ORÍ KẸTA
Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Aráyé?
1. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé?
OHUN àgbàyanu ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé. Ó dá Ádámù àti Éfà, ìyẹn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ sínú ọgbà kan tó rẹwà. Ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 9, 15; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 6.
2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun?
2 Ṣé o rò pé ayé yìí ṣì lè di Párádísè? Jèhófà sọ pé: “Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.” (Àìsáyà 46:9-11; 55:11) Ó dájú pé Jèhófà máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀, kò sí ohun tó lè dá a dúró. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ìdí tí òun fi dá ayé, pé òun “kò kàn dá a lásán.” (Àìsáyà 45:18) Ó fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbé ní gbogbo ayé. Irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run fẹ́ kó máa gbé ibẹ̀, ọdún mélòó sì ni wọ́n á fi gbé ibẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo [tàbí onígbọràn] ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:29; Ìfihàn 21:3, 4.
3. Torí pé àwọn èèyàn ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú, ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè?
3 Ṣùgbọ́n lónìí àwọn èèyàn ń ṣàìsàn wọ́n sì ń kú. Ní ibi púpọ̀, àwọn èèyàn ń jà, wọ́n sì ń para wọn. Ó dájú pé kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Kí wá ló fà á tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀? Bíbélì nìkan ló lè ṣàlàyé.
Ọ̀TÁ ỌLỌ́RUN
4, 5. (a) Ta ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì? (b) Kí ló lè sọ ẹnì kan tó jẹ́ olóòótọ́ di olè?
4 Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ní ọ̀tá kan, “ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” Sátánì lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. (Ìfihàn 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:1) Ó jẹ́ kó dà bíi pé ejò náà ló ń sọ̀rọ̀.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 7.
5 Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé Ọlọ́run ló dá Sátánì Èṣù? Rárá o! Áńgẹ́lì kan tó wà lọ́run tẹ́lẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ló yí ìwà rẹ̀ pa dà, ó sì sọ ara rẹ̀ di Èṣù. (Jóòbù 38:4, 7) Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Kí ló lè mú kí ẹnì kan tó jẹ́ olóòótọ́ di olè? Ohun kan ni pé olè kọ́ ni onítọ̀hún nígbà tí wọ́n bí i. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ ṣe máa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ó ń ronú ṣáá nípa nǹkan náà, èrò burúkú wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lọ́kàn rẹ̀. Tí àyè rẹ̀ bá yọ, ó lè jí nǹkan náà. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó di olè nìyẹn.—Ka Jémíìsì 1:13-15; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 8.
6. Báwo ni áńgẹ́lì kan ṣe di ọ̀tá Ọlọ́run?
6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí áńgẹ́lì yìí nìyẹn. Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà, ó ní kí wọ́n máa bímọ kí wọ́n sì “kún ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ó ṣeé ṣe kí áńgẹ́lì yẹn máa sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ì bá mà dáa gan-an o ká ní èmi ni gbogbo èèyàn ń jọ́sìn dípò Jèhófà!’ Torí pé kò yéé ronú nípa rẹ̀, ńṣe ni ọkàn rẹ̀ túbọ̀ ń fà sí ohun tó jẹ́ ti Jèhófà. Áńgẹ́lì yẹn fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun. Ìdí nìyẹn tó fi parọ́ fún Éfà, tó sì ṣì í lọ́nà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.) Bó ṣe di Sátánì Èṣù, ọ̀tá Ọlọ́run nìyẹn.
7. (a) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà fi kú? (b) Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú?
7 Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run bí wọ́n ṣe jẹ èso tó ní kí wọ́n má ṣe jẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6) Wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, nígbà tó yá wọ́n sì kú, bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà bí jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, torí náà àwọn náà kú. (Ka Róòmù 5:12.) Ká lè lóye ìdí táwọn ọmọ Ádámù àti Éfà náà fi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ká sọ pé o fẹ́ fi agolo kan ṣe búrẹ́dì, àmọ́ agolo náà ti tẹ̀ wọnú lápá ibì kan. Gbogbo búrẹ́dì tó o bá fi agolo yẹn ṣe ló máa tẹ̀ wọnú. Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó di ẹlẹ́ṣẹ̀. Torí pé a jẹ́ ọmọ Ádámù, gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ká sọ pé a ní àbùkù lára bíi tiẹ̀. Torí pé gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ la ṣe ń darúgbó tá a sì ń kú.—Róòmù 3:23; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 9.
