MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
O Lè Wàásù Kó O sì Máa Kọ́ni!
Mósè kọ́kọ́ rò pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún òun. (Ẹk 4:10, 13) Ṣé ìwọ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? Ṣé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣé o máa ń ronú pé bóyá ni wàá lè wàásù láti ilé dé ilé? Tàbí kò jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, kẹ́rù sì máa bà ẹ́ láti wàásù níléèwé. Ó sì ṣeé ṣe kẹ́rù máa bà ẹ́ láti wàásù lórí fóònù tàbí níbi térò pọ̀ sí. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (1Pe 4:11) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá gbé fún ẹ láṣeyọrí.—Ẹk 4:11, 12.
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ JẸ́ ONÍGBOYÀ . . . Ẹ̀YIN AKÉDE, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí lohun tó ṣòro fún Arábìnrin Aoyama láti ṣe?
Kí ló fún un ní okun àti ìgboyà tó nílò?—Jer 20:7-9
Àǹfààní wo ló rí nínú bó ṣe gbìyànjú láti ṣe púpọ̀ si?
Àwọn ìṣòro wo ni Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?