17 Ọlọ́run, o ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá,+
Títí di báyìí, mò ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+
18 Kódà tí mo bá darúgbó, tí mo sì hu ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀.+
Jẹ́ kí n lè sọ nípa agbára rẹ fún ìran tó ń bọ̀,
Kí n sì sọ nípa agbára ńlá rẹ fún gbogbo àwọn tó ń bọ̀.+