8, 9. (a) Kí ni Sátánì fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbà gbọ́? (b) Kí nìdí tí Jèhófà kò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?
8 Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà bó ṣe mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbà pé òpùrọ́ ni Jèhófà àti pé kò fẹ́ ohun tó dáa fún wọn. Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé kò yẹ kí Ọlọ́run máa sọ ohun tó yẹ ká ṣe fún wa àti pé ó yẹ kí Ádámù àti Éfà lè pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Kí ni Jèhófà máa ṣe báyìí? Tó bá fẹ́, ó lè pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn kó sì fòpin sí ọ̀tẹ̀ náà. Àmọ́, ṣé ìyẹn á fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì? Rárá o.
9 Torí náà, Jèhófà kò pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí àwọn èèyàn máa ṣàkóso ara wọn. Èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé òpùrọ́ ni Sátánì àti pé Jèhófà mọ ohun tó dáa jù lọ fáwa èèyàn. A máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa èyí ní Orí 11. Àmọ́ kí lo rò nípa ìpinnu tí Ádámù àti Éfà ṣe yẹn? Ṣó yẹ kí wọ́n gba Sátánì gbọ́, kí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run? Jèhófà ló fún Ádámù àti Éfà ní gbogbo ohun tí wọ́n ní. Ẹni pípé ni wọ́n, ibi tó rẹwà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ wọn. Àmọ́ Sátánì kò tíì ṣe nǹkan kan tó dáa fún wọn rí. Ká sọ pé o wà níbẹ̀, kí lo máa ṣe?
10. Ìpinnu pàtàkì wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan ní láti ṣe?
10 Lónìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó jọ ìyẹn, ohun tá a bá sì yàn ló máa pinnu bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí. A lè yan Jèhófà pé kó jẹ́ Alákòóso wa, ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. A sì lè yan Sátánì pé kó jẹ́ alákòóso wa. (Sáàmù 73:28; ka Òwe 27:11.) Àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run láyé yìí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run kọ́ ni alákòóso ayé yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé òun kọ́ ni alákòóso ayé, ta wá ni?
TA NI ALÁKÒÓSO AYÉ?
Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọba ayé kì í ṣe ti Sátánì, ṣé ó lè sọ pé òun á fún Jésù?
11, 12. (a) Kí ni ohun tí Sátánì fi lọ Jésù jẹ́ ká mọ̀? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí?
11 Jésù mọ ẹni tó ń darí ayé yìí. Nígbà kan, Sátánì “fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.” Lẹ́yìn náà, Sátánì ṣèlérí fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mátíù 4:8, 9; Lúùkù 4:5, 6) Rò ó wò ná, ‘Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọba yẹn kì í ṣe ti Sátánì, ṣé ó lè sọ pé òun á fún Jésù?’ Rárá. Sátánì ló ni gbogbo ìjọba ayé.
12 O lè máa rò ó pé: ‘Báwo ni Sátánì ṣe lè jẹ́ alákòóso ayé yìí? Ṣèbí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ló dá ayé àti ọ̀run?’ (Ìfihàn 4:11) Òótọ́ kúkú ni, àmọ́ Jésù pe Sátánì ní “alákòóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Sátánì Èṣù ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Àpọ́sítélì Jòhánù tún sọ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.
BÁWO NI AYÉ SÁTÁNÌ YÌÍ ṢE MÁA PA RUN?
13. Kí nìdí tá a fi nílò ayé tuntun?
13 Ayé yìí túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i. Ojoojúmọ́ ni ogun, ìwà ìbàjẹ́, ìwà ẹ̀tàn àti ìwà ipá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé. Bó ṣe wù kí àwa èèyàn gbìyànjú tó, a ò lè yanjú àwọn ìṣòro yìí. Àmọ́, Ọlọ́run máa tó pa ayé búburú yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ó sì máa fi ayé tuntun òdodo rọ́pò rẹ̀.—Ìfihàn 16:14-16; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 10.
14. Ta ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba rẹ̀? Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù?
14 Jèhófà ti yan Jésù Kristi láti jẹ́ ọba Ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa ṣàkóso bí “Ọmọ aládé Àlàáfíà” àti pé ìjọba rẹ̀ kò ní lópin. (Àìsáyà 9:6,7) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà nípa ìjọba yìí nígbà tó sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:10) Ní Orí 8, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa rọ́pò àwọn ìjọba ayé. (Ka Dáníẹ́lì 2:44.) Lẹ́yìn náà, Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 11.
AYÉ TUNTUN TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÉ!
