ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 1/8 ojú ìwé 26-28
  • Ewé àti Egbò Ṣé O Lè Lò Ó fún Ìwòsàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ewé àti Egbò Ṣé O Lè Lò Ó fún Ìwòsàn?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwúlò Egbòogi
  • Bí A Ṣe Lè Lo Egbòogi
  • Àwọn Ohun Kan Tó Yẹ Láti Ṣọ́ra Fún
  • Lílo Oògùn Ìbílẹ̀ Pọ̀ Mọ́ Oògùn Òyìnbó Léwu
  • Àbẹ̀wò sí Ilé Elégbòogi Kan ní China
    Jí!—2000
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ìlànà Ìtọ́jú Àfirọ́pò
    Jí!—2000
  • Àwọn Àǹfààní àti Ewu—Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 1/8 ojú ìwé 26-28

Ewé àti Egbò Ṣé O Lè Lò Ó fún Ìwòsàn?

LÁTI ìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn èèyàn ti ń lo ewé àti egbò láti fi wo àìsàn. Nínú ìwé kan nípa ìṣègùn tó ń jẹ́ Ebers Papyrus, èyí tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Íjíbítì ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣáájú Sànmánì Tiwa, wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ egbòogi tó wà fún ìtọ́jú onírúurú àmódi. Àmọ́ o, lọ́pọ̀ ìgbà, ẹnu ni wọ́n fi máa ń ṣàlàyé ìlò egbòogi láti ìran kan dé òmíràn.

Ní apá ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ó dà bíi pé ohun tó jẹ́ kí ìtọ́jú nípasẹ̀ egbòogi gbajúmọ̀ ni ìwé De Materia Medica, èyí tí Dioscorides oníṣègùn ará Gíríìkì kan ní ọ̀rúndún kìíní kọ. Ìwé yìí ló wá di olórí ìwé ìṣègùn ní gbogbo ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún tó tẹ̀ lé e. Ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń lo oògùn ìbílẹ̀. Nílẹ̀ Jámánì, àwọn ètò tí ìjọba dá sílẹ̀ nítorí ọ̀ràn ìlera pàápàá lè fowó ṣètìlẹyìn fún àwọn oògùn tí wọ́n fi ewé àti egbò ṣe.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń sọ pé àwọn egbòogi tí àwọn baba ńlá wa ti ń lò látayébáyé dára ju àwọn oògùn ìgbàlódé lọ, síbẹ̀ àwọn náà ṣì léwu. Èyí ló gbé àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí dìde: Àwọn nǹkan wo ló yẹ kéèyàn ṣọ́ra fún, àwọn ìdámọ̀ràn wo ló sì yẹ kéèyàn gbé yẹ̀ wò nípa lílo ewé àti egbò fún ìwòsàn? Àti pé, ǹjẹ́ ipò èyíkéyìí wà tó jẹ́ pé irú ìtọ́jú kan lè dára ju òmíràn lọ?a

Ìwúlò Egbòogi

Àwọn olùṣèwádìí ti sọ pé egbòogi ní ọ̀pọ̀ èròjà nínú tó ṣeé fi wo àìsàn. Wọ́n ní àwọn egbòogi kan lè ṣèrànwọ́ láti gbógun ti àwọn kòkòrò tó ń fi àrùn ṣeni. Wọ́n ní àwọn mìíràn lè jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú dáadáa, kí ara tuni pẹ̀sẹ̀, kí inú tó kún rọlẹ̀ tàbí kí àwọn ohun kan nínú ara máa ṣiṣẹ́ dáadáa.

Egbòogi lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ, ó sì tún lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oògùn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn irúgbìn kan tó ń jẹ́ kéèyàn tọ̀ dáadáa, irú bíi parsley tó ń móúnjẹ ta sánsán, tún ní ọ̀pọ̀ èròjà potassium tó dára fún ìlera nínú. Èròjà potassium tó wà nínú àwọn irúgbìn wọ̀nyí ló máa ń rọ́pò èyí tó bá kúrò nínú ara nígbà téèyàn bá tọ̀. Lọ́nà kan náà, irúgbìn valerian, tí wọ́n ti máa ń lò látọjọ́ pípẹ́ gẹ́gẹ́ bí oògùn amárarọni, ní ọ̀pọ̀ èròjà calcium nínú. Èròjà calcium tó wà nínú egbòogi yìí lè jẹ́ kí iṣẹ́ irúgbìn náà láti mú kí àwọn iṣan ara dẹ̀ gbéṣẹ́ sí i.

