Pátímọ́sì—Erékùṣù Àpókálíìsì
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÍRÍÌSÌ
LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN, àwọn ará Pátímọ́sì máa ń rí iná kan tó ń tàn, tó sì ń ṣẹ́jú wìrìwìrì ní ìsọdá Òkun Aegean lórí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá kan ní erékùṣù kan tó wà ní tòsí wọn tó ń jẹ́ Sámósì. Àwọn kan sọ pé iná mànàmáná tó wà lójú kan ni iná àràmàǹdà yìí, ṣùgbọ́n àwọn onísìn tí ń gbé Pátímọ́sì jiyàn pé kò rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn aládùúgbò wọn pé àwọn ti rí àmì mìíràn láti ọ̀dọ̀ ẹni tó lókìkí jù lọ tó ń gbé erékùṣù náà tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n lé lọ sí erékùṣù Gíríìsì kékeré yìí ní etíkun Éṣíà Kékeré ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún sẹ́yìn.
Ó lè jẹ́ Dòmítíà, Olú Ọba Róòmù ló dájọ́ ọkùnrin olókìkí yẹn, pé kó kúrò nílùú, kó lọ máa gbé Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí nípa Jésù.” Ó gbọ́ ohùn Ọlọ́run níbẹ̀, “bíi ìró kàkàkí,” tó sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà . . . Kọ ohun tí ìwọ rí sínú àkájọ ìwé.”—Ìṣípayá 1:8-11.
Àkájọ, tàbí ìwé yẹn, ni apá tó kẹ́yìn nínú ìwé tó tíì tà jù lọ rí. Àwọn kan ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìwé táa kọ táwọn èèyàn kò lóye—ìwé inú Bíbélì tí wọ́n pè ní Ìṣípayá, tàbí Àpókálíìsì la ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì. Jòhánù, tí í ṣe àpọ́sítélì Jésù, ló kọ ìwé náà. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìran tí Jòhánù rí nípa àjálù tí yóò dé kẹ́yìn sórí ayé búburú yìí ti gba àfiyèsí àwọn tó ń ka ìwé náà.a
Pátímọ́sì Lónìí
Ọ̀pọ̀ àlejò ni yóò gbà pé Pátímọ́sì—tó wà ní òkè pátápátá ní ìhà àríwá Erékùṣù Dodecanese—ni yóò jẹ́ ká lóye ìwé yìí. Àwọn òkè ayọnáyèéfín gíga-gíga àti ìsokọ́ra àwọn ọ̀gbun tó ṣú dùdù wà káàkiri àwọn òkè tí koríko hù sí náà àti àwọn ilẹ̀ eléwéko tútù tí òdòdó hù sí tí oòrùn tó ń mú ganrínganrín ní Aegean ń pa.
Láti mọ bí Pátímọ́sì ṣe rí lónìí, mo wọkọ̀ láti Piraievs, olórí èbúté wọn ní Gíríìsì. Lẹ́yìn agogo méjìlá òru, bí ọkọ̀ ojú omi náà ṣe dé èbúté tó jọ itọ́ òkun ní Skála—tó jẹ́ èbúté àti ìlú tó tóbi jù lọ ní Pátímọ́sì—kùrukùru wọ́ kúrò, òṣùpá tó mọ́lẹ̀ rekete sì jẹ́ kí á rí erékùṣù náà kedere.
Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí mo ti ń sófèrè kọfí kíkorò ti ilẹ̀ Gíríìsì ni mo ń múra láti lọ wo àwọn nǹkan tó wà káàkiri erékùṣù náà. Ohun tí mo rí lówùúrọ̀ kùtùkùtù ni àwọn ìyá àgbà, tí wọ́n wọ aṣọ dúdú látòkè délẹ̀, tí wọ́n ń gbìyànjú láti lé àwọn ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ mú. Apẹja kan tó ní irùngbọ̀n yẹ́úkẹ́, tó jókòó nítòsí ń la ẹja octopus tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mú nínú omi mọ́ orí pèpéle tí wọ́n ń já èrò ọkọ̀ sí kó bàa lè rọ̀, ìyẹn ló fẹ́ fi ṣe oúnjẹ ọ̀sán rẹ̀.