15. Kí ni “ayé tuntun”?
15 Bíbélì sọ pé: ‘À ń retí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun, níbi tí òdodo á máa gbé.’ (2 Pétérù 3:13; Àìsáyà 65:17) Nígbà míì tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ayé,” àwọn èèyàn tó ń gbé ayé ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Torí náà, “ayé tuntun” òdodo ń tọ́ka sí gbogbo èèyàn tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì rí ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀.
16. Ẹ̀bùn àgbàyanu wo ni Ọlọ́run máa fún àwọn tó bá ń gbé inú ayé tuntun rẹ̀, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ẹ̀bùn yìí gbà?
16 Jésù ṣèlérí pé àwọn tó máa gbé inú ayé tuntun Ọlọ́run máa rí “ìyè àìnípẹ̀kun” gbà. (Máàkù 10:30) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ẹ̀bùn yìí gbà? Jọ̀wọ́ ka Jòhánù 3:16 àti Jòhánù 17:3 kó o lè rí ìdáhùn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí ayé bá di Párádísè.
17, 18. Báwo la ṣe mọ̀ pé àlàáfíà máa wà ní gbogbo ayé àti pé kò ní sí ewu kankan?
17 Ìwà ibi, ogun, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kò ní sí mọ́. Kò ní sí àwọn èèyàn burúkú mọ́ láyé. (Sáàmù 37:10, 11) Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.” (Sáàmù 46:9; Àìsáyà 2:4) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i nìkan ló máa wà ní gbogbo ayé. Àlàáfíà máa wà títí láé.—Sáàmù 72:7.
18 Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó máa ń dáàbò bò wọ́n. (Léfítíkù 25:18, 19) Nínú Párádísè, a ò ní bẹ̀rù ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni. Títí ayé la ó máa gbé láìséwu!—Ka Àìsáyà 32:18; Míkà 4:4.
19. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé oúnjẹ máa pọ̀ gan-an nínú ayé tuntun?
19 Oúnjẹ máa pọ̀ gan-an. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀; ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.” (Sáàmù 72:16) Jèhófà “Ọlọ́run wa yóò bù kún wa,” àti pé “ilẹ̀ yóò mú èso jáde.”—Sáàmù 67:6.
20. Báwo la ṣe mọ̀ pé ayé máa di Párádísè?
20 Gbogbo ayé máa di Párádísè. Àwọn èèyàn máa ní ilé àti ọgbà tó rẹwà. (Ka Àìsáyà 65:21-24; Ìfihàn 11:18.) Gbogbo ayé máa lẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì ṣe rí tẹ́lẹ̀. Jèhófà máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “O ṣí ọwọ́ rẹ, o sì fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.”—Sáàmù 145:16.
21. Báwo la ṣe mọ̀ pé àlàáfíà máà wà láàárín àwọn èèyàn àti ẹranko?
21 Àlàáfíà máa wà láàárín àwọn èèyàn àti ẹranko. Àwọn ẹranko kò ní pa àwọn èèyàn lára mọ́. Àwọn ọmọdé kò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko mọ́, títí kan àwọn ẹranko tó léwu pàápàá.—Ka Àìsáyà 11:6-9; 65:25.
22. Kí ni Jésù máa ṣe fún àwọn tó ń ṣàìsàn?
22 Ẹnikẹ́ni ò ní ṣàìsàn mọ́. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn. (Mátíù 9:35: Máàkù 1:40-42; Jòhánù 5:5-9) Àmọ́ ní báyìí tí Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa wo gbogbo èèyàn sàn. Ẹni kankan ò ní sọ pé: “Ara mi ò yá.”—Àìsáyà 33:24; 35:5, 6.
23. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tó ti kú?
23 Àwọn òkú máa jíǹde. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa jí àìmọye èèyàn tó ti kú dìde. “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ka Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
24. Ṣé ó wù ẹ́ láti wà ní Párádísè?
24 Àwa la máa pinnu ohun tá a fẹ́ fi ayé wa ṣe. A lè yàn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ká sì máa sìn ín, a sì lè yàn láti ṣe ohun tó bá wù wá. Tá a bá yàn láti sin Jèhófà, ọjọ́ ọ̀la wa máa dáa gan-an. Nígbà tí ọkùnrin kan bẹ Jésù pé kó rántí òun lẹ́yìn tí òun bá kú, Jésù ṣèlérí fún un pé: “O máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jésù Kristi àti bó ṣe máa mú àwọn ìlérí àgbàyanu Ọlọ́run ṣẹ.