ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 93:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 93 Jèhófà ti di Ọba!+

      Ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí aṣọ;

      Jèhófà gbé agbára wọ̀;

      Ó fi di ara rẹ̀ bí àmùrè.

      Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in;

      Kò ṣeé ṣí nípò.*

  • Àìsáyà 33:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Torí Jèhófà ni Onídàájọ́ wa,+

      Jèhófà ni Afúnnilófin wa,+

      Jèhófà ni Ọba wa;+

      Òun ni Ẹni tó máa gbà wá.+

  • Míkà 4:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Èmi yóò mú kí ẹni* tó ń tiro ṣẹ́ kù,+

      Èmi yóò sì sọ ẹni tí wọ́n ti mú lọ sí ọ̀nà tó jìn di orílẹ̀-èdè alágbára;+

      Jèhófà yóò sì jọba lé wọn lórí ní Òkè Síónì,

      Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

  • Mátíù 24:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè,+ nígbà náà ni òpin yóò dé.

  • Ìfihàn 11:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+

  • Ìfihàn 11:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 wọ́n ní: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè, ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ torí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti ń jọba.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́