ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóòbù 7:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Àwọn ọjọ́ mi ń yára sáré ju ohun èlò tí wọ́n fi ń hun aṣọ,+

      Wọ́n sì dópin láìnírètí.+

  • Jóòbù 14:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “Èèyàn tí obìnrin bí,

      Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,+ wàhálà* rẹ̀ sì máa ń pọ̀ gan-an.+

       2 Ó jáde wá bí ìtànná, ó sì rọ dà nù;*+

      Ó ń sá lọ bí òjìji, ó sì pòórá.+

  • Sáàmù 39:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Lóòótọ́, o ti mú kí ọjọ́ ayé mi kéré;*+

      Gbogbo ọjọ́ ayé mi kò sì jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ.+

      Ní ti ọmọ èèyàn, bó tilẹ̀ dà bíi pé kò sí nínú ewu, bí èémí lásán ló rí.+ (Sélà)

       6 Dájúdájú, bí òjìji ni ọmọ èèyàn ń rìn kiri.

      Ó ń sáré kiri* lórí òfo.

      Ó ń kó ọrọ̀ jọ pelemọ láìmọ ẹni tó máa gbádùn rẹ̀.+

  • Sáàmù 103:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bíi ti koríko;+

      Ó rú jáde bí ìtànná orí pápá.+

      16 Àmọ́ nígbà tí atẹ́gùn fẹ́, kò sí mọ́,

      Àfi bíi pé kò sí níbẹ̀ rí.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́