ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 32:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Torí wọ́n ti pa ilé gogoro tó láàbò tì;

      Wọ́n ti pa ìlú aláriwo tì.+

      Ófélì+ àti ilé ìṣọ́ ti di ahoro títí láé,

      Ààyò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,

      Ibi ìjẹko àwọn agbo ẹran,+

  • Jeremáyà 9:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Màá sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì òkúta,+ ibùgbé àwọn ajáko,*+

      Màá sì sọ àwọn ìlú Júdà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀.+

  • Ìdárò 1:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Síónì ń ṣọ̀fọ̀, nítorí kò sí ẹni tó ń bọ̀ wá sí àjọyọ̀.+

      Gbogbo ẹnubodè rẹ̀ di ahoro;+ àwọn àlùfáà rẹ̀ ń kẹ́dùn.

      Ẹ̀dùn ọkàn ti bá àwọn wúńdíá* rẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá.

  • Ìdárò 2:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Jèhófà ti pinnu láti run ògiri ọmọbìnrin Síónì.+

      Ó ti na okùn ìdíwọ̀n.+

      Kò fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn láti mú ìparun wá.*

      Ó ń mú kí odi ààbò àti ògiri máa ṣọ̀fọ̀.

      Gbogbo wọn sì ti di aláìlágbára.

      ט [Tétì]

       9 Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì wọlẹ̀.+

      Ọlọ́run ti ba ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣẹ́ ẹ.

      Ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+

      Kò sí òfin;* kódà àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́