Bó Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Pé Kó O Tọ́ Ọmọ Rẹ
BÉÈYÀN bá ṣe kẹ́kọ̀ọ́ tó ní kékeré lè pinnu bó ṣe máa mọ nǹkan ṣe tó nígbà tó bá dàgbà. Nígbà náà, kí ló yẹ káwọn ọmọ kọ́ lọ́dọ̀ òbí kí wọ́n lè wúlò nígbà tí wọ́n bá dàgbà kí wọ́n sì lè ṣàṣeyọrí? Wo ohun táwọn kan ti sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí látàrí ìwádìí tí wọ́n ṣe láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn.
Ipa Táwọn Fọ́nrán Tó So Kọ́ra Nínú Ọpọlọ Ń Kó
Ìtẹ̀síwájú tó ń dé bá ìmọ̀ nípa fífi kọ̀ǹpútà wo inú ọpọlọ ti jẹ́ káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè túbọ̀ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ sí i nípa bí ọpọlọ ṣe ń dàgbà. Irú àwọn ìwádìí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àkókò tí ọmọ bá ṣì wà ní ìkókó ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé ìgbà yẹn làwọn apá tó máa mú kí ọpọlọ rẹ̀ lè máa gba ìsọfúnni, èyí tó máa mú kó lè fi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn bó ṣe yẹ àti èyí tá á mú kó lè kọ́ èdè máa ń dàgbà. Ìwé ìròyìn Nation sọ pé: “Ńṣe làwọn fọ́nrán inú ọpọlọ yára ń so pọ̀ mọ́ra lọ́nà kíkàmàmà nígbà tí ọmọ bá ṣì wà ní kékeré látàrí báwọn nǹkan tó là kọjá látìgbà tí wọ́n ti lóyún rẹ̀ àtàwọn ohun àbínibí ṣe ń dàpọ̀ nínú ọpọlọ.”
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà gbọ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìsokọ́ra yìí, tí wọ́n ń pè ní ìsokọ́ra àwọn fọ́nrán inú ọpọlọ máa ń wáyé láàárín àwọn ọdún mélòó kan tí ọmọ bá kọ́kọ́ lò láyé. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà T. Berry Brazelton, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìdágbàsókè ọmọ ṣe sọ, àsìkò yìí gan-an “làwọn ẹ̀yà inú ọpọlọ máa ń dàgbà, irú bí àwọn tó máa mú kí ọmọ gbọ́n, èyí tá á mú kó lè mọ bóun ṣe jẹ́, èyí tó máa jẹ́ kó lè nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹlòmíràn àti èyí tó máa jẹ́ kó lè kẹ́kọ̀ọ́.”
Láwọn ọdún díẹ̀ tí ọmọ bá kọ́kọ́ lò láyé, ọpọlọ rẹ̀ máa ń tóbi sí i, á yàtọ̀ ní irísi, iṣẹ́ tí ọpọlọ yìí lè ṣe á sì pọ̀ sí i. Nígbà tí ọmọ kan bá ń rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ta ọpọlọ rẹ̀ jí nípa dídá a lára yá àti ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè fi máa kẹ́kọ̀ọ́, àwọn fọ́nrán tó ń so kọ́ra nínú ọpọlọ á túbọ̀ pọ̀ sí i, ìyẹn á sì lè fún ọpọlọ lágbára púpọ̀ sí i láti gba ìsọfúnni. Bí ọpọlọ ṣe lágbára láti gba ìṣọfúnni yìí ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún èèyàn láti lè ronú, kó lè kẹ́kọ̀ọ́, kó sì mọ bá a ṣe ronú.