Dípò kí n wọ ọkọ̀, mo pinnu láti lọ sí ẹ̀bá òkè tó wà lẹ́yìn Skála kí n lè rí gbogbo erékùṣù náà. Àrímáleèlọ gbáà ni ohun tí mo rí. Erékùṣù náà lọ súà bí àwòrán ilẹ̀ ńlá kan tí wọ́n kùn tí omi òkun ń gbá kiri. Pátímọ́sì dà bí erékùṣù mẹ́ta tó para pọ̀ di ọ̀kan—àwọn ilẹ̀ tó yọrí jáde láàárín omi tí àwọn ilẹ̀ kéékèèké so kọ́ra. Ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ kéékèèké yìí wà ní Skála. Òmíràn wà ní ibi tí wọ́n pè ní Diakofti, orúkọ tó yẹ ẹ́, tó túmọ̀ sí “Àdádó,” ó wà nítòsí ìkángun ìhà gúúsù erékùṣù náà tí kò lólùgbé. Pátímọ́sì kò gùn tó kìlómítà mẹ́tàlá, kò sì jìnnà rárá láti ré kọjá láti ẹ̀gbẹ́ kan sí ẹ̀gbẹ́ kejì.
Nígbà Tí Nǹkan Le Koko
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láti ìgbà tí àwọn tó kọ́kọ́ wá tẹ Pátímọ́sì dó ti débẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn láti Éṣíà Kékeré ni wọ́n ti ń kà á sí ibi mímọ́. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ gbé ibẹ̀ yan ibi tó ga ṣìkejì ní erékùṣù náà fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì sí, ìyẹn abo ọlọ́run ti iṣẹ́ ọdẹ.
Ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a ronú pé wọ́n lé àpọ́sítélì Jòhánù lọ sígbèkùn ní Pátímọ́sì, abẹ́ àkóso ìjọba Róòmù ni Pátímọ́sì wà. Ní ọ̀rúndún kẹrin, erékùṣù náà di apá kan Ilẹ̀ Ọba Byzantine “tí wọ́n sọ di ti Kristẹni.” Lẹ́yìn náà, láàárín ọ̀rúndún keje sí ìkẹwàá, àwọn onísìn Ìsìláàmù ló ń ṣàkóso rẹ̀.
Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n pa Pátímọ́sì tì, ó sì di ahoro. Nígbà tó sì di apá ìparí ọ̀rúndún kọkànlá, ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó jẹ́ ọmọ ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé olódi ti àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Jòhánù “Mímọ́” sí ibi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì kèfèrí sí tẹ́lẹ̀ ní Átẹ́mísì. Àwọn olùtẹ̀dó wá bẹ̀rẹ̀ sí padà síbẹ̀ díẹ̀díẹ̀, wọ́n sì ń kọ́ àwọn ilé onígun mẹ́rin tí ó tò bẹẹrẹ tí wọ́n kùn lọ́dà funfun sí Hora, ìlú tó rí págunpàgun lẹ́yìn odi ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà.
Erékùṣù náà gbádùn ògo fúngbà díẹ̀ lápá ìparí ọ̀rúndún tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1800, nígbà tí àwọn kan lára àwọn aráàlú náà ní ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun ìṣòwò tó lọ́rọ̀ jù lọ lórí òkun Mẹditaréníà. Lọ́nà tí kò ṣe tààrà, ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun yẹn ló ṣokùnfà rírọ́ táwọn èèyàn rọ́ wá síbẹ̀ lákọ̀tun. Ní àárín ọdún 1970 sí 1979, mélòó kan lára àwọn ọlọ́rọ̀ ayé ṣàwárí ẹwà àti dúkìá ilé àti ilẹ̀ tí kò wọ́n, tó wà ní erékùṣù tí wọ́n ti gbàgbé látilẹ̀wá náà. Wọ́n ṣàtúnṣe púpọ̀ lára àwọn ògbólógbòó ilé ńláńlá táwọn oníṣòwò ojú òkun kọ́, ìwọ̀nyí àti àwọn ohun èlò tuntun tó wà ní èbúté òkun ló jẹ́ kí Pátímọ́sì tún di ibi táwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ń fẹ́ láti lọ.
