ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Fàyè Gba “Ẹ̀mí Ayé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣó Burú Kéèyàn Máa Mutí Líle?
    Jí!—2007
  • Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/1 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ojú wo ni ìjọ Kristẹni fi ń wo jíjẹ àjẹkì?

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn tó ń sin Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ mutí para tàbí jẹ àjẹkí, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwà tí kò bójú mu ni. Nítorí náà, ojú tí ìjọ Kristẹni fi ń wo àwọn tí ọtí àmupara ti wọ̀ lẹ́wù náà ló fi ń wo àwọn tó ti sọ àjẹkì dàṣà. Àti alámupara àti alájẹkì, kò sí èyí tó lè wà nínú ìjọ Kristẹni.

Òwe 23:20, 21 sọ pé: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì. Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì, àkísà lásán-làsàn sì ni ìṣesùẹ̀sùẹ̀ yóò fi wọ ènìyàn.” Ní Diutarónómì 21:20, a kà nípa ọkùnrin kan tó jẹ́ “alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,” tí ikú sì tọ́ sí i lábẹ́ Òfin Mósè. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe sọ, méjì lára ẹ̀ṣẹ̀ tí ọlọ̀tẹ̀ tí kò ronú pìwà dà náà dá ni pé ó jẹ́ “alájẹkì àti ọ̀mùtípara.” Èyí fi hàn kedere pé ohun tí kò bójú mu rárá ni wọ́n ka kí ẹni tó ń sin Ọlọ́run jẹ́ alájẹkì sí lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì.

Àmọ́, kí ló ń fi hàn pé alájẹkì lẹnì kan, kí sì ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ nípa kókó yìí? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ alájẹkì sí “ẹni tó máa ń jẹun lájẹjù tàbí tó máa ń mutí lámujù, tó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo.” Nítorí náà, ìwọra ló ń mú kí àwọn èèyàn jẹ àjẹkì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì sọ fún wa pé, “àwọn oníwọra” wà lára àwọn tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Fílípì 3:18, 19; 1 Pétérù 4:3) Láfikún sí i, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kìlọ̀ fáwọn Kristẹni láti má ṣe lọ́wọ́ sí “àwọn iṣẹ́ ti ara,” ó mẹ́nu kan “mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:19-21) Jíjẹ àjẹjù sábà máa ń bá mímu àmuyíràá àti àríyá aláriwo rìn. Síwájú sí i, kò sí àní-àní pé jíjẹ àjẹkì wà lára àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù pè ní irú “nǹkan báwọ̀nyí.” Gẹ́gẹ́ bó ti rí pẹ̀lú “àwọn iṣẹ́ ti ara” yòókù, Kristẹni kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ ní alájẹkì tí kò sì fi ìwà ìwọra tó ní sílẹ̀ yẹ lẹ́ni tí à ń yọ kúrò nínú ìjọ.—1 Kọ́ríńtì 5:11, 13.a

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun kan náà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ka ìmùtípara àti jíjẹ àjẹkì sí, ó rọrùn láti tètè dá ọ̀mùtípara mọ̀ ju alájẹkì lọ. Àwọn àmì tó ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ọ̀mùtípara sábà máa ń fara hàn kedere. Àmọ́, kì í rọrùn rárá láti mọ ẹni tá a lè pé ní alájẹkì, nítorí pé kì í ṣe bí ẹnì kan ṣe rí la fi ń sọ pé ó jẹ́ alájẹkì. Nítorí náà, ó gba ìṣọ́ra àti ìfòyemọ̀ gan-an nígbà táwọn alàgbà inú ìjọ bá fẹ́ bójú tó ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìṣòro yìí.

Bí àpẹẹrẹ, sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ lè jẹ́ àmì àjẹkì, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Àìsàn lè mú kí ẹnì kan sanra gan-an. Àbùdá ẹnì kan sì tún lè fà á. Bákan náà, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé bí ara ẹnì kan ṣe rí ni ọ̀rọ̀ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ nígbà tí àjẹkì jẹ́ ìwà téèyàn ń hù. Ohun tí ìwé àtúmọ̀ èdè kan tumọ̀ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ sí ni “níní àpọ̀jù ọ̀rá nínú ara” nígbà tó túmọ̀ jíjẹ àjẹkì sí “fífi ìwọra jẹun tàbí jíjẹ oúnjẹ ní àjẹjù.” Nípa bẹ́ẹ̀, bí ẹnì kan ṣe tóbi sí kọ́ la fi ń mọ ẹni tó ń jẹ àjẹkì bí kò ṣe bó ṣe máa ń ṣe tọ́rọ̀ oúnjẹ bá délẹ̀. Ẹnì kan lè máà tóbi, kódà ó tiẹ̀ lè tín-ín-rín pàápàá, síbẹ̀ kó jẹ́ alájẹkì. Síwájú sí i, ojú tí wọ́n fi ń wo kéèyàn sanra tàbí kéèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́ yàtọ̀ síra gan-an láti ibi kan sí òmíràn.

Àwọn àmì wo la fi ń dá alájẹkì mọ̀? Alájẹkì kì í lè kóra rẹ̀ níjàánu ní gbogbo ìgbà tó bá ti wà nídìí oúnjẹ, ó tiẹ̀ lè máa rọ́ oúnjẹ síkùn nìṣó débi tí kò fi ní ní àlàáfíà mọ́ nínú àgọ́ ara rẹ̀ tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu rẹ̀ fi hàn pé kò bìkítà rárá nípa ẹ̀gàn tó ń mú wá sórí orúkọ Jèhófà àti àbààwọ́n tó ń kó bá ìwà dáadáa táwọn èèyàn fi ń dá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a ò lè yára ka ẹni tó ń jẹ́ àjẹjù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan sí “oníwọra” èèyàn. (Éfésù 5:5) Síbẹ̀, lójú ohun tí Gálátíà 6:1 sọ, irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ lè nílò ìrànlọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.”

Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká yẹra fún àjẹjù fi ṣe pàtàkì gan-an lákòókò tá a wà yìí? Nítorí pé, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò wa yìí, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Lúùkù 21:34, 35) Ọ̀nà pàtàkì kan láti yàgò fún ìgbésí ayé tó lè ṣàkóbá fún ipò tẹ̀mí wá ni pé ká yẹra fún fífi oúnjẹ kẹ́ra ẹni bà jẹ́.

Ànímọ́ dáradára tó yẹ káwọn Kristẹni ní ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. (1 Tímótì 3:2, 11) Nítorí náà, ó dájú pé Jèhófà yóò bù kún gbogbo àwọn tó bá ń sapá gidigidi láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé ká máa jẹ ká sì máa mu ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Hébérù 4:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ “Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe” nínú Ilé-ìsọ́nà ti December 1, 1986.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́