Ó lè jẹ́ pé bí ọpọlọ ìkókó kan bá ṣe rí àwọn nǹkan tó máa ń dá a lára yá sí, bẹ́ẹ̀ làwọn èròjà inú ẹ̀ á ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ sì làwọn fọ́nrán inú ọpọlọ á ṣe lè so kọ́ra tó. Ó tiẹ̀ dáa tó jẹ́ pé kì í kàn ṣe ẹ̀kọ́ tá à ń kó sọ́mọ lórí nípa kíkàwé fún un àti kíkọ́ ọ lédè nìkan lá fi lè ta ọpọlọ rẹ̀ jí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tún ti rí i pé ó tún yẹ káwọn òbí máa
dá ọmọ lára yá. Ìwádìí fi hàn pé táwọn ìkókó kò bá rẹ́ni tó ń gbé wọn mọ́ra tí kò sì sẹ́ni tó ń fọwọ́ kàn wọ́n, tí wọn kò bá sì rẹ́ni bá wọn ṣeré tàbí kó dá wọn lára yá, àwọn fọ́nrán ọgbọ́n tó máa so kọ́ra nínú ọpọlọ wọn kò ní pọ̀.
Ṣé Ọ̀nà Tá A Gbà Tọ́ Ọmọ Lè Nípa Lórí Ohun Tá Á Lè Dá Ṣe?
Nígbà tó bá yá, bí àwọn ọmọdé ṣe ń dàgbà ọpọlọ á ṣe bí ẹni ń jo àwọn nǹkan dà nù. Á dà bíi pé ó ń gbá àwọn fọ́nrán kan tó lè má ṣe pàtàkì kúrò. Èyí lè nípa lórí ohun tí ọmọ kan á mọ̀ ọ́n ṣe. Max Cynader, tó jẹ́ olùṣèwádìí nípa ọpọlọ sọ pé: “Tí ọmọ ò bá rí ohun tó yẹ kó ta á jí láti kékeré, àwọn nǹkan tó ń mú kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ kò ní so kọ́ra dáadáa nínú ọpọlọ ẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí Dókítà J. Fraser Mustard ṣe sọ, èyí lè fa kí ọmọ ya èdìdàrẹ́, kó má lè mọ̀rọ̀ sọ dáadáa, kó má sì lè mọ ìṣirò tó bá dàgbà tán, ó lè ya olókùnrùn, kódà ó lè má mọ̀wàá hù.
Látàrí èyí, ó dà bíi pé ohun tí ọmọdé kan bá là kọjá ní kékeré ló máa mọ́ ọn lára dàgbà. Àwọn ohun tọ́mọ kan bá fojú rí ní kékeré ayé ẹ̀ lè pinnu bó bá máa ní ìrọ́jú tàbí bí ò bá ní lè mú nǹkan mọ́ra, bó bá máa lè finú wòye tàbí kó ya akúrí àti bó bá máa jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú tàbí ọ̀dájú. Nítorí náà, iṣẹ́ ń bẹ lọ́rùn àwọn òbí. Dókítà kan tó mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọdé sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká kíyè sí dáadáa lára ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ní kékeré ni pé “ọwọ́ tí wọ́n bá fi mú ọmọ ló máa sọ ohun tó máa yà bó bá dàgbà.”
Ó lè dà bíi pé kò sí ohun tó ṣòro nínu ìyẹn. Bó o bá ṣáà ti tọ́jú àwọn ọmọ ẹ, wọ́n á yàn wọ́n á sì yanjú. Àmọ́, ohun tó dunni níbẹ̀ ni pé àwọn òbí fúnra wọn mọ̀ pé àtilóye ọ̀nà tí wọ́n á gbà tọ́mọ dáadáa kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé gbogbo òbí kọ́ ló mọ bá a ti í tọ́mọ.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe fi hàn, ìdámẹ́rin àwọn òbí tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu wọn kò mọ̀ pé ohun tí wọ́n bá ṣe sí ọmọ wọn lè mú kí ọpọlọ rẹ̀ jí pépé tàbí kó kú u lọ́pọlọ àti pé ó lè fún un ní ìgboyà tàbí kó kó o láyà jẹ, ó sì lè nípa lórí bó ṣe máa fẹ́ràn ẹ̀kọ́ kíkọ́ sí. Ìbéèrè tó wá tìdí èyí jẹ yọ ni pé: Ọ̀nà wo ló dáa jù láti mú kí ọmọ rẹ láǹfààní láti lè mọ nǹkan ṣe débi tó lágbára láti mọ̀ ọ́n dé? Báwo lo ṣe lè mú kó rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wò ó nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn ìkókó tí wọ́n fi sílẹ̀ láìdá wọn lára yá lè má dàgbà dáadáa bí àwọn ọmọ yòókù