Títí di báyìí, Pátímọ́sì ti bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro àpọ̀jù àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, èyí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ba àwọn erékùṣù Gíríìkì mìíràn jẹ́. Lájorí ohun tó jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pápákọ̀ òfuurufú tí kò ní àti agídí táwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ṣe pé ibẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ àgbègbè mímọ́.
Dída Ìtàn Pọ̀ Mọ́ Àṣà
Agbóúnjẹ tó ta oúnjẹ fún mi ràn mí lọ́wọ́ láti ṣètò ìwádìí tí mo fẹ́ ṣe nípa erékùṣù náà, ó darí mi sí ògbólógbòó ọ̀nà olókùúta tó ti wà fún irínwó ọdún lẹ́yìn ìlú Skála, ọ̀nà náà la àárín igbó igi ahóyaya tó ń ta sánsán kọjá lọ sí ibi tí a ronú pé ó jẹ́ hòrò tí Jòhánù gbé, òun náà ló sì lọ dé ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Jòhánù “Mímọ́.” Ní àgbègbè ẹ̀yìn ìlú náà, mo kọjá níbi ògiri olókùúta kan tí wọ́n fi ọ̀dà pupa kọ ọ̀rọ̀ tí ń dẹ́rù ba èèyàn sára rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà kà pé: “Ohi sto 666” (Ṣọ́ra fún nọ́ńbà ẹ́ẹ́fà, ẹ́ẹ́fà àti ẹ́ẹ́fà), ọ̀kan lára àwọn àmì inú Ìṣípayá, táwọn èèyàn kò lóye.
Wọ́n kọ́ Ilé Àwọn Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé ti Àpókálíìsì, tí ilé ìjọsìn kékeré ti Anne “Mímọ́” wà, ní ọdún 1090 láti fi dí ẹnu ọ̀nà hòrò tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sọ pé ibẹ̀ ni a ti fi àwọn ìran tí Jòhánù rí hàn án. Mo rí obìnrin kan tó kúnlẹ̀ ní òun nìkan, tó sì so tama (ọrẹ) kan mọ́ ère Jòhánù “Mímọ́.” Obìnrin yìí tó jẹ́ ọmọ ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, tó gbà gbọ́ pé ère náà lè ṣe iṣẹ́ ìyanu, gbé tamata fún un, ìyẹn àwọn ère onírin tí wọ́n fi ṣe èèyàn, ẹ̀yà ara, ilé, kódà tí wọ́n fi ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ ojú omi. Mo rántí pé mo ti rí irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe ní tòsí Kọ́ríńtì nínú tẹ́ńpìlì ọlọ́run awonisàn ti àwọn ará Gíríìkì ìgbàanì náà, Asclepius. Ṣé wọ́n kàn ṣe kòńgẹ́ ara wọn lásán ni?
Àwọn Ohun Ìrántí ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ
Bí mo ṣe wọ àgbàlá ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Jòhánù “Mímọ́” ni mo rí ẹni bí ọ̀rẹ́ kan tó jáde wá láti inú àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ kọ́lọkọ̀lọ tó ṣókùnkùn. Inú “Papa Nikos” (Bàbá Nick) dùn gan-an láti fi àwọn ìṣúra ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà han èmi àti àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ mìíràn. Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà tó ni apá púpọ̀ lára Pátímọ́sì, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lọ́rọ̀ jù lọ tó sì ní ipa lórí àwọn èèyàn jù lọ ní Gíríìsì.
A la àárín ilé ìjọsìn kan kọjá, ibẹ̀ tutù, èéfín àbẹ́là sì ti sọ ọ́ di dúdú, ibẹ̀ ni wọ́n sìnkú ẹni tó dá ilé ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà sílẹ̀ sí, lẹ́yìn náà, a la àárín Ilé Ìjọsìn Wúńdíá náà kọjá, èyí tí wọ́n fi òkúta tí wọ́n kó láti tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì kọ́ apá kan rẹ̀. Níbi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, a rí wúrà àti àwọn ohun iyebíye rẹpẹtẹ tí àwọn olú ọba fi tọrẹ; ìwé àdéhùn àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti ọ̀rúndún kọkànlá tí wọ́n ṣe fún erékùṣù náà, tí Olú Ọba ìlú Byzantine náà, Alexius Kìíní, Comnenus, fọwọ́ sí; àti àjákù ìwé Ìhìn Rere Máàkù tí wọ́n fi fàdákà kọ sórí awọ dípò kí wọ́n fi tàdáwà kọ ọ́, èyí tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kẹfà, ó sì lẹ́wà. Ní àfikún sí àjákù yìí, ọ̀pọ̀ Bíbélì àti àwọn ìwé àfọwọ́kọ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ni wọ́n kó jọ sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà.