Bí A Ṣe Lè Lo Egbòogi

Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà lo ewé àti egbò, irú bíi mímu ún gẹ́gẹ́ bíi tíì, sísè é ní àgbo, rírẹ ẹ́ sí ọtí àti gígún un, ká sì máa fi wọ́ ibi tó ń dunni. Téèyàn bá fẹ́ mu tíì eléwé, á da omi gbígbóná lé e lórí. Àmọ́, àwọn kan tí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀ràn ìlera ti kìlọ̀ pé kò yẹ ká máa se ewé tíì. Ní ti àgbo, a máa ń se àwọn nǹkan bí ìtàkùn àti èèpo igi nínú omi kí àwọn èròjà inú rẹ̀ tó ṣeé fi wo àìsàn lè jáde.

Àwọn àgbo ọlọ́tí ńkọ́? Ìwé kan sọ pé àwọn wọ̀nyí “jẹ́ egbòogi tí a ti rẹ sínú ọtí ògógóró tàbí irú ọtí mìíràn.” Àwọn oògùn ìwọ́ra tí a ti gún náà tún wà níbẹ̀, èyí tí a lè ṣe ní onírúurú ọ̀nà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe la máa ń fi wọ́ apá ibi tó ń dunni lára.

Láìdàbí ọ̀pọ̀ èròjà fítámì tàbí àwọn oògùn mìíràn, ọ̀pọ̀ jù lọ egbòogi làwọn èèyàn kà sí oúnjẹ, wọ́n sì máa ń jẹ wọ́n bẹ́ẹ̀. Wọ́n tún lè lọ̀ wọ́n di ìyẹ̀fun, kí wọ́n wá ṣe wọ́n bíi káńsùlù, èyí tó máa jẹ́ kó rọrùn láti lò kó má sì korò lẹ́nu. Bó o bá pinnu láti lo ewé àti egbò fún ìwòsàn, ó bọ́gbọ́n mu láti gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó mọ̀ nípa rẹ̀.

Látọjọ́ pípẹ́ ni wọ́n ti máa ń lo egbòogi fún àwọn ohun bí otútù, àìdà oúnjẹ, kí inú kún, àìróorunsùn, àti kí èébì máa gbéni. Àmọ́ ṣá o, wọ́n tún máa ń lo egbòogi fún àwọn àìsàn tó le gan-an—kì í ṣe fún ìtọ́jú nìkan àmọ́ fún dídènà àìsàn pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Jámánì àti Austria, saw palmetto ni egbòogi tí wọ́n kọ́kọ́ máa ń lò láti fi tọ́jú àìsàn tó máa ń mú kí ẹ̀yà ara kan tó wà níbi àpòòtọ̀ wúlé. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àìsàn yìí máa ń ṣe nǹkan bí ìpín àádọ́ta sí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tó ń gbébẹ̀. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí oníṣègùn kan ṣàyẹ̀wò ohun tó fa ìwúlé náà láti rí i dájú pé àìsàn yìí kì í ṣe èyí tó máa gba ìtọ́jú tó lágbára gan-an, irú bí àrùn jẹjẹrẹ.

Àwọn Ohun Kan Tó Yẹ Láti Ṣọ́ra Fún

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa sọ pé egbòogi kan dára gan-an, èèyàn ṣì ní láti ṣọ́ra. Má ṣe fojú kéré ọ̀ràn lílo egbòogi kìkì nítorí pé wọ́n sọ pé oògùn kan jẹ́ “àdánidá.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan lórí ìlò egbòogi sọ pé: “Ohun kan tó kù-díẹ̀-káàtó nínú ọ̀ràn egbòogi ni pé àwọn kan wà tí wọ́n léwu gidigidi. [Ó ṣeni láàánú pé] àwọn èèyàn kan kì í ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó lè jẹ́ àbájáde lílo egbòogi, yálà ó léwu tàbí kò léwu.” Àwọn èròjà pàtàkì tó wà nínú egbòogi lè mú kí ìlùkìkì ọkàn rẹ, ìwọ̀n ìfúnpá rẹ àti ìwọ̀n èròjà gúlúkóòsì inú ẹ̀jẹ̀ rẹ lọ sókè tàbí kó wálẹ̀. Látàrí èyí, àwọn tó ní àìsàn ọkàn, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí àwọn àìsàn tó ń nípa lórí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀, irú bí àtọ̀gbẹ, ní láti ṣọ́ra gidigidi.

Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ́ yọ látinú lílo egbòogi kì í ju àwọn tó jẹ mọ́ èèwọ̀ ara lọ. Lára ìwọ̀nyí ni ẹ̀fọ́rí, òòyì, kí èébì máa gbéni tàbí kí àwọn nǹkan sú síni lára. Bákan náà, wọ́n sọ pé téèyàn bá lo egbòogi, àwọn àìlera tó fara jọ otútù tàbí àwọn mìíràn lè máa ṣeni, èyí táá mú kó dá bíi pé àìsàn náà burú sí i. Ó lè dà bíi pé ipò ẹni tó ń lo egbòogi náà ń burú sí i ṣáájú kó tó wá sàn. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó ń fa èyí ni àwọn èròjà onímájèlé tó ń kúrò nínú ara nígbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lo egbòogi.

