ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 31:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+ 17 Màá bínú sí wọn gidigidi nígbà yẹn,+ màá pa wọ́n tì,+ màá sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn+ títí wọ́n á fi pa run. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá wá dé bá wọn,+ wọ́n á sọ pé, ‘Ṣebí torí Ọlọ́run wa ò sí láàárín wa ni àjálù yìí ṣe dé bá wa?’+

  • Diutarónómì 32:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  20 Ó wá sọ pé, ‘Màá fojú pa mọ́ fún wọn;+

      Màá wo ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn.

      Torí ìran oníwà burúkú ni wọ́n,+

      Àwọn aláìṣòótọ́ ọmọ.+

  • Àìsáyà 57:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Inú bí mi torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, bó ṣe ń wá èrè tí kò tọ́,+

      Torí náà, mo kọ lù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, inú sì bí mi.

      Àmọ́ kò yéé rìn bí ọ̀dàlẹ̀,+ ó ń ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.

  • Ìsíkíẹ́lì 39:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé torí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, torí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi ni wọ́n fi lọ sí ìgbèkùn.+ Torí náà, mo fi ojú mi pa mọ́ fún wọn,+ mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́,+ idà sì pa gbogbo wọn.

  • Míkà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ní àkókò yẹn, wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,

      Àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn.

      Ó máa fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn ní àkókò yẹn,+

      Torí ìwà burúkú wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́