Orin 5
Kristi, Àwòfiṣàpẹẹrẹ Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Wo ìfẹ́ tí Jáà lò,
Wo bó ṣe bù kún wa,
Tó fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n fáráyé.
Kristi wá di oúnjẹ,
Tí gbogbo wa yóò jẹ,
Ká bàa lè rí ìyè àìnípẹ̀kun.
2. Kristi kọ́ wa wí pé
Ká máa gbàdúrà pé:
Kí oókọ ńlá Jèhófà di mímọ́.
Kí Ìjọba rẹ̀ dé
Kífẹ̀ẹ́ rẹ̀ di ṣíṣe.
Kó sì máa fún wa lóúnjẹ òòjọ́ wa.
3. Jésù fòótọ́ kọ́ wa,
Ó mú ìtùnú wá
Fáwọn àgùntàn tó ńtọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Ká fọjọ́ ayé wa
Fúnrúgbìn Ìjọba.
Aó sì rí ayọ̀ òun ìtẹ́lọ́rùn.
(Tún wo Mát. 6:9-11; Jòh. 3:16; 6:31-51; Éfé. 5:2.)