Ìmúrasílẹ̀—Kọ́kọ́rọ́ Àṣeyọrí
1 Ìmúrasílẹ̀ ṣáájú fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti borí ìlọ́tìkọ̀ èyíkéyìí tí ó lè ní nípa ṣíṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí o ti ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà, ìwọ yóò mọ ohun tí o fẹ́ bá onílé sọ. Ìwọ kì yóò ní láti dààmú nípa àwọn ìpèníjà tí o lè bá pàdé. Nígbà tí o bá padà délé láti ẹnu iṣẹ́ ìsìn, mímọ̀ pé o sapá dáradára nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò fún ọ níṣìírí. Bẹ́ẹ̀ ni, ìmúra kúnnákúnná ni kọ́kọ́rọ́ sí mímú òye ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa dán mọ́rán sí i.
2 Paulu tẹnu mọ́ ìmúrasílẹ̀ nípa rírọ̀ wá láti ‘fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ wa ní bàtà.’ (Efe. 6:15) Èyí kan mímúra èrò inú àti ọkàn-àyà wa sílẹ̀ ní àfikún sí níní ojú ìwòye onígbọkànlé àti ìṣarasíhùwà onímùúratán. Nígbà tí a bá múra sílẹ̀ láti ṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, a óò bù kún iṣẹ́ wa pẹ̀lú àwọn èso Ìjọba, tí yóò mú wa láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
3 Bí A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Iṣẹ́ Ìwàásù: A gbọ́dọ̀ yan ìgbékalẹ̀ tí ó rọrùn fún wa, bóyá láti inú àwọn tí a dábàá nínú ìwé Reasoning tàbí àwọn tí ó wà ní ojú ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ronú dáradára lórí ìwé mímọ́ tí o wéwèé láti lò, ní pípinnu ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí ìwọ yóò tẹnu mọ́ láti jẹ́ kí kókó ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. Kò pọn dandan láti kọ́ ìgbékalẹ̀ náà sórí; kàkà bẹ́ẹ̀, ó dára jù lọ láti lóye kókó náà, kí o sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ti ara rẹ, kí o sì sọ ọ́ ní ọ̀nà tí o rò pé yóò wọ olùgbọ́ rẹ lọ́kàn.
4 Ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀jáde tí o wéwèé láti fi lọni, kí o sì yan àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ tí ń fani lọ́kàn mọ́ra. Yan ohun tí o rò pé yóò fa àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ mọ́ra. Ronú nípa bí o ṣe lè yí ìgbékalẹ̀ rẹ padà lọ́dọ̀ onílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—ọkùnrin, obìnrin, àgbàlagbà, tàbí èwe.
5 O ha ti gbìyànjú ṣíṣe ìfidánrawò bí? Pe àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tàbí àwọn akéde mìíràn láti jíròrò àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó lè gbéṣẹ́, lẹ́yìn náà, kí ẹ sì sọ wọ́n jáde léraléra kí gbogbo yín lè ní wọn lọ́kàn dáradára. Ẹ gbìyànjú láti lo àwọn àyíká ipò tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an àti àwọn àtakò tí ẹ lè bá pàdé ní ìpínlẹ̀ yín. Irú ìfidánrawò bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu, kí ìdángájíá rẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ pọ̀ sí i, kí o sì túbọ̀ ní ìgboyà sí i.
6 Ní àfikún sí mímúra ìgbékalẹ̀ rẹ sílẹ̀ àti fífi wọ́n dánra wò, ó tún yẹ kí o bí ara rẹ léèrè pé, ‘Aṣọ tí mo wéwèé láti wọ̀ ha bójú mu fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí? Gbogbo ohun tí mo nílò ha wà nínú àpò ìwé mi, títí kan ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí mo wéwèé láti lò? Ó ha wà ní ipò tí ó dára bí? Mo ha ní ìwé Reasoning, ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé àkọsílẹ̀ ilé-dé-ilé, àti ìkọ̀wé bí?’ Ìwéwèé ṣáájú tí a fi ìrònújinlẹ̀ ṣe yóò jẹ́ kí ọjọ́ tí a lò nínú iṣẹ́ ìsìn túbọ̀ méso jáde.
7 Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti múra ara wa sílẹ̀, ó yẹ kí a gbàdúrà fún ẹ̀mí Jehofa láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí. (1 Joh. 5:14, 15) Fífún ìmúrasílẹ̀ ní àkíyèsí kínníkínní yóò mú kí á rí ayọ̀ tí ó túbọ̀ ga nínú iṣẹ́ wa, bí a tí ‘ń ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní kíkún.’—2 Tim. 4:5.