Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fi Ẹ̀dùn Ọkàn Hàn?
NÍNÚ ìwé náà, Children and Death, tí Dókítà Elisabeth Kübler-Ross kọ, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbàlagbà ni ara wọn ò balẹ̀ látàrí pé wọn ò tíì lè gbàgbé bí ìyà ṣe jẹ wọ́n tó nígbà ọmọdé. Nítorí náà, ó yẹ ká gba àwọn ọmọdé láyè láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn láìfún wọn lórúkọ bí ẹlẹ́kún, ojo tàbí ká máa gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹ̀yẹ́ náà pé ‘Ọmọ tó ti dàgbà kì í sunkún.’”
Èyí yàtọ̀ pátápátá sí àṣà wọn ní àwọn ilẹ̀ kan tó jẹ́ pé wọn kò gbọ́dọ̀ bo nǹkan burúkú mọ́ra.
Ìrírí Alábòójútó Ètò Ìsìnkú Kan
Ohun tí Robert Gallagher, tí ń ṣiṣẹ́ àbójútó ètò ìsìnkú ní ìlú New York sọ nígbà tí Jí! fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ yìí. A bi í léèrè bóyá ó ṣàkíyèsí ìyàtọ̀ kankan nínú bí àwọn ọmọ tí wọ́n bí sí Amẹ́ríkà àti àwọn tí wọ́n ṣí wá sí Amẹ́ríkà láti àwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà ṣe ń fi ìròbìnújẹ́ hàn.
“Bẹ́ẹ̀ ni, mo kíyè sí i. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí láàárín ọdún 1950 sí 1959, àwọn ìdílé àwọn ará Ítálì ayé ìgbà yẹn pọ̀ gan-an ládùúgbò wa. Wọ́n máa ń fi ìròbìnújẹ́ tí ó gogò hàn. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ wọn là ń bá ṣe ètò ìsìnkú. Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ banú jẹ́ púpọ̀ mọ́. Wọ́n kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ fi ìmọ̀lára wọn hàn.”
Àwọn ọmọ Hébérù, ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, máa ń fi ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn. Wo bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe bí Jékọ́bù ṣe ṣe nígbà tí wọ́n wí fún un pé ẹranko ẹhànnà kan ti pa Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀ jẹ: “Jékọ́bù sì gbọn aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ ìgbáròkó rẹ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ fún àkókò tó gùn. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gba ìtùnú. Ó wí pé: ‘Rárá o, èmi yóò máa bá a lọ láti ṣọ̀fọ̀ wọnú Ṣìọ́ọ̀lù nítorí ọmọkùnrin mi.’ Baba rẹ̀ sì sunkún nítorí rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:34, 35, The Jerusalem Bible; ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Bẹ́ẹ̀ ni, ojú kò ti Jékọ́bù láti sunkún nítorí ọmọ rẹ̀ tó sọnù.
Àṣà àti Ìṣesí Àwọn Èèyàn Yàtọ̀ Síra
Dájúdájú, àṣà yàtọ̀ síra. Fún àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní apá ibi púpọ̀ ní Nàìjíríà, wọ́n máa ń bímọ púpọ̀, tí ikú sì sábà máa ń pa àwọn ọmọ wọ̀nyí nítorí onírúurú àìsàn, ẹnì kan tó fi ìwé kíkọ ṣiṣẹ́ fún ogún ọdún ní Áfíríkà sọ pé, “wọ́n máa ń ṣọ̀fọ̀ gan-an bí ọmọ kan bá kú, pàápàá tó bá jẹ́ àkọ́bí wọn ni, ó sì máa ń le gan-an tó bá jẹ́ pé ọkùnrin ni ọmọ náà. Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé ní Nàìjíríà, ọ̀fọ̀ ṣíṣe kì í pẹ́ lọ títí, ṣùgbọ́n ó máa ń le gan-an. Wọn kì í ṣe é fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún.”
Ní àgbègbè Mẹditaréníà tàbí ní àwọn ilẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà, wọ́n tọ́ àwọn èèyàn dàgbà ní àyíká tó jẹ́ pé wọn kò rí ohun tó burú nínú fífi ìmọ̀lára hàn láìròtẹ́lẹ̀. Níbẹ̀, wọ́n máa ń fi ayọ̀ àti ìbànújẹ́ hàn ní gbangba. Wọn kì í fi ìkíni mọ sórí bíbọni lọ́wọ́; wọ́n tún máa ń gbáni mọ́ra. Bákan náà, wọ́n sábà máa ń ṣọ̀fọ̀ ní gbangba pẹ̀lú omijé àti ìdárò.
Òǹkọ̀wé Katherine Fair Donnelly sọ pé ohun tí bàbá tọ́mọ rẹ̀ kú “ń fara dà kì í ṣe ipa tí pípàdánù ọmọ ń ní lórí ìrònú òun ìhùwà rẹ̀ nìkan bí kò ṣe ìbẹ̀rù pípàdánù iyì rẹ̀ bí ọkùnrin tó bá banú jẹ́ ní gbangba.” Bó ti wù kó rí, ó ṣàlàyé pé, “pípàdánù ọmọ ẹni lágbára ju ìdènà òfin nípa bó ṣe yẹ ká fi ẹ̀dùn ọkàn hàn àti bí kò ṣe yẹ ká fi í hàn. Ńṣe ni fífi ìmọ̀lára ẹni hàn bó ṣe rí gan-an nípa dída omijé ìbànújẹ́ láti mú kí ọkàn ẹni fúyẹ́ dà bíi fífi abẹ la ojú egbò kí a lè yọ kòkòrò inú rẹ̀.”
Nítorí náà, tó bá di ọ̀ràn ti fífi ẹ̀dùn ọkàn hàn, ó wọ́pọ̀ ní àwọn ilẹ̀ kan ju àwọn mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ ka fífi ẹ̀dùn ọkàn hàn àti sísunkún sí àmì àìlera. Kódà, Jésù Kristi “da omijé” nítorí ikú Lásárù, ọ̀rẹ́ rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé òun yóò jí i dìde láìpẹ́.—Jòhánù 11:35.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Ojú kò ti Jékọ́bù láti sunkún nítorí ọmọ rẹ̀ tó sọnù