Àwọn Ohun Tó Wà Ní Erékùṣù Náà
Erékùṣù náà ní ẹwà àdánidá. Ní kìlómítà bíi mélòó kan sí ìhà gúúsù Skála, etíkun mímọ́ tónítóní kan wà níbi ìyawọlẹ̀ omi òkun kan tó láàbò. Etíkun náà tẹ́ pẹrẹsẹ, kò sì sí ohun pàtàkì níbẹ̀ àyàfi Kalikatsou, tó túmọ̀ sí “Ẹyẹ Àgò,” òkìtì àpáta bìrìkìtì kan sì tún wà láàárín etíkun náà tó ga bí ilé alájà márùn-ún tàbí mẹ́fà, wọ́n sì ṣe àwọn hòrò tó dà bíi wàràkàṣì dídì tó tóbi gan-an yí i ká.
Téèyàn bá fẹ́ gbádùn Pátímọ́sì dáadáa, kó sáà kàn rìn kiri ìlú náà. O lè fẹ́ láti jókòó láàárín àwọn àwókù ilé àtijọ́ tí wọn kò tíì walẹ̀ wọn tí wọ́n wà ní apá òkè ìlú Kastelli, nínú oòrùn tó ń jóni, kí o sì tẹ́tí sí àwọn agogo tí ń dún láti ọ̀nà jíjìn réré wá àti fèrè híhan gooro tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń fun. Tàbí láwọn ọ̀sán kan nígbà tí ìlú Aegean bá ń sẹ ìrì rẹ̀ tó jọ àwọ̀n wínníwínní lójú òfuurufú, o lè fẹ́ láti jókòó kí o sì máa wo àwọn etíkun bí àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ń gbéra láàárín ìrì tó ń sẹ̀ ṣe dà bíi pé ńṣe ni wọ́n ń pọ́nkè lọ sójú òfuurufú.
Ní ọjọ́ tí mo lò kẹ́yìn níbẹ̀, oòrùn aláwọ̀ pupa rírẹwà tó ń wọ̀ lọ tàn yòò sórí ìlú náà nísàlẹ̀. Ní gbangba níbi ìyawọlẹ̀ omi òkun, àwọn tí ń tanná pẹja ń múra àwọn ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ wọn kéékèèké sílẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń pè ní gri-gri, ọmọ pẹ́pẹ́yẹ, nítorí pé ńṣe ni wọ́n máa ń tò tẹ̀ lé ọkọ̀ òkun ńlá kan lẹ́yìn.
Ó jọ pé erékùṣù náà ń tàn yòò látòkè délẹ̀. Ẹ̀fúùfù tútù àti ìgbì omi tó ga ń gbé àwọn ọkọ̀ gri-gri náà lọ́nà tó léwu gan-an. Ní wákàtí mélòó kan lẹ́yìn náà, mo tún rí àwọn ọkọ̀ náà, láti orí ìtẹ́ apákó ọkọ̀ tó ń padà sí Piraievs bó ṣe yára kọjá lára wọn níbi tí wọ́n ti ń pẹja ní nǹkan bíi kìlómítà mélòó kan sí etídò. Àwọn ọkùnrin náà ti tan àwọn iná wọn mímọ́lẹ̀ rokoṣo tó máa ń fa àwọn ẹja mọ́ra. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àwòrán Jòhánù tí wọ́n lé lọ sí ìgbèkùn tó ń kọ àwọn ìran tó rí sílẹ̀ ní Pátímọ́sì wà lọ́kàn mi títí tí n kò fi rí àwọn àti erékùṣù tó wá lẹ́yìn wọn mọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Jòhánù “Mímọ́”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
© Miranda 2000