kúrò nílé, wọ́n máa ń mutí yó, wọ́n máa ń sorí kọ́, wọ́n máa ń fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn, wọ́n máa ń hùwà ọ̀daràn, wọ́n máa ń ṣèṣekúṣe, wọn kì í rí oorun sùn, wọ́n sì lè má lè kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa bíi tàwọn ẹgbẹ́ wọn. Àwọn nǹkan tó máa ń fà lọ́jọ́ iwájú ni pé wọ́n lè má lè tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú, wọ́n lè má gbádùn ìbálòpọ̀, wọ́n sì lè má fọkàn tán ọkùnrin kankan mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè lọ fẹ́ ẹni tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe, wọ́n lè máa bá obìnrin tàbí ọkùnrin bíi tiwọn lò pọ̀, àwọn fúnra wọn sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe.
Àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé lè má lè yẹra fún gbogbo àbájáde yìí, síbẹ̀ tí ẹnikẹ́ni bá hùwà àìtọ́, a ò lè dá a láre torí pé wọ́n bá òun náà lò pọ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé. Ti pé wọ́n bá ẹnì kan ṣèṣekúṣe lọ́mọdé ò ní kó di oníṣekúṣe tàbí ọ̀daràn, ìyẹn ò sì ní kí wọ́n má jẹ èrè ohun tí wọ́n bá pinnu láti ṣe ní ìgbésí ayé wọn. Ohun tí ìwà burúkú yìí ń yọrí sí léwu gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà pé, Báwo la ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe?