Ẹ̀KỌ́ 50
Rírí I Dájú Pé Ọ̀rọ̀ Wọni Lọ́kàn
LÁFIKÚN sí wíwàásù fáwọn èèyàn, o yẹ́ kí o tún sapá láti rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bíbélì sábà máa ń fi ìyàtọ̀ sáàárín ọkàn ẹni àti ìrísí ẹni. Ọkàn ìṣàpẹẹrẹ dúró fún irú ẹni téèyàn jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, ìyẹn bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni, gbogbo ohun tí ìrònú ẹni máa ń dá lé lórí, ìdí téèyàn fi ń ronú lórí nǹkan wọ̀nyẹn àti bí èrò wọ̀nyẹn ṣe ń nípa lórí ìṣe ẹni. Inú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ yìí ni a máa fúnrúgbìn òtítọ́ sí. (Mát. 13:19) Inú ọkàn yìí sì ni ìgbọràn sí Ọlọ́run ti gbọ́dọ̀ wá.—Òwe 3:1; Róòmù 6:17.
Kí ẹ̀kọ́ rẹ bàa lè wọni lọ́kàn jinlẹ̀, nǹkan mẹ́ta yìí ni kó o máa lépa: (1) Fi òye mọ irú èrò tó ti gba olùgbọ́ rẹ lọ́kàn tẹ́lẹ̀. (2) Túbọ̀ mú kí àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó o ní lágbára sí i. (3) Gba olùgbọ́ rẹ níyànjú pé kí ó ṣàyẹ̀wò ẹ̀mí tó ń sún un ṣe nǹkan kí o bàa lè máa ṣe ohun tó wu Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
Lílo Ìfòyemọ̀. Ìdí tí olúkúlùkù èèyàn kò fi tíì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ yàtọ̀ síra. Bí o bá ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè béèrè pé kó o mú ẹ̀mí ẹ̀tanú kúrò lọ́kàn akẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí o sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí yóò mú àwọn èrò òdì tó ti ní lọ́kàn kúrò, tàbí kí ó jẹ́ pé ẹ̀rí tó fìdí òótọ́ ọ̀rọ̀ múlẹ̀ lo máa sọ fún un. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ẹni yìí tiẹ̀ mọ̀ pé òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣàìní àwọn nǹkan kan nípa tẹ̀mí? Àwọn nǹkan wo ló ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀? Kí ni kò gbà gbọ́? Kí ló mú kí ó gba nǹkan wọ̀nyẹn gbọ́, kí ni kò sì jẹ́ kó gba àwọn ìyókù gbọ́? Ǹjẹ́ ó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lè borí ẹ̀mí tó lè dí i lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ tó wé mọ́ mímọ̀ tó mọ òtítọ́?’
Kì í sábà rọrùn láti mọ ìdí tí àwọn èèyàn fi nígbàgbọ́ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n gbà gbọ́. Òwe 20:5 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yóò fà á jáde.” Ìfòyemọ̀ ni pé kéèyàn lè lo òye láti fi mọ ohun kan tó fara sin. Ìyẹn sì gba pé kéèyàn lákìíyèsí, kó sì tún láájò ẹni.
Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ la fi ń báni sọ̀rọ̀. O lè rí i pé ìrísí ojú tàbí ohùn akẹ́kọ̀ọ́ kan yí padà nígbà tí ẹ kẹ́kọ̀ọ́ dórí àkòrí kan. Bí o bá jẹ́ òbí, kò sí àní-àní pé tí o bá rí i pé ìṣe ọmọ rẹ yí padà, wàá ti fura pé ó ti ń kọ́ ìkọ́kúkọ̀ọ́. Nítorí náà, má ṣe gbójú fo irú àwọn àmì tí o rí yẹn. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí irú ẹ̀mí tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀.
Tí o bá fara balẹ̀ bi èèyàn ní ìbéèrè, wàá lè mú kí onítọ̀hún tú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ síta. O lè béèrè pé: “Kí lèrò rẹ nípa . . . ?” “Kí ló jẹ́ kó o gbà pé . . . ?” “Kí lo máa ṣe bí . . . ?” Àmọ́ ṣá o, ṣọ́ra kó má di pé o kàn dédé ń da ìbéèrè bo àwọn èèyàn. O lè fọgbọ́n gbé ìbéèrè rẹ lọ́nà báyìí, “Jọ̀wọ́ ṣé mo lè bi ọ́ ní ìbéèrè kan?” Ó gba ẹ̀sọ̀ kéèyàn tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹlòmíràn, kò ṣeé fìkánjú ṣe rárá. Lọ́pọ̀ ìgbà, a ó ti dẹni tí ẹnì kan fọkàn tán dáadáa kónítọ̀hún tó lè máa sọ àṣírí ara rẹ̀ fún wa. Síbẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra o, kónítọ̀hún má wàá máa rò pé ńṣe là ń tojú bọ ọ̀rọ̀ òun.—1 Pét. 4:15.
Ìhùwàsí èèyàn nípa àwọn nǹkan tó gbọ́ tún gba òye pẹ̀lú. Rántí pé ohun tó o ní lọ́kàn ni pé o fẹ́ mọ irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́ kí o lè mọ irú ọ̀rọ̀ Bíbélì tó máa lè ta á jí. Bí ó bá kọ́kọ́ ṣe ọ́ bí i pé kó o sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ wọn kò tọ̀nà, ńṣe ni kó o tẹ ẹ̀mí yẹn rì ní kíá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sún wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn ló yẹ kí o máa fi òye wá. Ìyẹn láá jẹ́ kó o wá mọ bí o ṣe máa fèsì; èyí tí yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ gbà pé ọ̀rọ̀ òun yé ọ, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o bá sọ.—Òwe 16:23.
Kódà nígbà tó o bá ń bá àwùjọ ńlá sọ̀rọ̀ pàápàá, o ṣì lè fi ọ̀rọ̀ rẹ sún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ náà ṣe nǹkan kan. Bí o bá ń wojú àwùjọ bó ṣe yẹ, tí o kíyè sí ìrísí ojú wọn, tí o sì ń béèrè ìbéèrè mọ̀ọ́nú, tí yóò mú wọn ronú jinlẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti róye ohun tí àwọn olùgbọ́ rẹ lè máa rò nípa ohun tí ò ń sọ. Bí o bá ti mọ ohun tó lè jẹ́ ìṣarasíhùwà àwùjọ, gba tiwọn rò. Fi ohun tó jẹ́ ìṣarasíhùwà ìjọ náà lápapọ̀ sọ́kàn bí o ṣe ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.—Gál. 6:18.
Bí A Ṣe Ń Gbin Ẹ̀mí Rere Sọ́kàn Olùgbọ́. Bí o bá ti mọ ohun tẹ́nì kan gbà gbọ́ àti èyí tí kò gbà gbọ́ àti ìdí rẹ̀, wàá lè gbé àlàyé rẹ látorí ohun tó o mọ̀ yẹn. Ẹ̀yìn àjíǹde Jésù ló “ṣí Ìwé Mímọ́ payá” fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́” láti mú kí òye yé wọn dáadáa nípa ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. (Lúùkù 24:32) Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ pẹ̀lú ṣe gbìyànjú láti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rí ìsopọ̀ tó wà láàárín ohun tójú ẹ̀ ti rí, ohun tó ń wù ú láti rí, àti ohun tó ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ọ̀rọ̀ tó lè gún ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ ní kẹ́ṣẹ́, òun fúnra rẹ̀ ní láti gbà lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “ÒTÍTỌ́ gan-an nìyí!”
Tó o bá ń tẹnu mọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ olóore, onífẹ̀ẹ́, onínúure àti bí àwọn ọ̀nà rẹ ṣe tọ́ tó, ńṣe lò ń gbin ẹ̀mí láti fẹ́ràn Ọlọ́run sínú àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí o bá fara balẹ̀ mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ mọ àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run ń rí lára olúkúlùkù wọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n rí ìdí tí wọ́n á fi gbà gbọ́ pé àjọṣe tó dán mọ́ràn lè wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run. Èyí yóò ṣeé ṣe bí o bá ṣe àlàyé nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Sáàmù 139:1-3, Lúùkù 21:1-4 àti Jòhánù 6:44, tí o sì tún mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ mọ bí Jèhófà ṣe fi tìfẹ́tìfẹ́ sún mọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó. (Róòmù 8:38, 39) Ṣàlàyé pé kì í ṣe àwọn àṣìṣe wa nìkan ni Jèhófà ń rí, ó tún ń rí gbogbo bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa pẹ̀lú. Ó rí ìtara tí a fi ń ṣe ìsìn mímọ́ àti bí a ṣe fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ tó. (2 Kíró. 19:2, 3; Héb. 6:10) Àní ó rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ànímọ́ kálukú wa pátá, yóò sì jí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” dìde lọ́nà ìyanu. (Jòh. 5:28, 29; Lúùkù 12:6, 7) Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run dá ọmọ ènìyàn ní àwòrán àti ìrí òun fúnra rẹ̀, bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ wọ̀nyí, àwọn èèyàn sábà máa ń fi tọkàntọkàn kọbi ara sí ohun tí a bá sọ.—Jẹ́n. 1:27.
Ọ̀rọ̀ wa tún lè wọ ẹnì kan lọ́kàn bí a bá ti fi kọ́ra láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n pẹ̀lú. Ó sì bọ́gbọ́n mu pé bí Ọlọ́run bá lè fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwa fúnra wa, á jẹ́ pé yóò fi irú ọwọ́ kan náà mú àwọn èèyàn mìíràn pẹ̀lú láìka ìgbésí ayé wọn látilẹ̀wá, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí. (Ìṣe 10:34, 35) Bí òye ìyẹn bá ti lè yé ẹnì kan, yóò rí ìdí pàtàkì látinú Ìwé Mímọ́ tó fi yẹ kí òun mú ìkórìíra àti ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kúrò lọ́kàn pátápátá. Èyí á jẹ́ kó lè máa fẹ̀mí àlàáfíà kó àwọn èèyàn mọ́ra bó ṣe ń fi kọ́ra láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ẹ̀mí mìíràn tó tún yẹ kó o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti fi kọ́ra ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run. (Sm. 111:10; Ìṣí. 14:6, 7) Irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí ẹnì kan ṣàṣeyọrí ohun kan tí onítọ̀hún ì bá má lè dá ṣe rárá. Tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣe àti inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, ìyẹn lè mú kí o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dẹni tí yóò máa bẹ̀rù láti ṣe ohun tó lè bí Ọlọ́run nínú.—Sm. 66:5; Jer. 32:40.
Rí i dájú pé àwọn olùgbọ́ rẹ mọ̀ pé ìwà àwọn ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Jèhófà pẹ̀lú máa ń mọ bí nǹkan ṣe rí lára, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìhà tí a kọ sí ìtọ́sọ́nà rẹ̀, lè mú kí inú rẹ̀ bà jẹ́ tàbí kí inú rẹ̀ dùn. (Sm. 78:40-42) Jẹ́ kí àwọn èèyàn rí i pé ìwà tí wọ́n ń hù wà lára ohun tó máa fi hàn bóyá irọ́ ni Sátánì ń pa tàbí kì í ṣe irọ́ nígbà tó pe Ọlọ́run níjà.—Òwe 27:11.
Mú kí àwùjọ rẹ rí ọ̀nà tí ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wọn yóò gbà ṣe wọ́n láǹfààní. (Aísá. 48:17) Ọ̀nà kan tí o lè gbà ṣe èyí ni pé kí o sọ ìyọnu tó lè dé bá wọn nípa ti ara àti nípa ti ìmí ẹ̀dùn bí wọ́n bá kọ ọgbọ́n Ọlọ́run sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n. Ṣàlàyé bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe máa ń yà wá nípa sí Ọlọ́run, tí yóò mú ká dínà mọ́ àwọn ẹni ẹlẹ́ni tí wọ́n lè tipasẹ̀ wa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. (1 Tẹs. 4:6) Ran olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ láti fojú iyebíye wo àwọn ìbùkún tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Mú kí wọ́n túbọ̀ rí i pé fífi tí à ń fi àwọn ọ̀nà òdodo Jèhófà ṣe amọ̀nà wa ń kó wa yọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyọnu. Bí èèyàn bá ti dẹni tó gbà gbọ́ pé ọ̀nà Ọlọ́run ni ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu, kò ní fojúure wo ọ̀nàkọnà tó bá ti lòdì sí ti Ọlọ́run. (Sm. 119:104) Kò ní ka ṣíṣègbọràn sí Jèhófà sí ìnira, kàkà bẹ́ẹ̀ yóò kà á sí ọ̀nà láti gbà fi ìfọkànsìn ẹni hàn sí Jèhófà ní tààràtà.
Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Yẹ Ara Wọn Wò. Kí àwọn èèyàn tó lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, wọ́n ní láti dẹni tó ń kọbi ara sí ohun tó wà nínú ọkàn wọn. Ṣàlàyé fún wọn nípa bí Bíbélì yóò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe èyí.
