ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Jèhófà máa gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè (1-4)

      • Édómù máa di ahoro (5-17)

Àìsáyà 34:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 357

Àìsáyà 34:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:15; Joẹ 3:12; Sef 3:8; Sek 14:3
  • +Ais 30:27; Na 1:2
  • +Ifi 19:11, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 357-358, 363

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 121-122

Àìsáyà 34:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ̀jẹ̀ wọn á máa ṣàn lórí àwọn òkè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:33
  • +Isk 39:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 357-358

Àìsáyà 34:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 110-111

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 358-361

Àìsáyà 34:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:41
  • +Sm 137:7; Jer 49:7, 22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 361-366

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 123-125

Àìsáyà 34:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 3:16
  • +Ais 63:1-3; Ọbd 8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 361-364

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/15/1996, ojú ìwé 9

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 123-125

Àìsáyà 34:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 364

Àìsáyà 34:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:41; Sm 94:1
  • +Ais 35:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 364-366

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 124-126

Àìsáyà 34:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣe kedere pé Bósírà, olú ìlú Édómù ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 210

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126

Àìsáyà 34:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 1:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 210

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366-367

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-127

Àìsáyà 34:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àti àwọn òkúta ahoro.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366-367

    Jí!,

    1/8/1997, ojú ìwé 22-23

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-128

Àìsáyà 34:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-128

Àìsáyà 34:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akátá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366-367

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-128

Àìsáyà 34:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366-367

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-128

Àìsáyà 34:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 366-367

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 126-128

Àìsáyà 34:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 367-368

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 127

Àìsáyà 34:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi okùn ìdíwọ̀n pín in fún wọn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 367-368

Àwọn míì

Àìsá. 34:2Jer 25:15; Joẹ 3:12; Sef 3:8; Sek 14:3
Àìsá. 34:2Ais 30:27; Na 1:2
Àìsá. 34:2Ifi 19:11, 15
Àìsá. 34:3Jer 25:33
Àìsá. 34:3Isk 39:4
Àìsá. 34:5Di 32:41
Àìsá. 34:5Sm 137:7; Jer 49:7, 22
Àìsá. 34:6Le 3:16
Àìsá. 34:6Ais 63:1-3; Ọbd 8, 9
Àìsá. 34:8Di 32:41; Sm 94:1
Àìsá. 34:8Ais 35:4
Àìsá. 34:10Mal 1:4
Àìsá. 34:13Mal 1:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 34:1-17

Àìsáyà

34 Ẹ sún mọ́ tòsí kí ẹ lè gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

Kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn.

Kí ayé àti ohun tó kún inú rẹ̀ fetí sílẹ̀,

Ilẹ̀ àti gbogbo èso rẹ̀.

 2 Torí Jèhófà ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,+

Inú rẹ̀ sì ń ru sí gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.+

Ó máa pa wọ́n run;

Ó máa pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ.+

 3 A máa ju àwọn èèyàn tí a pa síta,

Òórùn burúkú àwọn òkú wọn sì máa ròkè;+

Àwọn òkè máa yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn.*+

 4 Gbogbo ọmọ ogun ọ̀run máa jẹrà dà nù,

A sì máa ká ọ̀run jọ bí àkájọ ìwé.

Gbogbo ọmọ ogun wọn máa rọ dà nù,

Bí ewé tó ti rọ ṣe ń já bọ́ lára àjàrà

Àti bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ ṣe ń já bọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

 5 “Torí idà mi máa rin gbingbin ní ọ̀run.+

Ó máa sọ̀ kalẹ̀ sórí Édómù láti ṣèdájọ́,+

Sórí àwọn èèyàn tí màá pa run.

 6 Jèhófà ní idà kan; ẹ̀jẹ̀ máa bò ó.

Ọ̀rá+ máa bò ó,

Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àgbò àti ewúrẹ́ máa bò ó,

Ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò máa bò ó.

Torí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà,

Ó máa pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Édómù.+

 7 Àwọn akọ màlúù igbó máa bá wọn sọ̀ kalẹ̀,

Àwọn akọ ọmọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára.

Ẹ̀jẹ̀ máa rin ilẹ̀ wọn gbingbin,

Ọ̀rá sì máa rin iyẹ̀pẹ̀ wọn gbingbin.”

 8 Torí Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san,+

Ọdún ẹ̀san torí ẹjọ́ lórí Síónì.+

 9 Àwọn odò rẹ̀* máa yí pa dà di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀,

Iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ máa di imí ọjọ́,

Ilẹ̀ rẹ̀ sì máa dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tó ń jó.

10 A ò ní pa á, ní òru tàbí ní ọ̀sán;

Èéfín rẹ̀ á máa ròkè títí láé.

Ibi ìparun ló máa jẹ́ láti ìran dé ìran;

Kò sẹ́ni tó máa gba ibẹ̀ kọjá títí láé àti láéláé.+

11 Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ á máa gbé ibẹ̀,

Àwọn òwìwí elétí gígùn àti àwọn ẹyẹ ìwò á máa gbé inú rẹ̀.

Ó máa na okùn ìdíwọ̀n òfìfo sórí rẹ̀

Àti okùn ìwọ̀n, láti sọ ọ́ di ahoro.*

12 Wọn ò ní pe ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì wá jọba,

Gbogbo ìjòyè rẹ̀ ò sì ní já mọ́ nǹkan kan mọ́.

13 Ẹ̀gún máa hù nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,

Èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún máa hù nínú àwọn ibi ààbò rẹ̀.

Ó máa di ilé àwọn ajáko,*+

Ibi àkámọ́ àwọn ògòǹgò.

14 Àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ máa pàdé àwọn ẹranko tó ń hu,

Ewúrẹ́ igbó* sì máa ké sí èkejì rẹ̀.

Àní, ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ máa wọ̀ sí, tó sì ti máa rí ibi ìsinmi.

15 Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà máa kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tó sì máa yé ẹyin sí,

Ó máa pa ẹyin, ó sì máa kó wọn jọ sábẹ́ òjìji rẹ̀.

Àní, ibẹ̀ ni àwọn àwòdì máa kóra jọ sí, kálukú pẹ̀lú èkejì rẹ̀.

16 Ẹ wá a nínú ìwé Jèhófà, kí ẹ sì kà á sókè:

A ò ní wá ìkankan nínú wọn tì;

Èyíkéyìí nínú wọn ò ní ṣaláìní ẹnì kejì,

Torí pé ẹnu Jèhófà ni àṣẹ náà ti wá,

Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì kó wọn jọ.

17 Òun ni Ẹni tó ṣẹ́ kèké fún wọn,

Ọwọ́ rẹ̀ sì ti wọn ibi tí a yàn fún wọn.*

Ó máa jẹ́ tiwọn títí láé;

Ibẹ̀ ni wọ́n á máa gbé láti ìran dé ìran.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́