-
Léfítíkù 2:3-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù lára ọrẹ ọkà náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́+ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
4 “‘Tí o bá fẹ́ fi ohun tí wọ́n yan nínú ààrò ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n fi òróró pò, tó rí bí òrùka tàbí búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+
5 “‘Tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n ṣe nínú agbada+ lo fẹ́ fi ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò mọ́ òróró, tí kò sì ní ìwúkàrà. 6 Kí o gé e sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró sórí rẹ̀.+ Ọrẹ ọkà ni.
7 “‘Tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n sè nínú páànù lo fẹ́ fi ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná pẹ̀lú òróró ṣe.
-
-
1 Kọ́ríńtì 9:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ máa ń jẹ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì àti pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ máa ń gba ìpín nídìí pẹpẹ?+
-