17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,
Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,+
Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+
18 Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+
Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+
Òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+