7 Wọ́n ni ín lára,+ ó sì jẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ òun,+
Àmọ́ kò la ẹnu rẹ̀.
Wọ́n mú un wá bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,+
Bí abo àgùntàn tó dákẹ́ níwájú àwọn tó ń rẹ́ irun rẹ̀,
Kò sì la ẹnu rẹ̀.+
8 Wọ́n mú un lọ torí àìṣẹ̀tọ́ àti ìdájọ́;
Ta ló sì máa da ara rẹ̀ láàmú nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀?
Torí wọ́n mú un kúrò lórí ilẹ̀ alààyè;+
Ó jẹ ìyà torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi.+
9 Wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú+
Àti àwọn ọlọ́rọ̀, nígbà tó kú,+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe ohunkóhun tí kò dáa,
Kò sì sí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu rẹ̀.+