Bí àwọn èèyàn ṣe ń kú látìgbàdégbà nítorí lílo egbòogi fi hàn pé ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra, kéèyàn sì gba ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Bí àpẹẹrẹ, irúgbìn ephedra, tí àwọn èèyàn sábà máa ń lò láti dín sísanra kù, tún lè mú kí ìwọ̀n ìfúnpá ẹni lọ sókè. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún èèyàn tó kú ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ pé àwọn egbòogi tí wọ́n mú jáde látinú irúgbìn ephedra ló fa ikú wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé onímọ̀ nípa àrùn inú ara kan láti San Francisco tó ń jẹ́ Steven Karch sọ pé: “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí mo mọ̀ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn [tó lo egbòogi tí wọ́n fi ephedra ṣe] kú, wáyé nítorí pé wọ́n ní àrùn inú òpójẹ̀ tó le gan-an tàbí wọ́n lo àpọ̀jù oògùn.”

Ọ̀mọ̀wé Logan Chamberlain, òǹkọ̀wé ìwé kan lórí egbòogi, sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìròyìn àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí nípa àbájáde búburú tó wà nínú lílo egbòogi ló ń wáyé nítorí pé àwọn èèyàn kì í tẹ̀ lé ìtọ́ni. . . . Ìwọ̀n tí wọ́n máa ń sọ pé kéèyàn lò lára àwọn egbòogi tó ṣeé gbára lé kò léwu, kódà ó máa ń gbéṣẹ́ gan-an pàápàá. Má ṣe ronú pé o lè fojú kéré ìtọ́ni tí wọ́n fún ọ kó o wá lọ lo àpọ̀jù oògùn, àyàfi bó o bá ti gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ oníṣègùn ìbílẹ̀ kan tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.”

Oníṣègùn ìbílẹ̀ kan tó ń jẹ́ Linda Page ṣèkìlọ̀ pé: “Kódà fún àìsàn tó le gan-an pàápàá, ìwọ̀nba oògùn ló yẹ kéèyàn lò, kì í ṣe kéèyàn máa rọ́ oògùn mì ṣáá. Ìlera rẹ á túbọ̀ jí pépé sí i bó o bá fún ara rẹ ní àkókò láti kọ́fẹ padà, tó o sì ń fẹ̀sọ̀ ṣe é. Ó máa ń gba àkókò kí ara tó bọ̀ sípò.”

Ìwé kan tó dá lórí fífi ewé àti egbò ṣèwòsàn ṣàlàyé pé àwọn egbòogi kan wà tó jẹ́ pé béèyàn bá lò wọ́n ju bó ṣe yẹ lọ, wọn ò lè pani lára. Bí àpẹẹrẹ, bíbì léèyàn á kàn bì béèyàn bá lo egbòogi kan tí wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí oògùn amáratuni lálòjù. Àmọ́ ṣá o, èyí ò ní ká máa lo egbòogi bá a ṣe fẹ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo egbòogi ló rí bẹ́ẹ̀.

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kí egbòogi kan tó lè ṣiṣẹ́, a gbọ́dọ̀ lo èyí tó pọ̀ tó, ká sì lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nígbà míì, ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kéèyàn lo ògidì rẹ̀. Bọ́ràn ṣe rí nìyí pẹ̀lú egbòogi ginkgo biloba, tí wọ́n ti ń lò látọjọ́ pípẹ́ fún mímú kí agbára ìrántí ẹni jí pépé kí ẹ̀jẹ̀ sì máa ṣàn dáadáa nínú ara, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé lèèyàn á nílò kó tó lè rí ìwọ̀nba tó máa ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan.

Lílo Oògùn Ìbílẹ̀ Pọ̀ Mọ́ Oògùn Òyìnbó Léwu

Onírúurú ọ̀nà ni egbòogi lè gbà nípa lórí oògùn òyìnbó. Bí àpẹẹrẹ, egbòogi lè mú kí iṣẹ́ tí oògùn òyìnbó kan máa ṣe pọ̀ sí i tàbí kó dín bó ṣe gbéṣẹ́ sí kù, kó jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ tètè kúrò lára, tàbí kó mú kí àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ nínú oògùn náà pọ̀ sí i. Irúgbìn kan tó ń jẹ́ St. John’s wort, tí àwọn oníṣègùn sábà máa ń júwe nílẹ̀ Jámánì fún àárẹ̀ ọkàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ le, kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ oògùn òyìnbó ṣiṣẹ́ pẹ́ lára, nípa bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Nítorí náà, bó o bá ń lo oògùn òyìnbó kan, títí kan àwọn oògùn ìfètò-sọ́mọ-bíbí, sọ fún dókítà rẹ ṣáájú kó o tó máa lo egbòogi.

