ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ojú ìwé 3
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ọ̀kan Lára Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Nasẹ̀ Ìwé Walaaye Titilae Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ojú ìwé 3

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

“Ó yẹ kí ẹ ti di olùkọ́.” (Héb. 5:12) Àbẹ́ ò rí nǹkan! Jèhófà tó jẹ́ Olùkọ́ tó dára jù lọ láyé àtọ̀run gbéṣẹ́ fún wa pé ká máa kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nípa òun! Nígbàkigbà tí wọ́n bá ní ká kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà, bóyá nínú ìdílé, nínú ìjọ, tàbí lóde ẹ̀rí, àǹfààní ńlá ló jẹ́, ojúṣe pàtàkì sì ni. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?

A lè rí ìdáhùn nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó ní: “Máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ, máa gbani níyànjú, kí o sì máa kọ́ni.” Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé: “Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:​13, 16) Ohun tó máa gbẹ̀mí àwọn èèyàn là lo fẹ́ sọ fún wọn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o máa sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kàwé àti bó o ṣe ń kọ́ni. Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Díẹ̀ rèé lára ohun tó wà níbẹ̀.

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lójú ìwé kọ̀ọ̀kan lè jẹ́ ìlànà Bíbélì tó bá ẹ̀kọ́ tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mu tàbí kó jẹ́ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè lo ẹ̀kọ́ náà

Àwọn àbá

Àwọn àbá nípa bá a ṣe lè lo ohun tí ẹ̀kọ́ náà dá lé

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Àwọn àbá tá a lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹ̀kọ́ míì nínú ìwé yìí la lè lò lóde ẹ̀rí àti nígbà tá a bá ń kọ́ni látorí pèpéle.

Jèhófà ni ‘Olùkọ́ Atóbilọ́lá.’ (Àìsá. 30:20) Òótọ́ ni pé ìwé yìí á mú kó o túbọ̀ mọ ìwé kà, ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ èèyàn kọ́, àmọ́ má gbàgbé pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ohun tí à ń wàásù ti wá, òun ló sì ń fa àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́. (Jòh. 6:44) Torí náà, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. Máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Jèhófà ni kó o máa pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí, kì í ṣe ara rẹ. Sapá gidigidi láti mú kí àwọn èèyàn ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí Jèhófà.

Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún ẹ pé kó o máa kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ọkàn wa balẹ̀ pé tó o bá gbára lé “okun tí Ọlọ́run ń fúnni,” wàá ṣàṣeyọrí.​—1 Pet. 4:11.

Àwa tá a jọ jẹ́ olùkọ́,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Arákùnrin kan ń sọ àsọyé; arábìnrin kan ń wàásù; arákùnrin ń wàásù níbi iṣẹ́; ọ̀dọ́bìnrin kan ń sọ̀rọ̀ ní kíláàsì rẹ̀
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́