ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 12
  • Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Wíwo Ojú Àwùjọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 12

Ẹ̀KỌ́ 9

Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Jẹ́nẹ́sísì 15:5

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Lo àwọn ohun tó ṣeé fojú rí lati mú kí kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ ṣe kedere.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Lo àwọn ohun tó ṣeé fojú rí tó máa mú kí ohun tó o fẹ́ kọ́ni túbọ̀ yéni. Lo fọ́tò, àwòrán tá a fọwọ́ yà, máàpù, àtẹ ìsọfúnni tàbí àwọn ohun míì tó ṣeé fojú rí láti ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì, má ṣe lò ó fún àwọn ohun tí kò pọn dandan. Fi sọ́kàn pé kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó ṣeé fojú rí tó o lò nìkan ni àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ máa rántí, ó tún yẹ kí wọ́n rántí ẹ̀kọ́ pàtàkì tó o kọ́ wọn.

  • Rí i dájú pé àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí ohun tó o fẹ́ fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ náà.

    Àwọn àbá

    Kó tó di ìgbà tó o máa ṣe iṣẹ́ rẹ, rí i dájú pé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ lò ti wà ní sẹpẹ́.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Fi àwòrán kan han ẹnì kan, kó o sì ní kó sọ ohun tó rí. O tún lè bi í láwọn ìbéèrè míì tó bá yẹ, kó o lè pàfíyèsí rẹ̀ sí àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀. Tó bá jẹ́ pé fídíò lo fẹ́ lò, kọjú rẹ̀ sí ẹni náà kó lè rí i dáadáa. Kò pọn dandan kó o sọ̀rọ̀ tí fídíò náà bá ń lọ lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́