Ìwé kan tó ṣàlàyé lórí agbára ìwòsàn tí egbòogi ní sọ pé: “Ọtí líle, igbó, kokéènì, àtàwọn oògùn mìíràn tó ń nípa lórí ìmọ̀lára ẹni, títí kan tábà, lè gbẹ̀mí ẹni béèyàn bá pò wọ́n mọ́ àwọn egbòogi kan. . . . Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o yẹra fún [irú àwọn ohun líle bẹ́ẹ̀], pàápàá nígbà tó o bá ń ṣàìsàn.” Bákan náà, ó yẹ kí àwọn aláboyún àtàwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀ràn yìí. Ká sòótọ́, bó bá dọ̀ràn lílo tábà àtàwọn oògùn líle mìíràn, ohun tó ń dáàbò bo àwọn Kristẹni ni pípa àṣẹ Bíbélì mọ́, ìyẹn èyí tó sọ pé kí a “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Nígbà tí ìwé kan ń sọ̀rọ̀ lórí lílo egbòogi, ó kìlọ̀ pé: “Bó o bá lóyún lẹ́nu ìgbà tó ò ń lo egbòogi kan, sọ fún oníṣègùn rẹ, kó o sì dá lílò ó dúró títí dìgbà tí wàá fi bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gbìyànjú láti rántí bí èyí tó o ti lò ṣe pọ̀ tó àti bí àkókò tó o ti ń lò ó ṣe gùn tó.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan lórí egbòogi sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ewu ló wà nínú lílo oògùn tí oníṣègùn kò júwe fúnni, irú bí egbòogi.” Nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, “Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Lílo Oògùn Tí Oníṣègùn Kò Júwe Fúnni,” o lè kà nípa àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ nínú lílo egbòogi.

Bíi ti gbogbo àwọn oògùn mìíràn tó wà fún ìlera ẹ̀dá, a gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa ìlò ewé àti egbò, ká ní ìmọ̀ kíkúnrẹ́rẹ́ nípa rẹ̀, àti pé, láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ́ ọ, ká wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì—ká sì máa rántí pé kò sí ìwòsàn fún àwọn àìsàn kan nísinsìnyí. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí ohun náà gan-an tó ń fa àìsàn àti ikú, ìyẹn ni àìpé tá a ti jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá lábẹ́ ìṣàkóso rere ti Ìjọba Ọlọ́run.—Róòmù 5:12; Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jí! kì í ṣe ìwé ìṣègùn, nípa bẹ́ẹ̀ kò sọ pé irú ìtọ́jú tàbí irú àwọn oúnjẹ kan pàtó, ì báà jẹ́ oògùn ìbílẹ̀ tàbí irú mìíràn, ló dára fún wíwo àìsàn. Ìlàlóye gbogbo gbòò ni ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí wà fún o. Àwọn òǹkàwé ni kó pinnu ohun tí wọ́n bá fẹ́ nípa ọ̀ràn ìlera àti ìtọ́jú fúnra wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Lílo Oògùn Tí Oníṣègùn Kò Júwe Fúnni

Àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí ni ewu tó wà nínú lílo egbòogi láìkọ́kọ́ ṣèwádìí lọ́wọ́ oníṣègùn tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.

O lè má mọ ohun náà gan-⁠an tó ń yọ ọ́ lẹ́nu.

Egbòogi tóò ń lò fúnra rẹ lè máà gbéṣẹ́ fún àìlera rẹ, kódà bó o bá tiẹ̀ mọ àìsàn tó ń ṣe ọ́ pàápàá.

Lílò tóò ń lo egbòogi fúnra rẹ lè máà jẹ́ kí ìtọ́jú tó pọn dandan tó sì bójú mu, tó máa lé àìsàn náà dà nù, tètè ṣiṣẹ́.

Egbòogi tóò ń lò fúnra rẹ lè máà jẹ́ kí èyí tí dókítà júwe fún ọ ṣiṣẹ́ dáadáa​​—⁠bí àpẹẹrẹ, oògùn tóò ń lò nítorí àwọn èèwọ̀ ara kan tàbí oògùn ẹ̀jẹ̀ ríru.

Egbòogi tóò ń lò fúnra rẹ lè wo àwọn àìlera pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan, àmọ́ ó tún lè mú kí àìsàn mìíràn burú sí i, irú bí ẹ̀jẹ̀ ríru.

[Credit Line]

Ibi tí a ti mú ìsọfúnni yìí: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Rodale’s Illustrated Encyclopedia of Herbs

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́