ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 41:51, 52
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 51 Jósẹ́fù sọ àkọ́bí rẹ̀ ní Mánásè,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú tó bá mi àti gbogbo ilé bàbá mi.” 52 Ó sì sọ èkejì ní Éfúrémù,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n di púpọ̀ ní ilẹ̀ tí mo ti jìyà.”+

  • Léfítíkù 26:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “‘Màá ṣojúure* sí yín, màá mú kí ẹ bímọ lémọ, kí ẹ sì di púpọ̀,+ màá sì mú májẹ̀mú tí mo bá yín dá ṣẹ.+

  • Jóòbù 42:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà wá bù kún ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ,+ Jóòbù wá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ràkúnmí, màlúù méjì-méjì lọ́nà ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 13 Ó tún wá bí ọmọkùnrin méje míì àti ọmọbìnrin mẹ́ta míì.+

  • Sáàmù 128:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ìyàwó rẹ yóò dà bí igi àjàrà tó ń so nínú ilé rẹ;+

      Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì, wọ́n á yí tábìlì rẹ ká.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́