ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 32:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.*+

  • Sáàmù 51:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 51 Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

      Nu àwọn àṣìṣe mi kúrò nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.+

  • Sáàmù 103:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà;

      Kí n má gbàgbé gbogbo ohun tó ti ṣe láé.+

       3 Ó ń dárí gbogbo àṣìṣe mi jì mí,+

      Ó sì ń wo gbogbo àìsàn mi sàn;+

  • Àìsáyà 1:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+

      “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,

      Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+

      Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,

      Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.

  • Àìsáyà 43:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Èmi, àní èmi ni Ẹni tó ń nu àwọn àṣìṣe* rẹ+ kúrò nítorí tèmi,+

      Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+

  • Àìsáyà 44:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+

      Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún.

      Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́