ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 11:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 màá mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti ti ìgbà ìrúwé, ẹ sì máa kó ọkà yín jọ àti wáìnì tuntun yín àti òróró yín.+

  • Jeremáyà 14:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ǹjẹ́ ìkankan lára àwọn òrìṣà lásánlàsàn tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bọ lè rọ òjò,

      Àbí ṣé ọ̀run fúnra rẹ̀ pàápàá lè dá rọ ọ̀wààrà òjò?

      Ìwọ nìkan lo lè ṣe é, Jèhófà Ọlọ́run wa.+

      A sì ní ìrètí nínú rẹ,

      Nítorí ìwọ nìkan ló ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.

  • Jeremáyà 51:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Nígbà tí ó bá fọhùn,

      Omi ojú ọ̀run á ru gùdù,

      Á sì mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé.

      Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò,

      Ó sì ń mú ẹ̀fúùfù wá láti inú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

  • Ìsíkíẹ́lì 34:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Èmi yóò mú kí wọ́n di ìbùkún, màá mú kí ibi tó yí òkè mi ká náà di ìbùkún,+ màá sì mú kí òjò rọ̀ ní àkókò tó yẹ. Ìbùkún á rọ̀ bí òjò.+

  • Jóẹ́lì 2:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ẹ̀yin ọmọ Síónì, ẹ máa yọ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì mú inú yín dùn;+

      Torí ó máa rọ òjò fún yín ní ìwọ̀n tó yẹ nígbà ìwọ́wé,

      Yóò sì rọ òjò lé yín lórí,

      Nígbà ìwọ́wé àti nígbà ìrúwé, bíi ti tẹ́lẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́