Ran àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ láti rí i pé kì í ṣe àkọsílẹ̀ àwọn òfin, ìmọ̀ràn, ìtàn, àti àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ló wà nínú Bíbélì. Èrò Ọlọ́run wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Jákọ́bù 1:22-25 fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé dígí. Ọ̀rọ̀ Bíbélì máa ń tipasẹ̀ ìṣarasíhùwà wa sí ohun tó sọ àti ìṣarasíhùwà wa sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń mú ète rẹ̀ ṣẹ fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Nípa báyìí, ó ń jẹ́ ká mọ irú ojú tí Ọlọ́run, “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà,” fi ń wò wá. (Òwe 17:3) Gba àwọn olùgbọ́ rẹ níyànjú láti fi èyí sọ́kàn. Rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run mú kó wà lákọsílẹ̀ fún wa nínú Bíbélì àti nípa àwọn àyípadà tí wọn yóò ní láti ṣe nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe ohun tó wù ú. Kọ́ wọn láti wo Bíbélì kíkà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ti wọn yóò gbà mọ bí Jèhófà ṣe ń díwọ̀n “ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà” kí wọ́n lè máa gbọ́rọ̀ sí Ọlọ́run lẹ́nu nípa ṣíṣe àyípadà tó bá yẹ.—Héb. 4:12; Róòmù 15:4.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n ń kọ́; síbẹ̀ kí wọ́n máa bẹ̀rù ohun tí àwọn èèyàn yóò máa rò. Wọ́n tiẹ̀ lè máa bá àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara kan jìjàkadì. Tàbí kí wọ́n máa wá àwíjàre nípa fífi tí wọn kò fi gbogbo ọkàn sin Ọlọ́run, àti bí wọn kò ṣe jáwọ́ nínú ìṣe ayé. Sọ ewu tó wà nínú irú ìwà kò-ṣekú-kò-ṣẹyẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn. (1 Ọba 18:21) Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó yẹ ọkàn wọn wò kí ó sì yọ́ ọ mọ́.—Sm. 26:2; 139:23, 24.
Fi hàn wọn pé Jèhófà mọ gbogbo akitiyan tí wọ́n ń ṣe àti pé Bíbélì ṣàlàyé nípa irú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí. (Róòmù 7:22, 23) Kọ́ wọn láti mọ bí wọ́n ṣe lè máa ṣọ́ra kí ohun tí ọkàn aláìpé máa ń fẹ́ má bàa borí wọn.—Òwe 3:5, 6; 28:26; Jer. 17:9, 10.
Rọ olúkúlùkù wọn láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀mí tó ń sún un ṣe nǹkan. Kọ́ ọ pé kó máa bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ ṣe nǹkan yìí? Ǹjẹ́ kiní yìí á jẹ́ kí Jèhófà rí i pé mo mọrírì gbogbo ohun tó ti ṣe fún mi?’ Sapá láti túbọ̀ jẹ́ kó dá a lójú pé jíjẹ́ kí àárín ẹni àti Jèhófà dán mọ́rán ló ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn téèyàn lè ní láyé yìí.
Ran àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ láti mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa fi “gbogbo ọkàn-àyà” wọn sin Jèhófà. (Lúùkù 10:27) Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ní láti rí i pé gbogbo èrò wọn, gbogbo ìfẹ́ ọkàn wọn àti ẹ̀mí tó ń sún wọn ṣe nǹkan wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ láti mọ̀ pé yàtọ̀ sí ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ń ṣe wọ́n tún ní láti ṣàyẹ̀wò èrò wọn nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn àti irú ẹ̀mí tó ń sún wọn láti sìn ín. (Sm. 37:4) Bí ẹni tó ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá sì ti ń rí àwọn ibi tó ti yẹ kóun ṣe àtúnṣe, gbà á níyànjú láti máa gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Sm. 86:11.
Bí ẹni tó ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti lè ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni yóò máa sún un láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run, dípò kí ó jẹ́ pé rírọ̀ tí ò ń rọ̀ ọ́ láti ṣègbọràn ló ń jẹ́ kó ṣe é. Yóò máa wá fúnra rẹ̀ “bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfé. 5:10; Fílí. 2:12) Irú ìgbọràn àtọkànwá bẹ́ẹ̀ ló ń mú inú Jèhófà dùn.—Òwe 23:15.
Rántí pé Jèhófà lẹni tó ń díwọ̀n ọkàn èèyàn tó sì ń fa àwọn èèyàn wọnú àjọṣe pẹ̀lú ara rẹ̀. (Òwe 21:2; Jòh. 6:44) Tiwa ni pé ká ti bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀. (1 Kọ́r. 3:9) “Bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa” lọ̀ràn náà ṣe rí. (2 Kọ́r. 5:20; Ìṣe 16:14) Jèhófà kì í sọ pé àfi dandan gbọ̀n kéèyàn tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ṣùgbọ́n bí a ṣe ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé fún àwọn olùgbọ́ wa, Jèhófà lè mú kí wọ́n róye rẹ̀ pé ohun tí àwọn ń gbọ́ yẹn jẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè àwọn tàbí pé ó jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà àwọn. Máa fi èyí sọ́kàn nígbàkigbà tí o bá ń kọ́ni, kí o sì máa wá ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́ Jèhófà tọkàntọkàn.—1 Kíró. 29:18, 19; Éfé. 1:16-18.