Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ọgbọ́n Ìṣèlú Lè Mú Àlàáfíà Kárí Ayé Wá?
ṢÉ WÀÁ fẹ́ kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá? Dájúdájú, ọgbọ́n kan gbọ́dọ̀ wà táwọn olóṣèlú á máa dá láti yanjú aáwọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti lágbàáyé. Ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ gbà gbọ́ pé bí àwọn aṣáájú ayé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ wọ́n lè fòpin sí ogun. Àmọ́ o, ó ṣeé ṣe kí kíkùnà tí ọgbọ́n ìṣèlú ń kùnà ti kó ìjákulẹ̀ bá ọ. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá làwọn olóṣèlú ayé ti ń fọwọ́ sí àwọn àdéhùn, tí wọ́n ń ṣe onírúurú ìpinnu, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ìpàdé àpérò, àmọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ lohun tí wọ́n tíì rí ojútùú wíwà pẹ́ títí sí.
Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa ọgbọ́n ìṣèlú àti àlàáfíà. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Kí lohun tó fà á tí ọgbọ́n ìṣèlú ò fi tíì mú àlàáfíà wá báyìí? Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa kọ́wọ́ ti lílo ọgbọ́n ìṣèlú? Báwo wá ni ọwọ́ á ṣe tẹ àlàáfíà tòótọ́?
Kí Ló Ń Dí Àlàáfíà Lọ́wọ́?
Àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì mélòó kan ṣàpèjúwe bí fífinú konú ṣe lè mú àlàáfíà wá. Bí àpẹẹrẹ, Ábígẹ́lì lo ọgbọ́n láti yí Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ́kàn padà kí wọ́n má bàa gbẹ̀san ara wọn lára agboolé rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:18-35) Jésù ṣe àkàwé nípa ọba kan tí kò sí ohun mìíràn tó bọ́gbọ́n mu tó lè ṣe ju pé kó rán àwọn ikọ̀ jáde láti lọ bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà. (Lúùkù 14:31, 32) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì gbà pé àwọn ọgbọ́n kan wà tá a lè dá láti yanjú aáwọ̀. Nígbà náà, kí ló wá fà á tí àwọn àpérò àlàáfíà kì í fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí?
Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an ló rí pé àkókò wa á kún fún wàhálà. Nítorí pé Sátánì Èṣù ẹni ibi náà ló ń darí ayé báyìí, àwọn èèyàn ò ní “ṣeé bá ṣe àdéhùn kankan” ṣùgbọ́n wọ́n á jẹ́ “òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:3, 4; Ìṣípayá 12:12) Ní àfikún sí i, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé lára ohun tí yóò sàmì sí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ni “àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun.” (Máàkù 13:7, 8) Ta ní jẹ́ sẹ́ ẹ pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló túbọ̀ ń gbilẹ̀ kárí ayé báyìí? Bí ọ̀ràn bá sì rí bẹ́ẹ̀, ṣé ó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé pàbó ni gbogbo ìgbìdánwò láti mú kí àlàáfíà wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè sábà máa ń já sí?
Bákan náà, tún gbé kókó yìí yẹ̀ wò: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóṣèlú ayé lè máa sapá torí tọrùn láti rí i pé kò sógun, ohun tó jẹ olúkúlùkù wọn lógún ni bí ọwọ́ ẹ̀ á ṣe tẹ ohun tó lè ṣe orílẹ̀-èdè tiẹ̀ láǹfààní. Ìyẹn gan-an sì ni ohun tí ọgbọ́n ìṣèlú dá lé. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
Láìka ohun yòówù tí àwọn olóṣèlú ayé lè ní lọ́kàn sí, wọn ò ní òye àti agbára tí wọ́n lè fi yanjú ìṣòro aráyé pátápátá
Ìhà Tí Àwọn Kristẹni Kọ sí Ọgbọ́n Ìṣèlú
Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Èyí túmọ̀ sí pé, láìka ohun yòówù tí àwọn olóṣèlú ayé lè ní lọ́kàn sí, wọn ò ní òye àti agbára tí wọ́n lè fi yanjú ìṣòro aráyé pátápátá.
Nígbà tí Jésù ń jẹ́jọ́ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù, ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Ìkórìíra orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe tẹni àti ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan nínú ọ̀ràn ìṣèlú ló sábà máa ń ṣàkóbá fún àwọn ìwéwèé láti mú àlàáfíà wá. Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí àwọn aáwọ̀ tó ń lọ nínú ayé àti fífi ọgbọ́n ìṣèlú wá ojútùú sí àwọn aáwọ̀ náà.
Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ńṣe làwọn Kristẹni ń dágunlá sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé? Àbí wọn ò bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ aráyé ni? Ká má ri. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì ṣàpèjúwe àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ti tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” nítorí àwọn nǹkan búburú tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Ọlọ́run làwọn Kristẹni gbọ́kàn lé pé yóò mú àlàáfíà wa gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí. Ṣé o gbà pé bí kò bá sí ogun mọ́ ni àlàáfíà tó lè wà? Ó dájú pé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe gan-an nìyẹn. (Sáàmù 46:8, 9) Àmọ́, láfikún sí ìyẹn, yóò tún mú kí ààbò pípéye àti ìgbé ayé rere wà fún gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé. (Míkà 4:3, 4; Ìṣípayá 21:3, 4) Ọwọ́ ò lè tẹ irú àlàáfíà tí kò láfiwé bẹ́ẹ̀ nípa lílo ọgbọ́n ìṣèlú tàbí nípasẹ̀ àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀ láti “pa àlàáfíà mọ́.”
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fi hàn kedere pé pàbó ni níní ìgbọ́kànlé pé ọgbọ́n ìṣèlú ẹ̀dá èèyàn ni yóò mú àlàáfíà wá yóò wulẹ̀ já sí. Àwọn tí wọ́n bá ní ìgbọ́kànlé pé Jésù Kristi ni yóò mú àlàáfíà wá tí wọ́n sì ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run yóò rí àlàáfíà tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. Síwájú sí i, wọn yóò gbádùn rẹ̀ títí láé!—Sáàmù 37:11, 29.